ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Àwọn Ọba

      • Ìjọba Sólómọ́nì (1-19)

      • Àwọn èèyàn láásìkí nígbà àkóso Sólómọ́nì (20-28)

        • Àwọn èèyàn wà láàbò lábẹ́ àjàrà àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ (25)

      • Ọgbọ́n Sólómọ́nì àti àwọn òwe rẹ̀ (29-34)

1 Àwọn Ọba 4:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 9:30; Onw 1:12

1 Àwọn Ọba 4:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “olórí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 6:8; 27:16, 17

1 Àwọn Ọba 4:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 8:17; 1Kr 27:32
  • +2Sa 8:16; 20:24

1 Àwọn Ọba 4:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 1:8; 2:35; 1Kr 27:5
  • +1Ọb 2:26

1 Àwọn Ọba 4:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 1:9, 10
  • +2Sa 15:37; 1Kr 27:33

1 Àwọn Ọba 4:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 20:24; 1Ọb 5:14; 12:18
  • +1Ọb 9:15

1 Àwọn Ọba 4:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 27:1

1 Àwọn Ọba 4:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 19:42, 48

1 Àwọn Ọba 4:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:29
  • +Joṣ 17:11; 1Sa 31:8, 10
  • +Joṣ 21:34

1 Àwọn Ọba 4:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:41-43; 1Ọb 22:3
  • +Nọ 32:41; Di 3:14
  • +Nọ 32:1
  • +Di 3:4
  • +Joṣ 13:8, 11

1 Àwọn Ọba 4:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 32:1, 2; 2Sa 2:8, 9

1 Àwọn Ọba 4:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 1:8
  • +Joṣ 18:11

1 Àwọn Ọba 4:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 17:1
  • +Nọ 21:21
  • +Di 3:4

1 Àwọn Ọba 4:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 22:15, 17
  • +Onw 2:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/1998, ojú ìwé 9-10

    2/1/1998, ojú ìwé 11

1 Àwọn Ọba 4:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, odò Yúfírétì.

  • *

    Tàbí “owó òde.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:18; Ẹk 23:31; 2Sa 8:3; Sm 72:8-10
  • +Sm 72:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ilẹ̀ Dáradára,” ojú ìwé 16

1 Àwọn Ọba 4:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Kọ́ọ̀ kan jẹ́ Lítà 220. Wo Àfikún B14.

1 Àwọn Ọba 4:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, ìwọ̀ oòrùn odò Yúfírétì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 1:4
  • +Jẹ 10:19
  • +1Ọb 5:4; 1Kr 22:9; Sm 72:7

1 Àwọn Ọba 4:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2003, ojú ìwé 24

    10/15/1998, ojú ìwé 9-10

1 Àwọn Ọba 4:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Iye yìí wà nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ kan àti ní àwọn apá míì tí ìtàn yìí ti fara hàn nínú Bíbélì. Àwọn ìwé àfọwọ́kọ míì pe iye yìí ní ọ̀kẹ́ méjì (40,000).

  • *

    Tàbí “agẹṣin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:15, 16; 1Ọb 10:24-26; 2Kr 1:14, 17

1 Àwọn Ọba 4:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 4:7

1 Àwọn Ọba 4:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọkàn tó gbòòrò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 10:23; 2Kr 1:10; Owe 2:6

1 Àwọn Ọba 4:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:22

1 Àwọn Ọba 4:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 89:àkọlé
  • +Sm 88:àkọlé
  • +1Kr 2:4, 6
  • +1Ọb 10:1, 7; Lk 11:31

1 Àwọn Ọba 4:32

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 1:1; Onw 12:9
  • +Sol 1:1

1 Àwọn Ọba 4:33

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn ẹ̀dá tó ń fò.”

  • *

    Ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹranko afàyàfà àti àwọn kòkòrò wà lára wọn.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:22
  • +Owe 30:30
  • +Owe 30:19
  • +Owe 6:6; 30:25

