Ìdí Yíyèkooro fún Níní Ẹ̀mí Nǹkan-Yóò-Dára Lónìí
ÒPÌTÀN àti onímọ̀ ìbágbépọ̀-ẹ̀dá náà, H. G. Wells, tí a bí ní 1866, ní ipa jíjinlẹ̀ gidigidi lórí ìrònú ọ̀rúndún ogún. Nípasẹ̀ àwọn ìwé rẹ̀, ó ṣàlàyé ìdánilójú rẹ̀ pé ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì yóò yọrí sí sáà ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn. Nípa báyìí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Collier’s Encyclopedia, ránni létí “ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára tí kò láàlà” tí Wells ní bí ó ti ń ṣiṣẹ́ láìsinmi láti mú kí ète rẹ̀ tẹ̀ síwájú. Ṣùgbọ́n ó tún sọ pé ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára tí ó ní parẹ́ nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀.
Bí Wells ṣe wá rí i pé “sáyẹ́ǹsì lè mú ire àti ibi wá, ìgbàgbọ́ rẹ̀ wọmi, ó sì di oníyèméjì,” ni ohun tí ìwé atúmọ̀ èdè náà, Chambers’s Biographical Dictionary, sọ. Èé ṣe tí èyí fi ṣẹlẹ̀?
Orí àṣeyọrí ẹ̀dá ènìyàn ni Wells gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára tí ó ní kà. Nígbà tí ó rí i pé ọwọ́ aráyé kò lè tẹ Ibi Aláìlálèébù tí òun ń retí, kò sí ibi tí ó lè yíjú sí mọ́. Kíá ni àìnírètí di iyè méjì.
Lónìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìrírí kan náà nítorí ìdí kan náà. Wọ́n máa ń kún fún ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára nígbà tí wọ́n bá wà ní ọ̀dọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ń di oníyèméjì bí wọ́n ti ń dàgbà sí i. Àwọn ọ̀dọ́ wà pàápàá tí wọ́n máa ń fi ohun tí a gbà pé ó jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó bójú mu sílẹ̀ tí wọ́n sì máa ń lọ́wọ́ nínú ìjoògùnyó, ìṣekúṣe, àti àwọn ọ̀nà ìgbésí ayé mìíràn tí ń pani run. Kí ni ojútùú náà? Ṣàyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ tí ó tẹ̀ lé e yìí láti inú àwọn àkókò kíkọ Bíbélì, kí o sì mọ ìdí tí a ní fún níní ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára—ní ìgbà tí ó ti kọjá, nísinsìnyí, àti ní ọjọ́ ọ̀la.
A San Èrè fún Ẹ̀mí Nǹkan-Yóò-Dára Tí Ábúráhámù Ní
Ní ọdún 1943 ṣááju Sànmánì Tiwa, Ábúráhámù ṣí kúrò ní Háránì, ó ré kọjá Odò Yúfírétì, ó sì wọ ilẹ̀ Kénáánì. A ṣàpèjúwe Ábúráhámù gẹ́gẹ́ bíi “bàbá gbogbo àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìgbàgbọ́,” ẹ sì wo àpẹẹrẹ àtàtà tí ó fi lélẹ̀!—Róòmù 4:11.
Lọ́ọ̀tì, ọmọ òrukàn, tí ó jẹ́ ọmọ arákùnrin Ábúráhámù àti ìdílé Lọ́ọ̀tì bá Ábúráhámù lọ. Lẹ́yìn náà, nígbà tí ìyàn kọ lu ilẹ̀ náà, ìdílé méjèèjì ṣí lọ sí Íjíbítì, nígbà tí ó sì yá wọ́n jọ pa dà. Ní àkókò yí, Ábúráhámù àti Lọ́ọ̀tì ti kó ọrọ̀ púpọ̀ jọ títí kan ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran. Nígbà tí aáwọ̀ ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn olùṣọ́ agbo ẹran wọn, Ábúráhámù lo ìdánúṣe, ó sì sọ pé: “Èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí gbólóhùn asọ̀ kí ó wà láàárín tèmi tìrẹ, àti láàárín àwọn darandaran mi, àti àwọn darandaran rẹ; nítorí pé ará ni àwa í ṣe. Gbogbo ilẹ̀ kọ́ èyí níwájú rẹ? Èmi bẹ̀ ọ́, ya ara rẹ kúrò lọ́dọ̀ mi: bí ìwọ bá pọ̀ sí apá òsì, ǹjẹ́ èmi óò pọ̀ sí ọ̀tún; tàbí bí ìwọ bá pọ̀ sí apá ọ̀tún, ǹjẹ́ èmi óò pọ̀ sí òsì.”—Jẹ́nẹ́sísì 13:8, 9.
Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Ábúráhámù làgbà, òun ì bá ti bójú tó àwọn ọ̀ràn lọ́nà tí yóò ṣàǹfààní fún un, Lọ́ọ̀tì ì bá sì ti gbà pẹ̀lú yíyàn tí Ábúráhámù bá ṣe níwọ̀n bí ó ti jẹ́ arákùnrin bàbá rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, “Lọ́ọ̀tì . . . gbójú rẹ̀ sí òkè, ó sì wo gbogbo àgbègbè Jọ́dánì, pé ó ní omi níbi gbogbo, kí OLÚWA kí ó tó pa Sódómù òun Gòmórà run, bí ọgbà OLÚWA, bí ilẹ̀ Íjíbítì, bí ìwọ ti ń bọ̀ wá sí Sóárì. Nígbà náà ni Lọ́ọ̀tì yan gbogbo àgbègbè Jọ́dánì fún ara rẹ̀.” Pẹ̀lú irú yíyàn yẹn, Lọ́ọ̀tì ní gbogbo ìdí láti ní ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára. Ṣùgbọ́n Ábúráhámù ńkọ́?—Jẹ́nẹ́sísì 13:10, 11.
Ṣé sùgọ́mù, tí ń fi ire ìdílé rẹ̀ sínú ewu ni Ábúráhámù ni? Rárá. Ìwà rere àti ẹ̀mí ọ̀làwọ́ tí Ábúráhámù ní mú èrè ńláǹlà wá. Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé: “Gbé ojú rẹ sókè nísinsìnyí, kí o sì wò láti ibi tí o gbé wà nì lọ, sí ìhà àríwá, àti sí ìhà gúúsù, sí ìhà ìlà oòrùn, àti sí ìhà ìwọ̀ oòrùn. Gbogbo ilẹ̀ tí o rí nì, ìwọ ni èmi óò sáà fi fún àti fún irú ọmọ rẹ láéláé.”—Jẹ́nẹ́sísì 13:14, 15.
Ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára tí Ábúráhámù ní ní ìpìlẹ̀ tí ó yè kooro. A gbé e ka ìlérí Ọlọ́run pé òun yóò mú orílẹ̀-èdè ńlá kan jáde láti inú Ábúráhámù kí “gbogbo ìdílé orí ilẹ̀ [lè] bù kún ara wọn dájúdájú nípasẹ̀ [Ábúráhámù].” (Jẹ́nẹ́sísì 12:2-4, 7, NW) Àwa pẹ̀lú ní ìdí láti ní ìgbọ́kànlé, ní mímọ̀ pé “Ọlọ́run ń mú kí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ fún ire àwọn wọnnì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:28.
Àwọn Amí Méjì Tí Wọ́n Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Nǹkan-Yóò-Dára
Ní èyí tí ó ju 400 ọdún lẹ́yìn náà, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe tán láti wọ ilẹ̀ Kénáánì, “ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.” (Ẹ́kísódù 3:8; Diutarónómì 6:3) Mósè yanṣẹ́ fún àwọn ìjòyè 12 láti ‘rin ilẹ̀ náà wò, kí wọ́n sì mú ìhìn pa dà wá ní ti ọ̀nà tí wọn yóò bá gòkè lọ àti àwọn ìlú tí wọn yóò yọ sí.’ (Diutarónómì 1:22; Númérì 13:2) Gbogbo amí 12 náà sọ ohun kan náà ní ti bí wọ́n ṣe ṣàpèjúwe aásìkí ilẹ̀ náà, ṣùgbọ́n 10 lára wọn mú ìròyìn oníyèméjì tí ó gbin ìbẹ̀rù sí ọkàn àyà àwọn ènìyàn náà wá.—Númérì 13:31-33.
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jóṣúà àti Kélẹ́ẹ̀bù sọ ìhìn iṣẹ́ ẹlẹ́mìí nǹkan-yóò-dára fún àwọn ènìyàn náà, wọ́n sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti dín ìbẹ̀rù wọn kù. Ìṣarasíhùwà àti ìròyìn wọn fi ìgbọ́kànlé kíkún hàn nínú agbára Jèhófà láti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti mú wọn pa dà sí Ilẹ̀ Ìlérí ṣẹ—ṣùgbọ́n kò wọ̀ wọ́n létí. Kàkà bẹ́ẹ̀, “gbogbo ìjọ . . . wí pé kí a sọ wọ́n ní òkúta.”—Númérì 13:30; 14:6-10.
