Ṣé Wàá Lọ?
Lọ síbo? Síbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọ̀sán Friday ti Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” tọdún 1999. Lọ́dún tó kọjá ní Nàìjíríà, góńgó iye àwọn tó wá sípàdé lọ́jọ́ Friday fi 112,005 dín sí góńgó iye àwọn tó wá lọ́jọ́ Sunday. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé, ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún àròpọ̀ àwọn tó wá lọ́jọ́ Sunday ni kò wá gbọ́ ìdá mẹ́ta ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà. Ṣé wàá ṣètò ìgbòkègbodò rẹ kí o bàa lè wà níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àpéjọpọ̀ tọdún 1999? A gbà pé wàá ṣe bẹ́ẹ̀.