ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Sámúẹ́lì 16
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Sámúẹ́lì

      • Síbà sọ̀rọ̀ Méfíbóṣétì láìdáa (1-4)

      • Ṣíméì gbé Dáfídì ṣépè (5-14)

      • Ábúsálómù gba Húṣáì sọ́dọ̀ (15-19)

      • Ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì (20-23)

2 Sámúẹ́lì 16:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí wọ́n dì ní gàárì.”

  • *

    Ní pàtàkì, èso ọ̀pọ̀tọ́ àti bóyá èso déètì.

  • *

    Ó dà bíi jọ́ọ̀gì omi.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 15:30
  • +2Sa 9:2, 9
  • +2Sa 9:6
  • +1Sa 25:18

2 Sámúẹ́lì 16:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 17:27-29

2 Sámúẹ́lì 16:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọmọ ọmọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 9:3
  • +2Sa 19:25-27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2002, ojú ìwé 14-15

2 Sámúẹ́lì 16:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 9:9, 10
  • +Owe 26:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    8/2018, ojú ìwé 6

2 Sámúẹ́lì 16:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 19:16; 1Ọb 2:8, 44
  • +Ẹk 22:28; Onw 10:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    9/2018, ojú ìwé 6-7

2 Sámúẹ́lì 16:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 24:6, 7; 26:9, 11; Sm 3:1, 2; 7:1; 71:10, 11

2 Sámúẹ́lì 16:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 2:15, 16
  • +1Sa 24:14
  • +Ẹk 22:28
  • +1Sa 26:8

2 Sámúẹ́lì 16:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 19:22; 1Ọb 2:5
  • +Sm 37:8; 1Pe 2:23
  • +2Sa 12:10

2 Sámúẹ́lì 16:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 12:11; 15:14; 17:12
  • +2Sa 19:16

2 Sámúẹ́lì 16:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 29:32; Ẹk 3:7; Sm 25:18
  • +Sm 109:28

2 Sámúẹ́lì 16:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 16:5

2 Sámúẹ́lì 16:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 15:12, 31

2 Sámúẹ́lì 16:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀rẹ́ àfinúhàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 15:32, 37; 1Kr 27:33
  • +Joṣ 16:1, 2
  • +1Ọb 1:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2017, ojú ìwé 29

2 Sámúẹ́lì 16:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 15:34

2 Sámúẹ́lì 16:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àmọ̀ràn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 37:12

2 Sámúẹ́lì 16:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìyàwó onípò kejì.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Wáhàrì.”

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:8; 20:11; 1Ọb 2:22
  • +2Sa 15:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2005, ojú ìwé 13

2 Sámúẹ́lì 16:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 11:2
  • +Di 22:30; 2Sa 20:3
  • +2Sa 12:11, 12

2 Sámúẹ́lì 16:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “bí ìgbà tí èèyàn bá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 15:12; 17:14, 23

Àwọn míì

2 Sám. 16:12Sa 15:30
2 Sám. 16:12Sa 9:2, 9
2 Sám. 16:12Sa 9:6
2 Sám. 16:11Sa 25:18
2 Sám. 16:22Sa 17:27-29
2 Sám. 16:32Sa 9:3
2 Sám. 16:32Sa 19:25-27
2 Sám. 16:42Sa 9:9, 10
2 Sám. 16:4Owe 26:22
2 Sám. 16:52Sa 19:16; 1Ọb 2:8, 44
2 Sám. 16:5Ẹk 22:28; Onw 10:20
2 Sám. 16:81Sa 24:6, 7; 26:9, 11; Sm 3:1, 2; 7:1; 71:10, 11
2 Sám. 16:91Kr 2:15, 16
2 Sám. 16:91Sa 24:14
2 Sám. 16:9Ẹk 22:28
2 Sám. 16:91Sa 26:8
2 Sám. 16:102Sa 19:22; 1Ọb 2:5
2 Sám. 16:10Sm 37:8; 1Pe 2:23
2 Sám. 16:102Sa 12:10
2 Sám. 16:112Sa 12:11; 15:14; 17:12
2 Sám. 16:112Sa 19:16
2 Sám. 16:12Jẹ 29:32; Ẹk 3:7; Sm 25:18
2 Sám. 16:12Sm 109:28
2 Sám. 16:132Sa 16:5
2 Sám. 16:152Sa 15:12, 31
2 Sám. 16:162Sa 15:32, 37; 1Kr 27:33
2 Sám. 16:16Joṣ 16:1, 2
2 Sám. 16:161Ọb 1:25
2 Sám. 16:192Sa 15:34
2 Sám. 16:20Sm 37:12
2 Sám. 16:21Le 18:8; 20:11; 1Ọb 2:22
2 Sám. 16:212Sa 15:16
2 Sám. 16:222Sa 11:2
2 Sám. 16:22Di 22:30; 2Sa 20:3
2 Sám. 16:222Sa 12:11, 12
2 Sám. 16:232Sa 15:12; 17:14, 23
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Sámúẹ́lì 16:1-23

