Bí Ìwà Ọ̀daràn Tí Ẹgbẹ́ Ń ṣètò Ṣe Ń nípa Lórí Rẹ
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ JAPAN
Ọ̀gá (olórí) ìdílé Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn kan fi nǹkan gún ṣẹ̀ṣẹ̀bẹ̀rẹ̀ kan níka. Ẹ̀jẹ̀ ro sórí àwòrán “ẹni mímọ́” kan. Lẹ́yìn náà, iná jó àwòrán náà. Olórí náà sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin ọ̀hún pé: ‘Bí o bá fi lè tú ọ̀kankan lára àwọn àṣírí ẹgbẹ́, ọkàn rẹ̀ yóò jóná bí ẹni mímọ́ yìí ṣe jóná.’
ÌLÀNÀ mẹ́numọ́—ní èdè Italian, omertà—ti fi ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò pa mọ́ láṣìírí gidigidi fún ọ̀pọ̀ ọdún. Bí ó ti wù kí ó rí, lónìí, ìròyìn àwọn àjọ ìpàǹpá ọ̀daràn ti ń gbawájú nínú ìròyìn níbi gbogbo nítorí pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ọ̀daràn kan ti ń di afinisùn. Ẹni títayọ lọ́lá jù lọ tí àwọn pentiti, tàbí ọ̀dàlẹ̀ Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn wọ̀nyí fẹ̀sùn kàn ni Giulio Andreotti, tí ó jẹ́ olórí ìjọba ilẹ̀ Ítálì nígbà méje, tí ó sì ń jẹ́jọ́ nísinsìnyí nítorí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn.
Àwọn àjọ ọ̀daràn níbi gbogbo ti tàn ká onírúurú ẹ̀ka ìgbésí ayé: Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn ní Ítálì àti ní United States, níbi tí a tún ti ń pè é ní Cosa Nostra; àwọn ẹgbẹ́ àwọn olówò oògùn olóró láìbófinmu ní Gúúsù America; Ẹgbẹ́ Ààrò Mẹ́ta ti China; ẹgbẹ́ yakuza ní Japan. Iṣẹ́ láabi wọn ń nípa lórí gbogbo wa, ó sì ń mú kí ìgbọ́bùkátà túbọ̀ gbówó lérí sí i.
Ní United States, a gbọ́ pé àwọn Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn pín ìlú ńlá New York láàárín ìdílé márùn-ún, tí wọ́n ń pa ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù owó nípa lílu jìbìtì, pípurọ́gbowó pé àwọn jẹ́ àjọ aláàbò, yíyánilówó-èlé-gọbọi, tẹ́tẹ́ títa, ṣíṣe fàyàwọ́ oògùn olóró, àti ṣíṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó. A ti gbọ́ ẹ̀sùn pé àwọn ìdílé Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn ní agbára ìdarí rírinlẹ̀ lórí àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ òwò tí ó kan ìpalẹ̀-ìdọ̀tí-mọ́, ìkẹ́rùkiri, ìkọ́lé, ìkóúnjẹkiri, àti aṣọ. Pẹ̀lú agbára tí wọ́n ní lórí àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, wọ́n lè yanjú àwọn èdèkòyédè ibi iṣẹ́, tàbí kí wọ́n bẹ́gi dí ìdáwọ́lé kan. Bí àpẹẹrẹ, níbi iṣẹ́ ìkọ́lé kan, katakata awúlẹ̀ kan kò ní ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ kan, lọ́jọ́ mìíràn, ìjánu ẹ̀rọ awalẹ̀ kan kò ní ṣiṣẹ́, àwọn atukọ̀ onímọ̀ ẹ̀rọ sì máa ń fi ìdáwọ́lé “falẹ̀”—àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí àti àwọn mìíràn ń bá a lọ títí di ìgbà tí onílé náà bá gbà láti ṣe ohun tí àwùjọ akọluni náà ń béèrè, yálà ó jẹ́ àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí àdéhùn iṣẹ́. Ní tòótọ́, ìwé ìròyìn Time sọ pé, “sísan àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún Àwùjọ Akọluni náà lè mú un dá àwọn oníṣòwò lójú pé wọn yóò máa rí ẹrù wọn gbà déédéé, wọn yóò ní àjọṣepọ̀ alálàáfíà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́, wọn yóò sì rí àwọn òṣìṣẹ́ olówó pọ́ọ́kú lò.”
Ní Colombia, àwọn ẹgbẹ́ àwọn olówò oògùn olóró láìbófinmu méjì bá ara wọn díje títí tí wọ́n fi yìnbọn pa Pablo Escobar, olórí ẹgbẹ́ àwọn olówò ti ìlú ńlá Medellín, ní 1993. Lẹ́yìn náà, iṣẹ́ fàyàwọ́ kokéènì lágbàáyé di iṣẹ́ ẹgbẹ́ àwọn olówò ti ìlú ńlá Cali nìkan. Ní pípa bílíọ̀nù méje dọ́là ní 1994, ní United States nìkan, ó ṣeé ṣe kí ó ti di àjọ ìpàǹpá ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò, tí ó tóbi jù lọ lágbàáyé. Ṣùgbọ́n ìfàsẹ́yìn ńlá dé bá ẹgbẹ́ àwọn olówò náà nígbà tí ọwọ́ tẹ babaàsàlẹ̀ rẹ̀, José Santacruz Londoño, ní 1995. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnì kan sábà máa ń wà tí ń hára gàgà láti gbapò bí olórí tí ó kàn.
