ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Ìsíkíẹ́lì wà ní Bábílónì, ó ń rí ìran látọ̀dọ̀ Ọlọ́run (1-3)

      • Ìran kẹ̀kẹ́ ẹṣin Jèhófà tó wà lọ́run (4-28)

        • Ìjì líle, ìkùukùu àti iná (4)

        • Ẹ̀dá alààyè mẹ́rin (5-14)

        • Àgbá kẹ̀kẹ́ mẹ́rin (15-21)

        • Ohun kan tó tẹ́ pẹrẹsẹ, tó ń tàn yinrin bíi yìnyín (22-24)

        • Ìtẹ́ Jèhófà (25-28)

Ìsíkíẹ́lì 1:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 3:15
  • +2Ọb 24:12, 14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 23, 31

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/1998, ojú ìwé 15

Ìsíkíẹ́lì 1:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:9, 10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 31

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/1998, ojú ìwé 15

Ìsíkíẹ́lì 1:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Ló Ń Fúnni Lókun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 22:25
  • +Isk 3:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 30, 48-49

Ìsíkíẹ́lì 1:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọsánmà.”

  • *

    Tàbí “mànàmáná.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:11
  • +Ẹk 19:18; Sm 97:2, 3
  • +Isk 8:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 30

Ìsíkíẹ́lì 1:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 10:9, 15; Ifi 4:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 43

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2007, ojú ìwé 12

    3/1/1991, ojú ìwé 31

Ìsíkíẹ́lì 1:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 6:2; Isk 10:20, 21; Ifi 4:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 43, 238

Ìsíkíẹ́lì 1:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 10:5, 6

Ìsíkíẹ́lì 1:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 10:11, 15

Ìsíkíẹ́lì 1:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 17:10; Owe 28:1
  • +Owe 14:4
  • +Isk 10:14, 15; Ifi 4:7
  • +Job 39:27, 29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 43, 238

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/15/1991, ojú ìwé 9

Ìsíkíẹ́lì 1:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 6:2

Ìsíkíẹ́lì 1:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 103:20; Heb 1:7, 14

Ìsíkíẹ́lì 1:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:9, 10

Ìsíkíẹ́lì 1:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 10:9-13; Ifi 4:7

Ìsíkíẹ́lì 1:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kí wọ́n dábùú ara wọn ní àárín méjì.

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 36-37

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/15/1991, ojú ìwé 9

Ìsíkíẹ́lì 1:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 37

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/15/1991, ojú ìwé 9-10

Ìsíkíẹ́lì 1:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 15:3; Sek 4:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 37

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/15/1991, ojú ìwé 9

Ìsíkíẹ́lì 1:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 10:15-17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 40

Ìsíkíẹ́lì 1:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹ̀mí ẹ̀dá alààyè náà.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 38-39

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/15/1991, ojú ìwé 10

Ìsíkíẹ́lì 1:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 38-39

Ìsíkíẹ́lì 1:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 10:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 38-39

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/15/1991, ojú ìwé 10

Ìsíkíẹ́lì 1:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ìyẹ́ wọn rí gbọọrọ.”

Ìsíkíẹ́lì 1:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 29:3; Isk 43:2; Ifi 14:2

Ìsíkíẹ́lì 1:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 24:10; Sm 96:6; Isk 10:1
  • +1Ọb 22:19; Sm 99:1; Ais 6:1; Ifi 4:2
  • +Da 7:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 33, 39

Ìsíkíẹ́lì 1:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 8:2
  • +Di 4:24; Sm 104:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 39-40

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 6 2016 ojú ìwé 4

Ìsíkíẹ́lì 1:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 4:3
  • +Ẹk 24:16, 17; Isk 8:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 39-40

