ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 9/15 ojú ìwé 24-27
  • Ètò Gbígba Owó Orí Ìyàwó Tó Mọ Níwọ̀n

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ètò Gbígba Owó Orí Ìyàwó Tó Mọ Níwọ̀n
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìlànà Bíbélì Tí Ó Bọ́gbọ́n Mu
  • Ta Ló Yẹ Kó Gbà Á?
  • Yíyẹra fún Àwọn Àṣà Tí Kò Yẹ Kristẹni
  • Àpẹẹrẹ Àwọn Tí Wọ́n Fòye Báni Lò
  • Àwọn Àǹfààní Ìfòyebánilò
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • “Ìgbéyàwó Ìbílẹ̀” ní Gánà
    Jí!—1996
  • Mímúra Sílẹ̀ fún Ìgbéyàwó Aláṣeyọrí
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ipa-iṣẹ́ Oníyì Ti Àwọn Obìnrin Láàárín Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọrun Ní Ìjímìjí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 9/15 ojú ìwé 24-27

Ètò Gbígba Owó Orí Ìyàwó Tó Mọ Níwọ̀n

LÓNÌÍ, ní àwọn àdúgbò kan, wọ́n máa ń béèrè pé kí ọkùnrin kan san owó orí ìyàwó kí ó tó fẹ́ obìnrin, bí ó ti rí ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì. Jékọ́bù wí fún Lábánì tí yóò wá di àna rẹ̀ pé: “Mo ṣe tán láti sìn ọ́ fún ọdún méje nítorí Rákélì ọmọbìnrin rẹ, èyí àbúrò.” (Jẹ́nẹ́sísì 29:18.) Nítorí ìfẹ́ tí Jékọ́bù ní sí Rákélì, ó san iye tí ó pọ̀—iye tí ó bá owó ọ̀yà ọdún méje dọ́gba! Lábánì gba ohun tí ó fún un, àmọ́, ó tan Jékọ́bù láti kọ́kọ́ fẹ́ Léà ọmọbìnrin rẹ̀, èyí ẹ̀gbọ́n. Ọ̀nà tí Lábánì gbà bá Jékọ́bù lò lẹ́yìn náà kún fún ìwà àrékérekè. (Jẹ́nẹ́sísì 31:41) Ìfẹ́ àníjù tí Lábánì ní fún ohun àlùmọ́nì ló mú kí àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ má bọ̀wọ̀ fún un mọ́. Wọ́n béèrè pé: “Ní ti gidi, a kò ha kà wá sí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè lójú rẹ̀ níwọ̀n bí ó ti tà wá, tí ó fi jẹ́ pé ó ń bá a nìṣó láti máa jẹ àní láti inú owó tí ó gbà lórí wa?”—Jẹ́nẹ́sísì 31:15.

Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ òbí ló dà bí Lábánì nínú ayé onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì tí a ń gbé yìí. Ti àwọn kan tilẹ̀ burú ju tirẹ̀ lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn kan ní Áfíríkà ti sọ, a máa ń ṣètò àwọn ìgbéyàwó kan “kìkì nítorí èrè tí àwọn oníwọ̀ra bàbá fẹ́ jẹ.” Kókó abájọ mìíràn ni wàhálà ètò ọrọ̀ ajé tí ń dán àwọn òbí kan wò láti wo àwọn ọmọbìnrin wọn bí ọ̀nà láti bọ́ nínú ìṣòro owó.a

Àwọn òbí kan kì í jẹ́ kí àwọn ọmọ wọn tètè lọ sílé ọkọ nítorí pé wọ́n ń dúró de ẹni tí yóò san owó tó pọ̀ jù. Èyí lè fa ìṣòro tí ó léwu gan-an. Oníròyìn kan tí ń gbé ìlà oòrùn Áfíríkà kọ̀wé pé: “Àwọn ọ̀dọ́ ń yàn láti sá lọ bá ọkọ láti lè sá fún nǹkan ìdána tí ó pọ̀ jù tí àwọn ọ̀kánjúà bàbá ìyàwó ń béèrè.” Ọ̀kan lára àwọn ìṣòro tí bíbèèrè owó orí ìyàwó tí ó pọ̀ ń dá sílẹ̀ ni ìṣekúṣe. Síwájú sí i, àwọn ọ̀dọ́kùnrin kan gbìyànjú láti ra ìyàwó, àmọ́, gbèsè ni wọn máa ń san lẹ́yìn náà. Òṣìṣẹ́ afẹ́dàáfẹ́re kan ní Gúúsù Áfíríkà dámọ̀ràn pé: “Ó yẹ kí àwọn òbí máa fòye hùwà. Kò yẹ kí wọ́n máa béèrè owó tí ó pọ̀ jù. Tọkọtaya tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ra náà ní láti máa gbọ́ bùkátà ara wọn . . . Nítorí náà, kí ló dé tí ẹ ó fi sún ọmọkùnrin náà wọko gbèsè?”

