ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 1/1 ojú ìwé 22-24
  • Ìwọ Ha Mọrírì Àwọn Ìbùkún Jèhófà Ní Tòótọ́ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Ha Mọrírì Àwọn Ìbùkún Jèhófà Ní Tòótọ́ Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kò Sí Olùpèsè Tí Ó Dàbí Rẹ̀
  • Àwọn Ìbùkún Tí Ń Múni Í Là
  • Fífi Sùúrù Dúró De Jèhófà
  • Wá Ìbùkún Rẹ̀
  • ‘Fifunrugbin Pẹlu Omije ati Kikarugbin Pẹlu Igbe Ayọ’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìbùkún Jèhófà Ní í Sọ Wá Dọlọ́rọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ayọ̀ Tó Wà Nínú Rírìn Nínú Ìwà Títọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • “Láti Ẹnu Àwọn Ìkókó”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 1/1 ojú ìwé 22-24

Ìwọ Ha Mọrírì Àwọn Ìbùkún Jèhófà Ní Tòótọ́ Bí?

KENICHI, ọkùnrin àgbàlagbà kan, ṣèbẹ̀wò sílé ìtoògùn láti ra oògùn fún òtútù tí ó ń mú un wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́. Nígbà tí ó lo oògùn náà, kò bá a lára mu, ó mú kí ara máa yún un, kí gbogbo ara rẹ̀ sì lé ròrò. Kò yani lẹ́nu pé Kenichi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì nípa bóyá elégbòogi náà fi bẹ́ẹ̀ kọbi ara sí ohun tí ó ń ṣe òun.

Àwọn kan lè ronú nípa Jèhófà Ọlọ́run ní ọ̀nà kan náà tí Kenichi gbà ronú nípa elégbòogi náà. Wọ́n ṣiyè méjì pé Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè, nífẹ̀ẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan ní tòótọ́. Bí wọ́n tilẹ̀ mọ̀ pé ẹniire ni Ọlọ́run, wọn kò ní ìdánilójú pé ó bìkítà fún wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan. Èyí jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì nígbà tí nǹkan kò bá dán mọ́rán fún wọn tàbí nígbà tí ìṣòro ńlá bá bá rírọ̀ tí wọ́n rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà Bíbélì rìn. Nítorí tí wọn kò ní ìfòyemọ̀, lójú wọn, ìṣòro wọ́n dà bíi ara tí ń ṣàdédé yún Kenichi, tí ó sì lé ròrò, bíi pé wọ́n jẹ́ ẹ̀bi Ọlọ́run lọ́nà kan ṣáá.—Òwe 19:3.

A kò lè fi Jèhófà wé àwọn ènìyàn aláìpé. Ó ní ibi tí ìmọ̀ àti agbára ẹ̀dá ènìyàn mọ. Wọ́n ń kùnà láti mọ àìní àwọn ẹlòmíràn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, bí elégbòogi Kenichi. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, kò sí ohun tí ó pamọ́ lójú Jèhófà. Jèhófà sábà máa ń ràn wá lọ́wọ́ láìjẹ́ pé a lóye tàbí mọrírì òtítọ́ náà, nítorí a nítẹ̀sí láti pọkàn pọ̀ sórí ohun tí a kò ní, kí a sì gbójú fo ọ̀pọ̀ ìbùkún tí a ní dá. Dípò títètè dá Jèhófà lẹ́bi fún ìṣòro èyíkéyìí tí ó dojú kọ wá, ó yẹ kí a gbìyànjú láti fòye mọ àwọn ìbùkún tí a ń gbádùn láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé atúmọ̀ èdè Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary ti sọ, “ìbùkún” lè túmọ̀ sí “ohun kan tí ń fi kún ayọ̀ tàbí ire.” Ìwọ ha róye pé èyí jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì pẹ̀lú àwọn ìbùkún tí ń wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà?

