ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Sámúẹ́lì 18
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Sámúẹ́lì

      • Dáfídì àti Jónátánì di ọ̀rẹ́ (1-4)

      • Sọ́ọ̀lù ń jowú torí pé Dáfídì ń ṣẹ́gun (5-9)

      • Sọ́ọ̀lù gbìyànjú láti pa Dáfídì (10-19)

      • Dáfídì fẹ́ Míkálì ọmọ Sọ́ọ̀lù (20-30)

1 Sámúẹ́lì 18:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn Jónátánì fà mọ́ ọkàn Dáfídì.”

  • *

    Tàbí “bí ọkàn ara rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 14:1, 49
  • +1Sa 19:2; 20:17, 41; 2Sa 1:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    1/2021, ojú ìwé 21-22

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 48

1 Sámúẹ́lì 18:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 8:11; 16:22; 17:15

1 Sámúẹ́lì 18:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “bí ọkàn ara rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 20:8, 42; 23:18; 2Sa 9:1; 21:7
  • +Owe 17:17; 18:24

1 Sámúẹ́lì 18:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “hùwà ọgbọ́n.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:30
  • +1Sa 14:52

1 Sámúẹ́lì 18:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:20, 21; Ond 5:1
  • +Ond 11:34

1 Sámúẹ́lì 18:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 21:11; 29:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 8/2020, ojú ìwé 3

1 Sámúẹ́lì 18:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 4:5; Owe 14:30
  • +1Sa 13:14; 15:27, 28; 16:13; 20:31; 24:17, 20

1 Sámúẹ́lì 18:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “bíi wòlíì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 16:14
  • +1Sa 16:16, 23
  • +1Sa 19:9, 10

1 Sámúẹ́lì 18:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 20:33

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/15/2008, ojú ìwé 4

1 Sámúẹ́lì 18:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:28, 29
  • +1Sa 16:14

1 Sámúẹ́lì 18:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ó ń jáde lọ, ó sì ń wọlé níwájú àwọn èèyàn náà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:2

1 Sámúẹ́lì 18:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “hùwà ọgbọ́n.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:5
  • +Jẹ 39:2; Joṣ 6:27; 1Sa 10:7; 16:18

1 Sámúẹ́lì 18:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 14:49
  • +1Sa 17:25
  • +1Sa 25:28
  • +1Sa 18:25

1 Sámúẹ́lì 18:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkọ ọmọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 7:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2004, ojú ìwé 15-16

1 Sámúẹ́lì 18:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 21:8

1 Sámúẹ́lì 18:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 14:49; 19:11; 25:44; 2Sa 3:13; 6:16

1 Sámúẹ́lì 18:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkọ ọmọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:17

1 Sámúẹ́lì 18:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:18

1 Sámúẹ́lì 18:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 29:18
  • +1Sa 17:26, 36; 2Sa 3:14

1 Sámúẹ́lì 18:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:21

1 Sámúẹ́lì 18:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 17:25

1 Sámúẹ́lì 18:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 16:13; 24:17, 20
  • +1Sa 18:20

1 Sámúẹ́lì 18:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:9, 12; 20:33

1 Sámúẹ́lì 18:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “hùwà ọgbọ́n.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:5
  • +2Sa 7:9

Àwọn míì

1 Sám. 18:11Sa 14:1, 49
1 Sám. 18:11Sa 19:2; 20:17, 41; 2Sa 1:26
1 Sám. 18:21Sa 8:11; 16:22; 17:15
1 Sám. 18:31Sa 20:8, 42; 23:18; 2Sa 9:1; 21:7
1 Sám. 18:3Owe 17:17; 18:24
1 Sám. 18:51Sa 18:30
1 Sám. 18:51Sa 14:52
1 Sám. 18:6Ẹk 15:20, 21; Ond 5:1
1 Sám. 18:6Ond 11:34
1 Sám. 18:71Sa 21:11; 29:5
1 Sám. 18:8Jẹ 4:5; Owe 14:30
1 Sám. 18:81Sa 13:14; 15:27, 28; 16:13; 20:31; 24:17, 20
1 Sám. 18:101Sa 16:14
1 Sám. 18:101Sa 16:16, 23
1 Sám. 18:101Sa 19:9, 10
1 Sám. 18:111Sa 20:33
1 Sám. 18:121Sa 18:28, 29
1 Sám. 18:121Sa 16:14
1 Sám. 18:132Sa 5:2
1 Sám. 18:141Sa 18:5
1 Sám. 18:14Jẹ 39:2; Joṣ 6:27; 1Sa 10:7; 16:18
1 Sám. 18:171Sa 14:49
1 Sám. 18:171Sa 17:25
1 Sám. 18:171Sa 25:28
1 Sám. 18:171Sa 18:25
1 Sám. 18:182Sa 7:18
1 Sám. 18:192Sa 21:8
1 Sám. 18:201Sa 14:49; 19:11; 25:44; 2Sa 3:13; 6:16
1 Sám. 18:211Sa 18:17
1 Sám. 18:231Sa 18:18
1 Sám. 18:25Jẹ 29:18
1 Sám. 18:251Sa 17:26, 36; 2Sa 3:14
1 Sám. 18:261Sa 18:21
1 Sám. 18:271Sa 17:25
1 Sám. 18:281Sa 16:13; 24:17, 20
1 Sám. 18:281Sa 18:20
1 Sám. 18:291Sa 18:9, 12; 20:33
1 Sám. 18:301Sa 18:5
1 Sám. 18:302Sa 7:9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Sámúẹ́lì 18:1-30

