ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/00 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 10
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 17
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 24
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 31
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 7
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 7/00 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 10

Orin 7

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ nípa ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá oṣù March lórílẹ̀-èdè yìí àti níjọ yín. Pe àfiyèsí sí àpótí tí ó ní àkọlé náà, “Wo Àwọn Ojú Ìwé Tó Kẹ́yìn” kí o sì jẹ́ kí a ṣàṣefihàn ọ̀kan lára àwọn ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí a dámọ̀ràn tí yóò gbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ yín.

15 min: “Àwa Kò Lè Dẹ́kun Sísọ̀rọ̀.” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹnu mọ́ ohun tó fà á tí a fi ń fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìwàásù tí a yàn fún wa. Fi àwọn kókó tó bá a mu kún un látinú Ilé Ìṣọ́, January 15, 1997, ojú ìwé 23 àti 24.

18 min: “Kí Ohun Gbogbo Máa Ṣẹlẹ̀ fún Ìgbéniró.” Alàgbà méjì jíròrò àpilẹ̀kọ yìí. Wọ́n ka gbogbo ìpínrọ̀ àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí. Wọ́n ṣàlàyé àwọn ìlànà tó wà níbẹ̀. Wọ́n tẹnu mọ́ ìdí tó fi yẹ kí á lo ìfòyemọ̀ nígbà tí a bá ń bójú tó ọ̀ràn òwò tàbí nígbà tí a bá ń dókòwò. Ṣàtúnyẹ̀wò ìmọ̀ràn tó wà nínú Ilé Ìṣọ́, March 15, 1997, ojú ìwé 18, 19 àti 22.

Orin 15 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 17

Orin 23

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Ní ṣókí, ṣàlàyé bí a ṣe lè lo ìwé pẹlẹbẹ Orukọ Atọrunwa láti fi ran olùfìfẹ́hàn kan lọ́wọ́ láti mọ ìdí tó fi yẹ kó mọ orúkọ Ọlọ́run, kí òun náà sì máa pè é.

13 min: “Máa Ṣàjọpín Nǹkan Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn Gẹ́gẹ́ Bí Wọ́n Ṣe Nílò Rẹ̀.” Àsọyé tí alàgbà sọ.

20 min: Ta Ló Yẹ Kí O Fi Ṣe Àwòkọ́ṣe? Bàbá kan darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ kan tàbí méjì tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́langba. Ó ti ṣàkíyèsí lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ pé ọ̀rọ̀ nípa àwọn akọni nínú eré ìdárayá, àwọn tó gbajúgbajà nínú eré sinimá, àwọn gbajúmọ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n, àti àwọn olórin ni wọ́n máa ń sọ. Ó sọ pé òun ń ṣàníyàn nípa èyí nítorí jíjẹ́ kí irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ máa gba àfiyèsí ẹni jẹ́ fífi ẹ̀mí ayé hàn. Wọ́n jíròrò Jí!, May 22, 1998, ojú ìwé 12 sí 14. Àwọn ọ̀dọ́ èèyàn náà rí i pé ewu ń bẹ nínú sísọ àwọn ẹni pàtàkì nínú ayé dòrìṣà, wọ́n sì gbà pé kò sí àǹfààní tí gbígbajúmọ̀ nínú ayé lè ṣe àwọn Kristẹni. Wọ́n jíròrò àǹfààní tó wà nínú fífi àwọn òbí, àwọn alàgbà, àwọn mìíràn tó jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú ìjọ—àti ní pàtàkì Jésù Kristi—ṣe àwòkọ́ṣe wọn.

Orin 34 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 24

Orin 45

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: Dídámọ̀ràn Ara Wa Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́ Ọlọ́run. Àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ méjì jíròrò ìṣílétí tó bá Ìwé Mímọ́ mu tí a fúnni nínú Ilé Ìṣọ́ December 15, 1998, ojú ìwé 19 àti 20. Wọ́n mọrírì ìdí tó fi yẹ kí àwọ́n kúnjú ìwọ̀n gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ́nà tó yẹ, wọ́n sì ṣàtúnyẹ̀wò ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lè ṣe láti fi hàn pé àwọn ń ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún àwọn. Wọ́n rí ìjẹ́pàtàkì jíjẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, wọ́n sì jíròrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi lè máa ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ nínú ṣíṣètìlẹyìn fún àwọn ẹlòmíràn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé àwọn á ṣe gbogbo ohun tí àwọn lè ṣe láti ran ìjọ lọ́wọ́ láti mọ bí àkókò yìí ti jẹ́ kánjúkánjú tó, kí ìjọ lè máa dàgbà sókè, kí ó sì láásìkí nípa tẹ̀mí.

