ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Diutarónómì

      • Orílẹ̀-èdè méje tí wọ́n máa pa run (1-6)

      • Ìdí tí Ọlọ́run fi yan Ísírẹ́lì (7-11)

      • Wọ́n á ṣàṣeyọrí tí wọ́n bá ṣègbọràn (12-26)

Diutarónómì 7:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 31:3
  • +Ẹk 33:2; Joṣ 3:10
  • +Jẹ 15:16
  • +Jẹ 10:15-17
  • +Di 20:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ilẹ̀ Dáradára,” ojú ìwé 10-11

Diutarónómì 7:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 33:52
  • +Le 27:29; Joṣ 6:17; 10:28
  • +Ẹk 23:32; 34:15; Di 20:16, 17

Diutarónómì 7:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ẹ ò gbọ́dọ̀ fẹ́ ara yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 23:12, 13; 1Ọb 11:1, 2; Ẹsr 9:2

Diutarónómì 7:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:16; 1Ọb 11:4
  • +Di 6:14, 15

Diutarónómì 7:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:24; 34:13
  • +Di 16:21, 22
  • +Di 7:25; 12:2, 3

Diutarónómì 7:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó ṣeyebíye.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:5, 6; Di 14:2; Emọ 3:2

Diutarónómì 7:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 10:15
  • +Di 10:22

Diutarónómì 7:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “lábẹ́ agbára.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 22:16, 17
  • +Ẹk 6:6; 13:3, 14

Diutarónómì 7:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 34:6, 7

Diutarónómì 7:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 2:22; 2Pe 3:7

Diutarónómì 7:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ó máa bù kún èso ikùn rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:9
  • +Le 26:4
  • +Jẹ 13:14, 15

Diutarónómì 7:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 33:29; Sm 147:20
  • +Ẹk 23:26; Di 28:11; Sm 127:3

Diutarónómì 7:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:15, 27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    6/15/1991, ojú ìwé 4

Diutarónómì 7:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ojú rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 7:1, 2; 20:16; Joṣ 10:28
  • +Jẹ 15:16; Le 18:25; Di 9:5
  • +Ẹk 20:3
  • +Ẹk 23:33; Di 12:30; Ond 2:2, 3; Sm 106:36

Diutarónómì 7:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 13:31

Diutarónómì 7:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 1:29; 31:6; Sm 27:1; Ais 41:10
  • +Ẹk 14:13

Diutarónómì 7:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìgbẹ́jọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 9:10, 11; Jer 32:20
  • +Di 4:34
  • +Ẹk 23:28; Joṣ 3:10

Diutarónómì 7:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “bẹ̀rù; wárìrì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:29; Di 2:25; Joṣ 2:9; 24:12

Diutarónómì 7:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 14:9
  • +Di 10:17; 1Sa 4:7, 8

Diutarónómì 7:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:30

Diutarónómì 7:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 9:3

Diutarónómì 7:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 10:24; 12:1
  • +Ẹk 17:14; Sm 9:5
  • +Di 11:25; Joṣ 1:5; Ro 8:31
  • +Joṣ 11:14

Diutarónómì 7:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 12:3; 1Kr 14:12
  • +Ais 30:22
  • +Di 27:15

