ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 25
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Diutarónómì

      • Iye ẹgba tí wọ́n lè na èèyàn (1-3)

      • O ò gbọ́dọ̀ dí akọ màlúù tó ń pa ọkà lẹ́nu (4)

      • Ṣíṣú obìnrin lópó (5-10)

      • Tí obìnrin bá rá ọkùnrin mú ní abẹ́ (11, 12)

      • Ìwọ̀n àti òṣùwọ̀n tó péye (13-16)

      • Kí wọ́n pa àwọn Ámálékì run (17-19)

Diutarónómì 25:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 16:18; 17:8, 9; 19:16, 17
  • +Ẹk 23:6; 2Kr 19:6; Owe 17:15; 31:9

Diutarónómì 25:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 10:13; 20:30; 26:3; Lk 12:48; Heb 2:2

Diutarónómì 25:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 11:24

Diutarónómì 25:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 12:10; 1Kọ 9:9; 1Ti 5:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/2012, ojú ìwé 29-30

Diutarónómì 25:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 38:7, 8; Rut 4:5; Mk 12:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1715

Diutarónómì 25:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 38:9; Rut 4:10, 17
  • +Nọ 27:1, 4

Diutarónómì 25:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 7/2021,

Diutarónómì 25:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Rut 4:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/15/2004, ojú ìwé 26

Diutarónómì 25:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “orúkọ agbo ilé rẹ̀.” Ní Héb., “orúkọ rẹ̀.”

Diutarónómì 25:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ojú rẹ.”

Diutarónómì 25:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 11:1; 20:10; Mik 6:11

Diutarónómì 25:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “eéfà àti eéfà nínú ilé rẹ.” Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:36

Diutarónómì 25:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:40

Diutarónómì 25:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:35

Diutarónómì 25:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 17:8; Nọ 24:20

Diutarónómì 25:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 22:4
  • +Ẹk 17:14; 1Sa 14:47, 48; 15:1-3; 1Kr 4:42, 43

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ, ojú ìwé 144

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2012, ojú ìwé 29

Àwọn míì

Diu. 25:1Di 16:18; 17:8, 9; 19:16, 17
Diu. 25:1Ẹk 23:6; 2Kr 19:6; Owe 17:15; 31:9
Diu. 25:2Owe 10:13; 20:30; 26:3; Lk 12:48; Heb 2:2
Diu. 25:32Kọ 11:24
Diu. 25:4Owe 12:10; 1Kọ 9:9; 1Ti 5:18
Diu. 25:5Jẹ 38:7, 8; Rut 4:5; Mk 12:19
Diu. 25:6Jẹ 38:9; Rut 4:10, 17
Diu. 25:6Nọ 27:1, 4
Diu. 25:9Rut 4:7
Diu. 25:13Owe 11:1; 20:10; Mik 6:11
Diu. 25:14Le 19:36
Diu. 25:15Di 4:40
Diu. 25:16Le 19:35
Diu. 25:17Ẹk 17:8; Nọ 24:20
Diu. 25:19Joṣ 22:4
Diu. 25:19Ẹk 17:14; 1Sa 14:47, 48; 15:1-3; 1Kr 4:42, 43
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Diutarónómì 25:1-19

Diutarónómì

25 “Tí àwọn èèyàn bá ń bára wọn fa ọ̀rọ̀, kí wọ́n kó ara wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn adájọ́,+ wọ́n á sì bá wọn dá ẹjọ́ wọn, wọ́n á dá olódodo láre, wọ́n á sì dá ẹni burúkú lẹ́bi.+ 2 Tí ẹgba bá tọ́ sí ẹni burúkú náà,+ kí adájọ́ dá a dọ̀bálẹ̀, kí wọ́n sì nà án níṣojú rẹ̀. Bí ohun tó ṣe bá ṣe burú tó ni kí iye ẹgba tó máa jẹ ṣe pọ̀ tó. 3 Ó lè nà án ní ogójì [40] ẹgba,+ àmọ́ kó má jù bẹ́ẹ̀ lọ. Tó bá nà án ní iye tó ju ìyẹn lọ, ó máa dójú ti arákùnrin rẹ níṣojú rẹ.

