Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 10
Orin 107
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ táa yàn látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: “Mímú Kí Gbogbo Ilẹ̀ Ayé Mọ̀ Nípa Orúkọ Jèhófà.” Ìjíròrò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé lórí ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà kún un láti inú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 93 àti 94.
20 min: Àkókò Tó Láti Gba Káàdì Advance Medical Directive/Release Wa Tuntun. Alàgbà kan tí ó tóótun ni kó sọ ọ̀rọ̀ yìí lọ́nà àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Lẹ́yìn ìpàdé yìí, kí àwọn Ẹlẹ́rìí tó ti ṣe batisí gba káàdì Advance Medical Directive/Release tuntun kọ̀ọ̀kan, kí àwọn tó sì ní àwọn ọmọ aláìtójúúbọ́, tí kò tíì ṣe batisí gba Identity Card (Káàdì Ìdánimọ̀) fún ọmọ kọ̀ọ̀kan. A ò ní kọ ọ̀rọ̀ sínú káàdì wọ̀nyí lálẹ́ òní. Kí ẹ fara balẹ̀ kọ ọ̀rọ̀ sínú wọn nílé, ṣùgbọ́n kí ẹ MÁ ṢE buwọ́ lù ú. Lẹ́yìn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tí ń bọ̀ ni a ó buwọ́ lu káàdì wọ̀nyí, ìgbà náà la óò jẹ́rìí sí i, ìgbà náà la ó sì kọ déètì sí i, pẹ̀lú ìrànwọ́ Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, bó bá pọndandan. Kí ẹ tó buwọ́ lù ú, ẹ rí i dájú pé ẹ ti kọ gbogbo ohun tí ó yẹ kí ẹ kọ sínú rẹ̀ tán pátápátá. Kí àwọn tí ń buwọ́ lu káàdì náà láti ṣe ẹlẹ́rìí jẹ́ kí ẹni tí ó ni káàdì náà buwọ́ lù ú níṣojú wọn. Àwọn akéde tí kò tíì ṣe batisí lè ṣe káàdì tiwọn, tí àwọn àtàwọn ọmọ wọn yóò máa lò, nípa títún àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò nínú káàdì yìí kọ láti fi bá ipò àti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ mu. Kí àwọn Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rí i dájú pé gbogbo àwọn tí a pín sí àwùjọ wọn rí ìrànwọ́ tí wọ́n ń fẹ́ gbà láti kọ ọ̀rọ̀ sínú káàdì Advance Medical Directive/Release. Láti lè ní ààbò tó gbópọn lábẹ́ òfin, ẹ kọ ọ̀rọ̀ sínú káàdì yìí. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n máa mú káàdì náà dání nígbà gbogbo. Ìròyìn táà ń gbọ́ ni pé àwọn kan kìí mú káàdì náà dání nígbà tí wọ́n bá lọ gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn. Èyí ti dá ọ̀pọ̀ ìṣòro sílẹ̀ fún wọn, àti fún àwọn ilé ìwòsàn.
Orin 155 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 17
Orin 12
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: Àìní àdúgbò.
20 min: “Lo Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò.” Ṣàtúnyẹ̀wò ìwé àṣàrò kúkúrú mẹ́rin èyíkéyìí tí ẹ sábà máa ń lò ní ìpínlẹ̀ yín. Béèrè ìbéèrè tí ìwé àṣàrò kúkúrú kọ̀ọ̀kan dáhùn. Sọ pé kí àwùjọ dábàá bí a ṣe lè lo ìbéèrè náà láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò, tí ó sì ṣeé ṣe kó yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi méjì nínú àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú náà ṣe èyí.
Orin 57 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 24
Orin 110
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò àti ìrírí látinú iṣẹ́ ìsìn pápá.
15 min: “Máa Ṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Jèhófà Lójoojúmọ́!” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Fún gbogbo ìjọ níṣìírí láti máa lo ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2000 dáadáa. Fi àlàyé kún un látinú ọ̀rọ̀ ìṣáájú, ojú ìwé 3 àti 4. Sọ pé kí àwọn akéde ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ń sapá lákànṣe láti máa ṣàyẹ̀wò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti àlàyé wọn lójoojúmọ́.
20 min: Wọ́n Ṣe Yíyàn Tó Bọ́gbọ́n Mu. Àsọyé tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́, October 15, 1997, ojú ìwé 19 sí 21, ìpínrọ̀ 3 sí 16. Sọ gbólóhùn tó tẹnu àwọn aṣáájú ọ̀nà jáde, tó fi ìdí tí wọ́n fi ronú pé àwọ́n ti lo ìgbésí ayé àwọn lọ́nà tí ń mérè wá, tó sì ṣàǹfààní jù lọ hàn. Fún gbogbo àwọn tó pésẹ̀ níṣìírí láti ṣàyẹ̀wò bóyá ó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe aṣáájú ọ̀nà.
Orin 182 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 31
Orin 16
12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù January sílẹ̀. Dárúkọ ìwé tí a ó fi lọni ní oṣù February: Ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. Ṣàṣefihàn bí a ṣe lè lo àwọn ìbéèrè mẹ́ta, tó wà nínú àpótí lójú ìwé 12 nínú ìwé náà, láti fi pilẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹnì kan.
15 min: Ìdáhùn sí Ìbéèrè Lórí ‘Sísàmì.’ Alàgbà ni kó sọ àsọyé tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́, July 15, 1999, ojú ìwé 29 sí 31 yìí.
18 min: Bí A Ṣe Lè Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ Láti Dá Ìsìn Tòótọ́ Mọ̀. Ìjíròrò láàárín ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tó tóótun àti akéde méjì tàbí mẹ́ta tó dáńgájíá, nípa bó ṣe jẹ́ pé àwọn èèyàn lé fẹ́ràn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣùgbọ́n tí wọn ò lóye dáadáa nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹ̀sìn tiwa àti tàwọn yòókù. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó mẹ́wàá tí a jíròrò nínú Jí! May 8, 1995, ojú ìwé 20. Ṣàlàyé bí mímọ àwọn kókó wọ̀nyí ṣe lè ran ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti rí ìyàtọ̀ láàárín ìjọsìn tòótọ́ àti ìjọsìn èké, àti ìdí tó fi yẹ kó kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà, kó sì dara pọ̀ mọ́ wọn.
Orin 60 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 7
Orin 113
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
20 min: ‘“Má Ṣe Jẹ́ Kí Ànímọ́ Rere Rẹ Di Àbùkù Rẹ.”’ Alàgbà ni kí ó sọ àsọyé yìí, tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́, December 1, 1999, ojú ìwé 26 sí 29.
15 min: “Àwọn Obìnrin Tí Ń Ṣiṣẹ́ Kára Nínú Olúwa.” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé kún un láti inú Ilé Ìṣọ́, September 15, 1996, ojú ìwé 14 àti 15, ìpínrọ̀ 18 àti 19. Fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà gbóríyìn fún àwọn arábìnrin nítorí ìtìlẹ́yìn tọkàntọkàn tí wọ́n ń ṣe, nítorí iṣẹ́ aláǹfààní tí wọ́n ń ṣe fún àwọn ẹlòmíràn, àti nítorí iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń fi ìtara ṣe.
Orin 82 àti àdúrà ìparí.