ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 5/8 ojú ìwé 17-18
  • O Lè Gbara Rẹ Lọ́wọ́ Ẹ̀mí Pé Nǹkan Ò Ní Dára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Lè Gbara Rẹ Lọ́wọ́ Ẹ̀mí Pé Nǹkan Ò Ní Dára
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó O Ṣe Lè Gbara Rẹ̀ Lọ́wọ́ Ẹ̀mí Pé Nǹkan Ò Ní Dáa
  • Èrò Tó Dára Tí Ń Múni Ṣàṣeyọrí
  • 12 Àfojúsùn
    Jí!—2018
  • Báwo Ni Ọwọ́ Mi Ṣe Lè Tẹ Àwọn Àfojúsùn Mi?
    Jí!—2011
  • Fi Àwọn Ohun Tó Ò Ń lé Nípa Tẹ̀mí Yin Ẹlẹ́dàá Rẹ Lógo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Bọ́wọ́ Rẹ Ṣe Lè Tẹ Àwọn Àfojúsùn Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́run
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 5/8 ojú ìwé 17-18

O Lè Gbara Rẹ Lọ́wọ́ Ẹ̀mí Pé Nǹkan Ò Ní Dára

OJÚ wo lo fi máa ń wò ó, bí ọ̀nà ò bá gba ibi tó o fojú sí? Ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi gbà pé ohun tó máa pinnu ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn ni irú ẹ̀mí tó o ní. Gbogbo wa pátá la ní ibi tí bàtà ti ń ta wá lẹ́sẹ̀, ìṣòro wa kàn jura lọ ni. Kí ló wá dé tó fi dà bí i pé àwọn kan máa ń tètè borí ìṣòro tó ń bá wọn fínra tí wọ́n á sì túnra mú, nígbà tó jẹ́ pé káwọn míì máà tíì rí ìṣòro ni, wọ́n ti pa ohun tí wọ́n ń ṣe tì?

Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ò ń wáṣẹ́. O lọ síbi tí wọ́n ti fọ̀rọ̀ wá àwọn tí wọ́n fẹ́ gbà lẹ́nu wò, àmọ́ iṣẹ́ náà ò bọ́ sí ọ lọ́wọ́. Kí ni wàá rò pé kò jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́? O lè rò pé ìwọ gan-an ni wọn ò fẹ́, kó o sì wá máa rò pé ìṣòro tí wàá máa gbé kiri nìyẹn, kó o wá máa sọ fúnra rẹ pé, ‘Kò sẹ́ni tá fẹ́ gba irú mi yìí síṣẹ́. Mi ò tiẹ̀ lè ríṣẹ́ ni.’ Èyí tó tún wá burú jù ni pé o lè wá tìtorí àmúbọ́ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo yìí ro ara rẹ pin nínú gbogbo ohun tó o bá dáwọ́ lé kó o máa ronú pé, ‘Kò sí nǹkan kan tí mo lè ṣe yọrí. Mi ò wúlò fún ẹnì kankan.’ Gbogbo ìgbà tó o bá ti ń ronú bẹ́ẹ̀, mọ̀ pé ẹ̀mí pé nǹkan ò lè dáa lo ní yẹn.

Bó O Ṣe Lè Gbara Rẹ̀ Lọ́wọ́ Ẹ̀mí Pé Nǹkan Ò Ní Dáa

Báwo lo ṣe lè gbara ẹ lọ́wọ́ ẹ̀mí pé nǹkan ò ní dáa? Ìgbésẹ̀ pàtàkì àkọ́kọ́ tó yẹ kó o gbé ni pé kó o mọ̀ bí èrò bẹ́ẹ̀ bá ti ń sọ sí ọ lọ́kàn. Lẹ́yìn náà kó o tètè lé e jáde kúrò lọ́kàn rẹ. Ronú ohun mìíràn tó mọ́gbọ́n dání tó lè fà á tọ́wọ́ rẹ kò fi tẹ ohun tó ò ń lé. Bí àpẹẹrẹ, ṣé lóòótọ́ ni pé nítorí pé ẹnikẹ́ni ò ní gbà ọ́ síṣẹ́ ni wọn ò ṣe gbà ọ́? Ṣé kò lè jẹ́ pé wọ́n kàn ń fẹ́ ẹlòmíràn tó ní irú ìwé ẹ̀rí tí ìwọ ò ní ni?

