Èé Ṣe Tí Ìwà Ọ̀daràn Tí Ẹgbẹ́ Ń Ṣètò Fi Ń Gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀?
AL CAPONE, mẹ́ńbà àjọ ìpàǹpá olórúkọ burúkú ti Sáà Ìfòfindè ní United States (1920 sí 1933), sọ pé òun wulẹ̀ jẹ́ oníṣòwò kan tí ń mófin ṣẹ ni—òfin ìpèsè ọjà àti ìbéèrè ọjà. Amòfin kan tí ń ṣojú fún àjọ ìpàǹpá yakuza tí ó tóbi jù lọ ní Japan sọ pé: “Kò ṣeé sẹ́ pé àwọn ènìyàn ń béèrè fún àwọn ìgbòkègbodò [ìbálòpọ̀, oògùn olóró, àti tẹ́tẹ́].” Ìbéèrèfún yẹn ní ń mú kí ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò máa gbilẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò sí ẹni tí ń fẹ́ fojú winá ìwà ọ̀daràn, àwọn kan lè yíjú sí àwọn àjọ ọ̀daràn, kí wọ́n sì gba ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ wọn.
Mú pípurọ́gbowó pé àwọn jẹ́ àjọ aláàbò tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ọ̀daràn fi ń kówó jọ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè bí àpẹẹrẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, nígbà kọ̀ọ̀kan, wọ́n ń fojú sun àwọn oníléètajà olóòótọ́ ọkàn, wọ́n sábà máa ń sọ àwọn tí ń ṣòwò tí kò bófin mu di ẹran ìjẹ. Onílé iṣẹ́ tẹ́tẹ́ casino kan ní àdúgbò Shinjuku, Tokyo, tí ń ṣòwò tẹ́tẹ́ rẹ̀ lábẹ́ ìbòjú pé ilé ìwòran fídíò ni òun ṣí síbẹ̀, sọ pé: “Wọ́n gún akọ̀wé kan lọ́bẹ, wọ́n sì jí mílíọ̀nù 2 [yen (20,000 dọ́là)] lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n a kò jẹ́ pe ọlọ́pàá.” Kí ló dé tí wọn kò jẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀? “Ó jẹ́ nítorí pé òwò tí kò bófin mu la ń ṣe (tẹ́tẹ́ títa), a kò fẹ́ bá ọlọ́pàá dòwò pọ̀. Nígbà tí oníbàárà kan bá fẹ́ yàyàkuyà nílé ìtajà wa, a ń ké sí yakuza.” Onílé tẹ́tẹ́ casino yìí ń san 4,000 dọ́là lóṣù fún yakuza, iye owó kékeré kan, bí a bá fi wéra pẹ̀lú èrè 300,000 dọ́là tí ó ń jẹ nígbà náà lọ́hùn-ún lórí òwò àìbófinmu tí ó ń ṣe. Ibo ni owó yẹn ti ń wá? Ó ń wá láti inú àpò àwọn tí ń gbádùn tẹ́tẹ́ títa láìbófinmu.
Ohun kan náà ní ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn òwò bíbófinmu tí ń fẹ́ yẹra fún ìṣòro. Ilé iṣẹ́ aláṣẹ kan ní New York fojú díwọ̀n rẹ̀ pé agbaṣẹ́ṣe kan tí ń kunlé, tí ń pa mílíọ̀nù 15 dọ́là lọ́dún fi mílíọ̀nù 3.8 dọ́là pa mọ́ nípa fífún àwọn mẹ́ńbà àjọ ìpàǹpá ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀. Ìyẹn fún agbaṣẹ́ṣe náà láǹfààní láti lo àwọn òṣìṣẹ́ olówó pọ́ọ́kú, kí ó sì yẹra fún fíforígbárí pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tí àwùjọ akọluni ń darí. Ní Japan, ní sáà kan tí ọrọ̀ ajé ń búrẹ́kẹ, àwọn olùdókòwò náwó rẹpẹtẹ sórí dúkìá ilé àti ilẹ̀, wọ́n sì wó àwọn ògbólógbòó ilé àti ilé ìtajà kí wọ́n lè kọ́ àwọn ilé àríkájé-kúùkalẹ̀ sí ipò wọn. Nígbà tí àwọn olùgbé kan kò bá fẹ́ kó kúrò tàbí tí wọn kò bá fẹ́ ta ilẹ̀ wọn, àwọn olùdókòwò ń ké sí jiageya, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn jẹ́ ilé iṣẹ́ yakuza, láti lé wọn lọ.