Sámúẹ́lì Kìíní

18 Gbàrà tí Dáfídì bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ tán, Jónátánì+ àti Dáfídì wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́,* Jónátánì sì bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ara rẹ̀.*+ 2 Láti ọjọ́ yẹn lọ, Sọ́ọ̀lù mú Dáfídì sọ́dọ̀, kò sì jẹ́ kó pa dà sí ilé bàbá rẹ̀.+ 3 Jónátánì àti Dáfídì dá májẹ̀mú,+ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí ara rẹ̀.*+ 4 Jónátánì bọ́ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá tí ó wọ̀, ó sì fún Dáfídì, ó tún fún un ní ìbòrí rẹ̀, idà rẹ̀, ọrun rẹ̀ àti àmùrè rẹ̀ pẹ̀lú. 5 Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í jáde lọ, ó sì ń ṣàṣeyọrí*+ níbikíbi tí Sọ́ọ̀lù bá rán an. Torí náà, Sọ́ọ̀lù ní kó máa bójú tó àwọn jagunjagun,+ èyí sì dùn mọ́ gbogbo àwọn èèyàn náà nínú àti àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù pẹ̀lú.

6 Nígbà tí Dáfídì àti àwọn tó kù ń pa dà láti ibi tí wọ́n ti lọ pa àwọn Filísínì, àwọn obìnrin jáde látinú gbogbo ìlú Ísírẹ́lì láti fi orin+ àti ijó pàdé Ọba Sọ́ọ̀lù, wọ́n ń lu ìlù tanboríìnì,+ wọ́n sì ń ta gòjé tìdùnnútìdùnnú. 7 Àwọn obìnrin tó ń ṣe ayẹyẹ náà ń kọrin pé:

“Sọ́ọ̀lù ti pa ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀tá,

Àmọ́ Dáfídì pa ẹgbẹẹgbàárùn-ún ọ̀tá.”+

8 Inú bí Sọ́ọ̀lù gan-an,+ orin yìí sì bà á lọ́kàn jẹ́, ó sọ pé: “Wọ́n fún Dáfídì ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún, àmọ́ wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún. Ipò ọba nìkan ló kù kí wọ́n fún un!”+ 9 Láti ọjọ́ yẹn lọ, ìgbà gbogbo ni Sọ́ọ̀lù ń wo Dáfídì tìfuratìfura.

10 Lọ́jọ́ kejì, Ọlọ́run jẹ́ kí ẹ̀mí búburú mú Sọ́ọ̀lù,+ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe wọ́nranwọ̀nran* nínú ilé, bí Dáfídì ṣe ń fi háàpù+ kọrin lọ́wọ́ bíi ti àtẹ̀yìnwá. Ọ̀kọ̀ kan wà lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù,+ 11 ó sì ju ọ̀kọ̀ náà,+ ó sọ fún ara rẹ̀ pé: ‘Màá gún Dáfídì mọ́ ògiri!’ Àmọ́ Dáfídì sá mọ́ ọn lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀mejì. 12 Sọ́ọ̀lù wá ń bẹ̀rù Dáfídì torí pé Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀,+ àmọ́ Ó ti fi Sọ́ọ̀lù sílẹ̀.+ 13 Torí náà, Sọ́ọ̀lù mú un kúrò níwájú rẹ̀, ó sì yàn án ṣe olórí ẹgbẹ̀rún, Dáfídì sì máa ń kó àwọn ọmọ ogun náà lọ sójú ogun.*+ 14 Dáfídì ń ṣàṣeyọrí*+ nínú gbogbo ohun tó ń ṣe, Jèhófà sì wà pẹ̀lú rẹ̀.+ 15 Bí Sọ́ọ̀lù ṣe rí i pé ó túbọ̀ ń ṣàṣeyọrí, ẹ̀rù rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í bà á. 16 Àmọ́ gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà nífẹ̀ẹ́ Dáfídì, nítorí pé òun ló ń kó wọn jáde.

