ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Sámúẹ́lì 1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Sámúẹ́lì

      • Dáfídì gbọ́ nípa ikú Sọ́ọ̀lù (1-16)

      • Orin arò tí Dáfídì kọ nítorí Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì (17-27)

2 Sámúẹ́lì 1:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pa.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 27:5, 6

2 Sámúẹ́lì 1:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 31:1, 6; 1Kr 10:4, 6

2 Sámúẹ́lì 1:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 28:4; 1Kr 10:1
  • +1Sa 31:3; 1Kr 10:3

2 Sámúẹ́lì 1:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 17:16; Di 25:19; 1Sa 15:20; 30:1

2 Sámúẹ́lì 1:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹ̀mí mi kò tíì bọ́.”

2 Sámúẹ́lì 1:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “dáyádémà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 31:4

2 Sámúẹ́lì 1:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 31:11, 13
  • +1Sa 31:1

2 Sámúẹ́lì 1:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 12:8; 1Sa 24:6; 26:9; 31:4

2 Sámúẹ́lì 1:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 4:10

2 Sámúẹ́lì 1:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 1:6, 10

2 Sámúẹ́lì 1:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀fọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 31:6

2 Sámúẹ́lì 1:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 10:13

2 Sámúẹ́lì 1:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 31:8

2 Sámúẹ́lì 1:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aláìkọlà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 31:9

2 Sámúẹ́lì 1:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 31:1; 1Kr 10:1
  • +Le 27:16

2 Sámúẹ́lì 1:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:4; 20:20
  • +1Sa 14:47

2 Sámúẹ́lì 1:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹni àrídunnú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:1
  • +1Sa 31:6; 1Kr 10:6
  • +Job 9:26
  • +Owe 30:30

2 Sámúẹ́lì 1:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 31:8

2 Sámúẹ́lì 1:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 18:1, 3
  • +1Sa 19:2; 20:17, 41; 23:16-18; Owe 17:17; 18:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 5/2022,

Àwọn míì

2 Sám. 1:11Sa 27:5, 6
2 Sám. 1:41Sa 31:1, 6; 1Kr 10:4, 6
2 Sám. 1:61Sa 28:4; 1Kr 10:1
2 Sám. 1:61Sa 31:3; 1Kr 10:3
2 Sám. 1:8Ẹk 17:16; Di 25:19; 1Sa 15:20; 30:1
2 Sám. 1:101Sa 31:4
2 Sám. 1:121Sa 31:11, 13
2 Sám. 1:121Sa 31:1
2 Sám. 1:14Nọ 12:8; 1Sa 24:6; 26:9; 31:4
2 Sám. 1:152Sa 4:10
2 Sám. 1:162Sa 1:6, 10
2 Sám. 1:171Sa 31:6
2 Sám. 1:18Joṣ 10:13
2 Sám. 1:191Sa 31:8
2 Sám. 1:201Sa 31:9
2 Sám. 1:211Sa 31:1; 1Kr 10:1
2 Sám. 1:21Le 27:16
2 Sám. 1:221Sa 18:4; 20:20
2 Sám. 1:221Sa 14:47
2 Sám. 1:231Sa 18:1
2 Sám. 1:231Sa 31:6; 1Kr 10:6
2 Sám. 1:23Job 9:26
2 Sám. 1:23Owe 30:30
2 Sám. 1:251Sa 31:8
2 Sám. 1:261Sa 18:1, 3
2 Sám. 1:261Sa 19:2; 20:17, 41; 23:16-18; Owe 17:17; 18:24
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Sámúẹ́lì 1:1-27

Sámúẹ́lì Kejì

1 Lẹ́yìn ikú Sọ́ọ̀lù, nígbà tí Dáfídì dé láti ibi tí ó ti lọ ṣẹ́gun* àwọn ọmọ Ámálékì, Dáfídì dúró sí Síkílágì+ fún ọjọ́ méjì. 2 Ní ọjọ́ kẹta, ọkùnrin kan wá láti ibùdó Sọ́ọ̀lù, aṣọ rẹ̀ ti ya, iyẹ̀pẹ̀ sì wà lórí rẹ̀. Nígbà tí ó wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ó wólẹ̀, ó sì dọ̀bálẹ̀.

3 Dáfídì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ibo lo ti ń bọ̀?” Ó dáhùn pé: “Ibùdó Ísírẹ́lì ni mo ti sá wá.” 4 Dáfídì sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Báwo ni ọ̀hún ṣe rí? Jọ̀ọ́, sọ fún mi.” Ó dáhùn pé: “Àwọn èèyàn ti sá kúrò lójú ogun, ọ̀pọ̀ ló ti ṣubú tí wọ́n sì ti kú. Kódà Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀ ti kú.”+ 5 Dáfídì bá béèrè lọ́wọ́ ọ̀dọ́kùnrin tí ó wá ròyìn fún un pé: “Báwo lo ṣe mọ̀ pé Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀ ti kú?” 6 Ọ̀dọ́kùnrin náà fèsì pé: “Ó ṣẹlẹ̀ pé mo wà ní orí Òkè Gíbóà,+ ni mo bá rí Sọ́ọ̀lù tó fi ara ti ọ̀kọ̀ rẹ̀, àwọn tó ń gun kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn agẹṣin sì ti ká a mọ́.+ 7 Nígbà tí ó bojú wẹ̀yìn, tí ó rí mi, ó pè mí, mo sì sọ pé, ‘Èmi nìyí!’ 8 Ó béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Ta ni ọ́?’ Mo dá a lóhùn pé, ‘Ọmọ Ámálékì+ ni mí.’ 9 Ni ó bá sọ pé, ‘Jọ̀wọ́, dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi, kí o sì pa mí, nítorí mò ń jẹ̀rora gan-an, àmọ́ mo ṣì wà láàyè.’* 10 Torí náà, mo dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, mo sì pa á,+ nítorí mo mọ̀ pé kò lè yè é lẹ́yìn tí ó ti fara gbọgbẹ́ tí ó sì ti ṣubú. Lẹ́yìn náà, mo ṣí adé* orí rẹ̀, mo sì bọ́ ẹ̀gbà tó wà ní apá rẹ̀, mo sì kó wọn wá fún olúwa mi.”

