ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àwọn Onídàájọ́ 5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àwọn Onídàájọ́

      • Dèbórà àti Bárákì kọrin ìṣẹ́gun (1-31)

        • Àwọn ìràwọ̀ bá Sísérà jà (20)

        • Ọ̀gbàrá Kíṣónì kún àkúnya (21)

        • Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dà bí oòrùn (31)

Àwọn Onídàájọ́ 5:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:4
  • +Ond 4:6; Heb 11:32
  • +Ẹk 15:1; Sm 18:àkọlé

Àwọn Onídàájọ́ 5:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn jagunjagun tó tú irun sílẹ̀ jọwọrọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:10

Àwọn Onídàájọ́ 5:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kọ orin sí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 22:50; Sm 7:17
  • +Ẹk 20:2

Àwọn Onídàájọ́ 5:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 33:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 14

Àwọn Onídàájọ́ 5:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “mì tìtì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:11
  • +Ẹk 19:18; Ne 9:13
  • +Ẹk 20:2

Àwọn Onídàájọ́ 5:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 3:31
  • +Ond 4:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 12-13

Àwọn Onídàájọ́ 5:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Àwọn ará abúlé tán.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:4
  • +Ond 4:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 12-13

    11/15/2003, ojú ìwé 28

Àwọn Onídàájọ́ 5:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:16, 17; Ond 2:12
  • +Ond 4:1-3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 12

    11/15/2003, ojú ìwé 29

    12/15/1998, ojú ìwé 11-12

Àwọn Onídàájọ́ 5:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:6
  • +Ond 4:10

Àwọn Onídàájọ́ 5:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2017, ojú ìwé 30-31

Àwọn Onídàájọ́ 5:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:4
  • +Ond 5:1
  • +Ond 4:6

Àwọn Onídàájọ́ 5:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “àwọn tó ń gbé ohun èlò àwọn akọ̀wé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 32:39

Àwọn Onídàájọ́ 5:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pẹ̀tẹ́lẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:6; Heb 11:32
  • +Ond 4:14

Àwọn Onídàájọ́ 5:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, àpò ẹrù tí wọ́n máa ń so mọ́ ẹ̀yìn ẹranko arẹrù.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 32:1

Àwọn Onídàájọ́ 5:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 22:9
  • +Joṣ 19:46, 48
  • +Joṣ 19:24, 29

Àwọn Onídàájọ́ 5:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kórìíra ọkàn wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:6, 10
  • +Ond 4:14

Àwọn Onídàájọ́ 5:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:13
  • +Ond 1:27
  • +Ond 4:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 14

Àwọn Onídàájọ́ 5:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2017, ojú ìwé 30

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2005, ojú ìwé 25

    11/15/2003, ojú ìwé 30

Àwọn Onídàájọ́ 5:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Odò.”

  • *

    Tàbí “Odò.”

  • *

    Tàbí “odò.”

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:7, 13; Sm 83:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2017, ojú ìwé 30

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 14

    12/15/1998, ojú ìwé 11-12

Àwọn Onídàájọ́ 5:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 20:7; Owe 21:31

Àwọn Onídàájọ́ 5:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2017, ojú ìwé 30

Àwọn Onídàájọ́ 5:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:17
  • +Ond 4:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 15

Àwọn Onídàájọ́ 5:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:19

Àwọn Onídàájọ́ 5:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:21, 22

Àwọn Onídàájọ́ 5:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wíńdò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 4:15, 16

Àwọn Onídàájọ́ 5:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ilé ọmọ.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2015, ojú ìwé 13

    11/15/2003, ojú ìwé 31

Àwọn Onídàájọ́ 5:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ilẹ̀ náà sì sinmi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 83:9
  • +Ond 3:10, 11, 30

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 18

Àwọn míì

Oníd. 5:1Ond 4:4
Oníd. 5:1Ond 4:6; Heb 11:32
Oníd. 5:1Ẹk 15:1; Sm 18:àkọlé
Oníd. 5:2Ond 4:10
Oníd. 5:32Sa 22:50; Sm 7:17
Oníd. 5:3Ẹk 20:2
Oníd. 5:4Di 33:2
Oníd. 5:5Di 4:11
Oníd. 5:5Ẹk 19:18; Ne 9:13
Oníd. 5:5Ẹk 20:2
Oníd. 5:6Ond 3:31
Oníd. 5:6Ond 4:17
Oníd. 5:7Ond 4:4
Oníd. 5:7Ond 4:5
Oníd. 5:8Di 32:16, 17; Ond 2:12
Oníd. 5:8Ond 4:1-3
Oníd. 5:9Ond 4:6
Oníd. 5:9Ond 4:10
Oníd. 5:12Ond 4:4
Oníd. 5:12Ond 5:1
Oníd. 5:12Ond 4:6
Oníd. 5:14Nọ 32:39
Oníd. 5:15Ond 4:6; Heb 11:32
Oníd. 5:15Ond 4:14
Oníd. 5:16Nọ 32:1
Oníd. 5:17Joṣ 22:9
Oníd. 5:17Joṣ 19:46, 48
Oníd. 5:17Joṣ 19:24, 29
Oníd. 5:18Ond 4:6, 10
Oníd. 5:18Ond 4:14
Oníd. 5:19Ond 4:13
Oníd. 5:19Ond 1:27
Oníd. 5:19Ond 4:16
Oníd. 5:21Ond 4:7, 13; Sm 83:9
Oníd. 5:22Sm 20:7; Owe 21:31
Oníd. 5:24Ond 4:17
Oníd. 5:24Ond 4:11
Oníd. 5:25Ond 4:19
Oníd. 5:26Ond 4:21, 22
Oníd. 5:28Ond 4:15, 16
Oníd. 5:31Sm 83:9
Oníd. 5:31Ond 3:10, 11, 30
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àwọn Onídàájọ́ 5:1-31

