ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Àwọn Ọba

      • Jéhù pa agbo ilé Áhábù (1-17)

        • Jèhónádábù dara pọ̀ mọ́ Jéhù (15-17)

      • Jéhù pa àwọn olùjọ́sìn Báálì (18-27)

      • Àkópọ̀ ìṣàkóso Jéhù (28-36)

2 Àwọn Ọba 10:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn olùtọ́jú Áhábù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 16:29
  • +1Ọb 21:8

2 Àwọn Ọba 10:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “dúró ṣánṣán.”

2 Àwọn Ọba 10:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 9:24, 27

2 Àwọn Ọba 10:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ilé.”

2 Àwọn Ọba 10:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 21:21

2 Àwọn Ọba 10:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Olódodo ni yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 9:14, 24

2 Àwọn Ọba 10:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “tó máa já bọ́ sílẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 15:29; Ais 14:27
  • +1Ọb 21:19-24; 2Ọb 9:7, 36

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 11/2022,

2 Àwọn Ọba 10:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 18:19; 2Ọb 23:19, 20
  • +1Ọb 21:21

2 Àwọn Ọba 10:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó jọ pé ibì kan tí wọ́n ti ń so àgùntàn kí wọ́n lè rẹ́ irun wọn ni.

2 Àwọn Ọba 10:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìyáàfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 8:29; 9:21, 27; 2Kr 22:1

2 Àwọn Ọba 10:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 22:8

2 Àwọn Ọba 10:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “súre fún un.”

  • *

    Ní Héb., “dúró ṣánṣán.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 35:6, 19
  • +1Kr 2:55

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2005, ojú ìwé 11

    1/1/1998, ojú ìwé 12-13

2 Àwọn Ọba 10:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kí o sì rí ìtara mi fún Jèhófà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 25:11; 1Ọb 19:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/1998, ojú ìwé 12-13

2 Àwọn Ọba 10:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 9:8; 2Kr 22:7
  • +1Ọb 21:20, 21; 2Ọb 9:26

2 Àwọn Ọba 10:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 16:32, 33; 18:22

2 Àwọn Ọba 10:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 3:13
  • +2Ọb 10:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2011, ojú ìwé 5

2 Àwọn Ọba 10:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ẹ ya àpéjọ ọ̀wọ̀ sí mímọ́.”

2 Àwọn Ọba 10:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tẹ́ńpìlì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 16:30, 32

2 Àwọn Ọba 10:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 10:15; Jer 35:6, 19

2 Àwọn Ọba 10:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

2 Àwọn Ọba 10:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn sárésáré.”

  • *

    Ní Héb., “ìlú,” ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ilé tí wọ́n kọ́ bí ibi tó láàbò.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 32:26, 27; Di 13:6-9; Isk 9:5

2 Àwọn Ọba 10:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:1
  • +Di 7:25

2 Àwọn Ọba 10:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:30; Di 7:5
  • +1Ọb 16:30, 32

2 Àwọn Ọba 10:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 12:28-30; 13:33; Ho 8:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2011, ojú ìwé 5

2 Àwọn Ọba 10:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 21:21
  • +2Ọb 13:1, 10; 14:23; 15:8, 12

2 Àwọn Ọba 10:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 10:12; Ho 1:4
  • +1Ọb 12:28-30; 13:34; 14:16

2 Àwọn Ọba 10:32

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “dín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 19:17; 2Ọb 8:12; 13:22

2 Àwọn Ọba 10:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 32:33; Joṣ 22:9
  • +Di 3:13-16; 28:63; Joṣ 13:8-12

2 Àwọn Ọba 10:35

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 13:1

2 Àwọn Ọba 10:36

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ọjọ́.”