Nígbà tí yakuza rí bí ó ṣe rọrùn tó láti yáwó, kí wọ́n sì kówó jọ ní àwọn ọdún 1980, wọ́n dá àwọn ilé iṣẹ́ sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ òwò dúkìá ilé àti ilẹ̀, wọ́n sì ń ra ìpín ìdókòwò ilé iṣẹ́ ńláńlá. Àwọn báńkì àti ilé iṣẹ́ ọ̀ràn okòwò dókòwò rẹpẹtẹ sórí àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá wọ̀nyí, tí ó ṣe kedere pé wọ́n ń fojú sun èrè tiwọn náà. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọrọ̀ ajé dorí kodò, ó ṣòro fún àwọn báńkì láti rí owó wọn gbà pa dà. Nígbà tí ọ̀gá ọlọ́pàá látijọ́ rí kan ń sọ̀rọ̀ nípa àìlọgeere ọrọ̀ ajé fúngbà pípẹ́ náà ní Japan, ó sọ nínú ìwé ìròyìn Newsweek pé: “Ìdí náà gan-an tí ọ̀ràn gbèsè ọlọ́jọ́ pípẹ́ náà kò fi lójútùú kíákíá ni pé, ọ̀pọ̀ lára wọn tan mọ́ ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò.”
Ní ti gidi, ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò ń fìdí múlẹ̀, ó sì ń gbilẹ̀ níbi tí àwọn ènìyàn bá ti ń hára gàgà láti tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́rùn láìka ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ sí. Ìwọra fún fàájì, ìbálòpọ̀, àti owó ń fàyè gba ṣíṣe fàyàwọ́ oògùn olóró, ṣíṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó, títa tẹ́tẹ́, àti yíyánilówó-èlé-gọbọi. Lílọ́wọ́ sí irú àwọn ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ sábà máa ń túmọ̀ sí sísanwó fún àwọn akọluni àti dídá ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò lọ́lá. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ òtítọ́ tó pé ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò ń bójú tó àwọn ohun tí àwọn ènìyàn tí ń fẹ́ tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn lọ́rùn ń béèrè fún!
Ìgbékalẹ̀ Ìdílé Aláfijọ
Ní àfikún sí ìbéèrè fún ṣíṣe iṣẹ́ láìbófinmu, ó tún ku àìní kan tí ń mú kí ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò máa gbilẹ̀ lónìí. Olóògbé olórí ọ̀kan lára àwọn àjọ ìpàǹpá yakuza títóbi jù lọ ní Japan rin kinkin pé òun ń kó àwọn ìgárá arúfin mọ́ra, òun sì ń bójú tó wọn, tí òun ń tipa bẹ́ẹ̀ dí wọn lọ́wọ́ọ bíburú sí i. Ó jẹ́wọ́ pé òun jẹ́ bàbá fún àwọn mẹ́ńbà àjọ ìpàǹpá náà. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àjọ ìpàǹpá oníwà ọ̀daràn, láìka orílẹ̀-èdè wọn sí, máa ń gbé àwọn àjọ wọn karí irú ipò ìbátan ìdílé aláfijọ bẹ́ẹ̀.
