Jóṣúà
11 Gbàrà tí Jábínì ọba Hásórì gbọ́ nípa rẹ̀, ó ránṣẹ́ sí Jóbábù ọba Mádónì,+ sí ọba Ṣímúrónì, ọba Ákíṣáfù,+ 2 àwọn ọba agbègbè olókè tó wà ní apá àríwá, àwọn tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀* apá gúúsù Kínérétì, àwọn tó wà ní Ṣẹ́fẹ́là àti ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Dórì+ ní ìwọ̀ oòrùn, 3 àwọn ọmọ Kénáánì+ lápá ìlà oòrùn àti ìwọ̀ oòrùn, àwọn Ámórì,+ àwọn ọmọ Hétì, àwọn Pérísì, àwọn ará Jébúsì ní agbègbè olókè àti àwọn Hífì+ ní ìsàlẹ̀ Hámónì+ ní ilẹ̀ Mísípà. 4 Wọ́n kó gbogbo ọmọ ogun wọn jáde, wọ́n pọ̀ bí iyanrìn etí òkun, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun. 5 Gbogbo àwọn ọba yìí ṣe àdéhùn láti pàdé, wọ́n wá, wọ́n sì jọ pàgọ́ síbi omi Mérómù láti bá Ísírẹ́lì jà.
6 Torí náà, Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé: “Má ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà ọ́,+ torí ní ìwòyí ọ̀la, màá fi gbogbo wọn lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́ láti pa wọ́n. Kí o já iṣan ẹsẹ̀*+ àwọn ẹṣin wọn, kí o sì dáná sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn.” 7 Jóṣúà àti gbogbo ọkùnrin ogun wá gbéjà kò wọ́n lójijì lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi Mérómù. 8 Jèhófà fi wọ́n lé Ísírẹ́lì lọ́wọ́,+ wọ́n ṣẹ́gun wọn, wọ́n lé wọn títí dé Sídónì Ńlá+ àti Misirefoti-máímù+ àti Àfonífojì Mísípè lápá ìlà oòrùn, wọ́n sì pa wọ́n láìku ẹnì kankan.+ 9 Jóṣúà wá ṣe ohun tí Jèhófà sọ fún un sí wọn; ó já iṣan ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin wọn, ó sì dáná sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn.+
10 Lẹ́yìn náà, Jóṣúà pa dà, ó sì gba Hásórì, o fi idà pa ọba rẹ̀,+ torí pé Hásórì ni olórí gbogbo àwọn ìlú yìí tẹ́lẹ̀. 11 Wọ́n fi idà pa gbogbo àwọn* tó ń gbé ibẹ̀ run pátápátá.+ Wọn ò dá ohun eléèémí kankan sí.+ Lẹ́yìn náà, ó dáná sun Hásórì. 12 Jóṣúà gba gbogbo ìlú àwọn ọba yìí, ó sì fi idà ṣẹ́gun gbogbo ọba wọn.+ Ó pa wọ́n run,+ bí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe pa á láṣẹ. 13 Àmọ́ Ísírẹ́lì ò dáná sun ìkankan nínú àwọn ìlú tó wà lórí òkìtì, àfi Hásórì; òun nìkan ni Jóṣúà dáná sun. 14 Gbogbo ẹrù àwọn ìlú yìí àti ẹran ọ̀sìn wọn ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó fún ara wọn.+ Àmọ́ wọ́n fi idà pa gbogbo èèyàn títí wọ́n fi pa gbogbo wọn run.+ Wọn ò dá ẹnikẹ́ni tó ń mí sí.+ 15 Bí Jèhófà ṣe pàṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Mósè ṣe pa á láṣẹ fún Jóṣúà,+ Jóṣúà sì ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè ni Jóṣúà ṣe láìṣẹ́ ìkankan kù.+
16 Jóṣúà ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ yìí, agbègbè olókè, gbogbo Négébù,+ gbogbo ilẹ̀ Góṣénì, Ṣẹ́fẹ́là,+ Árábà+ àti agbègbè olókè Ísírẹ́lì àti Ṣẹ́fẹ́là rẹ̀,* 17 láti Òkè Hálákì, tó lọ dé Séírì àti títí lọ dé Baali-gádì,+ ní Àfonífojì Lẹ́bánónì, ní ìsàlẹ̀ Òkè Hámónì,+ ó mú gbogbo ọba wọn, ó ṣẹ́gun wọn, ó sì pa wọ́n. 18 Ó ṣe díẹ̀ tí Jóṣúà fi bá gbogbo àwọn ọba yìí jagun. 19 Kò sí ìlú kankan tó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rẹ́ àfi àwọn Hífì tó ń gbé ní Gíbíónì.+ Gbogbo àwọn yòókù ni wọ́n bá jà tí wọ́n sì ṣẹ́gun wọn.+ 20 Jèhófà fàyè gbà á kí ọkàn wọn le,+ tí wọ́n fi bá Ísírẹ́lì jagun, kó lè pa wọ́n run láì ṣojú àánú sí wọn rárá.+ Ìparun tọ́ sí wọn, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.+
21 Ìgbà yẹn ni Jóṣúà pa àwọn Ánákímù+ run kúrò ní agbègbè olókè, ní Hébúrónì, Débírì, Ánábù àti gbogbo agbègbè olókè Júdà àti gbogbo agbègbè olókè Ísírẹ́lì. Jóṣúà pa àwọn àtàwọn ìlú wọn run.+ 22 Ánákímù kankan ò ṣẹ́ kù ní ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;+ Gásà,+ Gátì+ àti Áṣídódì+ nìkan ni wọ́n ṣẹ́ kù sí. 23 Jóṣúà wá gba gbogbo ilẹ̀ náà, bí Jèhófà ṣe ṣèlérí fún Mósè,+ Jóṣúà sì fi ṣe ogún fún Ísírẹ́lì, bí ìpín wọn, pé kí wọ́n pín in láàárín àwọn ẹ̀yà wọn.+ Ogun sì dáwọ́ dúró ní ilẹ̀ náà.+