10 min: Kíkọ Lẹ́tà sí Àwọn Èèyàn Tí Kò Ṣeé Ṣe fún Wa Láti Dé Ọ̀dọ̀ Wọn. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Bó ti túbọ̀ ń ṣòro sí i láti bá àwọn èèyàn nílé, àwọn akéde kan ti rí ojútùú kan tí ó dára nípa kíkọ lẹ́tà. Ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà wọ̀nyí: Lẹ́tà rẹ gbọ́dọ̀ ṣe ṣókí, kí o gbé e karí Ìwé Mímọ́, kí ó sì fi ọ̀wọ̀ hàn. Má ṣe fi lẹ́tà tí o kò kọ orúkọ rẹ sí ránṣẹ́. Kọ lẹ́tà náà, tàbí kí o tẹ̀ ẹ́, kó rí nigínnigín, kó sì ṣeé kà. Sọ àdírẹ́sì Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn àkókò tí ìjọ ń ṣe ìpàdé, kí o sì ké sí ẹni náà pé kí ó wá sí ìpàdé. Má ṣe lo àdírẹ́sì Society láti fi gba èsì. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìmọ̀ràn tí a pèsè nínú Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ojú ìwé 87 àti 88, àti Àpótí Ìbéèrè inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 1996.

15 min: Lo Àwọn Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tó Gbéṣẹ́. Yan ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ méjì tàbí mẹ́ta ní ojú ìwé 2 sí 7 nínú ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, kí o sì jíròrò bí ẹ ṣe lè lo èyí lọ́nà gbígbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín. Bi àwùjọ léèrè pé, “Àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wo lẹ máa ń lò nígbà tí ẹ bá fẹ́ bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ ní òpópónà, tàbí lọ́nà tí kò jẹ́ bí àṣà, tàbí ní àwọn ọ̀nà mìíràn?” Jẹ́ kí a ṣàṣefihàn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tàbí méjì bí àkókò bá ti wà tó.

Orin 54 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 31

Orin 66

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù July sílẹ̀. Sọ pé kí àwùjọ sọ ìrírí tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní lóṣù yìí nígbà tí wọ́n ń pín àwọn ìwé pẹlẹbẹ.

12 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

18 min: “Ǹjẹ́ O Mọrírì Sùúrù Jèhófà?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé tó bá a mu kún un nípa ìpamọ́ra Jèhófà.—Wo Insight, Apá 2, ojú ìwé 263 àti 264.

Orin 75 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 7

Orin 88

8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

17 min: “Ṣé O Máa Ń Tijú?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ ìrírí kan tó ń fúnni níṣìírí látinú ìwé 1997 Yearbook, ojú ìwé 43 àti 44.

20 min: Di Ọlọgbọ́n ní Ọjọ́ Ọ̀la Rẹ. Àsọyé tí alàgbà sọ. Àwọn ọ̀dọ́ máa ń fẹ́ láti gbádùn ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀ pẹ̀lú ẹni tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyẹn jẹ́ ìwà ẹ̀dá, wọ́n gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ràn Ọlọ́run sílò bí wọn yóò bá ṣàṣeyọrí. (Òwe 19:20) Nígbà èwe, èèyàn máa ń ní ìfẹ́ gbígbóná sí ẹ̀yà òdìkejì. Bí a kò bá kó ìmọ̀lára wa níjàánu, jàǹbá lè ṣẹlẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló ti dìde nípa bóyá ó bọ́gbọ́n mu kí àwọn ọ̀dọ́langba bẹ̀rẹ̀ wọlé wọ̀de pẹ̀lú ẹ̀yà òdìkejì, kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ àjọṣe olóòfà ìfẹ́ tó máa ń yọrí sí dídájọ́-àjọròde. Ṣàtúnyẹ̀wò ìṣílétí tó wà nínú ìwé Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè, ojú ìwé 231 sí 235. Tẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì nínú Ilé Ìṣọ́ November 15, 1999, ojú ìwé 18 sí 23, tó fi hàn pé ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọ̀dọ́ ṣe gbogbo ojúṣewọn níwájú Ọlọ́run. Fún àwọn ọ̀dọ́langba níṣìírí pé kí wọ́n ronú jinlẹ̀ lórí ìmọ̀ràn yìí, kí wọ́n sì bá àwọn òbí wọn jíròrò ìbéèrè tí wọ́n bá ní.

Orin 101 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́