Bí àpẹẹrẹ, ṣàyẹ̀wò ọ̀ràn Chi Sun,a tí ó wá láti ìdílé tálákà kan ní Hong Kong. Bàbá rẹ̀ sábà máa ń nà án nínàkunà nítorí àwọn ọ̀ràn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Nígbà tí ó ṣì kéré, Chi Sun di ẹlẹ́mìí ọ̀tẹ̀, ó sì parí rẹ̀ sí wíwọ ẹgbẹ́ Ààrò Mẹ́ta lílókìkí náà nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún 12. Nínú àjọ ọ̀daràn náà, ó rí àyè tí ó rò pé ó “yẹ” òun. Nítorí ìwà akin rẹ̀ nígbà tí ìjà bá ṣẹlẹ̀ pẹ̀lú ìhámọ́ra, kò pẹ́ tí wọ́n fi gbé e ga sípò kan, tí ó mú kí ó ní àwọn ọmọ abẹ́ mélòó kan lẹ́yìn rẹ̀. Níkẹyìn, nígbà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 17 péré, ó wẹ̀wọ̀n.
Ọ̀pọ̀ àwọn ẹni bíi Chi Sun yíjú sí àwọn àjọ ọ̀daràn, kí wọ́n lè ní ìdè ìdílé tí wọn kò ní nílé. Àwọn mẹ́ńbà náà sọ pé àwọn ń bìkítà, ṣùgbọ́n àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀dé sábà máa ń ní ìjákulẹ̀ nígbà tí wọ́n bá rí i pé olúkúlùkù mẹ́ńbà wulẹ̀ ń du ti ara rẹ̀ ni.
Áńgẹ́lì Ìmọ́lẹ̀
Nígbà tí wọ́n ka àjọ ìpàǹpá ìwà ọ̀daràn títóbi jù lọ ní Japan sí àwùjọ oníwà ipá kan lábẹ́ òfin ìgbóguntàjọ-ìpàǹpá tuntun tí wọ́n ṣe ní 1992, ọ̀kan lára àwọn aṣáájú rẹ̀ tẹnu mọ́ ọn pé àwọn ọmọ àjọ náà ka ara wọn sí “akíkanjú,” tí ń gbógun ti ìwà ibi. Nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ kíkàmàmà kan wáyé ní Kobe, ní 1995, àjọ ìpàǹpá kan náà pín oúnjẹ, omi, àti àwọn ohun kòṣeémánìí mìíràn fún àwọn aládùúgbò wọn. Ìwé agbéròyìnjáde Asahi Evening News ròyìn pé: “Irú ìwà ọ̀làwọ́ bẹ́ẹ̀ yóò túbọ̀ mú kí àwọn ènìyàn máa rí yakuza gẹ́gẹ́ bí àjọ tí a fòfin dè, ṣùgbọ́n tí ó ní ọ̀wọ̀ ará ìlú ní Japan.”
