Ṣé Ìyìn Ni Tàbí Ìpọ́nni?
ẸNÌ kan sọ fún ọ pé, “Irun tí o ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe yìí mà ti lọ wà jù o!” Ṣé ìyìn ni tàbí ìpọ́nni? “Aṣọ yẹn mà bá ọ mu rẹ́gí o!” Ṣé ìyìn ni tàbí ìpọ́nni? “N kò tí ì jẹ oúnjẹ tí ó dùn tó báyìí rí!” Ṣé ìyìn ni tàbí ìpọ́nni? Nígbà tí a bá gbọ́ irú àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ni bẹ́ẹ̀, a lè ṣe kàyéfì bóyá wọ́n jẹ́ látọkànwá, tí wọ́n sì jóòótọ́ ní ti gidi tàbí bóyá a wulẹ̀ pète wọn láti mú inú wa dùn ni láìfi dandan jẹ́ pé ẹni tí ó sọ ọ́ gbà pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí.
Báwo ni a ṣe lè mọ̀ bóyá ohun tí ẹnì kan sọ sí wa jẹ́ ìyìn tàbí ìpọ́nni? Ó ha já mọ́ nǹkan kan bí? A kò ha wulẹ̀ lè tẹ́wọ́ gba bí ohun tí a sọ bá ṣe dún létí wa, kí a sì gbádùn ayọ̀ tí ó bá fún wa bí? Nígbà tí a bá yin àwọn ẹlòmíràn ńkọ́? A ha ti ṣàyẹ̀wò ìsúnniṣe wa rí bí? Ríronú nípa àwọn ìbéèrè wọ̀nyí lè ràn wá lọ́wọ́ láti fòye mọ̀, kí a sì lo ahọ́n wa lọ́nà tí ń mú ìyìn wá fún Jèhófà Ọlọ́run.
Ìtumọ̀ Ìyìn àti Ìpọ́nni
Ìwé atúmọ̀ èdè náà, Webster’s Dictionary, túmọ̀ ìyìn gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìtẹ́wọ́gbà tàbí ìgbóríyìn, ọ̀rọ̀ náà sì tún lè túmọ̀ sí ìjọsìn tàbí fífi ògo fúnni. Ní kedere, ìtúmọ̀ méjì tí ó kẹ́yìn tọ́ka sí kìkì ìyìn tí a darí sí Jèhófà Ọlọ́run. Èyí jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí onísáàmù tí a mí sí ṣe gbani níyànjú pé: “Nítorí tí ó dára . . . , ó dùn mọ́ni—ìyìn yẹ ẹ́.” “Gbogbo ohun eléèémí—kí ó yin Jáà.”—Orin Dáfídì 147:1, NW; 150:6, NW.
Ṣùgbọ́n, èyí kò túmọ̀ sí pé a kò lè yin ènìyàn. A lè yìn ín, ní èrò ìgbóṣùbà fúnni, fífi ojú rere hàn síni, tàbí ṣíṣe ìdájọ́ ẹni lọ́nà tí ó bára dé. Nínú òwe àkàwé tí Jésù sọ, ọ̀gá kan sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “O káre láé, ẹrú rere àti olùṣòtítọ́!”—Mátíù 25:21.
Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, a túmọ̀ ìpọ́nni gẹ́gẹ́ bí ìyìn èké, tí kò ti ọkàn wá tàbí tí ó jẹ́ àṣerégèé, níbi tí apọ́nni náà ti ní ìsúnniṣe tí ó jẹ́ fún ire ara rẹ̀. Ìgbóríyìn tàbí àpọ́nlé orí ahọ́n ní a máa ń ṣe láti rí ojú rere tàbí àǹfààní ti ara láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn tàbí láti mú kí a ní ìmọ̀lára pé a ní ojúṣe kan sí ẹni tí ń pọ́nni náà. Nítorí náà, ìmọtara-ẹni-nìkan ní ń sún àwọn apọ́nni ṣiṣẹ́. Ní ìbámu pẹ̀lú Júúdà 16, wọ́n “ṣe tán láti pọ́n àwọn ẹlòmíràn nígbà tí wọ́n bá rí àwọn àǹfààní kan nínú rẹ̀.”—The Jerusalem Bible.