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 6 2016 ojú ìwé 4

Àwọn míì

Ìsík. 1:1Isk 3:15
Ìsík. 1:12Ọb 24:12, 14
Ìsík. 1:22Kr 36:9, 10
Ìsík. 1:3Jer 22:25
Ìsík. 1:3Isk 3:14
Ìsík. 1:41Ọb 19:11
Ìsík. 1:4Ẹk 19:18; Sm 97:2, 3
Ìsík. 1:4Isk 8:2
Ìsík. 1:5Isk 10:9, 15; Ifi 4:6
Ìsík. 1:6Ais 6:2; Isk 10:20, 21; Ifi 4:8
Ìsík. 1:7Da 10:5, 6
Ìsík. 1:9Isk 10:11, 15
Ìsík. 1:102Sa 17:10; Owe 28:1
Ìsík. 1:10Owe 14:4
Ìsík. 1:10Isk 10:14, 15; Ifi 4:7
Ìsík. 1:10Job 39:27, 29
Ìsík. 1:11Ais 6:2
Ìsík. 1:12Sm 103:20; Heb 1:7, 14
Ìsík. 1:13Da 7:9, 10
Ìsík. 1:15Isk 10:9-13; Ifi 4:7
Ìsík. 1:18Owe 15:3; Sek 4:10
Ìsík. 1:19Isk 10:15-17
Ìsík. 1:22Isk 10:1
Ìsík. 1:24Sm 29:3; Isk 43:2; Ifi 14:2
Ìsík. 1:26Ẹk 24:10; Sm 96:6; Isk 10:1
Ìsík. 1:261Ọb 22:19; Sm 99:1; Ais 6:1; Ifi 4:2
Ìsík. 1:26Da 7:9
Ìsík. 1:27Isk 8:2
Ìsík. 1:27Di 4:24; Sm 104:1, 2
Ìsík. 1:28Ifi 4:3
Ìsík. 1:28Ẹk 24:16, 17; Isk 8:4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 1:1-28

Ìsíkíẹ́lì

1 Ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹrin, ọdún ọgbọ̀n, nígbà tí mo wà lẹ́bàá odò Kébárì+ láàárín àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn,+ ọ̀run ṣí sílẹ̀, mo sì rí ìran látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. 2 Ní ọjọ́ karùn-ún oṣù náà, ìyẹn, ọdún karùn-ún tí Ọba Jèhóákínì ti wà ní ìgbèkùn,+ 3 Jèhófà bá Ìsíkíẹ́lì* ọmọ àlùfáà Búúsì sọ̀rọ̀ lẹ́bàá odò Kébárì ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà.+ Ọwọ́ Jèhófà sì wá sórí rẹ̀ níbẹ̀.+

4 Bí mo ṣe ń wò, mo rí i tí ìjì líle+ ń fẹ́ bọ̀ láti àríwá, ìkùukùu* ńlá wà níbẹ̀, iná* sì ń kọ mànà, ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò+ yí i ká, ohun kan sì wà nínú iná náà tó ń tàn yanran bí àyọ́pọ̀ wúrà àti fàdákà.+ 5 Àwọn ohun tó dà bí ẹ̀dá alààyè mẹ́rin+ wà nínú rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì rí bí èèyàn. 6 Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú mẹ́rin àti ìyẹ́ apá mẹ́rin.+ 7 Ẹsẹ̀ wọn rí gbọọrọ, àtẹ́lẹsẹ̀ wọn dà bíi ti ọmọ màlúù, wọ́n sì ń kọ mànà bíi bàbà dídán.+ 8 Wọ́n ní ọwọ́ èèyàn lábẹ́ ìyẹ́ wọn ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì ní ojú àti ìyẹ́. 9 Àwọn ìyẹ́ wọn ń kan ara wọn. Wọn kì í yà síbì kankan bí wọ́n ṣe ń lọ; iwájú tààrà ni kálukú wọn ń lọ.+

10 Bí ojú wọn ṣe rí nìyí: Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ojú èèyàn, ojú kìnnìún+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀tún, ojú akọ màlúù+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òsì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ní ojú+ idì.+ 11 Bí ojú wọn ṣe rí nìyẹn. Wọ́n na ìyẹ́ apá wọn sókè. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìyẹ́ méjì tó kanra àti ìyẹ́ méjì tó fi bo ara.+

12 Iwájú tààrà ni kálukú wọn ń lọ, ibikíbi tí ẹ̀mí bá darí wọn sí ni wọ́n ń lọ.+ Wọn kì í yà síbì kankan bí wọ́n ṣe ń lọ. 13 Àwọn ẹ̀dá alààyè náà rí bí ẹyin iná tó ń jó, ohun kan tó rí bí ògùṣọ̀ tí iná rẹ̀ mọ́lẹ̀ yòò ń lọ síwá-sẹ́yìn láàárín àwọn ẹ̀dá alààyè náà, mànàmáná sì ń kọ látinú iná náà.+ 14 Bí àwọn ẹ̀dá alààyè náà ṣe ń lọ tí wọ́n ń bọ̀, lílọ bíbọ̀ wọn dà bíi ti mànàmáná.