Àwọn olórí àjọ ìpàǹpá ti sábà máa ń gbìyànjú láti hùwà bí ẹni tí ń ṣèlú láǹfààní. Gẹ́gẹ́ bí Ana Carrigan ṣe kọ ọ́ nínú ìwé ìròyìn Newsweek, Pablo Escobar, gbajúmọ̀ olókìkí burúkú olórí ẹgbẹ́ àwọn olówò oògùn olóró láìbófinmu ti ìlú Medellín ní Colombia, jẹ́ “ẹni ìtàn pàtàkì—Mèsáyà lápá kan, ẹni tí ń jí ẹrù lọ́wọ́ olówó fún tálákà lápá kan, igi lẹ́yìn ọgbà ní èrò ìtumọ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ dọ́gba pẹ̀lú ti patrón, ọ̀gá pátápátá,” lójú àwọn tí ń gbé àgbègbè onílé ahẹrẹpẹ ní ìlú rẹ̀. Ó kan àwọn àpótí tí ń yọ̀ lórí yìnyín fún àwọn ọmọdé, ó kọ́ ilé tó wu ojú rí fún àwọn tálákà, ó sì pèsè iṣẹ́ fún àwọn ọmọ asùnta. Lójú àwọn tí wọ́n jàǹfààní lára ìwà ọ̀làwọ́ rẹ̀, akọni ló jẹ́.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọ̀daràn tí ó jọ pé wọ́n ń fojú pa mọ́ lẹ́yìn àwọn àjọ ìpàǹpá wọn wulẹ̀ jẹ́ irinṣẹ́ olórí ọ̀daràn kárí ayé kan ni. Bíbélì fi ẹni tí ìyẹn jẹ́ hàn. “Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀. Nítorí náà, kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá ń pa ara wọn dà di òjíṣẹ́ òdodo. Ṣùgbọ́n òpin wọn dájúdájú yóò rí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.” (Kọ́ríńtì Kejì 11:14, 15) Lónìí, ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn kò gbà gbọ́ pé Sátánì jẹ́ ẹni gidi kan. Akéwì ọmọ ilẹ̀ Faransé kan ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún sọ pé: “Ọgbọ́n àrékérekè gíga jù lọ tí Èṣù ń lò ni láti sún ọ gbà pé òun kò sí.” Ó lúgọ sẹ́yìn, ó sì ń fọgbọ́n darí ohun tí ń ṣẹlẹ̀, kì í ṣe nínú àwọn àjọ ìpàǹpá oníwà ọ̀daràn nìkan, bí kò ṣe ní gbogbo àgbáyé. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” Jésù ṣàpèjúwe Sátánì bí “apànìyàn . . . nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀, . . . òpùrọ́ àti bàbá irọ́.”—Jòhánù Kíní 5:19; Jòhánù 8:44.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi hàn pé Sátánì Èṣù ti ń gbéṣẹ́ ṣe ní pàtàkì láti ọdún 1914. Láti ọdún yẹn wá, ó ti ń darí àwọn àgbájọ ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ nínú ogun àjàmọ̀gá kan lòdì sí àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Ó ń fa aráyé sínú ìrúkèrúdò oníyánpọnyánrin kan. Òun ni okùnfà tí ó gbawájú jù lọ tí ń mú kí ìwà ọ̀daràn àti àjọ ọ̀daràn máa gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ lónìí.—Ìṣípayá 12:9-12.
A óò ha mú olórí olùdarí àwọn àjọ ọ̀daràn orí ilẹ̀ ayé wá sópin láé bí? Aráyé yóò ha gbádùn àlàáfíà àti ìwàlétòlétò láé bí? Ìwọ ha lè jàjàbọ́ lọ́wọ́ ilẹ̀ ìṣàkóso búburú tí Sátánì ti gbé kalẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé lónìí bí?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nítorí ààbò àwọn tí ọ̀ràn náà kàn.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Bí O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ìdílé Rẹ
ÀÌNÍ ipò ìdílé ọlọ́yàyà, tó ní ìṣọ̀kan, lè fìrọ̀rùn sọ àwọn ọ̀dọ́ di ẹran ìjẹ àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn. Ní United States, a gbọ́ pé, ọ̀pọ̀ lára àwọn èwe tí ń lọ́wọ́ nínú ìṣìkàpànìyàn àwọn àjọ ìpàǹpá wá láti ìdílé tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní láárí tàbí ìdílé tí ó ti tú ká. Òṣìṣẹ́ ibùdó àhámọ́ kan ní Àríwá Carolina sọ pé: “Nítorí tí wọ́n jẹ́ òtòṣì, ó rọrùn láti mú wọn nítorí ìdè lílágbára tí ó wà láàárín ọ̀gá náà àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀, àti ìmọ̀lára ìṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà àjọ kan, tí wọ́n ń ní fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn.”