Àwọn Onídàájọ́

5 Ní ọjọ́ yẹn, Dèbórà+ àti Bárákì+ ọmọ Ábínóámù kọ orin+ yìí, wọ́n ní:

 2 “Torí irun tí wọ́n tú sílẹ̀ jọwọrọ* ní Ísírẹ́lì,

Torí pé àwọn èèyàn yọ̀ǹda+ ara wọn,

Ẹ yin Jèhófà!

 3 Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ọba! Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ẹ̀yin aláṣẹ!

Jèhófà ni màá kọrin sí.

Màá fi orin yin* Jèhófà,+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+

 4 Jèhófà, nígbà tí o jáde ní Séírì,+

Nígbà tí o kúrò ní ilẹ̀ Édómù,

Ayé mì tìtì, omi ọ̀run sì ya,

Omi ya bolẹ̀ látojú ọ̀run.

 5 Àwọn òkè yọ́* níwájú Jèhófà,+

Títí kan Sínáì, níwájú Jèhófà,+ Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+

 6 Nígbà ayé Ṣámúgárì+ ọmọ Ánátì,

Nígbà ayé Jáẹ́lì,+ àwọn ojú ọ̀nà dá páropáro;

Ọ̀nà ẹ̀yìn ni àwọn arìnrìn-àjò ń gbà.

 7 Kò sí àwọn tó ń gbé ní abúlé mọ́* ní Ísírẹ́lì;

Wọn ò sí mọ́ títí èmi, Dèbórà,+ fi dìde,

Títí mo fi di ìyá ní Ísírẹ́lì.+

 8 Wọ́n yan àwọn ọlọ́run tuntun;+

Ogun wá dé àwọn ẹnubodè.+

A ò rí apata tàbí aṣóró kankan,

Láàárín ọ̀kẹ́ méjì (40,000) ní Ísírẹ́lì.

 9 Ọkàn mi wà lọ́dọ̀ àwọn ọ̀gágun Ísírẹ́lì,+

Tó yọ̀ǹda ara wọn láti bá àwọn èèyàn náà+ lọ.

Ẹ yin Jèhófà!

10 Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláwọ̀ pupa tí a pò mọ́ yẹ́lò,

Ẹ̀yin tí ẹ jókòó sórí àwọn kápẹ́ẹ̀tì tó rẹwà,

Àti ẹ̀yin tí ẹ̀ ń rìn lójú ọ̀nà,

Ẹ rò ó!

11 A gbọ́ ohùn àwọn tó ń pín omi níbi tí wọ́n ń pọn omi sí;

Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń ròyìn àwọn iṣẹ́ òdodo tí Jèhófà ṣe,

Àwọn iṣẹ́ òdodo tí àwọn ará abúlé rẹ̀ ní Ísírẹ́lì ṣe.

Àwọn èèyàn Jèhófà wá lọ sí àwọn ẹnubodè.

12 Jí, jí, ìwọ Dèbórà!+

Jí, jí, kọ orin kan!+

Dìde, Bárákì!+ Kó àwọn ẹrú rẹ lọ, ìwọ ọmọ Ábínóámù!

13 Àwọn yòókù wá bá àwọn èèyàn pàtàkì;

Àwọn èèyàn Jèhófà wá bá mi láti bá àwọn alágbára jà.

14 Éfúrémù ni wọ́n ti wá, àwọn tó wà ní àfonífojì;*

Ìwọ Bẹ́ńjámínì, wọ́n ń tẹ̀ lé ọ láàárín àwọn èèyàn rẹ.

Láti Mákírù+ ni àwọn olórí ogun ti lọ,

Láti Sébúlúnì sì ni àwọn tó ń lo ọ̀pá ọ̀gágun* ti jáde.

15 Àwọn olórí láti Ísákà wà lọ́dọ̀ Dèbórà,

Bíi ti Ísákà, bẹ́ẹ̀ náà ni Bárákì.+

Wọ́n rán an pé kó fi ẹsẹ̀ rìn+ lọ sí àfonífojì.*

A yẹ ọkàn àwọn ìpín Rúbẹ́nì wò fínnífínní.