11 Ni Dáfídì bá di ẹ̀wù ara rẹ̀ mú, ó sì fà á ya, gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. 12 Wọ́n pohùn réré ẹkún, wọ́n sunkún, wọ́n sì gbààwẹ̀+ títí di ìrọ̀lẹ́ nítorí Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀ àti nítorí àwọn èèyàn Jèhófà àti ilé Ísírẹ́lì+ torí pé wọ́n ti fi idà pa wọ́n.

13 Dáfídì béèrè lọ́wọ́ ọ̀dọ́kùnrin tó wá ròyìn fún un pé: “Ibo lo ti wá?” Ó sọ pé: “Ọmọ Ámálékì ni bàbá mi, àjèjì ni nílẹ̀ Ísírẹ́lì.” 14 Ìgbà náà ni Dáfídì sọ fún un pé: “Kí ló dé tí ẹ̀rù ò fi bà ọ́ láti gbé ọwọ́ rẹ sókè láti pa ẹni àmì òróró Jèhófà?”+ 15 Dáfídì bá pe ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀, ó sì sọ pé: “Bọ́ síwájú, kí o sì ṣá a balẹ̀.” Torí náà, ó ṣá a balẹ̀, ó sì kú.+ 16 Dáfídì sọ fún un pé: “Ẹ̀jẹ̀ rẹ wà ní orí ìwọ fúnra rẹ, nítorí ẹnu rẹ ló kó bá ọ, bí o ṣe sọ pé, ‘Èmi ni mo pa ẹni àmì òróró Jèhófà.’”+

17 Dáfídì wá kọ orin arò* yìí nítorí Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì ọmọ rẹ̀,+ 18 ó sì ní kí wọ́n kọ́ àwọn èèyàn Júdà ní orin arò tí wọ́n pè ní “Ọrun,” tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Jáṣárì:+

19 “Ìwọ Ísírẹ́lì, wọ́n ti pa ẹwà lórí àwọn ibi gíga rẹ.+

Wo bí àwọn alágbára ṣe ṣubú!

20 Ẹ má sọ ọ́ ní Gátì;+

Ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní àwọn ojú ọ̀nà Áṣíkẹ́lónì,

Kí àwọn ọmọbìnrin Filísínì má bàa yọ̀,

Kí àwọn ọmọbìnrin àwọn aláìdádọ̀dọ́* má bàa dunnú.

21 Ẹ̀yin òkè Gíbóà,+

Kí ìrì má sẹ̀, kí òjò má sì rọ̀ sórí yín,

Bẹ́ẹ̀ ni kí pápá má ṣe mú ọrẹ mímọ́+ jáde,

Nítorí pé ibẹ̀ ni wọ́n ti sọ apata àwọn alágbára di aláìmọ́,

A kò sì fi òróró pa apata Sọ́ọ̀lù mọ́.

22 Ọrun Jónátánì+ àti idà Sọ́ọ̀lù+

Ti rẹ nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn ọ̀tá, ó sì ti gún ọ̀rá àwọn jagunjagun,

Wọn kì í tàsé.

23 Sọ́ọ̀lù àti Jónátánì,+ àwọn ẹni ọ̀wọ́n àti àyànfẹ́* nígbà ayé wọn,

A kò sì pín wọn níyà nígbà ikú wọn.+

Wọ́n yára ju ẹyẹ idì lọ,+

Wọ́n lágbára ju kìnnìún lọ.+

24 Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ísírẹ́lì, ẹ sunkún nítorí Sọ́ọ̀lù,

Ẹni tí ó fi aṣọ rírẹ̀dòdò àti ohun ọ̀ṣọ́ wọ̀ yín,

Ẹni tí ó fi ohun ọ̀ṣọ́ wúrà sára aṣọ yín.

25 Wo bí àwọn alágbára ṣe ṣubú lójú ogun!

Wọ́n ti pa Jónátánì sílẹ̀ lórí ibi gíga!+

26 Ẹ̀dùn ọkàn bá mi nítorí rẹ, Jónátánì arákùnrin mi;

Ẹni ọ̀wọ́n lo jẹ́ sí mi.+

Ìfẹ́ tí o ní sí mi lágbára ju ti obìnrin lọ.+

27 Wo bí àwọn alágbára ṣe ṣubú

Tí àwọn ohun ìjà sì ṣègbé!”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́