Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 12
Orin 136
8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: “Òpò Yín Kì Í Ṣe Asán.” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé kún un látinú ìrírí tí a sọ nínú Ilé-Ìṣọ́nà, June 15, 1996, ojú ìwé 32.
22 min: Fífi Ìwé Pẹlẹbẹ Béèrè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́. Àsọyé, tó ń ṣàyẹ̀wò àpilẹ̀kọ inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 1999, ojú ìwé 4. Jẹ́ kí a ṣàṣefihàn ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà ní ìpínrọ̀ 6. Jẹ́ kí akéde kan tàbí méjì ṣe àlàyé tí kò gùn nípa àṣeyọrí tí wọ́n ti ṣe nínú bíbẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sọ bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, àti nǹkan tí wọ́n ṣe láti mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà máa bá a lọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.
Orin 209 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 19
Orin 14
12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó àti ìfilọ̀ ìròyìn àyẹ̀wò àkáǹtì táa máa ń ṣe lóṣù mẹ́tamẹ́ta. Bí ìjọ bá ní àwọn ẹ̀dà ìwé Awọn Ọ̀dọ́ Béèrè tàbí ìwé Igba Ewe lọ́wọ́, jẹ́ kí a ṣàṣefihàn bí a ṣe lè lò ó lọ́nà tó ṣàǹfààní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.
8 min: Àpótí Ìbéèrè. Àsọyé tí alàgbà sọ.
25 min: “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣe Bẹ́ẹ̀, Láìjẹ́ Pé Ẹnì Kan Fi Mí Mọ̀nà?” Ìbéèrè àti ìdáhùn tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn darí. Jẹ́ kí á ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan sókè ketekete, kí o sì ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà ní ìpínrọ̀ 3, 4, àti 7. Nígbà tí o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 6, ṣàlàyé ojúṣe alábòójútó iṣẹ́ ìsìn nínú pípinnu bóyá kí a tún bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tó ti ṣe batisí, tàbí ká má bẹ̀rẹ̀ rẹ̀.—Wo Àpótí Ìbéèrè nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 1998.
Orin 89 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 26
Orin 39
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù June sílẹ̀. Ṣàyẹ̀wò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní oṣù July. Fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ tọ́jọ́ wọn ti pẹ́ tí ìjọ ní lọ́wọ́ hàn, kí o sì sọ ète tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn wà fún ní ṣókí. Jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn kan tí wọ́n ti múra sílẹ̀ dáadáa, tí yóò fi bí a ṣe lè fi ọ̀kan nínú wọn lọni nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ hàn.
17 min: “Jẹ́ Aláìṣahun . . . Múra Tán Láti Ṣe Àjọpín.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àwọn ìdí mẹ́rin tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí “Ìdí Tí Ó Fi Yẹ Kí A Fún Un Ní Nǹkan” kún un, tí a ṣàlàyé nínú Ilé Ìṣọ́, November 1, 1996, ojú ìwé 29 àti 30.
18 min: Mọ Báa Ti Í Dáhùn. (Kól. 4:6) Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Kí lo máa ń ṣe nígbà tí o bá pàdé ẹni tó bẹ̀rẹ̀ àríyànjiyàn tí kò bá Ìwé Mímọ́ mú? Ìwé Reasoning sábà máa ń pèsè àwọn àbá gbígbéṣẹ́ nípa bí a ṣe lè fọgbọ́n dáhùn. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń wo ikú gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá kan tí a ó fi ìràpadà Kristi ṣẹ́gun rẹ̀, àwọn mìíràn ní ìdánilójú pé kò sóhun tó lè mú ikú kúrò, kódà wọ́n máa ń nígbàgbọ́ nínú èrò èké náà pé àtúnwáyé wà. Jíròrò àwọn ìdáhùn tí ìwé Reasoning pèsè ní ẹ̀ka tó sọ pé “If Someone Says—” (Bí Ẹnì Kan Bá Sọ Pé—), lójú ìwé 103, 104 àti 321. Fún gbogbo àwọn akéde níṣìírí pé kí wọ́n máa mú ìwé náà lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá.
Orin 44 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 3
Orin 213
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ pé kí àwọn akéde tí wọ́n ti ń bá àwọn èèyàn ṣèkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ṣàṣeyọrí èyí.
15 min: “Ṣé O Máa Wà Níbẹ̀?” Àsọyé àti ìrírí, alàgbà ni kí ó darí rẹ̀. Àpéjọ ńláńlá ti ṣe bẹbẹ nínú fífún àwọn èèyàn Ọlọ́run lókun látìgbà kíkọ Bíbélì títí dòní olónìí. (Wo ìwé Proclaimers, ojú ìwé 254, ìpínrọ̀ 1 sí 3, àti ìwé Insight, Apá Kìíní, ojú ìwé 821, ìpínrọ̀ 5.) Fún gbogbo ìjọ níṣìírí pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí múra báyìí láti lọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè tọdún yìí ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Sọ pé kí àwùjọ sọ àwọn ìrírí tó fi hàn pé a san èrè nípa tẹ̀mí fún wọn nítorí ìsapá aláápọn tí wọ́n ṣe láti lọ sí àpéjọpọ̀ láwọn ìgbà tó ti kọjá sẹ́yìn.
20 min: Fífi Àwọn Ìlànà Bíbélì Sílò Máa Ń Fún Ìgbésí Ayé Ìdílé Lókun. Ìjíròrò láàárín àwọn arákùnrin méjì, wọ́n gbé e karí àwọn kókó mẹ́jọ táa ṣàlàyé nínú ìwé Reasoning, ojú ìwé 253 àti 254. Ṣàlàyé pé ó ṣe pàtàkì láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n mọ̀ pé lílóye àwọn ìlànà inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti fífi wọ́n sílò ni àṣírí ayọ̀ ìdílé. Nípa lílo ẹ̀kọ́ 8 nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, jẹ́ kí a ṣàṣefihàn bí a ṣe lè ṣe ìyẹn. Àwọn ìdílé tó bá ń kọbi ara sí ìmọ̀ràn Bíbélì máa ń sún mọ́ ara wọn, wọ́n sì máa ń rí ayọ̀ tí ń pọ̀ sí i nínú ìdè ìfẹ́ tímọ́tímọ́ àti ìṣọ̀kan. Sọ ìrírí tó wà nínú ìwé Ayọ̀ Ìdílé, orí 13, ìpínrọ̀ 1, 21 àti 22.
Orin 51 àti àdúrà ìparí.