Kò Sí Olùpèsè Tí Ó Dàbí Rẹ̀

Nígbà tí aya kan bá sọ pé ọkọ òun jẹ́ olùpèsè rere, ohun tí ó ń sọ ní ti gidi ni pé, ó ń pèsè bí ó ti yẹ fún àìní ìdílé rẹ̀, ó ń pèsè oúnjẹ tí ó tó, ibùgbé, àti aṣọ fún ayọ̀ àti ire ìdílé rẹ̀. Báwo ni Jèhófà ti jẹ́ Olùpèsè fún wa dáradára tó? Wo pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé wa, ilé ènìyàn, fínnífínní. Ó wà ní 150,000,000 kìlómítà sí oòrùn, ibi tí ó yẹ kí ó jìnnà dé fún ìwọ̀n ìmóoru àti ìtutù tí ó wà déédéé, tí ó mú kí ìwàláàyè ṣeé ṣe lórí ilẹ̀ ayé. A ṣe títẹ̀ tí àgbáyé wá tẹ̀ ní ìwọ̀n 23.5 lọ́nà pípé, tí ó yọrí sí onírúurú ìgbà tí ó fi kún ìkórè púpọ̀ yanturu. Nítorí èyí, ilẹ̀ ayé ń pèsè oúnjẹ fún iye ènìyàn tí ó lé ní bílíọ̀nù márùn-ún. Olùpèsè àgbàyanu mà ni Jèhófà jẹ́ ní tòótọ́ o!

Síwájú sí i, Bíbélì mú un dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan àti sí ire wa gan-an. Ronú ná, Jèhófà mọ orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹgbàágbèje ìràwọ̀, kò sì sí ológoṣẹ́ kan tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé ó mọ̀. (Aísáyà 40:26; Mátíù 10:29-31) Ẹ wo bí yóò ti bìkítà tó nípa àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí ó sì fi ẹ̀jẹ̀ iyebíye Ọmọkùnrin rẹ̀ àyànfẹ́, Jésù Kristi, rà! (Ìṣe 20:28) Ọlọgbọ́n ọkùnrin náà pòkìkí lọ́nà yíyẹ pé: “Ìbùkún Olúwa ní í múni í là, kì í sì í fi làálàá pẹ̀lú rẹ̀.”—Òwe 10:22.

Àwọn Ìbùkún Tí Ń Múni Í Là

A ní ohun kan tí ó ṣeyebíye gidigidi ní ìkáwọ́ wa tí ó yẹ kí a mọrírì gidigidi. Kí ni ohun náà? Bíbélì fi í hàn nígbà tí ó sọ pé: “Òfin ẹnu rẹ dára fún mi ju ẹgbẹẹgbẹ̀rún wúrà àti fàdákà lọ.” (Orin Dáfídì 119:72; Òwe 8:10) Bí ojúlówó wúrà tilẹ̀ níyelórí gidigidi, òfin Jèhófà yẹ ní fífẹ́ jù ú lọ gan-an. Ìmọ̀ pípéye nípa òfin rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìjìnlẹ̀ òye àti ìfòyemọ̀ tí Jèhófà fi jíǹkí àwọn tí ń fi tọkàntọkàn wá òtítọ́ kiri jẹ́ ohun tí ó yẹ kí a ṣìkẹ́. Wọ́n ń mú wa gbára dì láti dáàbò bo ara wa, láti kojú àwọn ipò nínira, láti yanjú ìṣòro, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ ní ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀.

Èyí jẹ́ òtítọ́ àní nípa àwọn ọmọ kékeré pẹ̀lú. Gbé bí ọmọdébìnrin kan ṣe yanjú ìṣòro rẹ̀ nípa títẹ̀lé òfin Jèhófà yẹ̀ wò. Ọmọdébìnrin náà, Akemi, ń gbé nítòsí Tokyo. Bàbá àti ìyá rẹ̀ fi àwọn ìlànà Bíbélì tọ́ ọ, wọ́n sì ran ọmọbìnrin wọn lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ fún Jèhófà àti aládùúgbò rẹ̀ dàgbà nípa ọ̀rọ̀ àti àpẹẹrẹ wọn. Ní fífojú inú rí ìṣòro tí yóò dojú kọ ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́, wọ́n gbìyànjú láti múra rẹ̀ sílẹ̀ bí ó bá ti ṣeé ṣe tó. Ṣùgbọ́n, nígbà tí Akemi bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, àwọn kan lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ kà á sí ẹni tí ó “yàtọ̀,” nítorí ó máa ń gbàdúrà kí ó tó jẹun, ó sì máa ń fi gbogbo ọkàn yẹra fún àwọn ìgbòkègbodò kan tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Kò pẹ́ kò jìnnà, àwùjọ abúmọ́ni kan dójú sọ ọ́, wọn yóò dènà dè é lẹ́yìn tí wọ́n bá jáde ilé ẹ̀kọ́, wọn yóò sì fọ́ ọ létí, rọ́ ọ lọ́wọ́ sẹ́yìn, wọn yóò sì fi ṣe yẹ̀yẹ́.