15 Bí mo ṣe ń wo àwọn ẹ̀dá alààyè náà, mo rí àgbá kẹ̀kẹ́ kan lórí ilẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀dá alààyè tó ní ojú mẹ́rin náà.+ 16 Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà àti iṣẹ́ ara wọn ń dán bí òkúta kírísóláítì, àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sì jọra. Iṣẹ́ ara wọn àti bí wọ́n ṣe rí dà bí ìgbà tí àgbá kẹ̀kẹ́ kan wà nínú àgbá kẹ̀kẹ́ míì.* 17 Tí wọ́n bá ń lọ, wọ́n lè lọ sí ibikíbi ní ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin láì ṣẹ́rí pa dà. 18 Àwọn àgbá náà ga débi pé wọ́n ń bani lẹ́rù, ojú sì wà káàkiri ara àgbá mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà.+ 19 Tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá ń lọ, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà a lọ pẹ̀lú wọn, tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá sì gbéra sókè, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà á gbéra sókè.+ 20 Wọ́n á lọ sí ibi tí ẹ̀mí bá darí wọn sí, ìyẹn ibikíbi tí ẹ̀mí náà bá lọ. Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà á gbéra pẹ̀lú wọn, torí ẹ̀mí tó ń darí àwọn ẹ̀dá alààyè náà* tún wà nínú àwọn àgbá náà. 21 Tí wọ́n bá ń lọ, àwọn àgbá náà máa ń tẹ̀ lé wọn; tí wọ́n bá dúró, àwọn àgbá náà á dúró; tí wọ́n bá sì gbéra sókè, àwọn àgbá náà á gbéra pẹ̀lú wọn, torí ẹ̀mí tó ń darí àwọn ẹ̀dá alààyè náà tún wà nínú àwọn àgbá náà.

22 Ohun kan tó tẹ́ lọ pẹrẹsẹ wà lórí àwọn ẹ̀dá alààyè náà, ó ń dán bíi yìnyín tó mọ́ kedere, ó tẹ́ pẹrẹsẹ lórí wọn.+ 23 Wọ́n na ìyẹ́ wọn sókè* lábẹ́ ohun tó tẹ́ pẹrẹsẹ náà, wọ́n sì kanra wọn. Kálukú wọn ní ìyẹ́ méjì tó fi bo ara rẹ̀ lápá kan àti méjì tó fi bo ara rẹ̀ lápá kejì. 24 Nígbà tí mo gbọ́ ìró ìyẹ́ wọn, ó dà bí ìró omi púpọ̀ tó ń rọ́ jáde, bí ìró láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè.+ Tí wọ́n bá gbéra, ìró wọn dà bíi ti àwọn ọmọ ogun. Tí wọ́n bá dúró, wọ́n á ká ìyẹ́ wọn sílẹ̀.

25 Ohùn kan dún lókè ohun tó tẹ́ pẹrẹsẹ lórí wọn. (Tí wọ́n bá sì dúró, wọ́n á ká ìyẹ́ wọn sílẹ̀.) 26 Ohun tó rí bí òkúta sàfáyà+ wà lókè ohun tó tẹ́ pẹrẹsẹ lórí wọn, ó dà bí ìtẹ́.+ Ẹnì kan tó rí bí èèyàn sì jókòó sórí ìtẹ́ náà.+ 27 Mo sì rí ohun kan tó ń dán yanran bí àyọ́pọ̀ wúrà àti fàdákà,+ ó rí bí iná, ó jọ pé ó ń jó látibi ìbàdí rẹ̀ lọ sókè; mo rí ohun kan tó dà bí iná+ láti ìbàdí rẹ̀ lọ sísàlẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ sì tàn yòò yí i ká 28 bí òṣùmàrè+ tó yọ lójú ọ̀run lọ́jọ́ tí òjò rọ̀. Bí ìmọ́lẹ̀ iná tó yí i ká ṣe rí nìyẹn. Ó rí bí ògo Jèhófà.+ Nígbà tí mo rí i, mo dojú bolẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ ohùn ẹnì kan tó ń sọ̀rọ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́