4 “O ò gbọ́dọ̀ di ẹnu akọ màlúù nígbà tó bá ń pa ọkà.+

5 “Tí àwọn arákùnrin bá jọ ń gbé, tí ọ̀kan nínú wọn sì kú láìní ọmọ, ìyàwó èyí tó kú kò gbọ́dọ̀ fẹ́ ẹni tí kì í ṣe mọ̀lẹ́bí ọkọ rẹ̀. Kí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ọkọ rẹ̀ lọ bá a, kó sì fi ṣe aya, kó ṣú u lópó.+ 6 Ọmọ tí obìnrin náà bá kọ́kọ́ bí á mú kí orúkọ arákùnrin rẹ̀ tó kú náà ṣì máa wà,+ kí orúkọ náà má bàa pa rẹ́ ní Ísírẹ́lì.+

7 “Àmọ́ tí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ ṣú ìyàwó arákùnrin rẹ̀ lópó, kí ìyàwó arákùnrin rẹ̀ tó kú náà lọ bá àwọn àgbààgbà ní ẹnubodè ìlú, kó sì sọ fún wọn pé, ‘Arákùnrin ọkọ mi kò fẹ́ kí orúkọ arákùnrin rẹ̀ ṣì máa wà ní Ísírẹ́lì. Kò gbà láti ṣú mi lópó.’ 8 Kí àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀ wá pè é, kí wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀. Tó bá ṣì takú, tó ń sọ pé, ‘Mi ò fẹ́ ẹ,’ 9 kí ìyàwó arákùnrin rẹ̀ tó kú náà wá sún mọ́ ọn níṣojú àwọn àgbààgbà, kó bọ́ bàtà ẹsẹ̀ ọkùnrin náà,+ kó tutọ́ sí i lójú, kó sì sọ pé, ‘Ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe sí ọkùnrin tí kò fẹ́ kí ìdílé arákùnrin rẹ̀ ṣì máa wà nìyẹn.’ 10 Lẹ́yìn náà, wọ́n á mọ orúkọ ilé rẹ̀* sí ‘Ilé ẹni tí wọ́n bọ́ bàtà lẹ́sẹ̀ rẹ̀’ ní Ísírẹ́lì.

11 “Tí ọkùnrin méjì bá ń bára wọn jà, tí ìyàwó ọ̀kan sì wá gbèjà ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tó ń lù ú, tó na ọwọ́ rẹ̀, tó sì rá ọkùnrin náà mú ní abẹ́, 12 ṣe ni kí o gé ọwọ́ obìnrin náà. O* ò gbọ́dọ̀ káàánú rẹ̀.

13 “O ò gbọ́dọ̀ ní oríṣi òkúta ìwọ̀n méjì nínú àpò rẹ,+ èyí tó tóbi àti èyí tó kéré. 14 O ò gbọ́dọ̀ ní oríṣi òṣùwọ̀n méjì nínú ilé rẹ,*+ èyí tó tóbi àti èyí tó kéré. 15 Ìwọ̀n tó péye tó sì tọ́ àti òṣùwọ̀n tó péye tó sì tọ́ ni kí o máa lò, kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ.+ 16 Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ kórìíra gbogbo ẹni tó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, tó ń rẹ́ ẹlòmíì jẹ.+

17 “Ẹ rántí ohun tí Ámálékì ṣe sí yín lójú ọ̀nà nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì,+ 18 bó ṣe pàdé yín lójú ọ̀nà nígbà tó ti rẹ̀ yín, tí ẹ ò sì lókun, tó sì gbógun ja gbogbo àwọn tó ń wọ́ rìn lẹ́yìn yín. Kò bẹ̀rù Ọlọ́run. 19 Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ti mú kí o sinmi lọ́wọ́ gbogbo ọ̀tá rẹ tó yí ọ ká, ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún,+ kí o pa orúkọ Ámálékì rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run.+ O ò gbọ́dọ̀ gbàgbé.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́