Àwọn míì

2 Ọba 10:11Ọb 16:29
2 Ọba 10:11Ọb 21:8
2 Ọba 10:42Ọb 9:24, 27
2 Ọba 10:71Ọb 21:21
2 Ọba 10:92Ọb 9:14, 24
2 Ọba 10:101Sa 15:29; Ais 14:27
2 Ọba 10:101Ọb 21:19-24; 2Ọb 9:7, 36
2 Ọba 10:111Ọb 18:19; 2Ọb 23:19, 20
2 Ọba 10:111Ọb 21:21
2 Ọba 10:132Ọb 8:29; 9:21, 27; 2Kr 22:1
2 Ọba 10:142Kr 22:8
2 Ọba 10:15Jer 35:6, 19
2 Ọba 10:151Kr 2:55
2 Ọba 10:16Nọ 25:11; 1Ọb 19:10
2 Ọba 10:172Ọb 9:8; 2Kr 22:7
2 Ọba 10:171Ọb 21:20, 21; 2Ọb 9:26
2 Ọba 10:181Ọb 16:32, 33; 18:22
2 Ọba 10:192Ọb 3:13
2 Ọba 10:192Ọb 10:11
2 Ọba 10:211Ọb 16:30, 32
2 Ọba 10:232Ọb 10:15; Jer 35:6, 19
2 Ọba 10:25Ẹk 32:26, 27; Di 13:6-9; Isk 9:5
2 Ọba 10:26Le 26:1
2 Ọba 10:26Di 7:25
2 Ọba 10:27Le 26:30; Di 7:5
2 Ọba 10:271Ọb 16:30, 32
2 Ọba 10:291Ọb 12:28-30; 13:33; Ho 8:6
2 Ọba 10:301Ọb 21:21
2 Ọba 10:302Ọb 13:1, 10; 14:23; 15:8, 12
2 Ọba 10:31Di 10:12; Ho 1:4
2 Ọba 10:311Ọb 12:28-30; 13:34; 14:16
2 Ọba 10:321Ọb 19:17; 2Ọb 8:12; 13:22
2 Ọba 10:33Nọ 32:33; Joṣ 22:9
2 Ọba 10:33Di 3:13-16; 28:63; Joṣ 13:8-12
2 Ọba 10:352Ọb 13:1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Àwọn Ọba 10:1-36

Àwọn Ọba Kejì

10 Áhábù+ ní àádọ́rin (70) ọmọkùnrin ní Samáríà. Nítorí náà, Jéhù kọ àwọn lẹ́tà, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Samáríà, sí àwọn ìjòyè Jésírẹ́lì, àwọn àgbààgbà+ àti àwọn tó ń tọ́jú àwọn ọmọ Áhábù,* ó sọ pé: 2 “Bí lẹ́tà yìí bá ṣe ń tẹ̀ yín lọ́wọ́, àwọn ọmọkùnrin olúwa yín máa wà lọ́dọ̀ yín àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn ẹṣin pẹ̀lú àwọn ohun ìjà, ẹ sì wà nínú ìlú olódi. 3 Kí ẹ yan èyí tó bá dára jù, tó sì yẹ* lára àwọn ọmọkùnrin olúwa yín, kí ẹ sì gbé e gorí ìtẹ́ bàbá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, kí ẹ jà fún ilé olúwa yín.”

4 Àmọ́ ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n sì sọ pé: “Ẹ wò ó! Tí ọba méjì kò bá lè dúró níwájú rẹ̀,+ báwo ni àwa ṣe lè dúró?” 5 Torí náà, alábòójútó ààfin,* gómìnà ìlú, àwọn àgbààgbà àti àwọn olùtọ́jú ránṣẹ́ sí Jéhù pé: “Ìránṣẹ́ rẹ ni wá, a ó sì ṣe gbogbo ohun tí o bá sọ fún wa. A ò ní fi ẹnì kankan jẹ ọba. Ohun tó bá dára ní ojú rẹ ni kí o ṣe.”

6 Ló bá kọ lẹ́tà kejì sí wọn, ó ní: “Tó bá jẹ́ pé tèmi lẹ̀ ń ṣe, tó sì wù yín láti ṣègbọràn sí mi, ẹ kó orí àwọn ọmọkùnrin olúwa yín, kí ẹ sì wá bá mi ní Jésírẹ́lì ní ìwòyí ọ̀la.”

