ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/00 ojú ìwé 3-4
  • Ǹjẹ́ O Mọrírì Àwọn Ohun Ọlọ́wọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọrírì Àwọn Ohun Ọlọ́wọ̀?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” ti 1998
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” ti 1999
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Onídùnnú-Ayọ̀ Olùyìn” ti 1995
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Àpéjọ Àgbègbè Jẹ́ Àkókò Ìjọsìn Aláyọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 9/00 ojú ìwé 3-4

Ǹjẹ́ O Mọrírì Àwọn Ohun Ọlọ́wọ̀?

1 Bí wọ́n bá bi wá léèrè bóyá a mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀, a lè yára dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni! Kí wá ni díẹ̀ lára àwọn ìpèsè ọlọ́wọ̀ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí a mọrírì?

2 Ẹ wo bí a ṣe ń ṣìkẹ́ àjọṣe tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní pẹ̀lú Baba wa ọ̀run gidigidi tó! Ọlọ́run fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé bí a bá ‘sún mọ́ òun, òun yóò sún mọ́ wa.’ (Ják. 4:8) Bí kò bá sí ti ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi ni, kò sí èèyàn kankan tó lè rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà. (Jòh. 3:16) Bí a ti kún fún ìmoore látọkànwá, a máa ń sọ ìmọrírì jíjinlẹ̀ tí a ní fún ẹ̀bùn iyebíye tí Ọlọ́run fún wa nínú àdúrà wa ojoojúmọ́.

3 Bíbélì Mímọ́, Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí, tún jẹ́ ohun ọlọ́wọ̀ fún wa, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ètò àjọ Jèhófà orí ilẹ̀ ayé tún jẹ́ ohun ọlọ́wọ̀ fún wa. A ń fi ìmọrírì yíyẹ hàn fún àwọn ohun tí Jèhófà pèsè wọ̀nyí nígbà tí a bá ń gbé ìgbé ayé wa níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì, tí a ń mú kí ìdè ìfẹ́ ará lágbára sí i, tí a ń fara balẹ̀ tẹ̀ lé ìṣètò ìṣàkóso Ọlọ́run, tí a sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń mú ipò iwájú.—1 Pét. 1:22.

4 Nípasẹ̀ ẹrú olóòótọ́ àti olóye, a ń rí ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí gbà. Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ yóò ṣe rí lọ́dún yìí ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí.” Ibẹ̀ ni a óò ti gbọ́ àwọn ìtọ́ni ṣíṣe kókó, a óò sì gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ ọlọ́yàyà tí a nílò gidigidi báyìí. Báwo la ṣe lè fi ìmọrírì àtọkànwá hàn fún ìpèsè ọlọ́wọ̀ yìí?

5 Má Ṣe Ṣàìnáání Ilé Jèhófà: Nehemáyà ṣí àwọn tó ti ṣiṣẹ́ kára láti kọ́ àwọn odi Jerúsálẹ́mù létí pé kí wọ́n ‘má ṣe ṣàìnáání ilé Ọlọ́run wọn.’ (Neh. 10:39) Lónìí, “ilé” Jèhófà ni ètò ìjọsìn tó ṣe. Àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè wa jẹ́ apá kan ìṣètò yẹn. Bí a kò bá ní ṣàìnáání ìṣètò yìí, a gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀, kí a sì fetí sílẹ̀ dáadáa, kí a jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ wá pé a mọrírì àwọn ìpèsè rẹ̀ gidigidi. (Héb. 10:24, 25) Kí làwọn ìwéwèé tí a gbọ́dọ̀ ṣe nísinsìnyí láti fi hàn pé a mọrírì ìṣẹ̀lẹ̀ ọlọ́wọ̀ yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́?

