Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Èlíjà Gbé Ọlọ́run Tòótọ́ Ga
ÒUN ni ọkùnrin tí àwọn aláṣẹ ń wá kiri jù lọ ní Ísírẹ́lì. Ó dájú pé pípa ni a óò pa á bí ọwọ́ ọba bá tẹ̀ ẹ́. Ta ni ọkùnrin tí a ń ṣọdẹ rẹ̀ yí? Èlíjà wòlíì Jèhófà ni.
Ọba Áhábù àti aya rẹ̀ abọ̀rìṣà, Jésíbẹ́lì, ti mú kí ìjọsìn Báálì gbèrú ní Ísírẹ́lì. Nítorí èyí, Jèhófà ti mú kí ọ̀dá dá ní ilẹ̀ náà, tí ó ti tó ọdún mẹ́rin nísinsìnyí. Jésíbẹ́lì, tí ó gbaná jẹ ti ṣe tán láti ṣekú pa àwọn wòlíì Jèhófà, ṣùgbọ́n Áhábù ń wá Èlíjà ní pàtàkì. Èlíjà ni ó sọ fún Áhábù, ní èyí tí ó lé ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn pé: “Kì yóò sí ìrì tàbí òjò ní ọdún wọ̀nyí, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi.” (Àwọn Ọba Kìíní 17:1) Ọ̀dá tí ó yọrí sí ṣì ń bá a lọ.
Nínú ipò tí ó léwu yìí, Jèhófà sọ fún Èlíjà pé: “Lọ, fi ara rẹ han Áhábù; èmi óò sì rọ òjò sórí ilẹ̀.” Ní fífi ara rẹ̀ wewu gidigidi, Èlíjà ṣègbọràn sí àṣẹ Jèhófà.—Àwọn Ọba Kìíní 18:1, 2.
Àwọn Ọ̀tá Méjì Pàdé
Nígbà tí Áhábù tajú kán rí Èlíjà, ó bi í pé: “Ṣé ìwọ rèé, ẹni tí ń mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá sórí Ísírẹ́lì?” Èlíjà fìgboyà fèsì pé: “Èmi kò mú ìtanùlẹ́gbẹ́ wá sórí Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n ìwọ àti ilé baba rẹ ni ó ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí tí ẹ ti fi àwọn àṣẹ Jèhófà sílẹ̀, ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí tọ àwọn Báálì lẹ́yìn.” Lẹ́yìn náà Èlíjà pàṣẹ pé kí a kó gbogbo Ísírẹ́lì jọ sí Òkè Kámẹ́lì, títí kan “àádọ́ta-lé-nírinwó wòlíì Báálì àti irínwó wòlíì òpó ọlọ́wọ̀.” Lẹ́yìn náà, Èlíjà bá àwùjọ náà sọ̀rọ̀ pé: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ ó fi máa tiro lórí èrò méjì tí ó yàtọ̀ síra?a Bí Jèhófà bá ni Ọlọ́run tòótọ́, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; ṣùgbọ́n bí Báálì bá ni, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”—Àwọn Ọba Kìíní 18:17-21, NW.
Àwọn ènìyàn náà pa lọ́lọ́. Bóyá wọ́n mọ ẹ̀bi wọn ní ti kíkùnà láti fún Jèhófà ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gédégbé. (Ẹ́kísódù 20:4, 5) Ó sì lè jẹ́ pé ẹ̀rí ọkàn wọ́n ti kú débi pé wọn kò rí ẹ̀ṣẹ̀ nínú pípín ìdúróṣinṣin wọn láàárín Jèhófà àti Báálì. Bí ó ti wù kí ó rí, Èlíjà pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà láti mú ẹgbọrọ akọ màlúù méjì wá—ọ̀kan fún àwọn wòlíì Báálì àti èkejì fún òun. Wọ́n yóò ṣaáyan akọ màlúù méjèèjì náà láti fi wọ́n rúbọ, ṣùgbọ́n wọn kì yóò finá sí i. Èlíjà wí pé: “Kí ẹ . . ké pe orúkọ ọlọ́run yín, èmi, ní tèmi, yóò sì ké pe orúkọ Jèhófà; yóò sì ṣẹlẹ̀ pé Ọlọ́run tòótọ́ tí ó bá fi iná dáhùn ni Ọlọ́run tòótọ́.”—Àwọn Ọba Kìíní 18:23, 24, NW.
A Gbé Jèhófà Ga
Àwọn wòlíì Báálì bẹ̀rẹ̀ sí í “tiro yí ká pẹpẹ tí wọ́n ṣe.” Gbogbo òwúrọ̀ ni wọ́n fi kígbe pé: “Báálì, dá wa lóhùn!” Ṣùgbọ́n Báálì kò dáhùn. (Àwọn Ọba Kìíní 18:26, NW) Lẹ́yìn náà, Èlíjà bẹ̀rẹ̀ sí í fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà pé: “Ẹ kígbe lóhùn rara, ọlọ́run sáà ni òun.” (Àwọn Ọba Kìíní 18:27) Àwọn wòlíì Báálì náà tilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀bẹ aṣóró àti ọ̀kọ̀ gún ara wọn—àṣà kan tí àwọn abọ̀rìṣà máa ń lò láti mú kí àwọn ọlọ́run wọn bojú àánú wò wọ́n.b—Àwọn Ọba Kìíní 18:28.
