ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Sámúẹ́lì 7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Sámúẹ́lì

      • Dáfídì kò ní lè kọ́ tẹ́ńpìlì (1-7)

      • Ọlọ́run bá Dáfídì dá májẹ̀mú ìjọba (8-17)

      • Àdúrà ìdúpẹ́ tí Dáfídì gbà (18-29)

2 Sámúẹ́lì 7:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 17:1

2 Sámúẹ́lì 7:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 12:1; 1Kr 29:29
  • +2Sa 5:11
  • +2Sa 6:17

2 Sámúẹ́lì 7:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 8:17; 1Kr 17:2; 22:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2012, ojú ìwé 24-25

2 Sámúẹ́lì 7:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:3; 8:17-19; 1Kr 17:4-6; 22:7, 8

2 Sámúẹ́lì 7:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “rìn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 18:1
  • +Ẹk 40:18, 34

2 Sámúẹ́lì 7:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 16:11
  • +2Sa 5:2; 1Kr 17:7-10; 28:4; Sm 78:70, 71

2 Sámúẹ́lì 7:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ké.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:14; 2Sa 5:10
  • +2Sa 22:1; Sm 18:37
  • +1Kr 14:2, 17

2 Sámúẹ́lì 7:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 2:14; Sm 89:20, 22

2 Sámúẹ́lì 7:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sọ ìdílé rẹ di ìdílé tó ń jọba.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 2:16
  • +Di 25:19
  • +1Ọb 2:24; Sm 89:4

2 Sámúẹ́lì 7:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “èso.”

  • *

    Ní Héb., “ẹni tó máa jáde láti inú rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 2:1
  • +Jẹ 49:10; 1Ọb 8:20; 1Kr 17:11-14; Sm 132:11; Ais 9:7; 11:1; Mt 21:9; 22:42; Lk 1:32, 33; Jo 7:42; Iṣe 2:30

2 Sámúẹ́lì 7:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 5:5; 6:12; Sek 6:12, 13
  • +1Ọb 1:37; 1Kr 22:10; 28:7; Sm 89:4, 36

2 Sámúẹ́lì 7:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Ádámù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 28:6; Mt 3:17; Heb 1:5
  • +Sm 89:30, 32; Jer 52:3

2 Sámúẹ́lì 7:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 15:23, 26

2 Sámúẹ́lì 7:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 45:6; 89:36; Da 2:44; Heb 1:8; Ifi 11:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2010, ojú ìwé 20

    12/15/2006, ojú ìwé 4

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 123-126

2 Sámúẹ́lì 7:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 17:15

2 Sámúẹ́lì 7:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 17:16-22

2 Sámúẹ́lì 7:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “òfin.”

2 Sámúẹ́lì 7:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 16:7; Sm 17:3

2 Sámúẹ́lì 7:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ohun tó bá ìfẹ́ rẹ mu.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 25:14

2 Sámúẹ́lì 7:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 3:24; 1Kr 16:25
  • +Ẹk 15:11; Sm 83:18
  • +Di 4:35

2 Sámúẹ́lì 7:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:7; Sm 147:19, 20
  • +Ẹk 3:8; 19:5; Ais 63:9
  • +Ẹk 9:16
  • +Di 10:21

2 Sámúẹ́lì 7:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 26:18
  • +Ẹk 15:2

2 Sámúẹ́lì 7:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 17:23-27; Sm 89:20, 28

2 Sámúẹ́lì 7:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 29:11; Sm 72:19; Mt 6:9; Jo 12:28
  • +Ais 9:7; Jer 33:22

2 Sámúẹ́lì 7:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sọ ìdílé rẹ di ìdílé tó ń jọba.”

  • *

    Ní Héb., “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 7:11

2 Sámúẹ́lì 7:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 23:19; Sm 89:35; 132:11; Jo 17:17

2 Sámúẹ́lì 7:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 89:20, 36; 132:12
  • +2Sa 22:51; Sm 72:17

Àwọn míì

2 Sám. 7:11Kr 17:1
2 Sám. 7:22Sa 12:1; 1Kr 29:29
2 Sám. 7:22Sa 5:11
2 Sám. 7:22Sa 6:17
2 Sám. 7:31Ọb 8:17; 1Kr 17:2; 22:7
2 Sám. 7:51Ọb 5:3; 8:17-19; 1Kr 17:4-6; 22:7, 8
2 Sám. 7:6Joṣ 18:1
2 Sám. 7:6Ẹk 40:18, 34
2 Sám. 7:81Sa 16:11
2 Sám. 7:82Sa 5:2; 1Kr 17:7-10; 28:4; Sm 78:70, 71
2 Sám. 7:91Sa 18:14; 2Sa 5:10
2 Sám. 7:92Sa 22:1; Sm 18:37
2 Sám. 7:91Kr 14:2, 17
2 Sám. 7:10Ond 2:14; Sm 89:20, 22
2 Sám. 7:11Ond 2:16
2 Sám. 7:11Di 25:19
2 Sám. 7:111Ọb 2:24; Sm 89:4
2 Sám. 7:121Ọb 2:1
2 Sám. 7:12Jẹ 49:10; 1Ọb 8:20; 1Kr 17:11-14; Sm 132:11; Ais 9:7; 11:1; Mt 21:9; 22:42; Lk 1:32, 33; Jo 7:42; Iṣe 2:30
2 Sám. 7:131Ọb 5:5; 6:12; Sek 6:12, 13
2 Sám. 7:131Ọb 1:37; 1Kr 22:10; 28:7; Sm 89:4, 36
2 Sám. 7:141Kr 28:6; Mt 3:17; Heb 1:5
2 Sám. 7:14Sm 89:30, 32; Jer 52:3
2 Sám. 7:151Sa 15:23, 26
2 Sám. 7:16Sm 45:6; 89:36; Da 2:44; Heb 1:8; Ifi 11:15
2 Sám. 7:171Kr 17:15
2 Sám. 7:181Kr 17:16-22
2 Sám. 7:201Sa 16:7; Sm 17:3
2 Sám. 7:21Sm 25:14
2 Sám. 7:22Di 3:24; 1Kr 16:25
2 Sám. 7:22Ẹk 15:11; Sm 83:18
2 Sám. 7:22Di 4:35
2 Sám. 7:23Di 4:7; Sm 147:19, 20
2 Sám. 7:23Ẹk 3:8; 19:5; Ais 63:9
2 Sám. 7:23Ẹk 9:16
2 Sám. 7:23Di 10:21
2 Sám. 7:24Di 26:18
2 Sám. 7:24Ẹk 15:2
2 Sám. 7:251Kr 17:23-27; Sm 89:20, 28
2 Sám. 7:261Kr 29:11; Sm 72:19; Mt 6:9; Jo 12:28
2 Sám. 7:26Ais 9:7; Jer 33:22
2 Sám. 7:272Sa 7:11
2 Sám. 7:28Nọ 23:19; Sm 89:35; 132:11; Jo 17:17
2 Sám. 7:29Sm 89:20, 36; 132:12
2 Sám. 7:292Sa 22:51; Sm 72:17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Sámúẹ́lì 7:1-29

Sámúẹ́lì Kejì

7 Nígbà tí ọba ti ń gbé inú ilé* rẹ̀,+ tí Jèhófà sì ti fún un ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó yí i ká, 2 ọba sọ fún wòlíì Nátánì+ pé: “Mò ń gbé inú ilé tí wọ́n fi igi kédárì kọ́+ nígbà tí Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ wà láàárín àwọn aṣọ àgọ́.”+ 3 Nátánì dá ọba lóhùn pé: “Lọ ṣe ohunkóhun tó wà lọ́kàn rẹ, nítorí Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.”+

4 Lóru ọjọ́ yẹn, Jèhófà bá Nátánì sọ̀rọ̀, ó ní: 5 “Lọ sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ṣé ìwọ ló máa kọ́ ilé tí màá máa gbé  + fún mi ni? 6 Nítorí mi ò gbé inú ilé láti ọjọ́ tí mo ti mú àwọn èèyàn Ísírẹ́lì jáde kúrò ní Íjíbítì títí di òní yìí,+ àmọ́ mò ń lọ* káàkiri nínú àgọ́ àti nínú àgọ́ ìjọsìn.+ 7 Ní gbogbo àkókò tí mò ń bá gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn, ṣé mo fìgbà kankan sọ fún ọ̀kan lára àwọn olórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí mo yàn láti máa bójú tó àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bí àgùntàn, pé, ‘Kí ló dé tí ẹ ò fi kọ́ ilé onígi kédárì fún mi?’”’ 8 Ní báyìí, sọ fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Mo mú ọ láti ibi ìjẹko, pé kí o má da agbo ẹran mọ́,+ kí o lè wá di aṣáájú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.+ 9 Màá wà pẹ̀lú rẹ níbikíbi tí o bá lọ,+ màá sì mú* gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ kúrò níwájú rẹ;+ màá jẹ́ kí orúkọ rẹ lókìkí gan-an+ bí orúkọ àwọn ẹni ńlá tó wà láyé. 10 Màá yan ibì kan fún àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì, màá fìdí wọn kalẹ̀, wọ́n á sì máa gbé ibẹ̀ láìsí ìyọlẹ́nu mọ́; àwọn ẹni burúkú kò ní pọ́n wọn lójú mọ́, bí wọ́n ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀,+ 11 láti ọjọ́ tí mo ti yan àwọn onídàájọ́+ fún àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì. Màá sì fún ọ ní ìsinmi kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ.+