Nígbà tí Ìbòjú Onírin náà fà ya lójijì, Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn ilẹ̀ Rọ́ṣíà fara hàn kọjá ààlà ilẹ̀ orílẹ̀-èdè náà fún ìgbà àkọ́kọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, òṣìṣẹ́ báńkì kan tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú ìwé ìròyìn Newsweek sọ pé, “gbogbo iṣẹ́ òwò ní Rọ́ṣíà ní láti bá ẹgbẹ́ ọ̀daràn náà ṣe pọ̀.” Kódà, ní àgbègbè Brighton Beach, New York, a gbọ́ ìròyìn pé Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn ilẹ̀ Rọ́ṣíà ń jèrè rẹpẹtẹ láti inú àwọn ìṣètò jìbìtì tí ó ní í ṣe pẹ̀lú epo mọ́tò. Àwọn ọlọ́kọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ní ń forí fá a, tí ìjọba sì ń pàdánù owó orí. Àwọn àjọ ìpàǹpá ilẹ̀ Rọ́ṣíà náà tún ní àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ aṣẹ́wó ní Ìlà Oòrùn Europe. Wọ́n ń mú ọ̀pọ̀ jù lọ lára ìwà ọ̀daràn wọn jẹ. Ta ló máa fẹ́ kojú àwọn eléré ìdárayá àtijọ́ àti àwọn àbọ̀dé ológun tó ja ogun Afghan, tí gbogbo wọn dìhámọ́ra tẹnutẹnu?
Ọ̀ràn náà kò yàtọ̀ ní ìhà Ìlà Oòrùn. Ní Japan, àwọn olówò eré orí ìtàgé ní láti máa fojú sọ́nà fún onírúurú ìjọ̀ngbọ̀n, àyàfi bí wọ́n bá ń wárí fún ẹgbẹ́ yakuza àdúgbò, tí wọ́n sì ń fún wọn ní ìṣákọ́lẹ̀. Níhìn-ín pẹ̀lú, wọ́n ń béèrè owó ààbò lọ́wọ́ àwọn ilé ìtajà ọtí àti àwọn tí ń rìn lọ rìn bọ̀ ní títì pàápàá. Láfikún sí i, ẹgbẹ́ yakuza ti ri ara rẹ̀ bọ ètò ọrọ̀ ajé ilẹ̀ Japan jinlẹ̀jinlẹ̀ nípa ṣíṣàgbékalẹ̀ àwọn ilé iṣẹ́ tirẹ̀, lílu àwọn ilé ìṣòwò ńláńlá ní jìbìtì, àti bíbá àwọn àjọ ìpàǹpá oníwà ọ̀daràn lẹ́yìn odi ṣe pọ̀.
Àwọn àjọ ọ̀daràn tí wọ́n fìdí kalẹ̀ sí Hong Kong àti Taiwan pẹ̀lú ń gbòòrò kárí ayé. Yàtọ̀ sí orúkọ wọn, Ààrò Mẹ́ta, a kò mọ nǹkan púpọ̀ nípa ìṣètòjọ wọn. Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, nígbà tí àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé ọmọ ilẹ̀ China kó ara wọn jọ lòdì sí àwọn ará Manchuria tí ó gba ilẹ̀ China. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye wọn wọ ẹgbẹẹgbàárùn-ún, a gbọ́ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ààrò Mẹ́ta ní Hong Kong máa ń dá àjọ ìpàǹpá onígbà díẹ̀ sílẹ̀ fún ìwà ọ̀daràn pàtó kan tàbí fún ọ̀wọ́ àwọn ìwà ọ̀daràn, tí ó ń mú kí ó ṣòro fún àwọn ọlọ́pàá láti tọpa wọn. Wọ́n ń pa ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù dọ́là nípa ṣíṣe fàyàwọ́ oògùn olóró heroin, wọ́n sì ti sọ Hong Kong di ibùdó ìṣayédèrú káàdì ìrajà àwìn.
Nínú ìwé rẹ̀, The New Ethnic Mobs, William Kleinknecht kọ̀wé nípa ìwà ọ̀daràn ní United States pé: “Ní àgbègbè iṣẹ́ tuntun ti ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò, kò sí àjọ ìpàǹpá ti ẹ̀yà ìran kan tí ó ní ọjọ́ ọ̀la dídára ju àwọn ti ilẹ̀ China lọ. . . . Àwọn ẹgbẹ́ ọ̀daràn ilẹ̀ China ń yára lágbára ní àwọn ìlú ńlá kárí orílẹ̀-èdè náà. . . . Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn ti New York nìkan ló gbawájú wọn.”