Tó o bá ro gbogbo bọ́ràn ṣe rí gan-an látòkèdélẹ̀, wàá rí i pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an ò burú tó bó o ṣe ń rò ó. Ṣé kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ ọ́ níbì kan ti wá fi hàn pé o kò wúlò fún nǹkan míì mọ́ láyé, o ò ṣe ronú nípa àwọn apá ibòmíì tó o ti ń kẹ́sẹ járí nínú ìgbésí ayé rẹ, irú bí àwọn nǹkan tó o dáwọ́ lé nípa tẹ̀mí, àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, tàbí pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ? Mọ ọ̀nà tí wàá fi máa gbé èròkerò kúrò lọ́kàn rẹ, kó o máa wò ó bí ìgbà téèyàn “bá kàn ń kú sílẹ̀ kí ikú tó dé.” Ṣé o tiẹ̀ lè mọ̀ lóòótọ́ pé o kò ní ríṣẹ́ láé ni? Ọ̀pọ̀ nǹkan lo lè ṣe láti gbara ẹ lọ́wọ́ èrò òdì.

Èrò Tó Dára Tí Ń Múni Ṣàṣeyọrí

Láwọn ọdún ẹnu àìpẹ́ yìí, àwọn olùwádìí ti wá ọ̀nà mìíràn tí wọ́n á gbà máa ṣàlàyé ohun tó ń jẹ́ ìrètí bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtumọ̀ tí wọ́n fún un ò gbòòrò tó. Wọ́n ní ohun tó ń jẹ́ ìrètí ni ìgbàgbọ́ pé ọwọ́ rẹ yóò tẹ àwọn ohun tó ò ń lé. A ó rí i nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí pé ohun tó ń jẹ́ ìrètí ju bí wọ́n ṣe ṣàlàyé rẹ̀ yẹn lọ fíìfíì, àmọ́ ó tún láwọn ibì kan tá a ti lè lo ìtumọ̀ náà. Tá a bá ti apá ibẹ̀ yẹn wo ìrètí wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan a lè ní èrò tó dára tá sì múni ṣàṣeyọrí.

Ká tó lè gbà gbọ́ pé ọwọ́ wa á tẹ àwọn ohun tá à ń lépa, ó yẹ kó ti mọ́ wa lára láti máa lépa ohun kan kọ́wọ́ wa sì máa tẹ̀ ẹ́. Tó o bá rí i pé ọ̀ràn tìẹ ò rí bẹ́ẹ̀, a dáa kó o tètè rò ó dáadáa kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí lépa ohun kan. Dúró ná, ǹjẹ́ ohun kan tiẹ̀ wà tó ò ń lé? Tá à bá ṣọ́ra, làálàá kòókòó ìgbésí ayé lè gba gbogbo àkókò wa débi pé a ò ní lè ráyè ronú lórí ohun tá a fẹ́ gan-an nínú ìgbésí ayé, ìyẹn ohun tó jẹ wá lógún jù lọ. Tipẹ́tipẹ́ ni Bíbélì ti sọ̀rọ̀ lórí ìlànà pàtàkì yìí pẹ̀lú, ìyẹn pé ká máa ní ohun àkọ́múṣe, ó sọ pé: “Ẹ . . . máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.”—Fílípì 1:10.

Tá a bá ti ní àwọn ohun tá a kọ́kọ́ fẹ́ gbé ṣe, á wá rọrùn sí i láti pinnu àwọn ohun tó ṣe pàtàkì fún wa nínú ìgbésí ayé, bí àpẹẹrẹ, àwọn nǹkan tẹ̀mí, ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìdílé àti iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa. Àmọ́ o, ó ṣe pàtàkì pé ká má ṣe kó irin púpọ̀ bọná lẹ́ẹ̀kan náà, ká sì rí i pé kì í ṣe ohun tápá ò ní ká là ń lépa. Tó bá jẹ́ pé nǹkan tá ṣòro fún wa láti bá la gbé síwájú ara wa, ọkàn wa ò ní balẹ̀, kò sì ní pẹ́ sú wa. Nítorí náà, á dára ká dín àwọn ohun tá à ń lépa kù sí èyí tọ́wọ́ wa á tètè bà, tá ó sì lè máa ṣe díẹ̀díẹ̀.