Báwo ni àwọn Kristẹni òbí ṣe lè fi àpẹẹrẹ ìfòyebánilò lélẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣètò fún sísan owó orí ìyàwó tàbí gbígbà á? Ọ̀ràn tí ń béèrè àròjinlẹ̀ lèyí, nítorí Bíbélì pàṣẹ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.”—Fílípì 4:5.

Àwọn Ìlànà Bíbélì Tí Ó Bọ́gbọ́n Mu

Yálà àwọn Kristẹni òbí pinnu láti gba owó orí ìyàwó tàbí wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìpinnu tiwọn. Bí wọ́n bá fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe irú ètò bẹ́ẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó.” (Hébérù 13:5) Bí a kò bá fi ìlànà yìí sílò nínú ètò ìgbéyàwó, ó lè fi hàn pé Kristẹni òbí kan kì í ṣe àpẹẹrẹ rere. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n wà ní ipò ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ Kristẹni gbọ́dọ̀ jẹ́ “afòyebánilò,” kì í ṣe “olùfẹ́ owó” tàbí “oníwọra fún èrè àbòsí.” (1 Tímótì 3:3, 8) A tilẹ̀ lè yọ Kristẹni kan tí ó fi ìwọra gba owó orí ìyàwó tí ó pọ̀ lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ, tí kò bá ronú pìwà dà.—1 Kọ́ríńtì 5:11, 13; 6:9, 10.

Nítorí àwọn ìṣòro tí ìwọra ń fà, àwọn ìjọba kan ti gbé àwọn òfin tí ń pààlà sí owó orí ìyàwó kalẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, òfin kan ní orílẹ̀-èdè Tógò, ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà sọ pé owó orí ìyàwó “ni a lè fi ẹrù tàbí owó san tàbí méjèèjì.” Òfin náà fi kún un pé: “Owó náà kò gbọdọ̀ ju 10,000 F CFA (20 dọ́là ti U.S.) lọ.” Léraléra ni Bíbélì pàṣẹ fún àwọn Kristẹni láti máa ṣègbọràn sí òfin. (Títù 3:1) Bí ìjọba kò bá tilẹ̀ rí sí i pé irú òfin bẹ́ẹ̀ múlẹ̀, Kristẹni tòótọ́ kan yóò fẹ́ láti ṣègbọràn sí i. Yóò tipa bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rí ọkàn rere níwájú Ọlọ́run, kò sì ní jẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn.—Róòmù 13:1, 5; 1 Kọ́ríńtì 10:32, 33.

Ta Ló Yẹ Kó Gbà Á?

Ní àwọn àdúgbò kan, ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gba owó orí ìyàwó lè fara gbún ìlànà pàtàkì mìíràn. Bí Bíbélì ti sọ, bàbá ni ó yẹ kí ó ṣètò àlámọ̀rí ìdílé rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 11:3; Kólósè 3:18, 20) Nítorí náà, àwọn tí wọ́n ní ipò ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí “ń ṣe àbójútó àwọn ọmọ àti agbo ilé tiwọn lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.”—1 Tímótì 3:12.

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó lè wọ́pọ̀ kí àwọn olórí ìdílé kan ládùúgbò máa fa àwọn ètò pàtàkì nípa ìgbéyàwó lé àwọn ẹbí wọn lọ́wọ́. Àwọn ẹbí wọ̀nyí sì máa ń béèrè pé kí a pín fún àwọn nínú owó orí ìyàwó náà. Èyí gbé ìdánwò kan ka iwájú àwọn ìdílé Kristẹni. Àwọn olórí ilé kan ti gba àwọn ẹbí tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ láyè láti gba owó orí tí ó pọ̀ látàrí àṣà àdúgbò. Ní àwọn ìgbà kan, èyí ti yọrí sí kí ọmọbìnrin kan tí ó jẹ́ Kristẹni lọ fẹ́ aláìgbàgbọ́. Ìyẹn lòdì sí ìṣílétí náà pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ṣègbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:39) A kò lè wo olórí ilé kan tí ó gba àwọn ẹbí rẹ̀ aláìgbàgbọ́ láyè láti ṣe ìpinnu tí ó wu ipò tẹ̀mí àwọn ọmọ rẹ̀ léwu bí ẹni tí “ń ṣe àbójútó agbo ilé tirẹ̀ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.”—1 Tímótì 3:4.