Nípa oríṣi fàyàwọ́ ẹrù tí kò bófin mu mìíràn tí ń yọrí láti Hong Kong, òṣìṣẹ́ kan ní Ẹ̀ka Ìdájọ́ United States sọ pé: “Kíkó àwọn àjèjì wọ̀lú jẹ́ àfihàn ọ̀kan lára àwọn ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò.” Àwọn òṣìṣẹ́ kan fojú díwọ̀n rẹ̀ pé 100,000 ọmọ ilẹ̀ China ní ń wọ United States láìbófinmu lọ́dọọdún. Ó kéré tán, aṣíwọ̀lú kan máa ń san 15,000 dọ́là fún mímú tí wọ́n mú un wọ orílẹ̀-èdè kan tó ní láárí, ó sì ń san púpọ̀ lára owó náà nígbà tó bá gúnlẹ̀ sí ibi tó ń lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, ìgbésí ayé àwọn aṣíwọ̀lú kan ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n fọkàn fẹ́ ti di ti iṣẹ́ àfipáṣe ní àwọn ilé iṣẹ́ àṣelàágùn láìlówólórí àti nílé aṣẹ́wó.
O lè rò pé ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò kò kàn ọ́ nítorí pé o kì í lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò ìwà ọ̀daràn. Ṣùgbọ́n ìyẹn ha jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní ti gidi bí? Ọ̀pọ̀ àwọn ajoògùnyó, tí ń gbé ní àwọn kọ́ńtínẹ́ǹtì kan, ń hùwà ọ̀daràn láti rówó san fún àwọn oògùn líle tí àwọn ẹgbẹ́ olówò oògùn olóró láìbófinmu ń kó ránṣẹ́ sí wọn láti Gúúsù America. Ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò ń rí sí i pé, àwọn ilé iṣẹ́ tí ń bá òun ṣe pọ̀ ní ń gba iṣẹ́ ìpèsè àwọn ohun amúlùúdùn; nípa bẹ́ẹ̀, owó tí àwọn aráàlú ń san ń pọ̀ sí i. Ìgbìmọ̀ Amúṣẹ́ṣe Ààrẹ Lórí Ìwà Ọ̀daràn Tí Ẹgbẹ́ Ń Ṣètò sọ nígbà kan pé, ní United States, “ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò ń ṣe màdàrú iye tí a fi ń gbọ́ bùkátà nípa jíjalè, lílu jìbìtì, gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, fífi òòté lé orí iye owó ọjà, àti pípààlà sí iye ibùdó ìtajà,” àti pé a ń fipá mú àwọn arajàlò láti san “ohun tí a lè pè ní èléwó” fún Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn náà. Nítorí náà, kò sí ẹni tó bọ́ lọ́wọ́ ìyọrísí ìwà ọ̀daràn. Gbogbo wa la ń san gbèsè rẹ̀.
Ṣùgbọ́n èé ṣe tí ìwà ọ̀daràn tí ẹgbẹ́ ń ṣètò fi ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ lónìí?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn—Orírun Rẹ̀
“Mafia [tí a túmọ̀ sí Ẹgbẹ́ Ọ̀daràn] bẹ̀rẹ̀ ní Sísílì ní apá ìparí Sànmánnì Agbedeméjì, níbi tí ó ti ṣeé ṣe pé ó bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àjọ abẹ́lẹ̀ kan tí a gbé kalẹ̀ láti dojú ìṣàkóso àwọn onírúurú àjèjì tí ó ṣẹ́gun erékùṣù náà—àwọn bí àwọn alákòókiri ará Arabia, àwọn ará Normandy, àti àwọn ará Sípéènì. Mafia pìlẹ̀ láti inú àwọn ẹgbẹ́ ogun àdáni kéékèèké, tàbí mafie, tí àwọn onílẹ̀ tí kì í gbélé ń gbà láti máa dáàbò bo àwọn dúkìá orí ilẹ̀ wọn lọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà tí ń bẹ ninú ipò àìlófin tí ó gbilẹ̀ lápá ibi púpọ̀ ní Sísílì láàárín àwọn ọ̀rúndún náà, lára àwọn ẹgbẹ́ ogun náà sì ni àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ ti wá. Láàárín ọ̀rúndún kejìdínlógún àti ìkọkàndínlógún, àwọn alágbára oníjàgídíjàgan nínú àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àdáni wọ̀nyí kó ara wọn jọ, wọ́n sì di alágbára tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n yí pa dà sí àwọn onílẹ̀ náà, wọ́n sì di aláṣẹ lórí ọ̀pọ̀ lára àwọn dúkìá náà, tí wọ́n ń fi jìbìtì gba owó ààbò lọ́wọ́ àwọn onílẹ̀ bí àsanpadà lórí pé wọ́n ń bá wọn dáàbò bo àwọn ohun ọ̀gbìn wọn.” (The New Encyclopædia Britannica) Pípurọ́ gbowó ààbò di ọ̀nà ìṣeǹkan wọn. Wọ́n mú àwọn ọ̀nà ìṣeǹkan wọn wọ United States, níbi tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ sí tẹ́tẹ́ títa, pípurọ́gbowó iṣẹ́, yíyánilówó-èlé-gọbọi, ṣíṣe fàyàwọ́ oògùn olóró, àti ṣíṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó.