ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jóṣúà 15
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jóṣúà

      • Ogún Júdà (1-12)

      • Ọmọbìnrin Kélẹ́bù gba ilẹ̀ (13-19)

      • Àwọn ìlú Júdà (20-63)

Jóṣúà 15:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 26:55
  • +Jẹ 36:19

Jóṣúà 15:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Òkun Òkú.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 34:2, 3

Jóṣúà 15:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 1:36
  • +Nọ 34:4

Jóṣúà 15:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Òkun Ńlá, Òkun Mẹditaréníà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 34:2, 5
  • +1Ọb 8:65

Jóṣúà 15:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Òkun Òkú.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 34:12

Jóṣúà 15:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 18:19, 20
  • +Joṣ 18:21, 22
  • +Joṣ 18:17, 20

Jóṣúà 15:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 7:26
  • +Joṣ 5:8, 9
  • +Joṣ 18:17, 20
  • +1Ọb 1:9

Jóṣúà 15:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 18:16, 20; 2Ọb 23:10; Jer 7:31
  • +Ond 1:21
  • +Joṣ 18:28; Ond 19:10

Jóṣúà 15:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 18:15, 20
  • +Joṣ 9:16, 17; 2Sa 6:2; 1Kr 13:6

Jóṣúà 15:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 21:8, 16
  • +Joṣ 19:43, 48; Ond 14:1, 2; 2Kr 28:18

Jóṣúà 15:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 5:10; 7:14; 2Ọb 1:2

Jóṣúà 15:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Òkun Mẹditaréníà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 34:2, 6; Di 11:24

Jóṣúà 15:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 13:30; Di 1:36
  • +Jẹ 23:2; 35:27; Joṣ 20:7; 21:11, 12

Jóṣúà 15:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 13:33; Joṣ 11:21
  • +Nọ 13:22; Ond 1:10, 20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 9/2021,

Jóṣúà 15:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 10:38, 39

Jóṣúà 15:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 3:9-11
  • +1Kr 4:13
  • +1Kr 2:49

Jóṣúà 15:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ó pàtẹ́wọ́ látorí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 1:14, 15

Jóṣúà 15:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Négébù.”

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Bàsíà (Abọ́) Omi.”

Jóṣúà 15:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 34:2, 3; Di 2:5

Jóṣúà 15:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 19:1, 2

Jóṣúà 15:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 11:25, 26

Jóṣúà 15:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 21:31; Joṣ 19:1-3

Jóṣúà 15:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 14:44, 45; Joṣ 19:1, 4; Ond 1:17

Jóṣúà 15:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 19:1, 5; 1Sa 27:5, 6; 1Kr 12:1

Jóṣúà 15:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 19:1, 7; Ne 11:25, 29

Jóṣúà 15:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 1:9
  • +Joṣ 19:40, 41; Ond 16:31

Jóṣúà 15:35

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 22:1
  • +1Sa 17:1

Jóṣúà 15:36

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Gédérà àtàwọn ọgbà àgùntàn rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 17:52

Jóṣúà 15:39

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 18:14

Jóṣúà 15:41

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 10:28

Jóṣúà 15:42

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 10:29; 2Ọb 8:22
  • +Joṣ 19:1, 7

Jóṣúà 15:45

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìlú tó yí i ká.”

Jóṣúà 15:47

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìlú tó yí i ká.”

  • *

    Ìyẹn, Òkun Mẹditaréníà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 5:1
  • +Jẹ 10:19
  • +Nọ 34:2, 5

Jóṣúà 15:48

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 21:8, 14

Jóṣúà 15:50

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 6:57

Jóṣúà 15:51

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 11:16
  • +2Sa 15:12

Jóṣúà 15:54

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 14:15

Jóṣúà 15:55

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 23:25; 25:2, 3
  • +1Sa 23:14

Jóṣúà 15:57

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 38:12

Jóṣúà 15:60

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 9:16, 17; 18:11, 14; 1Sa 7:1

Jóṣúà 15:61

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 18:21, 22

Jóṣúà 15:62

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 23:29

Jóṣúà 15:63

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 10:15, 16
  • +1Kr 11:4
  • +Nọ 33:55; Ond 1:8, 21; 19:11; 2Sa 5:6

Àwọn míì

Jóṣ. 15:1Nọ 26:55
Jóṣ. 15:1Jẹ 36:19
Jóṣ. 15:2Nọ 34:2, 3
Jóṣ. 15:3Ond 1:36
Jóṣ. 15:3Nọ 34:4
Jóṣ. 15:4Nọ 34:2, 5
Jóṣ. 15:41Ọb 8:65
Jóṣ. 15:5Nọ 34:12
Jóṣ. 15:6Joṣ 18:19, 20
Jóṣ. 15:6Joṣ 18:21, 22
Jóṣ. 15:6Joṣ 18:17, 20
Jóṣ. 15:7Joṣ 7:26
Jóṣ. 15:7Joṣ 5:8, 9
Jóṣ. 15:7Joṣ 18:17, 20
Jóṣ. 15:71Ọb 1:9
Jóṣ. 15:8Joṣ 18:16, 20; 2Ọb 23:10; Jer 7:31
Jóṣ. 15:8Ond 1:21
Jóṣ. 15:8Joṣ 18:28; Ond 19:10
Jóṣ. 15:9Joṣ 18:15, 20
Jóṣ. 15:9Joṣ 9:16, 17; 2Sa 6:2; 1Kr 13:6
Jóṣ. 15:10Joṣ 21:8, 16
Jóṣ. 15:10Joṣ 19:43, 48; Ond 14:1, 2; 2Kr 28:18
Jóṣ. 15:111Sa 5:10; 7:14; 2Ọb 1:2
Jóṣ. 15:12Nọ 34:2, 6; Di 11:24
Jóṣ. 15:13Nọ 13:30; Di 1:36
Jóṣ. 15:13Jẹ 23:2; 35:27; Joṣ 20:7; 21:11, 12
Jóṣ. 15:14Nọ 13:33; Joṣ 11:21
Jóṣ. 15:14Nọ 13:22; Ond 1:10, 20
Jóṣ. 15:15Joṣ 10:38, 39
Jóṣ. 15:17Ond 3:9-11
Jóṣ. 15:171Kr 4:13
Jóṣ. 15:171Kr 2:49
Jóṣ. 15:18Ond 1:14, 15
Jóṣ. 15:21Nọ 34:2, 3; Di 2:5
Jóṣ. 15:26Joṣ 19:1, 2
Jóṣ. 15:27Ne 11:25, 26
Jóṣ. 15:28Jẹ 21:31; Joṣ 19:1-3
Jóṣ. 15:30Nọ 14:44, 45; Joṣ 19:1, 4; Ond 1:17
Jóṣ. 15:31Joṣ 19:1, 5; 1Sa 27:5, 6; 1Kr 12:1
Jóṣ. 15:32Joṣ 19:1, 7; Ne 11:25, 29
Jóṣ. 15:33Ond 1:9
Jóṣ. 15:33Joṣ 19:40, 41; Ond 16:31
Jóṣ. 15:351Sa 22:1
Jóṣ. 15:351Sa 17:1
Jóṣ. 15:361Sa 17:52
Jóṣ. 15:392Ọb 18:14
Jóṣ. 15:41Joṣ 10:28
Jóṣ. 15:42Joṣ 10:29; 2Ọb 8:22
Jóṣ. 15:42Joṣ 19:1, 7
Jóṣ. 15:471Sa 5:1
Jóṣ. 15:47Jẹ 10:19
Jóṣ. 15:47Nọ 34:2, 5
Jóṣ. 15:48Joṣ 21:8, 14
Jóṣ. 15:501Kr 6:57
Jóṣ. 15:51Joṣ 11:16
Jóṣ. 15:512Sa 15:12
Jóṣ. 15:54Joṣ 14:15
Jóṣ. 15:551Sa 23:25; 25:2, 3
Jóṣ. 15:551Sa 23:14
Jóṣ. 15:57Jẹ 38:12
Jóṣ. 15:60Joṣ 9:16, 17; 18:11, 14; 1Sa 7:1
Jóṣ. 15:61Joṣ 18:21, 22
Jóṣ. 15:621Sa 23:29
Jóṣ. 15:63Jẹ 10:15, 16
Jóṣ. 15:631Kr 11:4
Jóṣ. 15:63Nọ 33:55; Ond 1:8, 21; 19:11; 2Sa 5:6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
  • 39
  • 40
  • 41
  • 42
  • 43
  • 44
  • 45
  • 46
  • 47
  • 48
  • 49
  • 50
  • 51
  • 52
  • 53
  • 54
  • 55
  • 56
  • 57
  • 58
  • 59
  • 60
  • 61
  • 62
  • 63
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jóṣúà 15:1-63

Jóṣúà

15 Ilẹ̀ tí wọ́n pín+ fún ẹ̀yà Júdà ní ìdílé-ìdílé lọ dé ààlà Édómù,+ aginjù Síínì, dé ìpẹ̀kun Négébù lápá gúúsù. 2 Ààlà wọn lápá gúúsù bẹ̀rẹ̀ láti ìkángun Òkun Iyọ̀,*+ láti ibi tí omi ti ya wọ ilẹ̀, tó dojú kọ gúúsù. 3 Ó sì lọ sápá gúúsù dé ibi tí wọ́n ń gbà gòkè ní Ákírábímù,+ ó dé Síínì, ó gba gúúsù lọ sí Kadeṣi-báníà,+ ó dé Hésírónì, lọ dé Ádáárì, ó sì yí gba ọ̀nà Káríkà. 4 Ó tún lọ dé Ásímónì,+ títí dé Àfonífojì Íjíbítì,+ ààlà náà sì parí sí Òkun.* Èyí ni ààlà wọn lápá gúúsù.

5 Ààlà wọn lápá ìlà oòrùn jẹ́ Òkun Iyọ̀* títí dé ìpẹ̀kun Jọ́dánì, ààlà náà ní igun apá àríwá jẹ́ ibi tí òkun ti ya wọ ilẹ̀, ní ìpẹ̀kun Jọ́dánì.+ 6 Ààlà náà lọ dé Bẹti-hógílà,+ ó sì kọjá lọ lápá àríwá Bẹti-árábà,+ ààlà náà sì dé ibi òkúta Bóhánì+ ọmọ Rúbẹ́nì. 7 Ààlà náà tún dé Débírì ní Àfonífojì* Ákórì,+ ó sì yí gba apá àríwá lọ sí Gílígálì,+ tó wà níwájú ibi tí wọ́n ń gbà gòkè ní Ádúmímù, ní gúúsù àfonífojì, ààlà náà dé ibi omi Ẹ́ń-ṣímẹ́ṣì,+ ó sì parí sí Ẹ́ń-rógélì.+ 8 Ààlà náà dé Àfonífojì Ọmọ Hínómù,+ ó dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn ará Jébúsì+ ní gúúsù, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,+ ààlà náà dé orí òkè tó dojú kọ Àfonífojì Hínómù lápá ìwọ̀ oòrùn, èyí tó wà ní ìkángun Àfonífojì* Réfáímù lápá àríwá. 9 Wọ́n pààlà náà látorí òkè dé ibi ìsun omi Néfítóà,+ ó sì lọ dé àwọn ìlú Òkè Éfúrónì; wọ́n tún pààlà dé Báálà, ìyẹn Kiriati-jéárímù.+ 10 Ààlà náà yí láti Báálà gba apá ìwọ̀ oòrùn lọ sí Òkè Séírì, ó kọjá lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Jéárímù ní àríwá, ìyẹn Kẹ́sálónì, ó lọ sí Bẹti-ṣémẹ́ṣì,+ ó sì dé Tímúnà.+ 11 Ààlà náà tún lọ dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Ẹ́kírónì+ lápá àríwá, wọ́n sì pààlà náà dé Ṣíkẹ́rónì, ó kọjá lọ sí Òkè Báálà, ó dé Jábínéélì, ààlà náà sì parí sí òkun.

12 Ààlà náà lápá ìwọ̀ oòrùn ni Òkun Ńlá*+ àti èbúté rẹ̀. Èyí ni ààlà àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà ní ìdílé-ìdílé yí ká.

13 Ó fún Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè, ní ìpín láàárín àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Jóṣúà, ìpín náà ni Kiriati-ábà, (Ábà ni bàbá Ánákì), ìyẹn Hébúrónì.+ 14 Kélẹ́bù lé àwọn ọmọ Ánákì+ mẹ́ta kúrò níbẹ̀, ìyẹn: Ṣéṣáì, Áhímánì àti Tálímáì,+ àwọn àtọmọdọ́mọ Ánákì. 15 Ó sì gòkè látibẹ̀ lọ bá àwọn tó ń gbé Débírì+ jà. (Kiriati-séférì ni Débírì ń jẹ́ tẹ́lẹ̀.) 16 Kélẹ́bù sọ pé: “Ẹni tó bá pa Kiriati-séférì run, tó sì gbà á, màá fún un ní Ákúsà ọmọ mi pé kó fi ṣe aya.” 17 Ótíníẹ́lì+ ọmọ Kénásì,+ arákùnrin Kélẹ́bù sì gbà á. Torí náà, ó fún un ní Ákúsà+ ọmọ rẹ̀ pé kó fi ṣe aya. 18 Nígbà tí ọmọbìnrin náà ń lọ sílé, ó rọ ọmọkùnrin náà pé kó tọrọ ilẹ̀ lọ́wọ́ bàbá òun. Ọmọbìnrin náà wá sọ̀ kalẹ̀ látorí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀.* Kélẹ́bù sì bi í pé: “Kí lo fẹ́?”+ 19 Ó sọ pé: “Jọ̀ọ́, bù kún mi, o ti fún mi ní ilẹ̀ kan ní gúúsù;* tún fún mi ní Guloti-máímù.”* Torí náà, ó fún un ní Gúlótì Òkè àti Gúlótì Ìsàlẹ̀.