Sámúẹ́lì Kejì

16 Nígbà tí Dáfídì kọjá orí òkè+ náà díẹ̀, Síbà+ ìránṣẹ́ Méfíbóṣétì+ wá pàdé rẹ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ méjì tí wọ́n de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́,* igba (200) búrẹ́dì, ọgọ́rùn-ún (100) ìṣù àjàrà gbígbẹ, ọgọ́rùn-ún (100) ìṣù èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn* àti ìṣà* wáìnì ńlá+ kan sì wà lórí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà. 2 Ọba wá béèrè lọ́wọ́ Síbà pé: “Kí nìdí tí o fi kó àwọn nǹkan yìí wá?” Síbà dáhùn pé: “Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wà fún agbo ilé ọba láti gùn, búrẹ́dì àti èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn wà fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin láti jẹ, wáìnì sì wà fún àwọn tí ó bá rẹ̀ ní aginjù láti mu.”+ 3 Ọba wá béèrè pé: “Ọmọ* ọ̀gá rẹ ńkọ́?”+ Síbà dá ọba lóhùn pé: “Ó wà ní Jerúsálẹ́mù, nítorí ó sọ pé, ‘Lónìí, ilé Ísírẹ́lì máa dá ìjọba bàbá mi pa dà fún mi.’”+ 4 Ọba wá sọ fún Síbà pé: “Wò ó! Kí gbogbo ohun tó jẹ́ ti Méfíbóṣétì di tìrẹ.”+ Síbà sọ pé: “Mo tẹrí ba níwájú rẹ. Jẹ́ kí n rí ojú rere rẹ, olúwa mi ọba.”+

5 Nígbà tí Ọba Dáfídì dé Báhúrímù, ọkùnrin ará ilé Sọ́ọ̀lù kan tó ń jẹ́ Ṣíméì+ ọmọ Gérà jáde wá, ó sì ń ṣépè bí ó ṣe ń bọ̀.+ 6 Ó ń sọ òkúta lu Dáfídì àti gbogbo ìránṣẹ́ Ọba Dáfídì àti gbogbo àwọn èèyàn náà títí kan àwọn alágbára ọkùnrin tó wà lápá ọ̀tún àti lápá òsì rẹ̀. 7 Bí Ṣíméì ṣe ń ṣépè ló ń sọ pé: “Kúrò níbí, kúrò níbí, ìwọ apààyàn aláìníláárí yìí! 8 Jèhófà ti mú gbogbo ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ilé Sọ́ọ̀lù wá sórí rẹ, ẹni tí o jọba ní ipò rẹ̀, Jèhófà sì ti fi ìjọba náà lé ọwọ́ Ábúsálómù ọmọ rẹ. Ní báyìí, àjálù ti bá ọ torí pé apààyàn ni ọ́!”+