Ọ̀sán ti pọ́n báyìí, àwọn wòlíì Báálì ṣì ń bá a lọ láti “fi wèrè sọ tẹ́lẹ̀”—àpólà ọ̀rọ̀ tí ó gbé èrò ṣíṣe bíi wèrè àti híhùwà lọ́nà àìníjàánu rù nínú àyíká ọ̀rọ̀ yí. Nígbà tí ó ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́, Èlíjà wá sọ nígbẹ̀yìngbẹ́yín fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé: “Ẹ sún mọ́ mi.” Gbogbo wọ́n tẹjú mọ́ Èlíjà roro bí ó ti ń tún pẹpẹ Jèhófà kọ́, tí ó ń wa yàrà yí i ká, tí ó ń gé ẹgbọrọ akọ màlúù náà sí wẹ́wẹ́, tí ó sì gbé e sórí pẹpẹ tí ó ní igi tí a óò fi sun ún. Lẹ́yìn èyí, a fi omi rin akọ màlúù, pẹpẹ, àti igi náà gbingbin, a sì pọn omi (dájúdájú, omi tí a pọn láti inú Òkun Mẹditaréníà wá) kún inú yàrà náà. Lẹ́yìn náà, Èlíjà gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Jẹ́ kí ó di mímọ̀ lónìí pé, ìwọ ni Ọlọ́run ní Ísírẹ́lì, èmi sì ni ìránṣẹ́ rẹ, àti pé mo ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí nípa ọ̀rọ̀ rẹ. Gbọ́ ti èmi, Olúwa, gbọ́ ti èmi, kí àwọn ènìyàn yí kí ó lè mọ̀ pé, Ìwọ Olúwa ni Ọlọ́run, àti pé, Ìwọ tún yí ọkàn wọn pa dà.”—Àwọn Ọba Kìíní 18:29-37.
Lójijì, iná sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀run, “ó sì sun ẹbọ sísun náà àti igi, àti òkúta wọnnì, àti erùpẹ̀, ó sì lá omi tí ń bẹ nínú yàrà náà.” Kíá ni àwọn ènìyàn tí ó ń wòran forí balẹ̀, tí wọ́n ń wí pé: “Olúwa, òun ni Ọlọ́run; Olúwa, òun ni Ọlọ́run!” Lábẹ́ àṣẹ Èlíjà, wọ́n gbá àwọn wòlíì Báálì mú, wọ́n sì mú wọn lọ sí àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kíṣónì, wọ́n sì pa wọ́n síbẹ̀.—Àwọn Ọba Kìíní 18:38-40.
Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
Èlíjà fi ìgboyà tí ó jọ bíi pé ó ju ti ẹ̀dá ènìyàn lọ hàn. Síbẹ̀, Jákọ́bù, òǹkọ̀wé Bíbélì, mú un dá wa lójú pé “Èlíjà jẹ́ ènìyàn kan tí ó ní ìmọ̀lára bíi tiwa.” (Jákọ́bù 5:17) Ìbẹ̀rù àti hílàhílo kò yọ ọ́ sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésíbẹ́lì búra pé òun yóò gbẹ̀san nítorí ikú àwọn wòlíì Báálì, Èlíjà sá lọ, ó sì kígbe lóhùn rara sí Jèhófà nínú àdúrà pé: “Ó tó; nísinsìnyí, Olúwa, gba ẹ̀mí mi kúrò.”—Àwọn Ọba Kìíní 19:4.
Jèhófà kò gbẹ̀mí Èlíjà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi àánú pèsè ìrànwọ́. (Àwọn Ọba Kìíní 19:5-8) Ó yẹ kí ó dá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí lójú pé Jèhófà yóò ṣe ohun kan náà nígbà tí wọ́n bá dojú kọ àkókò hílàhílo gbígbóná janjan, bóyá nítorí àtakò. Láìṣe àní-àní, bí wọ́n bá gbàdúrà sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́, òun lè fún wọn ní “agbára tí ó rékọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá,” débi pé bí a tilẹ̀ ‘há wọn gádígádí ní gbogbo ọ̀nà,’ a kì yóò ‘há wọn rékọjá yíyíra.’ Nípa báyìí, a óò lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fara dà á, bíi ti Èlíjà.—Kọ́ríńtì Kejì 4:7, 8.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé Èlíjà lè máa sọ nípa ijó tí àwọn olùjọ́sìn Báálì máa ń jó nígbà ààtò ìsìn wọn. A lè rí ọ̀nà kan náà tí a gbà lo ọ̀rọ̀ náà, “tiro,” nínú Àwọn Ọba Kìíní 18:26 (NW) láti ṣàpèjúwe ijó àwọn wòlíì Báálì.
b Àwọn kan sọ pé ṣíṣera-ẹni-léṣe ní í ṣe pẹ̀lú àṣà fífi ènìyàn rúbọ. Àwọn ìṣe méjèèjì dọ́gbọ́n fi hàn pé ṣíṣára-ẹni-lọ́gbẹ́ tàbí títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ lè sún ọlọ́run kan láti fi ojú rere hàn.