Ṣé O Máa Wà Níbẹ̀?
1 Ẹlẹ́rìí kan tọ́jọ́ rẹ̀ ti pẹ́ sọ nígbà kan rí pé: “Bí o kò bá lọ sí àpéjọpọ̀ lọ́jọ́ àkọ́kọ́, ohun tóo pàdánù rẹ̀ kúrò ní kèrémí!” Kí ló dé tó fi ronú bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ọjọ́ àkọ́kọ́ ni ìbẹ̀rẹ̀ àsè dídọ́ṣọ̀ nípa tẹ̀mí tí ètò àjọ Jèhófà ti pèsè sílẹ̀ fún wa. (Aísá. 25:6) Wíwà tí a bá wà níbẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ fi hàn pé a fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú èrò onísáàmù náà pé: “Mo yọ̀ nígbà tí wọ́n ń wí fún mi pé: ‘Jẹ́ kí a lọ sí ilé Jèhófà.’”—Sm. 122:1.
2 Ṣùgbọ́n, lọ́dún tó kọjá, ní bíi mélòó kan lára Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run,” iye àwọn tó wá lọ́jọ́ Friday kéré jọjọ sí ti ọjọ́ Saturday àti Sunday. Èyí túmọ̀ sí pé púpọ̀ àwọn ará ni kò gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ àpéjọpọ̀ tó sọ àwọn kókó pàtàkì nípa ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà. Wọ́n tún pàdánù ìbákẹ́gbẹ́ aláyọ̀ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn.
3 Má Ṣe Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Oúnjẹ Òòjọ́ Ṣèdíwọ́: Àníyàn wí pé káwọn má lọ pàdánù iṣẹ́ àwọn lè jẹ́ ìdí tí àwọn kan ò fi wá lọ́jọ́ Friday. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ti rí i pé àwọn agbanisíṣẹ́ wọn ṣe tán láti gbà pẹ̀lú wọn lórí ọ̀ràn yìí, bí wọ́n bá tètè tọrọ àyè ṣáájú. Ìpinnu arábìnrin kan láti máa lọ sí gbogbo ìpàdé ìjọ àti àpéjọpọ̀ wú agbanisíṣẹ́ rẹ̀ lórí débi pé ó bá arábìnrin yìí lọ sí àpéjọpọ̀ fódindi ọjọ́ kan!
4 Kò yẹ kí o méfò pé agbanisíṣẹ́ rẹ kò ní fẹ́ fún ọ láyè, má sì ṣe ronú pé kò ṣe nǹkan bí o kò bá lọ ti ọjọ́ kan nínú ọjọ́ àpéjọpọ̀ náà. Pẹ̀lú ìdánilójú àtọkànwá, múra láti fọgbọ́n ṣàlàyé fún ọ̀gá rẹ látinú Ìwé Mímọ́ nípa ìdí tí lílọ sí àpéjọpọ̀ fi jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn rẹ. (Héb. 10:24, 25) Lẹ́yìn náà, ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú àwọn ìlérí Jèhófà, kí o mọ̀ pé bí o bá fi àwọn àìní tẹ̀mí ṣáájú nínú ìgbésí ayé rẹ, yóò pèsè ohun yòówù tí o bá nílò nípa ti ara.—Mát. 6:33; Héb. 13:5, 6.
5 Mímọrírì “àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù” ni kókó pàtàkì tó wà níbẹ̀. (Fílí. 1:10, 11; Sm. 27:4) Èyí ló ń sún wa láti wéwèé láti jàǹfààní ní kíkún láti inú ìpèsè pàtàkì tó ń ti ọ̀dọ̀ Jèhófà wá yìí. Bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àwọn ìwéwèé tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nísinsìnyí, kí o sì pinnu pé wàá wà níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta!