Rírí Ìdùnnú Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Mímọ́ Rẹ
1 Wọ́n padà dé “pẹ̀lú ìdùnnú.” Àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ bí ó ṣe rí lára àwọn àádọ́rin ọmọ ẹ̀yìn wọ̀nyẹn nígbà tí wọ́n padà wá ròyìn fún Jésù lẹ́yìn ìrìn àjò iṣẹ́ ìwàásù wọn tó gbòòrò gan-an. Wọ́n láyọ̀ látọkànwá nítorí pé wọ́n ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́. (Lúùkù 10:17) Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ní irú ìdùnnú kan náà nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́?
2 Ìṣarasíhùwà Tó Dáa: Ọlọ́run fún ẹ láǹfààní pé kí o ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa ète títóbilọ́lá ti Jèhófà. Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tí o ń ṣe, o lè gba àwọn kan sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn àṣà ayé yìí tí kò buyì kúnni, kí o sì dá wọn nídè kúrò nínú ẹ̀sìn èké. O lè sọ fún àwọn èèyàn nípa ìrètí ìyè nínú ayé tó bọ́ lọ́wọ́ gbọ́nmisi-omi-ò-to tó yí wa ká lónìí. Ronú nípa bí inú Jèhófà ṣe máa ń dùn tó nígbà tóo bá ṣàṣeyọrí nínú gbígbin irúgbìn òtítọ́ sínú ẹnì kan tó láyà ìgbàṣe. Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa gbàdúrà pé kí ẹ̀mí Ọlọ́run jẹ́ kí inú rẹ máa dùn bí o ti ń fi gbogbo ọkàn rẹ ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ.
3 Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Tó Gbéṣẹ́: Àkókò tí Jésù fi fún àwọn àádọ́rin ọmọ ẹ̀yìn wọ̀nyẹn nítọ̀ọ́ni la lè fi wé Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí a ń ṣe lóde òní. Ó kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn kúnnákúnná. (Lúùkù 10:1-16) Lónìí, Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ń kọ́ ẹ ní àwọn ọ̀nà tí o lè gbà bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, bí o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò, àti bí o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé kí o sì máa darí wọn. Nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù àti mímú kí òye iṣẹ́ ìwàásù tí o ní pọ̀ sí i, wàá rí i pé ara rẹ tí ò balẹ̀ tàbí èrò àìtóótun tó ń dààmú rẹ yóò dín kù, ìgboyà àti ìdùnnú yóò sì borí wọn.
4 Máa Wo Ọjọ́ Iwájú: Iṣẹ́ ìsìn mímọ́ tí Jésù ṣe mú inú rẹ̀ dùn láìka ìyà tó jẹ sí. Èé ṣe? Nítorí pé ó tẹjú mọ́ àwọn ìbùkún àti àǹfààní tó wà níwájú rẹ̀. (Héb. 12:2) Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa jíjẹ́ kí orúkọ Jèhófà àti àwọn ìbùkún tí ayé tuntun Ọlọ́run yóò mú wá máa wà lọ́kàn rẹ nígbà gbogbo. Èyí yóò mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ nítumọ̀, yóò sì máa mú inú rẹ dùn.
5 Ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ sí Jèhófà ni àǹfààní gíga jù lọ tí o lè ní lónìí. Nítorí náà, kí o sọ pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí.”—Sm. 40:8.