ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 11
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Diutarónómì

      • Ẹ ti rí bí Jèhófà ṣe tóbi tó (1-7)

      • Ilẹ̀ Ìlérí (8-12)

      • Wọ́n á rí ìbùkún tí wọ́n bá ṣègbọràn (13-17)

      • Kí wọ́n tẹ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́ ọkàn wọn (18-25)

      • “Ìbùkún àti ègún” (26-32)

Diutarónómì 11:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 6:5; 10:12; Mk 12:30

Diutarónómì 11:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 8:5; Heb 12:6
  • +Di 5:24; 9:26
  • +Ẹk 13:3

Diutarónómì 11:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:34

Diutarónómì 11:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “títí di òní olónìí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 14:23, 28; Heb 11:29

Diutarónómì 11:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sí.”

Diutarónómì 11:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 16:1, 32

Diutarónómì 11:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:40; Owe 3:1, 2
  • +Jẹ 13:14, 15; 26:3; 28:13
  • +Ẹk 3:8; Isk 20:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2007, ojú ìwé 29

Diutarónómì 11:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fi ẹsẹ̀ yín bu omi sí i,” ìyẹn ni pé kí wọ́n fi ẹsẹ̀ wa ẹ̀rọ, ó lè jẹ́ àgbá kẹ̀kẹ́ tó ń bu omi tàbí kí wọ́n fi ẹsẹ̀ la ibi tí omi á máa gbà.

Diutarónómì 11:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 1:7
  • +Di 8:7

Diutarónómì 11:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2007, ojú ìwé 29

Diutarónómì 11:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:29; 6:5; 10:12; Mt 22:37

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 7/2021,

Diutarónómì 11:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:4; Di 8:7-9; 28:12; Jer 14:22

Diutarónómì 11:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 8:10

Diutarónómì 11:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 8:19; 29:18; Heb 3:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    6/2019, ojú ìwé 3-4

Diutarónómì 11:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:15, 23; 1Ọb 8:35, 36; 2Kr 7:13, 14
  • +Di 8:19

Diutarónómì 11:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ọkàn.”

  • *

    Ní Héb., “láàárín ojú yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 7:1-3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 196-197

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/1998, ojú ìwé 20

    Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 70-71

Diutarónómì 11:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 6:6-9; Owe 22:6; Ef 6:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 70-71

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    5/1/1995, ojú ìwé 10

Diutarónómì 11:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:40; Owe 4:10
  • +Jẹ 13:14, 15

Diutarónómì 11:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 6:5; Lk 10:27
  • +Di 10:20; 13:4; Joṣ 22:5

Diutarónómì 11:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:28; Joṣ 3:10
  • +Di 7:1; 9:1, 5

Diutarónómì 11:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Òkun Ńlá, Òkun Mẹditaréníà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 14:9
  • +Jẹ 15:18; Ẹk 23:31

Diutarónómì 11:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:24; Joṣ 1:5
  • +Ẹk 23:27; Joṣ 2:9, 10; 5:1

Diutarónómì 11:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 30:15

Diutarónómì 11:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:1, 2; Sm 19:8, 11

Diutarónómì 11:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:15, 16; Ais 1:20

Diutarónómì 11:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kéde ìbùkún.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 27:12, 13; Joṣ 8:33, 34