Àwọn míì

Diu. 7:1Di 31:3
Diu. 7:1Ẹk 33:2; Joṣ 3:10
Diu. 7:1Jẹ 15:16
Diu. 7:1Jẹ 10:15-17
Diu. 7:1Di 20:1
Diu. 7:2Nọ 33:52
Diu. 7:2Le 27:29; Joṣ 6:17; 10:28
Diu. 7:2Ẹk 23:32; 34:15; Di 20:16, 17
Diu. 7:3Joṣ 23:12, 13; 1Ọb 11:1, 2; Ẹsr 9:2
Diu. 7:4Ẹk 34:16; 1Ọb 11:4
Diu. 7:4Di 6:14, 15
Diu. 7:5Ẹk 23:24; 34:13
Diu. 7:5Di 16:21, 22
Diu. 7:5Di 7:25; 12:2, 3
Diu. 7:6Ẹk 19:5, 6; Di 14:2; Emọ 3:2
Diu. 7:7Di 10:15
Diu. 7:7Di 10:22
Diu. 7:8Jẹ 22:16, 17
Diu. 7:8Ẹk 6:6; 13:3, 14
Diu. 7:9Ẹk 34:6, 7
Diu. 7:10Owe 2:22; 2Pe 3:7
Diu. 7:13Le 26:9
Diu. 7:13Le 26:4
Diu. 7:13Jẹ 13:14, 15
Diu. 7:14Di 33:29; Sm 147:20
Diu. 7:14Ẹk 23:26; Di 28:11; Sm 127:3
Diu. 7:15Di 28:15, 27
Diu. 7:16Di 7:1, 2; 20:16; Joṣ 10:28
Diu. 7:16Jẹ 15:16; Le 18:25; Di 9:5
Diu. 7:16Ẹk 20:3
Diu. 7:16Ẹk 23:33; Di 12:30; Ond 2:2, 3; Sm 106:36
Diu. 7:17Nọ 13:31
Diu. 7:18Di 1:29; 31:6; Sm 27:1; Ais 41:10
Diu. 7:18Ẹk 14:13
Diu. 7:19Ne 9:10, 11; Jer 32:20
Diu. 7:19Di 4:34
Diu. 7:19Ẹk 23:28; Joṣ 3:10
Diu. 7:20Ẹk 23:29; Di 2:25; Joṣ 2:9; 24:12
Diu. 7:21Nọ 14:9
Diu. 7:21Di 10:17; 1Sa 4:7, 8
Diu. 7:22Ẹk 23:30
Diu. 7:23Di 9:3
Diu. 7:24Joṣ 10:24; 12:1
Diu. 7:24Ẹk 17:14; Sm 9:5
Diu. 7:24Di 11:25; Joṣ 1:5; Ro 8:31
Diu. 7:24Joṣ 11:14
Diu. 7:25Di 12:3; 1Kr 14:12
Diu. 7:25Ais 30:22
Diu. 7:25Di 27:15
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Diutarónómì 7:1-26

Diutarónómì

7 “Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá mú ọ dé ilẹ̀ tí o fẹ́ wọ̀ tí o sì máa gbà,+ ó máa mú àwọn orílẹ̀-èdè tí èèyàn wọn pọ̀ kúrò níwájú rẹ:+ àwọn ọmọ Hétì, àwọn Gẹ́gáṣì, àwọn Ámórì,+ àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn Pérísì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì,+ àwọn orílẹ̀-èdè méje tí èèyàn wọn pọ̀ tí wọ́n sì lágbára jù ọ́ lọ.+ 2 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́, wàá sì ṣẹ́gun wọn.+ Kí o rí i pé o pa wọ́n run pátápátá.+ O ò gbọ́dọ̀ bá wọn dá májẹ̀mú kankan, o ò sì gbọ́dọ̀ ṣojúure sí wọn rárá.+ 3 O ò gbọ́dọ̀ bá wọn dána rárá.* O ò gbọ́dọ̀ fi àwọn ọmọbìnrin rẹ fún àwọn ọmọkùnrin wọn, o ò sì gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ.+ 4 Torí wọn ò ní jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin rẹ tọ̀ mí lẹ́yìn mọ́, wọ́n á mú kí wọ́n máa sin àwọn ọlọ́run míì;+ Jèhófà máa wá bínú gidigidi sí ọ, kíákíá ló sì máa pa ọ́ run.+

5 “Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹ máa ṣe sí wọn nìyí: Ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn lulẹ̀, ẹ sì wó àwọn ọwọ̀n òrìṣà wọn,+ ẹ gé àwọn òpó òrìṣà* wọn,+ kí ẹ sì dáná sun àwọn ère gbígbẹ́ wọn.+ 6 Torí èèyàn mímọ́ lẹ jẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run yín, Jèhófà Ọlọ́run yín sì ti yàn yín kí ẹ lè di èèyàn rẹ̀, ohun ìní rẹ̀ pàtàkì,* nínú gbogbo èèyàn tó wà láyé.+

7 “Kì í ṣe torí pé ẹ̀yin lẹ pọ̀ jù nínú gbogbo èèyàn ni Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ yín tó sì yàn yín,+ ẹ̀yin lẹ kéré jù nínú gbogbo èèyàn.+ 8 Àmọ́ torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ yín, tó sì ṣe ohun tó búra fún àwọn baba ńlá yín+ pé òun máa ṣe ni Jèhófà ṣe fi ọwọ́ agbára mú yín kúrò, kó lè rà yín pa dà kúrò ní ilé ẹrú,+ kúrò lọ́wọ́* Fáráò ọba Íjíbítì. 9 O mọ̀ dáadáa pé Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run tó ṣeé fọkàn tán, tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́, tó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn títí dé ẹgbẹ̀rún ìran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.+ 10 Àmọ́ ó máa fi ìparun san ẹ̀san fún àwọn tó kórìíra rẹ̀ ní tààràtà.+ Kò ní jáfara láti fìyà jẹ àwọn tó kórìíra rẹ̀; ó máa san wọ́n lẹ́san lójúkojú. 11 Torí náà, rí i pé o pa àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà àti àwọn ìdájọ́ tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí mọ́, kí o máa tẹ̀ lé wọn.

