“Òpò Yín Kì Í Ṣe Asán”
1 Èrò yìí mà ń fúnni níṣìírí o! Ìsapá rẹ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kò ní já sí asán. (1 Kọ́r. 15:58) Ní òdì kejì, ronú nípa bí àwọn èèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́ kìràkìtà láti mú kí ipò tí wọ́n wà ní ìgbésí ayé, tàbí ipò ìṣúnná owó wọn sunwọ̀n sí i. Wọ́n lè máa fi ọ̀pọ̀ ọdún lépa ẹ̀kọ́ gíga, wọ́n sì lè máa ṣiṣẹ́ àṣebólórí nítorí àtilà. Síbẹ̀, nítorí “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀,” ọwọ́ wọn lè má tẹ ipò iyì tí wọ́n ń wá, tàbí kẹ̀ wọ́n lè wá fi tipátipá tẹ́wọ́ gba ipò tó rẹlẹ̀ gan-an nípa ti ara táa bá fi wé irú èyí tí wọ́n ń wá tẹ́lẹ̀. Gẹ́gẹ́ bíi “lílépa ẹ̀fúùfù,” asán ni gbogbo ìsapá wọn. (Oníw. 1:14; 9:11) Nígbà náà, ẹ lè rí i pé ó ṣe pàtàkì pé ká ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ kan ṣoṣo tí kì í ṣe asán, nítorí pé ìníyelórí rẹ̀ wà pẹ́ títí!
2 Iṣẹ́ Tó Níyelórí Ní Tòótọ́: Wíwàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ lórí ilẹ̀ ayé. A gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ yìí yálà àwọn èèyàn gbọ́ tàbí wọn ò gbọ́. A fẹ́ kí a lè sọ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ pé: “Ọrùn mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn gbogbo, nítorí pé èmi kò fà sẹ́yìn kúrò nínú sísọ gbogbo ìpinnu Ọlọ́run fún yín.”—Ìṣe 20:26, 27.
3 Nígbà tí àwọn èèyàn bá tẹ́tí sílẹ̀, tí wọ́n sì dáhùn sí iṣẹ́ Ìjọba náà, ayọ̀ ló mà máa ń jẹ́ o! Obìnrin kan báyìí wà tí àǹtí rẹ̀ kú. Ó ṣe kàyéfì nípa ibi tí àǹtí òun lọ, bóyá ọ̀run ni o tàbí hẹ́ẹ̀lì. Ó gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó ran òun lọ́wọ́, ó pe orúkọ náà, Jèhófà, bí arábìnrin rẹ̀ ṣe kọ́ ọ pé kí ó ṣe. Kò pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì ń lọ sí ìpàdé Kristẹni. Èrò tó ní nípa ìgbésí ayé yí padà pátápátá, ó sì jáwọ́ nínú lílájọṣe pẹ̀lú ẹgbẹ́ àwọn ọmọọ̀ta. Ọ̀dọ́bìnrin yìí jáwọ́ nínú sìgá mímu, oògùn lílò, àti olè jíjà. Ó sọ pé: “Ìfẹ́ fún Jèhófà ló mú kí n jáwọ́ nínú ọ̀nà ìgbésí ayé búburú yẹn. Jèhófà nìkan ṣoṣo nínú àánú rẹ̀ ńláǹlà ló lè fún mi ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun.” Kò tún lo ìgbésí ayé rẹ̀ fún àwọn ìlépa asán mọ́.
4 Àní báwọn èèyàn bá tiẹ̀ kọ̀ láti fetí sílẹ̀, síbẹ̀, o ń ṣàṣeparí ohun kan tó níye lórí. Wọ́n mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dé ọ̀dọ̀ àwọn. O ń fi hàn pé o jẹ́ oníwà títọ́, o jẹ́ olóòótọ́, àti pé o ní ìfẹ́. Nítorí náà, ǹjẹ́ òpò rẹ nínú iṣẹ́ Olúwa jẹ́ asán? Ká má ri!