Ojú Ìwòye Ìwé Mímọ́
Kí ni ojú ìwòye Ìwé Mímọ́ nípa yíyin ènìyàn ẹlẹgbẹ́ ẹni? Jèhófà fi àwòkọ́ṣe lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé lórí èyí. A sọ fún wa nínú Bíbélì pé a óò yìn wá bí a bá ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé “olúkúlùkù yóò . . . gba ìyìn rẹ̀ tí yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Pétérù sọ fún wa pé ìjójúlówó ìgbàgbọ́ wa tí a ti dán wò “lè jẹ́ èyí tí a rí gẹ́gẹ́ bí okùnfà fún ìyìn.” Nítorí náà, òtítọ́ náà pé Jèhófà yóò yin àwọn ẹ̀dá ènìyàn fi hàn wá pé fífúnni ní ìyìn ojúlówó jẹ́ ìṣe onínúure, onífẹ̀ẹ́, tí ó sì ṣàǹfààní, èyí tí a kò gbọ́dọ̀ gbójú fò dá.—Kọ́ríńtì Kíní 4:5; Pétérù Kíní 1:7.
Orísun mìíràn tí ìyìn ti lè wá fún wa, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, jẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ ìjọba tí wọ́n ń kíyè sí ìwà rere wa, tí wọ́n sì ń gbóríyìn fún wa láìṣàbòsí. A sọ fún wa pé: “Máa ṣe rere, ìwọ yóò sì gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (Róòmù 13:3) A tún lè gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n gbà tọkàntọkàn pé bẹ́ẹ̀ ni ohun tí wọ́n ń sọ rí tí wọn kò sì ní ìsúnniṣe kọ́lọ́fín ní yíyìn wá. Ìwé Mímọ́ tí a mí sí sọ ní Òwe 27:2 (NW) pé: “Àjèjì ni kí ó yìn ọ́, kí ó má ṣe jẹ́ ẹnu ìwọ fúnra rẹ.” Èyí fi hàn pé títẹ́wọ́gba ìyìn láti ọ̀dọ̀ ènìyàn bójú mu.
Kò rí bẹ́ẹ̀ ní ti pípọ́nni tàbí gbígba ìpọ́nni. Èé ṣe tí ọ̀rọ̀ ìpọ́nni fi ń ba Jèhófà nínú jẹ́ tó bẹ́ẹ̀? Fún ìdí kan, ó jẹ́ ìwà àgàbàgebè, Jèhófà sì dẹ́bi fún ìwà àgàbàgebè. (Fi wé Òwe 23:6, 7.) Síwájú sí i, kò fi àìlábòsí hàn. Nígbà tí ó ń ṣàpèjúwe àwọn tí kò yẹ kí wọ́n rí ojú rere Ọlọ́run, onísáàmù náà sọ pé: “Gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe ni láti parọ́ fún ẹnì kíní kejì, ètè ìpọ́nni, sísọ̀rọ̀ láti inú ọkàn àyà méjì. Ǹjẹ́ kí Yahweh ké gbogbo ètè ìpọ́nni sí wẹ́wẹ́.”—Orin Dáfídì 12:2, 3, JB.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìpọ́nni kò fi ìfẹ́ hàn. Ìmọtara-ẹni-nìkan ní ń sún un ṣiṣẹ́. Lẹ́yìn tí ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn apọ́nni, onísáàmù náà, Dáfídì, ṣàyọlò ọ̀rọ̀ wọn ní sísọ pé: “Ahọ́n wa ni àwa óò fi ṣẹ́gun; ètè wa ni tiwa: ta ní í ṣe olúwa wa?” Jèhófà ṣàpèjúwe irú àwọn onímọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ‘àwọn tí ń fi àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ ṣe ìjẹ.’ Wọ́n ti lo ahọ́n ìpọ́nni wọn, kì í ṣe láti gbé àwọn ẹlòmíràn ró, ṣùgbọ́n láti fi wọ́n ṣe ìjẹ, kí wọ́n sì ṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́.—Orin Dáfídì 12:4, 5.
Ìpọ́nni—Pańpẹ́ Kan
Ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì wí pé: “Ẹni tí ó ń pọ́n ẹnì kejì rẹ̀ ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ rẹ̀,” ẹ sì wo bí ìyẹn ti jẹ́ òtítọ́ tó! (Òwe 29:5) Àwọn Farisí gbìyànjú láti dẹ pańpẹ́ sílẹ̀ fún Jésù ní lílo ìpọ́nni. Wọ́n wí pé: “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé ìwọ jẹ́ olùsọ òtítọ́ o sì ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́, ìwọ kò sì bìkítà fún ẹnikẹ́ni, nítorí ìwọ kì í wo ìrísí òde àwọn ènìyàn.” Ẹ wo bí ìyẹn ti fọkàn ẹni balẹ̀ tó! Ṣùgbọ́n, Jésù kò jẹ́ kí wọ́n fi ọ̀rọ̀ dídùn wọn tan òun jẹ. Ó mọ̀ pé wọn kò gba ẹ̀kọ́ òun tí ó jẹ́ òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n wọ́n wulẹ̀ ń gbìyànjú láti dẹ pańpẹ́ mú òun nínú ọ̀rọ̀ tí òun bá sọ nípa sísan owó orí fún Késárì.—Mátíù 22:15-22.