Lákòókò yìí, àádọ́rin (70) àwọn ọmọkùnrin ọba wà lọ́dọ̀ àwọn sàràkí ọkùnrin ìlú, ìyẹn àwọn tó ń tọ́ wọn. 7 Gbàrà tí lẹ́tà náà tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́, wọ́n kó àwọn ọmọkùnrin ọba, wọ́n sì pa wọ́n, àwọn àádọ́rin (70) ọkùnrin,+ wọ́n kó orí wọn sínú apẹ̀rẹ̀, wọ́n sì kó wọn ránṣẹ́ sí i ní Jésírẹ́lì. 8 Òjíṣẹ́ náà wọlé, ó sì sọ fún un pé: “Wọ́n ti kó orí àwọn ọmọkùnrin ọba dé.” Torí náà, ó sọ pé: “Ẹ kó wọn jọ ní òkìtì méjì sí ibi àtiwọ ẹnubodè ìlú títí di àárọ̀.” 9 Nígbà tó jáde ní àárọ̀, ó dúró níwájú gbogbo àwọn èèyàn náà, ó sì sọ pé: “Ẹ ò ní ẹ̀bi kankan.* Òótọ́ ni pé mo ṣọ̀tẹ̀ sí olúwa mi, mo sì pa á,+ àmọ́ ta ló pa gbogbo àwọn yìí? 10 Torí náà, ẹ mọ̀ dájú pé kò sí ìkankan nínú ọ̀rọ̀ Jèhófà tí Jèhófà kéde sórí ilé Áhábù tí kò ní ṣẹ,*+ Jèhófà sì ti ṣe ohun tó gbẹnu ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà sọ.”+ 11 Yàtọ̀ síyẹn, Jéhù pa gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù ní ilé Áhábù ní Jésírẹ́lì, títí kan gbogbo sàràkí ọkùnrin rẹ̀, àwọn ojúlùmọ̀ rẹ̀ àti àwọn àlùfáà rẹ̀,+ kò jẹ́ kí èèyàn rẹ̀ kankan ṣẹ́ kù.+

12 Lẹ́yìn náà, ó dìde, ó sì forí lé Samáríà. Ilé tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ti ń so àgùntàn mọ́lẹ̀* wà lójú ọ̀nà. 13 Ibẹ̀ ni Jéhù ti bá àwọn arákùnrin Ahasáyà+ ọba Júdà pàdé, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni yín?” Wọ́n sọ pé: “Arákùnrin Ahasáyà ni wá, a fẹ́ lọ béèrè àlàáfíà àwọn ọmọ ọba àti àwọn ọmọ ìyá ọba.”* 14 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sọ pé: “Ẹ mú wọn láàyè!” Torí náà, wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n sì pa wọ́n níbi kòtò omi tó wà ní ilé tí wọ́n ti ń so àgùntàn mọ́lẹ̀, gbogbo àwọn ọkùnrin náà jẹ́ méjìlélógójì (42). Kò sì jẹ́ kí ìkankan lára wọn ṣẹ́ kù.+

15 Bó ṣe kúrò níbẹ̀, ó bá Jèhónádábù+ ọmọ Rékábù+ pàdé tó ń bọ̀ wá bá a. Nígbà tó kí i,* ó sọ fún un pé: “Ṣé gbogbo ọkàn rẹ wà* pẹ̀lú mi bí ọkàn mi ṣe wà pẹ̀lú ọkàn rẹ?”

Jèhónádábù fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni.”

Jéhù wá sọ pé: “Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, fún mi ní ọwọ́ rẹ.”

Torí náà, ó na ọwọ́ sí i, Jéhù sì fà á gòkè sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀. 16 Ló bá sọ pé: “Bá mi ká lọ, kí o sì rí bí mi ò ṣe fàyè gba bíbá Jèhófà díje.”*+ Torí náà, wọ́n mú un wọnú kẹ́kẹ́ ogun rẹ̀, wọ́n sì jọ ń lọ. 17 Nígbà tí wọ́n dé Samáríà, ó pa gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù ní ilé Áhábù ní Samáríà, títí ó fi pa gbogbo wọn run,+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Èlíjà.+

18 Bákan náà, Jéhù kó gbogbo àwọn èèyàn náà jọ, ó sì sọ fún wọn pé: “Áhábù jọ́sìn Báálì díẹ̀,+ àmọ́ Jéhù yóò jọ́sìn rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀. 19 Torí náà, ẹ pe gbogbo àwọn wòlíì Báálì,+ gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ àti gbogbo àwọn àlùfáà rẹ̀+ wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ rí i dájú pé gbogbo wọn ló wá, nítorí mo fẹ́ rú ẹbọ ńlá sí Báálì. Ẹnikẹ́ni tí kò bá wá máa kú.” Àmọ́, ńṣe ni Jéhù ń lo ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti pa àwọn tó ń jọ́sìn Báálì run.