Akemi kékeré kò gbẹ̀san, bẹ́ẹ̀ sì ni kò gbọ̀n jìnnìjìnnì níwájú àwọn tí ń fín in níràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbìyànjú láti fi ohun tí ó ti kọ́ sílò. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ìwà rere àti ìgboyà rẹ̀, ó jèrè ọ̀wọ̀ púpọ̀ lọ́dọ̀ àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Wọ́n mú ọ̀ràn náà wá sí etígbọ̀ọ́ olùkọ́ wọn, láti ọjọ́ náà lọ, kò sí ẹni tí ó jẹ́ hùwà ìkà sí Akemi ní ilé ẹ̀kọ́ mọ́.

Kí ní ran Akemi lọ́wọ́ láti yanjú ipò nínira náà? Ìmọ̀ pípéye, ìjìnlẹ̀ òye, àti ọgbọ́n tí ó ti ọ̀dọ̀ Jèhófà wá, tí àwọn òbí rẹ̀ ti gbìn sí i lọ́kàn ni. Ó mọ̀ nípa ìforítì Jésù dáradára, ìyẹn sì sún un láti kọ́ àpẹẹrẹ rẹ̀. Bíbélì ràn án lọ́wọ́ láti fòye mọ̀ pé àwọn ènìyàn kan máa ń hùwà ibi nítorí àìmọ̀kan, ó sì fún un níṣìírí láti kórìíra ìwà ibi tí àwọn abúmọ́ni wọ̀nyẹn hù sí i, bí kò tilẹ̀ kórìíra àwọn ènìyàn náà fúnra wọn.—Lúùkù 23:34; Róòmù 12:9, 17-21.

Àmọ́ ṣáá o, kò sí òbí tí yóò fẹ́ láti rí i kí a fi ọmọ wọn ṣe ẹlẹ́yà, kí a sì hùwà ìkà sí i. Síbẹ̀, o lè finúwòye bí inú àwọn òbí Akemi ti dùn tó nígbà tí wọ́n gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà ní tòótọ́.—Orin Dáfídì 127:3; Pétérù Kíní 1:6, 7.

Fífi Sùúrù Dúró De Jèhófà

Ṣùgbọ́n, kí o tó lè gba ìbùkún Jèhófà, nígbà míràn, o ní láti dúró de àkókò rẹ̀. Jèhófà mọ ipò rẹ, ó sì ń bójú tó àìní kọ̀ọ̀kan nígbà tí yóò ṣe ọ́ láǹfààní jù lọ. (Orin Dáfídì 145:16; Oníwàásù 3:1; Jákọ́bù 1:17) O lè jẹ́ ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ sí èso, ṣùgbọ́n kí ni ìwọ yóò rò nípa olùgbàlejò kan tí ó fi èso tí kò tí ì gbó ṣe ọ́ lálejò? Yálà ó jẹ́ ápù, ọsàn, tàbí ohun mìíràn, ìwọ yóò fẹ́ kì èso rẹ pọ́n, kí ó lómi nínú, kí ó sì dùn. Bákan náà, Jèhófà ń pèsè ohun tí o nílò ní àkókò yíyẹ—kì í yá jù, kì í sì í pẹ́ jù.

Rántí ìrírí Jósẹ́fù. Láìmọwọ́mẹsẹ̀, ó bá ara rẹ̀ nínú àjàalẹ̀ kan ní Íjíbítì. Ẹlẹ́wọ̀n bíi tirẹ̀ kan, agbọ́tí Fáráò, nírètí pé a óò tú òun sílẹ̀, ó sì ṣèlérí láti mú ọ̀ràn Jósẹ́fù wá sí àfiyèsí Fáráò. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìtúsílẹ̀ rẹ̀, ó gbàgbé pátápátá nípa Jósẹ́fù. Ń ṣe ni ó dà bíi pé a ti pa Jósẹ́fù tì. Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn ọdún méjì gbáko, a tú u sílẹ̀ nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, a fi ṣe igbákejì alákòóso Íjíbítì. Dípò tí yóò fi jẹ́ aláìnísùúrù, Jósẹ́fù dúró de Jèhófà. Nítorí èyí, a bù kún un ní ọ̀nà tí ó túmọ̀ sí pípa ẹ̀mí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti ti àwọn ará Íjíbítì mọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 39:1–41:57.