Ọba Hẹ́rọ́dù ti ọ̀rúndún kìíní yàtọ̀ pátápátá sí Jésù. Nígbà tí ó bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ ní gbangba ní ìlú Kesaréà, àwọn ènìyàn náà dáhùn pa dà pé: “Ohùn ọlọ́run kan, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!” Dípò kí ó bá àwọn ènìyàn náà wí fún irú ìyìn èké, tí ó lòdì bẹ́ẹ̀, Hẹ́rọ́dù tẹ́wọ́ gba ìpọ́nni náà. Áńgẹ́lì Jèhófà mú ẹ̀san ojú ẹsẹ̀ wá bí àwọn aràn ti ṣe jẹ Hẹ́rọ́dù, tí ó sì yọrí sí ikú rẹ̀.—Ìṣe 12:21-23.
Kristẹni kan tí ó dàgbà dénú yóò wà lójúfò láti mọ ohun tí ìpọ́nni jẹ́. Àwọn alàgbà ìjọ gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ní pàtàkì nígbà tí ẹnì kan tí ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́ kàn bá ń kan sáárá sí wọn lọ́nà tí ó kọjá ààlà, bóyá débi fífi alàgbà kan wé òmíràn pàápàá, tí ó sì ń sọ nípa bí èyí tí ó ń bá sọ̀rọ̀ ti jẹ́ onínúure àti olùgbatẹnirò tó.
Ní kedere, Bíbélì tún fi ìdẹkùn míràn tí ìpọ́nni lè gbé kalẹ̀ hàn nígbà tí ó ṣàpèjúwe bí obìnrin asúnnidẹ́ṣẹ̀ kan ṣe tan ọ̀dọ́kùnrin kan sínú ìwà pálapàla. (Òwe 7:5, 21) Ìkìlọ̀ yí bá ipò tí ó wà lónìí mu. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí a ń yọ lẹ́gbẹ́ kúrò nínú ìjọ Kristẹni lọ́dọọdún ní a ń yọ nítorí ìwà pálapàla. Ó ha lè jẹ́ pé irú ìṣubú sínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo bẹ́ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ nípasẹ̀ ìpọ́nni bí? Níwọ̀n bí ẹ̀dá ènìyàn ti ń fẹ́ ìgbóríyìn gidigidi, tí a sì ń fẹ́ kí a sọ̀rọ̀ dáadáa nípa ẹni, ọ̀rọ̀ dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in tí ètè ìpọ́nni sọ lè mú kí dídènà tí Kristẹni kan ń dènà ìwà àìtọ́ dín kù. Nígbà tí a kò bá dènà irú ọ̀rọ̀ ìpọ́nni bẹ́ẹ̀, ó lè yọrí sí àbájáde búburú.
Dáàbò Bo Ara Rẹ Lọ́wọ́ Ìpọ́nni
Ìpọ́nni máa ń tẹ́ ìfẹ́ ara ẹni tàbí ìjọra-ẹni-lójú ẹni tí a ń pọ́n lọ́rùn. Ó máa ń fún onítọ̀hún ní ojú ìwòye tí a gbé ga nípa bí òun ti tó, ní mímú kí ó nímọ̀lára pé òun ṣe pàtàkì ju àwọn ẹlòmíràn lọ ní àwọn ọ̀nà kan. Ọlọ́gbọ́n èrò orí náà, François de La Rochefoucauld, fi ìpọ́nni wé owó ayédèrú, “tí ó jẹ́ pé, ká sọ pé kò sí ti ìjọra-ẹni-lójú ni, kì bá tí tàn kálẹ̀.” Nípa báyìí, ọ̀nà láti dáàbò bo ara ẹni jẹ́ nípa kíkọbi ara sí ìṣílétí gbígbéṣẹ́ ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Mo sọ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàárín yín níbẹ̀ láti má ṣe ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ; ṣùgbọ́n láti ronú kí ó baà lè ní èrò inú yíyè kooro, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti há ìwọ̀n ìgbàgbọ́ fún un.”—Róòmù 12:3.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtẹ̀sí àdánidá wa ni láti fẹ́ láti gbọ́ ohun tí ó dùn mọ́ wa, ohun tí a nílò ní ti gidi lọ́pọ̀ ìgbà jù lọ ni ìmọ̀ràn àti ìbáwí tí a gbé karí Bíbélì. (Òwe 16:25) Ọba Áhábù fẹ́ láti gbọ́ kìkì ohun tí ó dùn mọ́ ọn nínú; àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pàápàá sọ fún wòlíì Mikáyà pé kí ó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ “dà bí ọ̀rọ̀ ọ̀kan nínú wọn [àwọn wòlíì tí ń pọ́n Áhábù], kí o sì sọ rere.” (Àwọn Ọba Kìíní 22:13) Ká ní Áhábù ti múra tán láti fetí sí ọ̀rọ̀ aláìlẹ́tàn kí ó sì yí ọ̀nà ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ pa dà ni, òun ì bá ti dènà pípàdánù tí Ísírẹ́lì pàdánù lọ́nà bíbanilẹ́rù nínú ogun àti kíkú tí òun fúnra rẹ̀ kú. Fún ire tẹ̀mí wa, a gbọ́dọ̀ yára láti dáhùn pa dà sí ìmọ̀ràn tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣùgbọ́n tí ó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni alàgbà tí a yàn sípò, tí wọ́n ń fẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́ láti wà ní ojú ọ̀nà títọ́ ti òtítọ́, dípò wíwá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ fún wa nípa bí a ti gbayì tó, ní fífi ọ̀rọ̀ ìpọ́nni rìn wá létí!—Fi wé Tímótì Kejì 4:3.