17 Nígbà tó yá, Sọ́ọ̀lù sọ fún Dáfídì pé: “Wo Mérábù+ ọmọbìnrin mi àgbà. Màá fún ọ kí o fi ṣe aya.+ Síbẹ̀, jẹ́ kí n máa rí i pé o nígboyà, kí o sì máa ja àwọn ogun Jèhófà.”+ Torí Sọ́ọ̀lù sọ lọ́kàn ara rẹ̀ pé: ‘Mi ò ní fi ọwọ́ ara mi pa á. Àwọn Filísínì ló máa pa á.’+ 18 Ni Dáfídì bá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé: “Ta ni mí, ta sì ni àwọn ẹbí mi àti ìdílé bàbá mi ní Ísírẹ́lì, tí màá fi di àna* ọba?”+ 19 Àmọ́, nígbà tí ó tó àkókò láti fún Dáfídì ní Mérábù ọmọ Sọ́ọ̀lù, wọ́n ti fi í fún Ádíríélì+ ará Méhólá láti fi ṣe aya.

20 Míkálì, ọmọbìnrin Sọ́ọ̀lù,+ nífẹ̀ẹ́ Dáfídì gan-an, wọ́n sọ fún Sọ́ọ̀lù nípa rẹ̀, inú rẹ̀ sì dùn sí i. 21 Torí náà, Sọ́ọ̀lù sọ pé: “Màá fi fún un kó lè di ìdẹkùn fún un, kí ọwọ́ àwọn Filísínì lè tẹ̀ ẹ́.”+ Sọ́ọ̀lù bá sọ fún Dáfídì lẹ́ẹ̀kejì pé: “Wàá di àna* mi lónìí yìí.” 22 Yàtọ̀ síyẹn, Sọ́ọ̀lù pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ bá Dáfídì sọ̀rọ̀ ní bòókẹ́lẹ́ pé, ‘Wò ó! Inú ọba dùn sí ọ, gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gba tìẹ. Ní báyìí, bá ọba dána.’” 23 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Dáfídì, Dáfídì sọ pé: “Ṣé nǹkan kékeré ni lójú yín láti bá ọba dána, nígbà tí mo jẹ́ ọkùnrin aláìní àti ẹni tí a kò fi bẹ́ẹ̀ kà sí?”+ 24 Ìgbà náà ni àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù ròyìn ohun tí Dáfídì sọ fún un.

25 Sọ́ọ̀lù wá sọ pé: “Ohun tí ẹ máa sọ fún Dáfídì nìyí, ‘Ọba ò fẹ́ nǹkan ìdána kankan,+ àfi ọgọ́rùn-ún (100) adọ̀dọ́+ àwọn Filísínì, kó lè gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.’” Torí Sọ́ọ̀lù ń gbèrò pé kí Dáfídì ti ọwọ́ àwọn Filísínì ṣubú. 26 Torí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ ọ̀rọ̀ náà fún Dáfídì, ó sì dára lójú Dáfídì láti bá ọba dána.+ Ṣáájú àkókò tí wọ́n dá, 27 Dáfídì àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ lọ, wọ́n sì pa igba (200) lára àwọn ọkùnrin Filísínì, Dáfídì kó gbogbo adọ̀dọ́ wọn wá fún ọba, kó lè bá ọba dána. Torí náà, Sọ́ọ̀lù fún un ní Míkálì ọmọ rẹ̀ láti fi ṣe aya.+ 28 Sọ́ọ̀lù wá rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú Dáfídì+ àti pé Míkálì ọmọ rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Dáfídì.+ 29 Èyí mú kí Sọ́ọ̀lù túbọ̀ máa bẹ̀rù Dáfídì, Sọ́ọ̀lù sì wá di ọ̀tá Dáfídì jálẹ̀ ọjọ́ ayé rẹ̀.+

30 Àwọn ìjòyè Filísínì máa ń lọ sí ogun, àmọ́ ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá lọ, Dáfídì máa ń ṣàṣeyọrí* ju gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Sọ́ọ̀lù;+ wọ́n sì wá gbé orúkọ rẹ̀ ga gan-an.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́