9 Ábíṣáì ọmọ Seruáyà+ bá sọ fún ọba pé: “Kí nìdí tí òkú ajá+ yìí á fi máa ṣépè fún olúwa mi ọba?+ Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ, kí n sì bẹ́ orí rẹ̀ dà nù.”+ 10 Ṣùgbọ́n ọba sọ pé: “Kí ló kàn yín nínú ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin ọmọ Seruáyà?+ Ẹ jẹ́ kó máa ṣépè fún mi,+ torí pé Jèhófà ti sọ fún un pé,+ ‘Ṣépè fún Dáfídì!’ Ta ló máa wá sọ pé, ‘Kí nìdí tí o fi ń ṣe báyìí?’” 11 Dáfídì bá sọ fún Ábíṣáì àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ wò ó, ọmọ tèmi, tó ti ara mi wá ń wọ́nà láti gba ẹ̀mí* mi,+ ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti ẹni tó wá láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì!+ Ẹ fi sílẹ̀, kó máa ṣépè fún mi, torí Jèhófà ti sọ fún un pé kó ṣe bẹ́ẹ̀! 12 Bóyá Jèhófà máa rí ìpọ́njú mi,+ tí Jèhófà yóò sì fi ire san án pa dà fún mi dípò èpè tí ó ń ṣẹ́ lé mi lórí lónìí yìí.”+ 13 Torí náà, Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ ń lọ lójú ọ̀nà bí Ṣíméì ṣe ń rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkè náà, tí ó sì ń lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Dáfídì, ó ń ṣépè,+ ó ń ju òkúta, ó sì ń da iyẹ̀pẹ̀ lù wọ́n.

14 Níkẹyìn, ọba àti gbogbo àwọn èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀ dé ibi tí wọ́n ń lọ, ó ti rẹ̀ wọ́n, torí náà wọ́n sinmi.

15 Ní àkókò yìí, Ábúsálómù àti gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì dé sí Jerúsálẹ́mù, Áhítófẹ́lì+ sì wà pẹ̀lú rẹ̀. 16 Nígbà tí Húṣáì+ ará Áríkì,+ ọ̀rẹ́* Dáfídì, wọlé wá sọ́dọ̀ Ábúsálómù, Húṣáì sọ fún Ábúsálómù pé: “Kí ẹ̀mí ọba ó gùn o!+ Kí ẹ̀mí ọba ó gùn o!” 17 Ábúsálómù bá sọ fún Húṣáì pé: “Ṣé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí o ní sí ọ̀rẹ́ rẹ nìyí? Kí ló dé tí o ò fi bá ọ̀rẹ́ rẹ lọ?” 18 Nítorí náà, Húṣáì sọ fún Ábúsálómù pé: “Rárá, ọ̀dọ̀ ẹni tí Jèhófà àti àwọn èèyàn yìí pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì yàn ni mo wà. Mi ò sì ní kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 19 Mo tún sọ pé, Ta ni mi ò bá tún sìn tí kì í bá ṣe ọmọ rẹ̀? Bí mo ṣe sin bàbá rẹ ni màá ṣe sìn ọ́.”+

20 Ni Ábúsálómù bá sọ fún Áhítófẹ́lì pé: “Ẹ gbà mí ní ìmọ̀ràn.*+ Kí ni ká ṣe?” 21 Áhítófẹ́lì wá sọ fún Ábúsálómù pé: “Bá àwọn wáhàrì* bàbá rẹ lò pọ̀,+ àwọn tó fi sílẹ̀ pé kí wọ́n máa tọ́jú ilé.*+ Gbogbo Ísírẹ́lì á wá gbọ́ pé o ti sọ ara rẹ di ẹni ìkórìíra lójú bàbá rẹ, ọkàn gbogbo àwọn tó ń tì ọ́ lẹ́yìn á sì balẹ̀.” 22 Nítorí náà, wọ́n pa àgọ́ kan fún Ábúsálómù sórí òrùlé,+ Ábúsálómù sì bá àwọn wáhàrì bàbá rẹ̀ lò pọ̀+ níṣojú gbogbo Ísírẹ́lì.+

23 Láyé ìgbà yẹn, ńṣe ni wọ́n máa ń wo ìmọ̀ràn tí Áhítófẹ́lì+ bá fúnni bí ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run tòótọ́ sọ.* Irú ojú yẹn náà sì ni Dáfídì àti Ábúsálómù fi máa ń wo gbogbo ìmọ̀ràn Áhítófẹ́lì.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́