12 “Tí ẹ bá ń tẹ́tí sí àwọn ìdájọ́ yìí, tí ẹ̀ ń tẹ̀ lé wọn, tí ẹ sì ń pa wọ́n mọ́, Jèhófà Ọlọ́run yín máa pa májẹ̀mú tó bá àwọn baba ńlá yín dá mọ́, ó sì máa fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn bó ṣe ṣèlérí. 13 Ó máa nífẹ̀ẹ́ rẹ, ó máa bù kún ọ, ó sì máa sọ ọ́ di púpọ̀. Àní, ó máa fi ọmọ púpọ̀ bù kún ọ,*+ ó máa fi èso ilẹ̀ rẹ bù kún ọ, ó sì máa fi ọkà rẹ, wáìnì tuntun rẹ, òróró rẹ,+ àwọn ọmọ màlúù nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn nínú agbo ẹran rẹ bù kún ọ ní ilẹ̀ tó búra fún àwọn baba ńlá rẹ pé òun máa fún ọ.+ 14 Ìwọ lo máa gba ìbùkún jù nínú gbogbo èèyàn;+ kò ní sí ọkùnrin tàbí obìnrin kankan láàárín rẹ tí kò ní bímọ, ẹran ọ̀sìn rẹ ò sì ní wà láìbímọ.+ 15 Jèhófà máa mú gbogbo àìsàn kúrò lára rẹ; kò sì ní jẹ́ kí ìkankan nínú gbogbo àrùn burúkú tí o ti mọ̀ ní Íjíbítì ṣe ọ́.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo àwọn tó kórìíra rẹ ló máa fi àrùn náà ṣe. 16 Kí o run gbogbo èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá fi lé ọ lọ́wọ́.+ O* ò gbọ́dọ̀ káàánú wọn,+ o ò sì gbọ́dọ̀ sin àwọn ọlọ́run wọn,+ torí ìdẹkùn ló máa jẹ́ fún ọ.+

17 “Tí o bá sọ ní ọkàn rẹ pé, ‘Àwọn orílẹ̀-èdè yìí pọ̀ jù wá lọ. Báwo ni màá ṣe lé wọn lọ?’+ 18 o ò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù wọn.+ Rán ara rẹ létí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣe sí Fáráò àti gbogbo Íjíbítì,+ 19 àwọn ìdájọ́* tó rinlẹ̀ tí o fojú ara rẹ rí, àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu+ àti ọwọ́ agbára àti apá tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ nà jáde tó fi mú ọ kúrò.+ Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa ṣe sí gbogbo àwọn tí ò ń bẹ̀rù nìyẹn.+ 20 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì* títí àwọn tó ṣẹ́ kù+ àti àwọn tó ń fara pa mọ́ fún ọ fi máa pa run. 21 Má gbọ̀n rìrì nítorí wọn, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà pẹ̀lú rẹ,+ Ọlọ́run tó tóbi ni, tó sì yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù.+

22 “Ó dájú pé díẹ̀díẹ̀ ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa lé àwọn orílẹ̀-èdè yìí kúrò níwájú rẹ.+ Kò ní jẹ́ kí o pa wọ́n run kíákíá, kí àwọn ẹranko búburú má bàa pọ̀ níbẹ̀ kí wọ́n sì ṣe yín lọ́ṣẹ́. 23 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ títí o fi máa ṣẹ́gun wọn tí o sì máa pa wọ́n run pátápátá.+ 24 Ó máa fi àwọn ọba wọn lé ọ lọ́wọ́,+ o sì máa pa orúkọ wọn run kúrò lábẹ́ ọ̀run.+ Kò sẹ́ni tó máa dìde sí ọ+ títí o fi máa pa wọ́n run tán.+ 25 Kí ẹ dáná sun ère àwọn ọlọ́run wọn tí wọ́n gbẹ́.+ Má ṣe jẹ́ kí ojú rẹ wọ fàdákà àti wúrà tó wà lára wọn, o ò sì gbọ́dọ̀ mú un fún ara rẹ,+ kó má bàa jẹ́ ìdẹkùn fún ọ, torí ohun ìríra ló jẹ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ 26 O ò gbọ́dọ̀ mú ohun ìríra wọnú ilé rẹ, kí o má bàa di ohun tí a máa pa run bí ohun ìríra náà. Kí o kà á sí ẹ̀gbin, kí o sì kórìíra rẹ̀ pátápátá, torí ohun tí a máa pa run ni.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́