20 Èyí ni ogún ẹ̀yà Júdà ní ìdílé-ìdílé.

21 Àwọn ìlú tó wà ní ìkángun ẹ̀yà Júdà lápá ibi tí ààlà Édómù+ wà ní gúúsù nìyí: Kábúséélì, Édérì, Jágúrì, 22 Kínà, Dímónà, Ádádà, 23 Kédéṣì, Hásórì, Ítínánì, 24 Sífù, Télémù, Béálótì, 25 Hasori-hádátà àti Kerioti-hésírónì, ìyẹn Hásórì, 26 Ámámù, Ṣímà, Móládà,+ 27 Hasari-gádà, Hẹ́ṣímónì, Bẹti-pélétì,+ 28 Hasari-ṣúálì, Bíá-ṣébà,+ Bisiotáyà, 29 Báálà, Ímù, Ésémù, 30 Élítóládì, Kẹ́sílì, Hóómà,+ 31 Síkílágì,+ Mádímánà, Sánsánà, 32 Lẹ́báótì, Ṣílíhímù, Áyínì àti Rímónì,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

33 Ní Ṣẹ́fẹ́là,+ àwọn ìlú náà ni: Éṣítáólì, Sórà,+ Áṣínà, 34 Sánóà, Ẹ́ń-gánímù, Tápúà, Énámù, 35 Jámútì, Ádúlámù,+ Sókọ̀, Ásékà,+ 36 Ṣááráímù,+ Ádítáímù àti Gédérà pẹ̀lú Gédérótáímù,* gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́rìnlá (14), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

37 Sénánì, Hádáṣà, Migidali-gádì, 38 Díléánì, Mísípè, Jókítéélì, 39 Lákíṣì,+ Bósíkátì, Ẹ́gílónì, 40 Kábónì, Lámámù, Kítílíṣì, 41 Gédérótì, Bẹti-dágónì, Náámà àti Mákédà,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́rìndínlógún (16), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

42 Líbínà,+ Étérì, Áṣánì,+ 43 Ífítà, Áṣínà, Nésíbù, 44 Kéílà, Ákísíbù àti Máréṣà, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́sàn-án pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

45 Ẹ́kírónì, àwọn àrọko rẹ̀* àtàwọn ìgbèríko rẹ̀; 46 láti Ẹ́kírónì sí apá ìwọ̀ oòrùn, gbogbo ibi tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Áṣídódì pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

47 Áṣídódì,+ àwọn àrọko rẹ̀* àti àwọn ìgbèríko rẹ̀; Gásà,+ àwọn àrọko rẹ̀ àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, dé Àfonífojì Íjíbítì àti Òkun Ńlá* pẹ̀lú ibi tó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.+

48 Ní agbègbè olókè, Ṣámírù, Játírì,+ Sókọ̀, 49 Dánà, Kiriati-sánà, ìyẹn Débírì, 50 Ánábù, Éṣítémò,+ Ánímù, 51 Góṣénì,+ Hólónì àti Gílò,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mọ́kànlá (11), pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

52 Árábù, Dúmà, Éṣánì, 53 Jánímù, Bẹti-tápúà, Áfékà, 54 Húmítà, Kiriati-ábà, ìyẹn Hébúrónì+ àti Síórì, gbógbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́sàn-án pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

55 Máónì,+ Kámẹ́lì, Sífù,+ Jútà, 56 Jésírẹ́lì, Jókídéámù, Sánóà, 57 Kénì, Gíbíà àti Tímúnà;+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́wàá pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

58 Hálíhúlù, Bẹti-súrì, Gédórì, 59 Máárátì, Bẹti-ánótì àti Élítékónì, gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́fà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

60 Kiriati-báálì, ìyẹn Kiriati-jéárímù+ àti Rábà, ó jẹ́ ìlú méjì pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

61 Ní aginjù, Bẹti-árábà,+ Mídínì, Sékákà, 62 Níbúṣánì, Ìlú Iyọ̀ àti Ẹ́ń-gédì,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ ìlú mẹ́fà pẹ̀lú àwọn ìgbèríko wọn.

63 Àmọ́ àwọn ọkùnrin Júdà kò lè lé àwọn ará Jébúsì+ tó ń gbé Jerúsálẹ́mù+ lọ,+ torí náà àwọn ará Jébúsì ṣì ń gbé pẹ̀lú àwọn èèyàn Júdà ní Jerúsálẹ́mù títí di òní yìí.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́