6 Wà Níbẹ̀ Ní Gbogbo Ọjọ́ Mẹ́tẹ̀ẹ̀ta: Gbogbo wa gbọ́dọ̀ ṣètò láti wà ní àpéjọpọ̀ náà ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí a óò fi ṣe é. Ǹjẹ́ o ń wéwèé láti tètè dé lójoojúmọ́, kí o sì wà níbẹ̀ títí di ìgbà tí wọ́n bá gba àdúrà ìparí lọ́jọ́ Sunday? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, wàá rí àwọn ìbùkún ọlọ́ràá gbà. Ó lè má fi gbogbo ìgbà rọrùn láti lọ sí àpéjọpọ̀ kan. Ṣíṣe ìyípadà nínú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ lè béèrè pé kí o dúró lórí ìpinnu rẹ. Wíwọ ọkọ̀ lè má fi gbogbo ìgbà rọrùn. Ṣùgbọ́n, má ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan yìí mú ọ rẹ̀wẹ̀sì débi tí o kò fi ní lọ sí àpéjọpọ̀.

7 Ronú Nípa Àpẹẹrẹ Dáradára Yìí: Nígbà tí àwùjọ àwọn ará ní orílẹ̀-èdè Áfíríkà kan níbi tí ìjà ìgboro ti ń ṣẹlẹ̀ ń lọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè lọ́dún tó kọjá, wọ́n pàdé àwọn ológun. Wọ́n bi àwọn ará náà pé: “Ta ni yín o, ibo lẹ sì ń lọ?” Wọ́n dáhùn pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, a ń lọ ṣe ìpàdé àgbègbè ni.” Ọ̀kan lára àwọn sójà náà sọ pé: “Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í bẹ̀rù ohunkóhun. Ẹ máa lọ, yóò sì ṣeé ṣe fún yín láti ṣe àpéjọpọ̀ yín láìsí wàhálà. Ṣùgbọ́n o, ẹ máa pàdé ọ̀pọ̀ sójà. Àárín ọ̀nà ni kẹ́ máa rìn o! Bí ẹ bá rí ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n pé jọ, ẹ ṣáà máa rin àárín ọ̀nà lọ!” Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì dé àpéjọpọ̀ láìséwu. A san èrè fún àwọn ará wọ̀nyí nítorí pé wọ́n fi ìmọrírì wọn hàn fún àwọn ohun ọlọ́wọ̀.

8 Gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn arákùnrin wa ní orílẹ̀-èdè yẹn, àwa pẹ̀lú ń kojú ìpèníjà. Ṣùgbọ́n, ó dájú pé a lè ṣàfarawé ìgbàgbọ́ wọn, kí a sì pinnu láti wà lórí ìjókòó ní gbogbo àkókò ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ àgbègbè wa. Bí ó bá yẹ kí o ṣe àwọn ìyípadà kan, yíjú sí Jèhófà fún ìtọ́sọ́nà, kí o mọ̀ pé yóò bù kún àwọn ìsapá wa láti wà níbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà látìbẹ̀rẹ̀ dópin.

9 Jèrè Àwọn Ìbùkún: A ń yán hànhàn fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nítorí a mọ̀ pé nípasẹ̀ rẹ̀ la fi lè rí ìgbàlà. (1 Pét. 2:2) Lílọ tí a bá lọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè, tí a bá sì fetí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà yóò ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ tó túbọ̀ lágbára nínú Ọ̀rọ̀ náà, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ túbọ̀ ṣeé ṣe fún wa láti dènà ìkọlù gbígbónájanjan látọ̀dọ̀ Sátánì. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a óò fi han Jèhófà àti àwọn tó ń wò wá pé a mọrírì àwọn ohun ọlọ́wọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ àti pé “àwa kì í ṣe irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn . . . ṣùgbọ́n irú àwọn tí ó ní ìgbàgbọ́ fún pípa ọkàn mọ́ láàyè.”—Héb. 10:39; 12:16; Òwe 27:11.

10 A lè máa wo ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run pé yóò ṣí ibodè ibú omi ọ̀run, yóò sì tú ìbùkún tẹ̀mí lọ́pọ̀ yanturu dà sórí wa. (Mál. 3:10) Fi ṣe góńgó rẹ láti wà ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí” láti ìbẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà gan-an ní òwúrọ̀ ọjọ́ Friday títí di ìgbà àdúrà ìparí àti “Àmín!” lọ́sàn-án ọjọ́ Sunday. Wàá láyọ̀ pé o wà níbẹ̀!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́