Bí bàbá kan tí ó jẹ́ Kristẹni kò bá lọ́wọ́ nínú ètò ìgbéyàwó ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀ ní tààràtà, bí ó ti rí nínú ọ̀ràn baba ńlá náà, Ábúráhámù, tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run ńkọ́? (Jẹ́nẹ́sísì 24:2-4) Bí bàbá kan tí ó jẹ́ Kristẹni bá yan ẹnì kan láti ṣe èyí, ó gbọ́dọ̀ rí i dájú pé ẹni tí ń bójú tó ètò náà tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni ti ìlànà Bíbélì tí ó bọ́gbọ́n mu. Síwájú sí i, kí a tó gbé ìgbésẹ̀ kankan láti gba owó orí ìyàwó kan, àwọn Kristẹni òbí gbọ́dọ̀ fara balẹ̀ ronú lórí ọ̀ràn náà, kí wọ́n má sì jẹ́ kí pọ̀pọ̀ṣìnṣìn àwọn àṣà tí kò bọ́gbọ́n mu mú àwọn gbàgbé ohun tí ó tọ́.—Òwe 22:3.

Yíyẹra fún Àwọn Àṣà Tí Kò Yẹ Kristẹni

Bíbélì dẹ́bi fún ìgbéraga àti fífi “àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími.” (1 Jòhánù 2:16; Òwe 21:4) Síbẹ̀, àwọn kan tí wọ́n ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ Kristẹni ti hu irú àwọn ìwà yìí nígbà tí wọ́n ń ṣètò ìgbéyàwó wọn. Àwọn kan ti káṣà ayé nípa fífi bí owó orí ìyàwó tí wọ́n san tàbí tí wọ́n gbà ṣe pọ̀ tó yangàn. Ní ọ̀wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society ní Áfíríkà ròyìn pé: “Àwọn ọkọ kan kì í fi ọ̀wọ̀ hàn nígbà tí àwọn ẹbí ìyàwó bá fòye hùwà nípa ohun tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ wọn, ńṣe ni wọ́n máa ń wo ìyàwó wọn bí ẹni tí wọ́n rà ní ‘owó pọ́ọ́kú.’”

Ìwọra àtigba owó orí ìyàwó tí ó pọ̀ ti jàrábà àwọn Kristẹni kan, ó sì ti yọrí sí ohun tí kò dára. Fún àpẹẹrẹ, gbé ìròyìn yìí tí ó wá láti ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society mìíràn yẹ̀ wò: “Ní gbogbo gbòò, ó ṣòro fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin àpọ́n láti rí ẹni tí wọ́n yóò fẹ́. Èyí ló fà á tí iye àwọn tí a ń yọ lẹ́gbẹ́ nítorí ìṣekúṣe ṣe ń pọ̀ sí i. Àwọn arákùnrin kan máa ń lọ wa kùsà góòlù tàbí dáyámọ́ńdì tí wọ́n óò tà kí wọ́n lè ní owó tí ó tó láti gbéyàwó. Èyí lè gbà wọ́n tó ọdún méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó sì máa ń sọ wọ́n di aláìlera nípa tẹ̀mí bí wọ́n ti ń pa ìpàdé ìjọ jẹ, tí wọn kò sì sí láàárín àwọn ará.”

Láti yẹra fún irú àbájáde búburú bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí àwọn Kristẹni òbí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tí wọ́n dàgbà dénú nínú ìjọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kì í ṣe òbí, ó fòye hùwà lọ́nà tí ó ń gbà bá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lò. Ó máa ń ṣọ́ra kí ó má bàa ni ènìyàn kankan lára. (Ìṣe 20:33) Dájúdájú, nígbà tí àwọn Kristẹni òbí bá fẹ́ gba owó orí ìyàwó, ó yẹ kí wọ́n máa ronú nípa àpẹẹrẹ aláìmọtara-ẹni-nìkan rẹ̀. Ní gidi, ìmísí àtọ̀runwá ló mú Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ di aláfarawé mi ní ìsopọ̀ṣọ̀kan, ẹ̀yin ará, kí ẹ sì tẹ ojú yín mọ́ àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà tí ó bá àpẹẹrẹ tí ẹ rí nínú wa mu.”—Fílípì 3:17.