Mósè rọ àwọn ènìyàn náà láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti tẹ́tí sílẹ̀. Nítorí pé wọ́n ń bá a nìṣó ní jíjẹ́ oníyèméjì, odindi orílẹ̀-èdè ní láti rìn kiri nínú aginjù fún 40 ọdún. Nínú àwọn amí 12 náà, Jóṣúà àti Kélẹ́ẹ̀bù nìkan ni wọ́n jèrè níní ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára. Kí ni ìṣòro náà gan-an? Àìnígbàgbọ́ ni, níwọ̀n bí àwọn ènìyàn náà ti gbẹ́kẹ̀ lé ọgbọ́n ara wọn.—Númérì 14:26-30; Hébérù 3:7-12.
Iyè Méjì Jónà
Jónà gbé ayé ní ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣááju Sànmánì Tiwa. Bíbélì fi hàn pé òun jẹ́ wòlíì olùṣòtítọ́ sí Jèhófà fún ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì, fún sáà kan nígbà ìṣàkóso Jèróbóámù Kejì. Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ àṣẹ kan láti lọ sí Nínéfè láti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn. Òpìtàn náà, Josephus, sọ pé Jónà “ronú pé ó sàn jù láti fẹsẹ̀ fẹ” kí òun sì sá lọ sí Jópà dípò ìyẹn. Níbẹ̀, ó wọ ọkọ̀ ojú omi tí ń lọ sí Táṣíṣì, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ Sípéènì òde òní. (Jónà 1:1-3) A ṣàlàyé ìdí tí Jónà fi ní irú ojú ìwòye oníyèméjì bẹ́ẹ̀ nípa iṣẹ́ àyànfúnni yìí ní Jónà 4:2.
Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, Jónà gbà láti ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún un, ṣùgbọ́n ó bínú nígbà tí àwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà. Nítorí náà, Jèhófà kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́ àtàtà kan nípa ìyọ́nú ní mímú kí ewéko akèrègbè tí Jónà forí pa mọ́ sí lábẹ́ rọ kí ó sì kú. (Jónà 4:1-8) Ì bá ti tọ́ ká ní Jónà fi ìbànújẹ́ tí ó fi hàn nígbà tí ewéko náà kú hàn sí àwọn 120,000 ènìyàn ìlú Nínéfè tí wọn kò “mọ ọ̀tún mọ òsì nínú ọwọ́ wọn.”—Jónà 4:11.
Kí ni a lè kọ́ láti inú ìrírí Jónà? Iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ kò fàyè gba iyè méjì. Bí a bá fòye mọ ìdarísọ́nà Jèhófà tí a sì fi ìgbọ́kànlé kíkún tẹ̀ lé e, a óò ṣe àṣeyọrí.—Òwe 3:5, 6.
Ẹ̀mí Nǹkan-Yóò-Dára Nígbà Ìpọ́njú
Ọba Dáfídì polongo pé: “Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣe búburú, kí ìwọ kí ó má ṣe ìlara nítorí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.” (Orin Dáfídì 37:1) Ní tòótọ́, ìyẹn jẹ́ ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n, nítorí lónìí, àìṣèdájọ́ òdodo àti ìwà wíwọ́ yí wa ká.—Oníwàásù 8:11.
Ṣùgbọ́n, bí a kò bá ṣe ìlara àwọn aláìṣòdodo pàápàá, ó rọrùn láti di ẹni tí a tán ní sùúrù nígbà tí a bá rí i tí àwọn ènìyàn búburú ń fìyà jẹ àwọn tí kò mọwọ́mẹsẹ̀ tàbí nígbà tí a kò bá fi ìdájọ́ òdodo bá àwa gan-an alára lò. Irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀ tilẹ̀ lè mú kí a mú ìṣarasíhùwà onírẹ̀wẹ̀sì tàbí ti oníyèméjì dàgbà. Nígbà tí a bá nímọ̀lára lọ́nà yẹn, kí ni ó yẹ kí a ṣe? Lákọ̀ọ́kọ́, a lè fi í sọ́kàn pé àwọn ẹni búburú kò lè fi àìkàsí ronú pé ẹ̀san kì yóò dé. Orin Dáfídì 37 ń bá a nìṣó láti mú un dá wa lójú ní ẹsẹ 2 pé: “A óò ké wọn [àwọn olùṣe búburú] lulẹ̀ láìpẹ́ bíi koríko, wọn óò sì rọ bí ewéko tútù.”
Ní àfikún sí i, a lè máa bá a nìṣó ní ṣíṣe rere, ní jíjẹ́ ẹlẹ́mìí nǹkan-yóò-dára, kí a sì dúró de Jèhófà. Onísáàmù náà ń bá a nìṣó pé: “Kúrò nínú ibi kí o sì máa ṣe rere; kí o sì máa jókòó láéláé. Nítorí tí Olúwa fẹ́ ìdájọ́, kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.”—Orin Dáfídì 37:27, 28.