1 Àwọn Ọba 4:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 9:1, 23

Àwọn míì

1 Ọba 4:12Kr 9:30; Onw 1:12
1 Ọba 4:21Kr 6:8; 27:16, 17
1 Ọba 4:32Sa 8:17; 1Kr 27:32
1 Ọba 4:32Sa 8:16; 20:24
1 Ọba 4:41Ọb 1:8; 2:35; 1Kr 27:5
1 Ọba 4:41Ọb 2:26
1 Ọba 4:51Ọb 1:9, 10
1 Ọba 4:52Sa 15:37; 1Kr 27:33
1 Ọba 4:62Sa 20:24; 1Ọb 5:14; 12:18
1 Ọba 4:61Ọb 9:15
1 Ọba 4:71Kr 27:1
1 Ọba 4:9Joṣ 19:42, 48
1 Ọba 4:122Ọb 23:29
1 Ọba 4:12Joṣ 17:11; 1Sa 31:8, 10
1 Ọba 4:12Joṣ 21:34
1 Ọba 4:13Di 4:41-43; 1Ọb 22:3
1 Ọba 4:13Nọ 32:41; Di 3:14
1 Ọba 4:13Nọ 32:1
1 Ọba 4:13Di 3:4
1 Ọba 4:13Joṣ 13:8, 11
1 Ọba 4:14Jẹ 32:1, 2; 2Sa 2:8, 9
1 Ọba 4:181Ọb 1:8
1 Ọba 4:18Joṣ 18:11
1 Ọba 4:19Joṣ 17:1
1 Ọba 4:19Nọ 21:21
1 Ọba 4:19Di 3:4
1 Ọba 4:20Jẹ 22:15, 17
1 Ọba 4:20Onw 2:24
1 Ọba 4:21Jẹ 15:18; Ẹk 23:31; 2Sa 8:3; Sm 72:8-10
1 Ọba 4:21Sm 72:10
1 Ọba 4:24Joṣ 1:4
1 Ọba 4:24Jẹ 10:19
1 Ọba 4:241Ọb 5:4; 1Kr 22:9; Sm 72:7
1 Ọba 4:26Di 17:15, 16; 1Ọb 10:24-26; 2Kr 1:14, 17
1 Ọba 4:271Ọb 4:7
1 Ọba 4:291Ọb 10:23; 2Kr 1:10; Owe 2:6
1 Ọba 4:30Iṣe 7:22
1 Ọba 4:31Sm 89:àkọlé
1 Ọba 4:31Sm 88:àkọlé
1 Ọba 4:311Kr 2:4, 6
1 Ọba 4:311Ọb 10:1, 7; Lk 11:31
1 Ọba 4:32Owe 1:1; Onw 12:9
1 Ọba 4:32Sol 1:1
1 Ọba 4:33Ẹk 12:22
1 Ọba 4:33Owe 30:30
1 Ọba 4:33Owe 30:19
1 Ọba 4:33Owe 6:6; 30:25
1 Ọba 4:342Kr 9:1, 23
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Àwọn Ọba 4:1-34

Àwọn Ọba Kìíní

4 Ọba Sólómọ́nì ṣàkóso lórí gbogbo Ísírẹ́lì.+ 2 Àwọn ìjòyè* rẹ̀ nìyí: Asaráyà ọmọ Sádókù+ ni àlùfáà; 3 Élíhóréfì àti Áhíjà, àwọn ọmọ Ṣíṣà ni akọ̀wé;+ Jèhóṣáfátì+ ọmọ Áhílúdù ni akọ̀wé ìrántí; 4 Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà ló ń bójú tó àwọn ọmọ ogun; Sádókù àti Ábíátárì+ sì jẹ́ àlùfáà; 5 Asaráyà ọmọ Nátánì+ ni olórí àwọn alábòójútó; Sábúdù ọmọ Nátánì jẹ́ àlùfáà àti ọ̀rẹ́ ọba;+ 6 Áhíṣà ló ń bójú tó agbo ilé; Ádónírámù+ ọmọ Ábídà ni olórí àwọn tí ọba ní kí ó máa ṣiṣẹ́ fún òun.+

7 Sólómọ́nì ní àwọn alábòójútó méjìlá (12) tó ń bójú tó gbogbo Ísírẹ́lì, wọ́n sì ń pèsè oúnjẹ fún ọba àti agbo ilé rẹ̀. Ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ni láti pèsè oúnjẹ ní oṣù kan lọ́dún.+ 8 Àwọn alábòójútó náà ni: Ọmọ Húrì tó ń bójú tó agbègbè olókè Éfúrémù; 9 ọmọ Dékérì tó ń bójú tó Mákásì, Ṣáálíbímù,+ Bẹti-ṣémẹ́ṣì àti Eloni-bẹti-hánánì; 10 ọmọ Hésédì tó ń bójú tó Árúbótì (tirẹ̀ ni Sókọ̀ àti gbogbo ilẹ̀ Héfà); 11 ọmọ Ábínádábù tó ń bójú tó gbogbo gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Dórì (ó fi Táfátì, ọmọ Sólómọ́nì ṣe aya); 12 Béánà ọmọ Áhílúdù tó ń bójú tó Táánákì, Mẹ́gídò+ àti gbogbo Bẹti-ṣéánì+ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Sárétánì nísàlẹ̀ Jésírẹ́lì, láti Bẹti-ṣéánì sí Ebẹli-méhólà títí dé agbègbè Jókíméámù;+ 13 ọmọ Gébérì tó ń bójú tó Ramoti-gílíádì+ (tirẹ̀ ni àwọn abúlé àgọ́ Jáírì+ ọmọ Mánásè, tó wà ní Gílíádì;+ òun ló tún ni agbègbè Ágóbù,+ tó wà ní Báṣánì:+ ọgọ́ta [60] ìlú tó tóbi, tó sì ní ògiri àti ọ̀pá ìdábùú bàbà); 14 Áhínádábù ọmọ Ídò tó ń bójú tó Máhánáímù;+ 15 Áhímáásì tó ń bójú tó Náfútálì (ó fi Básémátì, tó tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Sólómọ́nì, ṣe aya); 16 Béánà ọmọ Húṣáì, tó ń bójú tó Áṣérì àti Béálótì; 17 Jèhóṣáfátì ọmọ Párúà tó ń bójú tó Ísákà; 18 Ṣíméì+ ọmọ Ílà tó ń bójú tó Bẹ́ńjámínì;+ 19 Gébérì ọmọ Úráì tó ń bójú tó ilẹ̀ Gílíádì,+ ilẹ̀ Síhónì+ ọba àwọn Ámórì àti ti Ógù+ ọba Báṣánì. Alábòójútó kan tún wà tó ń bójú tó gbogbo àwọn alábòójútó yòókù ní ilẹ̀ náà.