Àpẹẹrẹ Àwọn Tí Wọ́n Fòye Báni Lò

Tí ó bá kan ọ̀ràn ṣíṣe ètò ìgbéyàwó, ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni òbí ti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ ní ti ìfòyebánilò. Gbé ọ̀ràn Joseph àti ìyàwó rẹ̀, Mae, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ bí ajíhìnrere alákòókò kíkún, yẹ̀ wò.b Wọ́n ń gbé ní ọ̀kan nínú àwọn Erékùṣù Solomon, níbi tí ètò gbígba owó orí ìyàwó ti máa ń jẹ́ ìṣòro lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Láti yẹra fún irú ìṣòro bẹ́ẹ̀, Joseph àti Mae ṣètò kí ọmọbìnrin wọn, Helen, lọ ṣègbéyàwó ní erékùṣù mìíràn tí kò jìnnà sí wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sì ṣe fún ọmọbìnrin wọn kejì, Esther. Joseph tún gbà pé kí ọkọ ọmọ rẹ̀, Peter, san owó orí ìyàwó tí ó kéré ju ohun tí a lè retí kí ó san. A béèrè ìdí tí Joseph fi ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣàlàyé pé: “N kò fẹ́ ni ọkọ ọmọ mi, tí ó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà lára.”

Ọ̀pọ̀ lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n wà ní Áfíríkà pẹ̀lú ti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ ní ti ìfòyebánilò. Ní àwọn àgbègbè kan, ní gbogbo gbòò, a retí pé kí a san owó tí ó pọ̀ fún àwọn ẹbí àti ìbátan ìyàwó kí ó tó di ọjọ́ tí wọ́n dá fún gbígba owó orí ìyàwó. Kí ọkùnrin kan tó ri ìyàwó fẹ́, wọ́n lè retí pé kí ó ṣèlérí pé òun yóò bá àbúrò àfẹ́sọ́nà rẹ̀, tí ó jẹ́ ọkùnrin, san owó orí ìyàwó rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, gbé àpẹẹrẹ Kossi àti ìyàwó rẹ̀, Mara, yẹ̀ wò. Ọmọbìnrin wọn, Beboko, fẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan láìpẹ́ yìí. Ṣáájú ìgbéyàwó wọn, àwọn ẹbí da àwọn òbí rẹ̀ láàmú láti gba owó orí ìyàwó tí ó pọ̀ kí tiwọn lè yọ níbẹ̀. Àmọ́, àwọn òbí náà dúró lórí ìpinnu wọn, wọn kò sì fara mọ́ ohun tí wọ́n ń béèrè náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ṣètò pẹ̀lú ẹni náà gangan tí ó fẹ́ mú ọmọbìnrin wọn náà ṣaya, wọ́n sì béèrè owó orí tí ó kéré gan-an lórí ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì dá ìdajì rẹ̀ padà fún àwọn ọmọ méjèèjì tí wọ́n fẹ́ ṣègbéyàwó náà láti fi ṣètò ìgbéyàwó wọn.

Àpẹẹrẹ mìíràn ní orílẹ̀-èdè kan náà ni ti ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan tí ń jẹ́ Itongo. Lákọ̀ọ́kọ́, ìdílé rẹ̀ béèrè owó orí tí ó mọ níwọ̀n. Àmọ́, àwọn ẹbí ní kí wọ́n fi kún iye náà. Nǹkan ò fararọ níbẹ̀, ó sì jọ pé àwọn ẹbí wọ̀nyí lè rọ́wọ́ mú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ tó máa ń tijú ni Itongo, ó dìde dúró, ó sì sọ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé òun ti pinnu láti fẹ́ Kristẹni aláápọn kan tí ń jẹ́ Sanze, gẹ́gẹ́ bí àwọ́n ti ṣètò. Lẹ́yìn náà, ni ó fi ìgboyà sọ pé, “Mbi ke” (tí ó túmọ̀ sí, “Kò jù bẹ́ẹ̀ lọ”), ó sì jókòó. Ìyá rẹ̀, Sambeko, tí ó jẹ́ Kristẹni, kín in lẹ́yìn. Bí ìjíròrò náà ṣe parí nìyẹn, àwọn méjèèjì sì fẹ́ra wọn bí wọ́n ti ṣètò tẹ́lẹ̀.

