Ìwọ Ha Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Nǹkan-Yóò-Dára Tàbí Oníyèméjì?
“Ó JẸ́ àkókò tí ó lárinrin jù lọ, ó jẹ́ àkókò tí ó burú jù lọ, . . . sáà tí ó kún fún ìrètí ni, sáà àìnírètí ni, gbogbo nǹkan ni a ní, kò sí ohun tí a ní.” Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ àgbàyanu ìwé lítíréṣọ̀ náà, A Tale of Two Cities (Ìtàn Àròsọ Nípa Ìlú Méjì), ti Charles Dickens fi òye fi ìyàtọ̀ sí bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ṣe lè nípa lórí ìrònú wa, ìmọ̀lára wa, àti ojú ìwòye wa.
Ìlú méjì tí a tọ́ka sí ni London àti Paris nígbà pákáǹleke Ìyípadà Tegbòtigaga Ilẹ̀ Faransé. Lójú àwọn ará ìlú tí a ni lára ní ilẹ̀ Faransé ti ọ̀rúndún kejìdínlógún, ìpolongo ìyípadà tegbòtigaga náà nípa ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn jẹ́ “sáà tí ó kún fún ìrètí” ní ti gidi. Ṣùgbọ́n lójú ìjọba tí ó wà lóde tẹ́lẹ̀, tàbí ètò ìṣèlú tí ń fi ipò sílẹ̀, ó jẹ́ “sáà àìnírètí,” tí ó yọrí sí ikú àti ìparun.
Ṣé ó jẹ́ ẹlẹ́mìí nǹkan-yóò-dára ni tàbí oníyèméjì? Ó sinmi lórí ìhà tí o wà. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó ṣì ṣe rí.
Àkókò fún Àyẹ̀wò Ara Ẹni
Ìwọ ha jẹ́ ẹlẹ́mìí nǹkan-yóò-dára bí? Ìwọ ha máa ń wo ìhà tí ń múni láyọ̀ nínú ìgbésí ayé, ní fífojúsọ́nà nígbà gbogbo pé yóò dára bí? Tàbí o ha máa ń ní ìtẹ̀sí láti ṣiyè méjì, ní níní ojú ìwòye tí kò dára tó nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ, tí o ń retí ohun tí ó dára jù lọ ṣùgbọ́n lọ́wọ́ kan náà tí o ń retí ohun tí ó burú jù lọ?
Ní 60 ọdún sẹ́yìn, akọ̀tàn, ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà náà, James Branch Cabell, ṣàkópọ̀ àwọn èrò méjì tí ń forí gbárí náà lọ́nà yí pé: “Ẹni tí ó jẹ́ ẹlẹ́mìí nǹkan-yóò-dára ń polongo pé a ń gbé nínú àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tí ó dára jù lọ tí a lè rí; ẹni tí ó sì jẹ́ oníyèméjì kọminú pé òtítọ́ ni èyí.” Bí o bá ronú pé ojú ìwòye yìí jẹ́ ti aṣelámèyítọ́, ṣàyẹ̀wò tọ̀tún tòsì apá mẹ́ta péré nínú ayé òde òní bí a ti fi hàn nísàlẹ̀. Lẹ́yìn náà, ṣàyẹ̀wò ìhùwàpadà rẹ kínníkínní kí o sì bi ara rẹ pé, ‘Mo ha jẹ́ ẹlẹ́mìí nǹkan-yóò-dára tàbí oníyèméjì bí?’
Àlàáfíà Pípẹ́ Títí: Ibi mélòó tí ìjọ̀ngbọ̀n ti ń ṣẹlẹ̀ láyé ni o lè dárúkọ? Ireland, Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí, Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn, Burundi, Rwanda—ìwọ̀nyí ni ó tètè wá síni lọ́kàn. A ha lè yanjú ìwọ̀nyí àti àwọn ìjàkadì míràn láé láti mú kí àlàáfíà pípẹ́ títí, tí ó kárí ayé dájú bí? Ayé ha forí lé àlàáfíà bí?
Ipò Ọrọ̀ Ajé Tí Ó Fẹsẹ̀ Múlẹ̀: Ní ríretí ìṣọ̀kan ní ti ọ̀ràn ìnáwó nígbà tí ó bá fi di ọdún 1999, àwọn orílẹ̀ èdè tí ó jẹ́ ara Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ń kojú àwọn ìṣòro líle koko ní ti ọ̀wọ́n gógó ọjà àti yíyáwó lọ́wọ́ àwọn ará ìlú. Ní àwọn ibòmíràn, ìwà ìbàjẹ́ ń mú kí ètò ọrọ̀ ajé ti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Áfíríkà yìnrìn, níbi tí ọ̀wọ́n gógó ọjà ti ń gbé ẹrù ìnira tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé fara dà kani lórí, tí àwọn ìṣòro ẹ̀yà ìran ṣì ń pín àwọn ènìyàn níyà. Ipò ọrọ̀ ajé tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ karí ayé ha wà gẹ́rẹ́ níwájú bí?
Àìríṣẹ́ṣe: Nínú ìbò àpapọ̀ ti 1997, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì para pọ̀ láti rọ gbogbo ẹgbẹ́ ìṣèlú láti fún ìpèsè iṣẹ́ ní àfiyèsí gíga nínú àkọsílẹ̀ àwọn ohun àmúṣe wọn. Ṣùgbọ́n, bí èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn òṣìṣẹ́ lágbàáyé kò ti rí iṣẹ́ ṣe tàbí tí wọn kò rí iṣẹ́ ṣe tó, ìpèsè iṣẹ́ tí yóò wà pẹ́ títí—ní pàtàkì fún àwọn ọ̀dọ́ ha lè ṣeé ṣe bí?
Ẹ wo bí ó ti rọrùn tó láti jẹ́ oníyèméjì! Síbẹ̀ ìhà tí ń múni láyọ̀ ń bẹ, a sì ké sí ọ láti ṣàyẹ̀wò bí ó ti rọrùn láti mú ojú ìwòye ẹlẹ́mìí nǹkan-yóò-dára dàgbà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Ìyípadà Tegbòtigaga Ilẹ̀ Faransé
[Credit Line]
Láti inú ìwé Pictorial History of the World