20 Júdà àti Ísírẹ́lì pọ̀ bí iyanrìn etí òkun;+ wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń yọ̀.+

21 Sólómọ́nì ṣàkóso gbogbo àwọn ìjọba láti Odò*+ dé ilẹ̀ àwọn Filísínì àti títí dé ààlà Íjíbítì. Wọ́n ń mú ìṣákọ́lẹ̀* wá, wọ́n sì ń sin Sólómọ́nì ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.+

22 Oúnjẹ Sólómọ́nì ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n (30) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀* ìyẹ̀fun kíkúnná àti ọgọ́ta (60) òṣùwọ̀n kọ́ọ̀ ìyẹ̀fun, 23 màlúù àbọ́sanra mẹ́wàá, ogún (20) màlúù láti ibi ìjẹko àti ọgọ́rùn-ún (100) àgùntàn, yàtọ̀ sí àwọn akọ àgbọ̀nrín mélòó kan, àwọn egbin, àwọn èsúwó àti àwọn ẹ̀lúlùú tí ó sanra. 24 Ó ń bójú tó gbogbo ohun tó wà lápá Odò+ níbí,* láti Tífísà dé Gásà,+ títí kan gbogbo àwọn ọba tó wà lápá Odò níbí; ó sì ní àlàáfíà ní gbogbo agbègbè tó yí i ká.+ 25 Júdà àti Ísírẹ́lì ń gbé lábẹ́ ààbò ní gbogbo ọjọ́ ayé Sólómọ́nì, kálukú lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, láti Dánì títí dé Bíá-ṣébà.

26 Sólómọ́nì ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000)* ilé ẹṣin fún àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ àti ẹgbẹ̀rún méjìlá (12,000) ẹṣin.*+

27 Àwọn alábòójútó yìí ń pèsè oúnjẹ fún Ọba Sólómọ́nì àti gbogbo àwọn tó ń jẹun ní tábìlì Ọba Sólómọ́nì. Kálukú ní oṣù tirẹ̀ tó ń pèsè oúnjẹ, á sì rí i dájú pé gbogbo ohun tí wọ́n nílò ló wà.+ 28 Wọ́n á tún mú ọkà bálì àti pòròpórò wá níbikíbi tí a bá ti nílò rẹ̀ fún àwọn ẹṣin títí kan àwọn ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ ẹṣin, bí iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún kálukú wọn bá ṣe gbà.

29 Ọlọ́run fún Sólómọ́nì ní ọgbọ́n àti òye tó pọ̀ gan-an àti ìjìnlẹ̀ òye tó pọ̀* bí iyanrìn etí òkun.+ 30 Ọgbọ́n Sólómọ́nì pọ̀ ju ọgbọ́n gbogbo àwọn ará Ìlà Oòrùn àti gbogbo ọgbọ́n Íjíbítì.+ 31 Ó gbọ́n ju èèyàn èyíkéyìí lọ, ó gbọ́n ju Étánì+ tó jẹ́ Ẹ́síráhì àti Hémánì,+ Kálíkólì+ àti Dáádà, àwọn ọmọ Máhólì; òkìkí rẹ̀ sì kàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí i ká.+ 32 Ó kọ* ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) òwe,+ àwọn orin rẹ̀+ sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé márùn-ún (1,005). 33 Ó máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn igi, látorí kédárì tó wà ní Lẹ́bánónì dórí hísópù+ tó ń hù lára ògiri; ó máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹranko,+ àwọn ẹyẹ,*+ àwọn ohun tó ń rákò*+ àti àwọn ẹja. 34 Àwọn èèyàn ń wá láti gbogbo orílẹ̀-èdè kí wọ́n lè gbọ́ ọgbọ́n Sólómọ́nì, títí kan àwọn ọba láti ibi gbogbo láyé tí wọ́n ti gbọ́ nípa ọgbọ́n rẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́