Àwọn ohun kan wà tí ó jẹ àwọn Kristẹni òbí lọ́kàn gan-an ju àǹfààní tí wọ́n lè rí jẹ nínú owó orí ìyàwó lọ. Ọkọ kan ní Cameroon ṣàlàyé pé: “Ìyá ìyàwó mi máa ń lo gbogbo àǹfààní tí ó bá ní láti sọ fún mi pé ohunkóhun tí mo bá fẹ́ fún òun bí owó orí ìyàwó, kí n máa fi tọ́jú ọmọ òun.” Ipò tẹ̀mí àwọn ọmọ ló tún máa ń jẹ àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ onífẹ̀ẹ́ lọ́kàn. Fún àpẹẹrẹ, ṣàyẹ̀wò ọ̀ràn Farai àti Rudo, tí wọ́n ń gbé Zimbabwe, tí wọ́n sì máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í gba owó ọ̀yà, owó orí tí wọ́n gbà lórí àwọn ọmọbìnrin wọn méjèèjì nígbà tí wọ́n ń fi wọ́n fọ́kọ kéré gan-an sí iye tí ó sábà máa ń jẹ́. Kí ni wọ́n sọ pé ó mú kí àwọn ṣe bẹ́ẹ̀? Wọ́n fẹ́ kí àwọn ọmọbìnrin wọn jàǹfààní nínú ìgbéyàwó wọn pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ní ti gidi. Wọ́n ṣàlàyé pé: “Ohun tí a kà sí pàtàkì gan-an ni ipò tẹ̀mí àwọn ọmọ wa àti àwọn ọkọ wọn.” Ẹ wo bí èyí ṣe mú ọrùn wọn fúyẹ́ tó! Ó yẹ kí a gbóṣùbà fún àwọn àna tí wọ́n fi àníyàn onífẹ̀ẹ́ hàn nípa ipò tẹ̀mí àti ti ara àwọn ọmọ wọn tí wọ́n ti lọ sílé ọkọ.

Àwọn Àǹfààní Ìfòyebánilò

A bù kún Joseph àti Mae tí wọ́n ń gbé ní ọ̀kan nínú àwọn Erékùṣù Solomon nítorí ìwà ọ̀làwọ́ àti ìṣọ́ra tí wọ́n lò ní bíbójútó ìgbéyàwó àwọn ọmọbìnrin wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, wọn kò kó àwọn ọkọ ọmọ wọn sínú gbèsè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ti ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ tí wọ́n fẹ́ra náà láti lo ọ̀pọ̀ ọdún nínú iṣẹ́ alákòókò kíkún ti títan ìhìn iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run káàkiri. Joseph rántí àwọn ìgbà tó ti kọjá, ó sì wí pé: “Ìpinnu tí èmi àti ìdílé mi ṣe ti yọrí sí ìbùkún ńláǹlà. Lótìítọ́, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn tí wọn kò lóye máa ń dààmú wa gan-an, àmọ́ mo ní ẹ̀rí ọkàn rere àti ìtẹ́lọ́rùn bí mo ṣe ń rí i tí ọwọ́ àwọn ọmọ mi ń dí, tí wọ́n sì ń di alágbára nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Inú àwọn pẹ̀lú ń dùn, èmi àti ìyàwó mi sì túbọ̀ ń láyọ̀ gan-an.”

Ohun rere mìíràn tí ń ti ibẹ̀ wá ni ipò ìbátan rere láàárín àwọn àna. Fún àpẹẹrẹ, Zondai àti Sibusiso pẹ̀lú àwọn ìyàwó wọn, tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́ntàbúrò, ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùyọ̀ǹda ara ẹni ní ẹ̀ka Watch Tower Society tó wà ní Zimbabwe. Bàbá àwọn ìyàwó wọn, Dakarai, jẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún, kì í sì í gba owó ọ̀yà. Nígbà tí wọ́n ń ṣètò gbígba owó orí ìyàwó, ó sọ pé ohunkóhun tí wọ́n bá lágbára rẹ̀ ni òun yóò gbà. Zondai àti Sibusiso sọ pé: “A fẹ́ràn bàbá àwọn ìyàwó wa gidigidi, gbogbo ohun tí a bá lágbára ni a óò ṣe láti ràn án lọ́wọ́ tí ó bá nílò rẹ̀.”