Masashi jẹ́ alàgbà ní ìjọ kan ní àríwá Japan. A kò fi òun sínú àjàalẹ̀, ṣùgbọ́n ó ní láti dúró de Jèhófà. Èé ṣe? Láti ìgbà tí a ti dá Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, ilé ẹ̀kọ́ kan fún dídá àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ tí wọ́n tóótun lẹ́kọ̀ọ́, sílẹ̀ ní ilẹ̀ Japan, ni ó ti sọ ọ́ di góńgó pàtàkì láti lọ. Ó gbàdúrà lọ́nà gbígbóná janjan nípa àǹfààní náà. A ké sí aṣáájú ọ̀nà alájọṣiṣẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n, láìka ìfẹ́ ọkàn oníhàáragàgà rẹ̀ sí, a kò ké sí Masashi. Ó nímọ̀lára ìjákulẹ̀ gidigidi.

Bí ó ti wù kí ó rí, ó gbégbèésẹ̀ láti kojú ìmọ̀lára rẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn ìwé tí Watch Tower Society tẹ̀ jáde, ó pọkàn pọ̀ sórí àwọn kókó bíi jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ṣíṣàkóso ìmọ̀lára ẹni. Ó tún ìrònú rẹ̀ ṣe, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ nírìírí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ tí a yàn fún un. Lẹ́yìn náà, nígbà tí kò tilẹ̀ ronú rẹ̀ rárá, ó gba lẹ́tà ìkésíni kan láti wá sí ilé ẹ̀kọ́ náà.

Nítorí tí ó ti mú àwọn ànímọ́ bíi sùúrù àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ dàgbà, ó túbọ̀ jèrè láti inú ilé ẹ̀kọ́ náà. Lẹ́yìn náà, a fún Masashi ní àǹfààní sísin àwọn arákùnrin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò. Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà mọ ohun tí Masashi nílò, ó sì pèsè rẹ̀ fún un ní àkókò gan-an tí yóò ṣàǹfààní jù lọ.

Wá Ìbùkún Rẹ̀

Nítorí náà, Jèhófà kò dà bí elégbòogi náà. Bí a tilẹ̀ lè ṣàìfòyemọ ìtọ́jú àti ìbìkítà Jèhófà, inúrere rẹ̀ ń wá ní onírúurú ọ̀nà—ní àkókò àti ní ọ̀nà tí yóò ṣe wá láǹfààní jù lọ. Nítorí náà, máa bá a lọ ní wíwá ìbùkún rẹ̀. Rántí pé, o ní ọ̀pọ̀ ìdí nísinsìnyí láti kún fún ọpẹ́. A ti fi àwọn ìpèsè ṣíṣe kókó fún bíbá a lọ láti wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé jíǹkí rẹ. A ti fún ọ ní ìmọ̀ Jèhófà àti ti àwọn ọ̀nà pípé rẹ̀. A ti fi ìjìnlẹ̀ òye jíǹkí rẹ. O sì ti jèrè ìfòyemọ̀. Gbogbo ìwọ̀nyí ń fi kún ire àti ayọ̀ rẹ.

Láti lè jèrè ìbùkún Jèhófà ní kíkún sí i, máa bá a lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ tí ó dà bí ohun iyebíye nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó mí sí, kí o sì lò wọ́n. Wọn yóò jẹ́ kí o di ọlọ́rọ̀ ní tòótọ́, débi pé ohunkóhun kò ní wọ́n ọ. Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n yóò túmọ̀ sí ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn fún ọ nísinsìnyí àti ìyè yanturu nínú ayé tuntun tí ń bọ̀.—Jòhánù 10:10; Tímótì Kíní 4:8, 9.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìbùkún Jèhófà ṣeyebíye ju wúrà lọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́