20 Jéhù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ẹ kéde àpéjọ ọlọ́wọ̀ kan* fún Báálì.” Torí náà, wọ́n kéde rẹ̀. 21 Lẹ́yìn ìyẹn, Jéhù ránṣẹ́ káàkiri gbogbo Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn Báálì sì wá. Kò sí ìkankan lára wọn tó ṣẹ́ kù tí kò wá. Wọ́n wọ ilé* Báálì,+ ilé Báálì sì kún láti ìpẹ̀kun kan dé ìpẹ̀kun kejì. 22 Ó sọ fún ẹni tó wà nídìí ibi tí wọ́n ń kó aṣọ sí pé: “Kó aṣọ jáde fún gbogbo àwọn tó ń jọ́sìn Báálì.” Torí náà, ó kó aṣọ jáde fún wọn. 23 Lẹ́yìn náà, Jéhù àti Jèhónádábù+ ọmọ Rékábù wọ inú ilé Báálì. Ó wá sọ fún àwọn tó ń jọ́sìn Báálì pé: “Ẹ fara balẹ̀ wá ibí yìí dáadáa pé kò sí olùjọsìn Jèhófà kankan níbí, àfi àwọn olùjọsìn Báálì nìkan.” 24 Níkẹyìn, wọ́n wọlé láti rú àwọn ẹbọ àti ẹbọ sísun. Àmọ́ Jéhù ti yan ọgọ́rin (80) lára àwọn ọkùnrin rẹ̀ síta, ó ní: “Tí ìkankan lára àwọn ọkùnrin tí mo fi sí ìkáwọ́ yín bá lọ pẹ́nrẹ́n, ẹ̀mí* yín lẹ máa fi dí i.”

25 Gbàrà tí Jéhù rú ẹbọ sísun náà tán, ó sọ fún àwọn ẹ̀ṣọ́* àti àwọn olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun pé: “Ẹ wọlé, kí ẹ sì ṣá wọn balẹ̀! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkankan lára wọn lọ!”+ Torí náà, àwọn ẹ̀ṣọ́ àti àwọn olùrànlọ́wọ́ ọ̀gágun fi idà ṣá wọn balẹ̀, wọ́n gbé òkú wọn jù síta, wọ́n sì ń lọ títí dé ibi mímọ́* ilé Báálì. 26 Nígbà náà, wọ́n kó àwọn ọwọ̀n òrìṣà+ tó wà ní ilé Báálì jáde, wọ́n sì dáná sun wọ́n lọ́kọ̀ọ̀kan.+ 27 Wọ́n ti ọwọ̀n òrìṣà Báálì ṣubú,+ wọ́n wó ilé Báálì+ lulẹ̀, wọ́n sì sọ ọ́ di ilé ìyàgbẹ́, bó ṣe wà títí di òní yìí.

28 Bí Jéhù ṣe pa Báálì rẹ́ ní Ísírẹ́lì nìyẹn. 29 Àmọ́, Jéhù ò kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù ọmọ Nébátì mú kí Ísírẹ́lì dá, ìyẹn jíjọ́sìn àwọn ọmọ màlúù wúrà tó wà ní Bẹ́tẹ́lì àti Dánì.+ 30 Torí náà, Jèhófà sọ fún Jéhù pé: “Nítorí pé o ṣe dáadáa, tí o sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi, bí o ṣe ṣe gbogbo ohun tó wà lọ́kàn mi sí ilé Áhábù,+ àwọn ọmọ rẹ títí dé ìran kẹrin yóò máa jókòó lórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.”+ 31 Àmọ́ Jéhù ò kíyè sára láti fi gbogbo ọkàn rẹ̀ pa Òfin Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì mọ́.+ Kò kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Jèróbóámù mú kí Ísírẹ́lì dá.+

32 Lákòókò yẹn, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í gé* ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì kù. Hásáẹ́lì ń kọ lù wọ́n léraléra káàkiri ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì,+ 33 láti Jọ́dánì sápá ìlà oòrùn, gbogbo ilẹ̀ Gílíádì, níbi tí ẹ̀yà Gádì, ẹ̀yà Rúbẹ́nì àti ẹ̀yà Mánásè+ ń gbé. Ìpínlẹ̀ Áróérì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Àfonífojì Áánónì títí dé Gílíádì àti Báṣánì wà lára wọn.+

34 Ní ti ìyókù ìtàn Jéhù àti gbogbo ohun tí ó ṣe àti gbogbo agbára rẹ̀, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn ìgbà àwọn ọba Ísírẹ́lì? 35 Níkẹyìn, Jéhù sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Samáríà; Jèhóáhásì+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀. 36 Àkókò* tí Jéhù fi jọba lórí Ísírẹ́lì jẹ́ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n (28) ní Samáríà.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́