Ojúlówó Ẹ̀mí Nǹkan-Yóò-Dára Máa Ń Borí!
Nígbà náà, ọjọ́ ọ̀la wa ńkọ́? Ìwé Bíbélì náà, Ìṣípayá, sọ fún wa nípa “àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ láìjìnnà.” Lára wọn, a fi ẹnì kan tí ó gun ẹṣin aláwọ̀-iná, tí ó ṣàpèjúwe ogun, hàn, tí yóò “mú àlàáfíà kúrò ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 1:1; 6:4.
Èrò kan tí ó wọ́pọ̀—tí ó sì jẹ́ ẹlẹ́mìí nǹkan-yóò-dára—tí wọ́n ní ní ilẹ̀ Britain nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní ni pé òun ni yóò jẹ́ ogun pàtàkì tí yóò jẹ́ àjàkẹ́yìn. Ní ọdún 1916, òṣèlú ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, David Lloyd George, sọ ojú abẹ níkòó. Ó wí pé: “Ogun yìí, bí ogun tí yóò tẹ̀ lé e, yóò jẹ́ ogun tí yóò fòpin sí ogun.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Òótọ́ ló sọ. Ṣe ni Ogun Àgbáyé Kejì mú kí ìmújáde àwọn ọ̀nà ìparun runlérùnnà tí ó burú gidigidi túbọ̀ yára kánkán. Ní èyí tí ó ju 50 ọdún lẹ́yìn náà, síbẹ̀ kò sí ìrètí pé ogun yóò dópin láìpẹ́.
Nínú ìwé Ìṣípayá kan náà, a kà nípa àwọn ẹlẹ́ṣin mìíràn—tí ń ṣàpẹẹrẹ ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn, àti ikú. (Ìṣípayá 6:5-8) Wọ́n jẹ́ apá mìíràn nínú àmì àwọn àkókò.—Mátíù 24:3-8.
Ìwọ̀nyí ha jẹ́ okùnfà ṣíṣiyèméjì bí? Rárá o, nítorí ìran náà tún ṣàpèjúwe “ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní ọrun kan; a sì fún un ní adé, ó sì jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.” (Ìṣípayá 6:2) Níhìn-ín ni a ti rí Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Ọba ọ̀run tí ń mú gbogbo ìwà ibi kúrò, ní gígẹṣinlọ láti fìdí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan múlẹ̀ kárí ayé.a
Gẹ́gẹ́ bí Ọba lọ́la, Jésù Kristi kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tí ó fi wà lórí ilẹ̀ ayé láti gbàdúrà fún Ìjọba yẹn. Bóyá a ti kọ́ ìwọ pàápàá láti ka “Bàbá Wa,” tàbí Àdúrà Olúwa. Nínú rẹ̀ ni a ti ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, pé kí a ṣe ìfẹ́ rẹ̀ níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run.—Mátíù 6:9-13.
Dípò kí ó gbìyànjú láti ṣàtúnṣe ètò nǹkan ìsinsìnyí, Jèhófà, tí ń gbégbèésẹ̀ nípasẹ̀ Mèsáyà Ọba rẹ̀, Kristi Jésù, yóò mú un kúrò pátápátá. Ní ipò rẹ̀, Jèhófà wí pé, “Èmi óò dá ọ̀run tuntun àti ayé tuntun: a kì yóò sì rántí àwọn ti ìṣáájú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí àyà.” Lábẹ́ àkóso Ìjọba ọ̀run náà, ilẹ̀ ayé yóò di ilé alálàáfíà àti aláyọ̀ fún ìran ènìyàn níbi tí ìgbésí ayé àti iṣẹ́ yóò ti máa mú ìdùnnú wá nígbà gbogbo. Jèhófà wí pé: “Kí inú yín kí ó . . . dùn títí láé nínú èyí tí èmi óò dá . . . àwọn ìyànfẹ́ mi yóò . . . jìfà iṣẹ́ ọwọ́ wọn.” (Aísáyà 65:17-22) Bí o bá gbé ìrètí rẹ fún ọjọ́ ọ̀la karí ìlérí tí kò lè kùnà yẹn, ìwọ yóò ní gbogbo ìdí láti jẹ́ ẹlẹ́mìí nǹkan-yóò-dára—nísinsìnyí àti títí láé!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìjíròrò ìran yìí, jọ̀wọ́ wo orí 16 nínú ìwé Revelation—Its Grand Climax At Hand!, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
H. G. Wells
[Credit Line]
Corbis-Bettmann