Òtítọ́ ni, fífòye hùwà nígbà tí a bá ń gba owó orí ìyàwó ń fi kún ayọ̀ ìdílé. Fún àpẹẹrẹ, àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó kò ní tọrùn bọ gbèsè, ó sì ń mú kí ó túbọ̀ rọrùn fún wọn láti mú ara wọn bá ipò lọ́kọláya mu. Èyí ti mú kí ọ̀pọ̀ tọkọtaya tí wọn kò dàgbà jù máa lépa àwọn ìbùkún tẹ̀mí, bí ṣíṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún nínú iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn tí ó jẹ́ kánjúkánjú náà. Èyí yóò wá mú ògo wá fún Olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbéyàwó náà, tí ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́, Jèhófà Ọlọ́run.—Mátíù 24:14; 28:19, 20.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní àwọn àdúgbò kan, ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀. Àwọn òbí ọkọ ló máa ń retí àtigbà nǹkan ìdána lọ́wọ́ àwọn òbí ìyàwó.

b Kì í ṣe orúkọ wọn gangan ni a lò nínú àpilẹ̀kọ yìí.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]

WỌ́N DÁ OWÓ ORÍ ÌYÀWÓ PADÀ

Ní àwọn àdúgbò kan, àwọn ènìyàn máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú ìyàwó àti àwọn òbí rẹ̀ bí owó orí ìyàwó tí wọ́n gbà bá kéré. Nípa bẹ́ẹ̀, ìgbéraga àti ìfẹ́ ọkàn láti fi ipò ìdílé ẹni ṣe ṣekárími ló máa ń fa gbígba owó orí ìyàwó tí ó pọ̀. Ìdílé kan ní Èkó, Nàìjíríà, ṣe ohun tí ó yàtọ̀ pátápátá sí èyí. Délé, ọkọ ọmọ wọn, ṣàlàyé pé:

“Àwọn ẹbí ìyàwó mi kò jẹ́ kí n ṣe ìnáwó púpọ̀ lórí àwọn ohun ìdána tí ó máa ń bá ayẹyẹ sísan owó orí ìyàwó rìn, bí ríra àwọn aṣọ olówó ńláńlá. Kódà, nígbà tí àwọn ẹbí mi gbé owó orí ìyàwó fún wọn, alága ìjókòó tí ó ṣojú fún wọn béèrè pé: ‘Ṣé ẹ fẹ́ mú ọmọbìnrin yìí bí ìyàwó ni àbí ẹ fẹ́ mú un bí ọmọ?’ Àwọn ẹbí mi panu pọ̀ dáhùn pé: ‘A fẹ́ mú un bí ọmọ ni.’ Lẹ́yìn náà, wọ́n dá owó orí ìyàwó náà padà fún wa nínú àpòòwé tó wà.

“Títí di òní yìí, mo mọrírì ọ̀nà tí àwọn àna mi gbà ṣètò ìgbéyàwó wa. Ó mú kí n ní ọ̀wọ̀ tí ó ga fún wọn. Èrò dídára tí wọ́n ní nípa ohun tẹ̀mí ń mú kí n máa wò wọ́n bí ìbátan tímọ́tímọ́. Ó tún ní ipa ńláǹlà lórí ojú tí mo fi ń wo ìyàwó mi. Mo mọyì rẹ̀ gan-an nítorí ọ̀nà tí àwọn ẹbí rẹ̀ gbà ṣe sí mi. Tí a bá ní èdèkòyédè, n kì í jẹ́ kí ó di nǹkan ńlá. Gbàrà tí mo bá ti rántí irú ìdílé tí ó ti wá, èdèkòyédè náà yóò rọlẹ̀.

“Ọwọ́ àwọn ẹbí mi àti tirẹ̀ ti wọ ọwọ́ gan-an. Kódà, títí di ìsinsìnyí, tí ọdún méjì ti lọ lẹ́yìn ìgbéyàwó wa, bàbá mi ṣì máa ń fi ẹ̀bùn àti oúnjẹ ránṣẹ́ sí àwọn ẹbí ìyàwó mi.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́