Ẹ̀mí Àwọn Èèyàn Mà Wà Nínú Ewu!
1 Bíbélì mú kó ṣe kedere pé ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là.” Ṣùgbọ́n o, òótọ́ tún ni pé ìrètí ìyè ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù tó ń gbé orí ilẹ̀ ayé sinmi lórí ìṣarasíhùwà wọn sí Jèhófà Ọlọ́run àti sí Ìjọba rẹ̀ lọ́wọ́ Jésù Kristi. “Ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́” nìkan ló lè mú kí èèyàn ní ìṣarasíhùwà yíyẹ. (1 Tím. 2:3, 4) Bí a ti ń kéde pé láìpẹ́, a óò fọ gbogbo ìwà ibi kúrò lórí ilẹ̀ ayé láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ayé tuntun òdodo ti Ọlọ́run, a tún pàṣẹ fún wa láti máa ṣe iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà kan tó ṣe pàtàkì.—Mát. 24:14; 28:19, 20; Róòmù 10:13-15.
2 Kí Ló Dé Tó Fi Jẹ́ Kánjúkánjú Bẹ́ẹ̀? Jésù kìlọ̀ nípa “ìpọ́njú ńlá . . . irúfẹ́ èyí tí kò tíì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé.” (Mát. 24:21) Ìpọ́njú yẹn yóò dé òtéńté rẹ̀ ní Amágẹ́dọ́nì. (Ìṣí. 16:16) Àwọn ìbátan wa, aládùúgbò wa, òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa, ọmọ ilé ìwé ẹlẹgbẹ́ wa, àti àwọn ojúlùmọ̀ wa tí wọn kò gbà gbọ́ wà lára àwùjọ ènìyàn tí yóò pa run bí wọ́n bá kọ̀ láti kọbi ara sí ìhìn rere náà. Ṣùgbọ́n àníyàn wa ni pé kí a dé ọ̀dọ̀ “gbogbo onírúurú ènìyàn” ní ṣíṣàfarawé Ọlọ́run, tó fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí gbogbo aráyé nípa fífi Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà fún gbogbo èèyàn. (Jòh. 3:16) A gbọ́dọ̀ fi ìtara sakun láti ké sí gbogbo èèyàn pé kí wọ́n sá lọ sí ibi ààbò ti Ọlọ́run. Nípa ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, a lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀.—Ìsík. 33:1-7; 1 Kọ́r. 9:16.
3 Ète Wo La Ní Lọ́kàn? Látòkèdélẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ ìwàásù. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti sọ, “ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa” láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà Ọlọ́run. (2 Kọ́r. 5:14) Láfikún sí i, Ilé Ìṣọ́ sábà máa ń tẹnu mọ́ àìgbọ́dọ̀máṣe tí a ní láti wàásù. Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa kò dáwọ́ dúró láti pèsè ìtọ́sọ́nà nípa bí a ṣe lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà. Àwọn alàgbà máa ń ṣètò iṣẹ́ náà, wọ́n sì máa ń fún wa níṣìírí láti kópa nínú rẹ̀. Àwọn akéde ẹlẹgbẹ́ wa máa ń ké sí wa pé kí a jọ lọ ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ la máa ń gbọ́ nípa bí a ṣe lè múra àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀, fífi ìwé ìròyìn àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọni, ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò, dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àti lílo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti jẹ́rìí. Gbogbo èyí ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeparí ète táa ní lọ́kàn láti gba ẹ̀mí là.—1 Kọ́r. 9:22, 23; Éfé. 1:13.