Bákan náà, ní ìhà Ìlà Oòrùn, ọ̀dọ́ yakuza kan tí ó múra tán láti jẹ́ ìbòjú fún ọ̀gá rẹ̀ sọ pé: “Nílé, mo máa ń dá wà nígbà gbogbo. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé kan ni wá nígbà náà, n kò rò pé a lè jùmọ̀ finú hanra wa. . . . Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mo lè finú han àwọn mẹ́ńbà àjọ wa.” Àwọn èwe tí ń nímọ̀lára ìdáwà máa ń ṣọpẹ́ láti rí àwọn mẹ́ńbà àjọ ọ̀daràn tí ń fà wọ́n sínú ìgbékalẹ̀ kan tí ó jọ ti ìdílé.
Aṣíwájú àwùjọ àwọn ọmọdébìnrin agunkẹ̀kẹ́ ológeere nínú àjọ ìpàǹpá kan ní Okinawa sọ pé: “Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yakuza máa ń bìkítà gidigidi. Bóyá ọgbọ́n ẹ̀tàn tí wọ́n ń lò nìyẹn; ṣùgbọ́n, níwọ̀n bí kò ti sí ẹni tí ń bá wa lò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ rí, èyí fà wá mọ́ra.” Alábòójútó ilé lílò kan fún àwọn ọmọdébìnrin olùyapòkíì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, àwọn mẹ́ńbà àjọ ìpàǹpá “mọwọ́ fífa ọkàn àyà àwọn ọmọdébìnrin mọ́ra ní ti gidi.” Nígbà tí àwọn ọmọdébìnrin anìkànwà bá ké sí wọn láàjìn, àwọn mẹ́ńbà àjọ ìpàǹpá máa ń yára dá wọn lóhùn, wọ́n sì ń tẹ́tí sí ohun tí wọ́n bá ní láti sọ, láìsí pé wọ́n ń fi ìbálòpọ̀ takọtabo lọ̀ wọ́n.
Ìhùwà ìbìkítà wọn máa ń wà títí di ìgbà tí wọ́n bá ti gba àwọn èwe tí wọ́n ń mú bí ẹran ìjẹ lọ́kàn tán. Nígbà tí ọwọ́ bá ti tẹ àwọn èwe náà tán, wọ́n máa ń lò wọ́n yọ́—àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin nínú ẹgbẹ́ aṣẹ́wó, àti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin nínú àjọ ọ̀daràn tí wọ́n ń darí náà.
Báwo Ni O Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Olólùfẹ́ Rẹ?
Bíbélì ṣíni létí pé: “Ẹ̀yin bàbá, ẹ má ṣe máa dá àwọn ọmọ yín lágara, kí wọ́n má baà sorí kodò.” (Kólósè 3:21) Èyí kò fún àwọn òbí níṣìírí láti máa gbọ̀jẹ̀gẹ́. Òwe Bíbélì kan sọ pé: “Ọmọ tí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ fún ara rẹ̀, á dójú ti ìyá rẹ̀.” (Òwe 29:15) Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì fún àwọn bàbá—àti ìyá pẹ̀lú—níṣìírí láti máa fòye bá àwọn ọmọ wọn lò, kí wọ́n máa tẹ́tí sí wọn, kí wọ́n sì ní ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tí ó ṣí sílẹ̀ pẹ̀lú wọn. Nígbà náà ni àwọn ọmọ yóò ní ìsúnniṣe láti máa finú han àwọn òbí nígbà tí wọ́n bá ní ìrora ọkàn.
Ní àfikún sí níní ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tí ó ṣí sílẹ̀, ó yẹ kí àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn ní ọ̀pá ìdíwọ̀n ìgbésí ayé. Níbo ni bàbá kan ti lè rí irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀? Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin, bàbá, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.” (Éfésù 6:4) Lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ láti ṣàyẹ̀wò Bíbélì nípasẹ̀ àwọn ìjókòó ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé. Sì gbin ìbẹ̀rù Jèhófà lọ́nà gbígbámúṣé sí wọn ní ọkàn àyà, kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà nígbà gbogbo, fún àǹfààní ara wọn.—Aísáyà 48:17.