Fún ìdí èyíkéyìí, àwọn Kristẹni kì yóò fẹ́ láti yíjú sí ìpọ́nni láé. Gẹ́gẹ́ bí Élíhù olùṣòtítọ́, wọ́n ń fi ìdúróṣinṣin gbàdúrà pé: “Jọ̀wọ́, kí n má ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni, kí n má ṣe pọ́n ènìyàn èyíkéyìí; nítorí pé èmi kò mọ bí a ti ń pọ́nni, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ni, Olùṣẹ̀dá mi ì bá mú mi kúrò láìpẹ́.” Lẹ́yìn náà, bíi Pọ́ọ̀lù, wọn yóò lè sọ pé: “Kò sí ìgbà kankan rí tí a fara hàn yálà nínú ọ̀rọ̀ ìpọ́nni . . . tàbí nínú ìrísí ẹ̀tàn fún ojú kòkòrò.”—Jóòbù 32:21, 22, An American Translation; Tẹsalóníkà Kíní 2:5, 6.
Ìyìn Nígbà Tí Ó Bá Yẹ
Òwe tí a mí sí fi hàn pé ìyìn lè ṣiṣẹ́ bí ohun tí a fi ń dán ìjójúlówó nǹkan wò, ní sísọ pé: “Ìkòkò ìyọ́-nǹkan wà fún fàdákà, ìléru sì wà fún wúrà, ṣùgbọ́n ìyìn ni a fi ń dán ìwà wò.” (Òwe 27:21, The New English Bible) Bẹ́ẹ̀ ni, ìyìn lè fún ìmọ̀lára ìlọ́lájù tàbí ìgbéraga níṣìírí, tí ó sì lè ṣamọ̀nà sí ìṣubú ẹni. Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, ó lè fi ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ hàn bí òun bá gbà pé Jèhófà ni ó mú kí òun lè ṣe ohunkóhun tí òun ṣe tí ó mú ìyìn wá fún òun.
Ìyìn àtọkànwá fún ìwà tàbí àṣeyọrí yíyẹ ń gbé ẹni tí ń fúnni àti ẹni tí ń gbà á ró. Ó ń fi kún ìmọrírì ọlọ́yàyà tí ń gbéni ró fún ẹnì kíní kejì. Ó ń fún títiraka fún àwọn góńgó tí ó yẹ fún ìyìn níṣìírí. Ìyìn yíyẹ tí a bá fún àwọn ọ̀dọ́ lè mú kí wọ́n fẹ́ láti ṣiṣẹ́ kára sí i. Ó lè ṣèrànwọ́ láti tún ìwà wọn ṣe bí wọ́n ti ń fẹ́ láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n tí a retí kí wọ́n tẹ̀ lé.
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a yẹra fún ìpọ́nni—bóyá ní fífúnni tàbí ní gbígbà á. Ẹ jẹ́ kí a rẹ ara wa sílẹ̀ nígbà tí a bá ń gba ìyìn. Ẹ sì jẹ́ kí a jẹ́ ọ̀làwọ́, ní fífi ìyìn fún Jèhófà tọkàntọkàn—déédéé nínú ìjọsìn wa, kí ó jẹ́ látọkànwá pẹ̀lú nígbà tí a bá ń fún àwọn ẹlòmíràn lọ́nà ìgbóríyìnfúnni àti ìmọrírì gbígbámúṣé, ní rírántí pé “ọ̀rọ̀ tí ó . . . bọ́ sí àkókò mà dára o!”—Òwe 15:23, NW.