Òwe àtijọ́ kan sọ pé: “Àyè kì í há adìyẹ kó máà dé ìdí àba rẹ̀.” Ó sì dà bí i pé òótọ́ díẹ̀ wà nínú òwe yẹn. Tá a bá ti ní àwọn ohun kan lọ́kàn tá a fẹ́ gbé ṣe, ohun tó kù wá kù láti lè bá a ni ìpinnu, ìyẹn ìfẹ́ àtọkànwá àti ìmúratán tá jẹ́ ká lè jára mọ́ ohun tá à ń ṣe. A lè jẹ́ kí ìpinnu wa lágbára sí i tá a bá ronú lórí bí ohun tá à ń lépa ti ṣe pàtàkì tó àtàwọn àǹfààní tá a máa rí níbẹ̀ tọ́wọ́ wa bá tẹ̀ ẹ́. Ìṣòro ò ní ṣaláì sí o, ṣùgbọ́n ṣe ló yẹ ká máa wò wọ́n bí ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ fún ìtẹ̀síwájú dípò ká máa kà wọ́n sí ibodè wáàsinmi.

Àmọ́ ṣá, ó yẹ ká tún ronú ọ̀nà tọ́wọ́ wa ó fi máa tẹ àwọn ohun tá a bá ń lépa. Òǹkọ̀wé C. R. Snyder, ẹni tó ti ṣe ìwádìí jinlẹ̀ lórí ìwúlò ìrètí, sọ pé ó yẹ ká máa wá oríṣiríṣi ọ̀nà tọ́wọ́ wa ó fi máa tẹ àwọn ohun tá a bá ń lépa. Ìyẹn á lè jẹ́ ká yẹ ọ̀nà mìíràn wò bí ọ̀nà kan bá dí, nítorí pé ọ̀nà kan ò wọjà.

Snyder tún dábàá pé ó yẹ ká kọ́ bá a ṣe ń fi ìkan dí ìkan. Tó bá di pé ohun tá à ń lépa fẹ́ bọ́ rẹ́lẹ̀, dídààmú nípa rẹ̀ á wulẹ̀ mú ká rẹ̀wẹ̀sì ni. Àmọ́, tá a bá fi ìlépa mìíràn tí ò pọ̀ jura lọ rọ́pò rẹ̀, a óò lè ní ohun mìíràn tí yóò máa fún wa nírètí.

Àpẹẹrẹ kan wà nínú Bíbélì tá jẹ́ kí ohun tá à ń sọ yìí yé wa yékéyéké. Ó wu Ọba Dáfídì bíi kó kọ́ tẹ́ńpìlì fún Jèhófà, Ọlọ́run rẹ̀. Àmọ́, Ọlọ́run sọ fún Dáfídì pé Sólómọ́nì ọmọkùnrin rẹ̀ ló máa láǹfààní àtikọ́ ọ. Kàkà kí Dáfídì wá kárí sọ tàbí kó kàn máa ṣe kìràkìtà nídìí àléèbá, ńṣe ló dáwọ́ lé àwọn nǹkan míì. Ó lo gbogbo agbára ẹ̀ láti kó owó àti gbogbo ohun èlò tí ọmọ rẹ̀ máa nílò láti parí iṣẹ́ ilé náà jọ.—1 Àwọn Ọba 8:17-19; 1 Kíróníkà 29:3-7.

Kódà, tá a bá ti bá a débi tí ìrètí wa ti lágbára láti borí ẹ̀mí pé nǹkan ò ní dáa, tá a sì ti wá lérò tó dára, tó lè múni ṣàṣeyọrí pàápàá, ó tún ṣì lè dà bí ẹni pé àìnírètí ń dà wá láàmú. Kí ló lè fà á? Ohun tó wà níbẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó ń fa àìnírètí láyé yìí kọjá àwọn nǹkan tí agbára wá lè ká pátápátá. Tá a bá wá ronú nípa àwọn àrágbá yamúyamù ìṣòro tó ń gbo aráyé mọ́lẹ̀ yìí, ìyẹn àwọn bí òṣì, ogun, àìsídàájọ́ òdodo àti bí ikú òun àrùn ṣe ń fẹjú mọ́ wa, báwo la ṣe lè ní èrò tó dára lọ́kàn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Bí wọn ò bá gbà ọ́ níbi iṣẹ́ kan, ṣé o máa ń ro ara rẹ pin pé o ò lè ríṣẹ́ mọ́?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ọba Dáfídì térò rẹ̀ pa nígbà tó dọ̀rọ̀ pípinnu ohun tó máa ṣe

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́