“‘“Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà sọ fún ọ pé, Jèhófà yóò kọ́ ilé fún ọ.*+ 12 Nígbà tí o bá kú,+ tí o sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ, nígbà náà, màá gbé ọmọ* rẹ dìde lẹ́yìn rẹ, ọmọ ìwọ fúnra rẹ,* màá sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.+ 13 Òun ló máa kọ́ ilé fún orúkọ mi,+ màá sì fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.+ 14 Màá di bàbá rẹ̀, á sì di ọmọ mi.+ Tí ó bá ṣe àìtọ́, màá fi ọ̀pá àti ẹgba àwọn ọmọ aráyé*+ bá a wí. 15 Ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kò ní kúrò lára rẹ̀ bí mo ṣe mú un kúrò lára Sọ́ọ̀lù,+ ẹni tí mo mú kúrò níwájú rẹ. 16 Ilé rẹ àti ìjọba rẹ máa fẹsẹ̀ múlẹ̀ títí láé níwájú rẹ; ìtẹ́ rẹ á sì fìdí múlẹ̀ títí láé.”’”+

17 Nátánì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí àti gbogbo ìran tó rí+ fún Dáfídì.

18 Ni Ọba Dáfídì bá wọlé, ó jókòó níwájú Jèhófà, ó sì sọ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ta ni mí? Kí ni ilé mi sì já mọ́ tí o fi mú mi dé ibi tí mo dé yìí?+ 19 Àfi bíi pé ìyẹn ò tó, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, o tún sọ nípa ilé ìránṣẹ́ rẹ títí lọ dé ọjọ́ iwájú tó jìnnà; èyí sì jẹ́ ìtọ́ni* fún gbogbo aráyé, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. 20 Kí ni Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ tún lè sọ fún ọ nígbà tó jẹ́ pé o mọ̀ mí dáadáa,+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ? 21 Nítorí ọ̀rọ̀ rẹ àti nítorí ohun tó wà lọ́kàn rẹ* ni o fi ṣe gbogbo àwọn ohun ńlá yìí, tí o sì jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ+ mọ̀ nípa wọn. 22 Ìdí nìyẹn tí o fi tóbi gan-an,+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ. Kò sí ẹni tó dà bí rẹ,+ kò sì sí Ọlọ́run kankan àfi ìwọ;+ gbogbo ohun tí a ti fi etí wa gbọ́ jẹ́rìí sí i. 23 Orílẹ̀-èdè wo ní gbogbo ayé ló dà bí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì?+ Ọlọ́run lọ rà wọ́n pa dà nítorí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ̀,+ ó sì ṣe orúkọ fún ara rẹ̀+ bí ó ṣe ń ṣe àwọn ohun ńlá àti àwọn ohun àgbàyanu fún wọn.+ O lé àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ọlọ́run wọn jáde nítorí àwọn èèyàn rẹ, tí o rà pa dà fún ara rẹ láti Íjíbítì. 24 O fìdí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì múlẹ̀ láti máa jẹ́ àwọn èèyàn rẹ títí lọ;+ ìwọ Jèhófà sì di Ọlọ́run wọn.+

25 “Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run, mú ìlérí tí o ṣe nípa ìránṣẹ́ rẹ àti nípa ilé rẹ̀ ṣẹ títí láé, kí o sì ṣe ohun tí o ṣèlérí.+ 26 Kí a gbé orúkọ rẹ ga títí láé,+ kí àwọn èèyàn lè sọ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni Ọlọ́run Ísírẹ́lì,’ kí ilé Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ sì fìdí múlẹ̀ níwájú rẹ.+ 27 Nítorí ìwọ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti fi han ìránṣẹ́ rẹ pé, ‘Màá kọ́ ilé fún ọ.’*+ Ìdí nìyẹn tí ìránṣẹ́ rẹ fi ní ìgboyà* láti gba àdúrà yìí sí ọ. 28 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìwọ ni Ọlọ́run tòótọ́, òtítọ́+ ni ọ̀rọ̀ rẹ, o sì ti ṣèlérí àwọn ohun rere yìí fún ìránṣẹ́ rẹ. 29 Nítorí náà, jẹ́ kí ó dùn mọ́ ọ nínú láti bù kún ilé ìránṣẹ́ rẹ, sì jẹ́ kí ó máa wà títí láé níwájú rẹ;+ nítorí ìwọ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ti ṣèlérí, sì jẹ́ kí ìbùkún rẹ máa wà lórí ilé ìránṣẹ́ rẹ títí láé.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́