Diutarónómì 11:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 12:6

Diutarónómì 11:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 1:11

Diutarónómì 11:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 5:32; 12:32

Àwọn míì

Diu. 11:1Di 6:5; 10:12; Mk 12:30
Diu. 11:2Di 8:5; Heb 12:6
Diu. 11:2Di 5:24; 9:26
Diu. 11:2Ẹk 13:3
Diu. 11:3Di 4:34
Diu. 11:4Ẹk 14:23, 28; Heb 11:29
Diu. 11:6Nọ 16:1, 32
Diu. 11:9Di 4:40; Owe 3:1, 2
Diu. 11:9Jẹ 13:14, 15; 26:3; 28:13
Diu. 11:9Ẹk 3:8; Isk 20:6
Diu. 11:11Di 1:7
Diu. 11:11Di 8:7
Diu. 11:13Di 4:29; 6:5; 10:12; Mt 22:37
Diu. 11:14Le 26:4; Di 8:7-9; 28:12; Jer 14:22
Diu. 11:15Di 8:10
Diu. 11:16Di 8:19; 29:18; Heb 3:12
Diu. 11:17Di 28:15, 23; 1Ọb 8:35, 36; 2Kr 7:13, 14
Diu. 11:17Di 8:19
Diu. 11:18Owe 7:1-3
Diu. 11:19Di 6:6-9; Owe 22:6; Ef 6:4
Diu. 11:21Di 4:40; Owe 4:10
Diu. 11:21Jẹ 13:14, 15
Diu. 11:22Di 6:5; Lk 10:27
Diu. 11:22Di 10:20; 13:4; Joṣ 22:5
Diu. 11:23Ẹk 23:28; Joṣ 3:10
Diu. 11:23Di 7:1; 9:1, 5
Diu. 11:24Joṣ 14:9
Diu. 11:24Jẹ 15:18; Ẹk 23:31
Diu. 11:25Di 7:24; Joṣ 1:5
Diu. 11:25Ẹk 23:27; Joṣ 2:9, 10; 5:1
Diu. 11:26Di 30:15
Diu. 11:27Di 28:1, 2; Sm 19:8, 11
Diu. 11:28Le 26:15, 16; Ais 1:20
Diu. 11:29Di 27:12, 13; Joṣ 8:33, 34
Diu. 11:30Jẹ 12:6
Diu. 11:31Joṣ 1:11
Diu. 11:32Di 5:32; 12:32
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Diutarónómì 11:1-32

Diutarónómì

11 “Rí i pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ,+ kí o máa ṣe ojúṣe rẹ sí i, kí o sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀, àwọn ìdájọ́ rẹ̀ àti àwọn òfin rẹ̀ mọ́ nígbà gbogbo. 2 Ẹ mọ̀ pé ẹ̀yin ni mò ń bá sọ̀rọ̀ lónìí, kì í ṣe àwọn ọmọ yín tí wọn ò tíì mọ ìbáwí Jèhófà Ọlọ́run yín,+ títóbi rẹ̀,+ ọwọ́ agbára rẹ̀+ àti apá tó nà jáde, tí wọn ò sì tíì rí nǹkan wọ̀nyí. 3 Wọn ò rí àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ àti àwọn ohun tó ṣe ní Íjíbítì sí Fáráò ọba Íjíbítì àti sí gbogbo ilẹ̀ rẹ̀;+ 4 bẹ́ẹ̀ ni wọn ò rí ohun tó ṣe sí àwọn ọmọ ogun Íjíbítì, sí àwọn ẹṣin Fáráò àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀, èyí tí omi Òkun Pupa bò mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n ń lé yín, tí Jèhófà sì pa wọ́n run lẹ́ẹ̀kan náà.*+ 5 Wọn ò rí ohun tó ṣe fún* yín nínú aginjù títí ẹ fi dé ibí yìí, 6 tàbí ohun tó ṣe sí Dátánì àti Ábírámù, àwọn ọmọ Élíábù ọmọ Rúbẹ́nì níṣojú gbogbo Ísírẹ́lì, nígbà tí ilẹ̀ lanu tó sì gbé wọn mì pẹ̀lú agbo ilé wọn àti àwọn àgọ́ wọn àti gbogbo ohun alààyè tó tẹ̀ lé wọn.+ 7 Ẹ ti fi ojú ara yín rí gbogbo nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà ṣe.

8 “Kí ẹ máa pa gbogbo àṣẹ tí mò ń pa fún yín lónìí mọ́, kí ẹ lè di alágbára, kí ẹ lè kọjá sí ilẹ̀ náà, kí ẹ sì gbà á, 9 kí ẹ sì lè pẹ́ lórí ilẹ̀+ tí Jèhófà búra pé òun máa fún àwọn baba ńlá yín àti àtọmọdọ́mọ* wọn,+ ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+

10 “Ilẹ̀ tí ẹ fẹ́ lọ gbà kò dà bí ilẹ̀ Íjíbítì tí ẹ ti jáde wá, níbi tí ẹ ti máa ń fún irúgbìn yín, tí ẹ sì máa ń fi ẹsẹ̀ yín bomi rin ín,* bí ọgbà tí ẹ gbin nǹkan sí. 11 Ilẹ̀ tó ní àwọn òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ ni ilẹ̀ tí ẹ fẹ́ sọdá lọ gbà.+ Òjò tó ń rọ̀ láti ọ̀run ló ń bomi rin ín;+ 12 Jèhófà Ọlọ́run yín ló ń bójú tó ilẹ̀ náà. Ojú Jèhófà Ọlọ́run yín kì í sì í kúrò ní ilẹ̀ náà, láti ìbẹ̀rẹ̀ ọdún títí di ìparí ọdún.