16 Kí ló dé tí o jókòó sáàárín àpò ẹrù méjì,*

Tí ò ń fetí sí wọn bí wọ́n ṣe ń fọn fèrè ape wọn fún agbo ẹran?+

A yẹ ọkàn àwọn ìpín Rúbẹ́nì wò fínnífínní.

17 Gílíádì ṣì wà ní ìsọdá Jọ́dánì;+

Kí ló dé tí Dánì fi dúró ti àwọn ọkọ̀ òkun?+

Áṣérì jókòó gẹlẹtẹ sí etíkun,

Kò sì kúrò+ níbi tí àwọn ọkọ̀ òkun rẹ̀ ń gúnlẹ̀ sí.

18 Àwọn èèyàn tó fi ẹ̀mí wọn wewu* dójú ikú ni Sébúlúnì;

Bẹ́ẹ̀ náà ni Náfútálì,+ lórí àwọn ibi gíga níbi gbalasa.+

19 Àwọn ọba wá, wọ́n sì jà;

Àwọn ọba Kénáánì wá jà  +

Ní Táánákì, létí omi Mẹ́gídò.+

Wọn ò kó+ fàdákà kankan lójú ogun.

20 Àwọn ìràwọ̀ jà láti ọ̀run;

Wọ́n bá Sísérà jà láti ibi tí wọ́n ń gbà yí po.

21 Ọ̀gbàrá* Kíṣónì gbá wọn lọ,+

Ọ̀gbàrá* àtijọ́, ọ̀gbàrá* Kíṣónì.

O tẹ alágbára mọ́lẹ̀, ìwọ ọkàn* mi.

22 Pátákò àwọn ẹṣin wá ń kilẹ̀

Bí àwọn akọ ẹṣin rẹ̀ ṣe ń bẹ́ gìjà.+

23 Áńgẹ́lì Jèhófà sọ pé, ‘Ẹ gégùn-ún fún Mérósì,

Àní, ẹ gégùn-ún fún àwọn tó ń gbé ibẹ̀,

Torí wọn ò wá ran Jèhófà lọ́wọ́,

Wọn ò tẹ̀ lé àwọn alágbára láti wá ran Jèhófà lọ́wọ́.’

24 Ẹni tí a bù kún jù lọ nínú àwọn obìnrin ni Jáẹ́lì,+

Ìyàwó Hébà+ ará Kénì;

Òun ni a bù kún jù lọ nínú àwọn obìnrin tó ń gbé inú àgọ́.

25 Omi ló béèrè; wàrà ló fún un.

Abọ́ tó níyì tí wọ́n fi ń jẹ àsè ló fi gbé wàrà dídì+ fún un.

26 Ó na ọwọ́ mú èèkàn àgọ́,

Ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù àwọn òṣìṣẹ́.

Ó sì fi kàn án mọ́ Sísérà, ó fọ́ orí rẹ̀,

Ó fọ́ ẹ̀bátí rẹ̀,+ ó dá a lu.

27 Ó wó lulẹ̀ sáàárín ẹsẹ̀ rẹ̀; ó ṣubú, kò lè dìde;

Ó wó lulẹ̀, ó sì ṣubú sáàárín ẹsẹ̀ rẹ̀;

Ibi tó wó lulẹ̀ sí, ibẹ̀ ló ṣubú sí tí wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀.

28 Obìnrin kan yọjú lójú fèrèsé,*

Ìyá Sísérà yọjú níbi fèrèsé tó ní asẹ́ onígi,

‘Kí ló dé tí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ò tíì dé?

Kí ló dé tí a ò gbúròó ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin tó ń fa kẹ̀kẹ́ rẹ̀?’+

29 Àwọn tó gbọ́n jù nínú àwọn obìnrin rẹ̀ pàtàkì máa dá a lóhùn;

Àní, òun náà máa tún un sọ fún ara rẹ̀ pé,

30 ‘Ó ní láti jẹ́ pé ẹrù ogun tí wọ́n kó ni wọ́n ń pín,

Ọmọbìnrin* kan, ọmọbìnrin méjì, fún jagunjagun kọ̀ọ̀kan,

Aṣọ aláró tí wọ́n kó lójú ogun fún Sísérà, aṣọ aláró tí wọ́n kó,

Aṣọ tí wọ́n kóṣẹ́ sí, aṣọ aláró, aṣọ méjì tí wọ́n kóṣẹ́ sí

Fún ọrùn àwọn tó kó ẹrù ogun.’

31 Jẹ́ kí gbogbo ọ̀tá rẹ ṣègbé,+ Jèhófà,

Àmọ́ kí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ dà bí oòrùn tó ń yọ nínú ògo rẹ̀.”

Àlàáfíà sì wà ní ilẹ̀ náà* fún ogójì (40) ọdún.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́