13 “Tí ẹ bá ń pa àwọn àṣẹ mi mọ́ délẹ̀délẹ̀, èyí tí mò ń pa fún yín lónìí, tí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín, tí ẹ fi gbogbo ọkàn yín àti gbogbo ara* yín sìn ín,+ 14 màá mú kí òjò rọ̀ sórí ilẹ̀ yín ní àkókò rẹ̀, òjò ìgbà ìkórè àti ti ìgbà ìrúwé, ẹ sì máa kó ọkà yín jọ àti wáìnì tuntun yín àti òróró yín.+ 15 Màá mú kí ewéko hù ní oko yín fún àwọn ẹran ọ̀sìn yín, ẹ máa jẹun, ẹ sì máa yó.+ 16 Kí ẹ rí i pé ẹ ò jẹ́ kí ọkàn yín fà sí àwọn ọlọ́run míì, kí ẹ wá yà bàrá lọ sìn wọ́n tàbí kí ẹ forí balẹ̀ fún wọn.+ 17 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bínú sí yín gidigidi, ó sì máa sé ọ̀run pa kí òjò má bàa rọ̀,+ ilẹ̀ ò ní mú èso jáde, ẹ sì máa tètè pa run lórí ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà fẹ́ fún yín.+

18 “Kí ẹ rí i pé ẹ tẹ àwọn ọ̀rọ̀ mi yìí mọ́ ọkàn yín, kó sì di ara* yín, kí ẹ so ó mọ́ ọwọ́ yín bí ohun ìrántí, kó sì dà bí aṣọ ìwérí níwájú orí yín.*+ 19 Kí ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín, kí ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí ẹ bá jókòó nínú ilé yín, tí ẹ bá ń rìn lójú ọ̀nà, tí ẹ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá dìde.+ 20 Kí ẹ kọ ọ́ sára àwọn òpó ilẹ̀kùn ilé yín àti sí àwọn ẹnubodè yín, 21 kí ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín lè pẹ́+ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà búra pé òun máa fún àwọn baba ńlá yín,+ níwọ̀n ìgbà tí ayé bá ṣì wà lábẹ́ ọ̀run.

22 “Tí ẹ bá pa àṣẹ yìí tí mò ń pa fún yín mọ́ délẹ̀délẹ̀, tí ẹ sì ń tẹ̀ lé e, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run yín,+ kí ẹ máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀, kí ẹ sì rọ̀ mọ́ ọn,+ 23 Jèhófà máa lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí kúrò níwájú yín,+ ẹ sì máa lé àwọn orílẹ̀-èdè tó tóbi, tí wọ́n sì pọ̀ jù yín lọ kúrò.+ 24 Gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ló máa di tiyín.+ Láti aginjù títí dé Lẹ́bánónì, láti Odò, ìyẹn odò Yúfírétì, dé òkun* tó wà ní ìwọ̀ oòrùn ló máa jẹ́ ààlà yín.+ 25 Ẹnì kankan ò ní dìde sí yín.+ Jèhófà Ọlọ́run yín máa kó jìnnìjìnnì bá àwọn èèyàn gbogbo ilẹ̀ tí ẹ máa tẹ̀, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù yín,+ bó ṣe ṣèlérí fún yín gẹ́lẹ́.

26 “Wò ó, mò ń fi ìbùkún àti ègún síwájú yín lónìí:+ 27 ẹ máa rí ìbùkún tí ẹ bá ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín tí mò ń pa fún yín lónìí,+ 28 àmọ́ ègún máa wà lórí yín bí ẹ kò bá ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín,+ tí ẹ sì yà kúrò lójú ọ̀nà tí mò ń pa láṣẹ fún yín pé kí ẹ máa rìn lónìí, tí ẹ wá lọ ń tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run tí ẹ ò mọ̀.

29 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ tó máa di tìrẹ, kí o súre* ní Òkè Gérísímù, kí o sì gégùn-ún ní Òkè Ébálì.+ 30 Ṣebí òdìkejì Jọ́dánì ni wọ́n wà lápá ìwọ̀ oòrùn, ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Kénáánì tí wọ́n ń gbé ní Árábà, ní òdìkejì Gílígálì, lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn igi ńlá Mórè?+ 31 Ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì láti wọ ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín, kí ẹ sì gbà á.+ Tí ẹ bá ti gbà á, tí ẹ sì wá ń gbé níbẹ̀, 32 kí ẹ rí i pé ẹ̀ ń tẹ̀ lé gbogbo ìlànà àti ìdájọ́ tí mò ń fi síwájú yín lónìí.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́