Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
ÀKÍYÈSÍ: Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yóò ṣètò Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní àkókò àpéjọpọ̀. Kí àwọn ìjọ ṣe àtúnṣe tó yẹ láti fàyè sílẹ̀ fún lílọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí.” Níbi tó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀, ẹ lo ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó kẹ́yìn kí ẹ́ tó lọ sí àpéjọpọ̀ láti ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìmọ̀ràn pàtàkì nínú àkìbọnú ti oṣù yìí. Rọ gbogbo àwọn ará pé kí wọ́n ló ìṣẹ́jú díẹ̀ láti fi wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí a tẹ̀ kí ìpàdé òwúrọ̀ àti ti ọ̀sán ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó bẹ̀rẹ̀, kí wọ́n sì fojú sọ́nà fún ohun tó ṣeé ṣe kí a jíròrò. Èyí yóò mú kó rọrùn láti pọkàn pọ̀ sórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, kí a sì kọ nǹkan sílẹ̀ ní ṣókí, lọ́nà tó nítumọ̀. Ní ọ̀sẹ̀ méjì sí mẹ́rin lẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà, kí ẹ ṣètò fún àtúnyẹ̀wò ọlọ́gbọ̀n ìṣẹ́jú lórí àwọn kókó pàtàkì inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Lákòókò yẹn, ẹnì kọ̀ọ̀kan ní láti múra sílẹ̀ láti ṣe àlàyé ṣókí nígbà tí àwọn arákùnrin títóótun mẹ́ta tí a yàn pé kí wọ́n bójú tó apá yìí bá ké sí i láti ṣe bẹ́ẹ̀. Irú àlàyé bẹ́ẹ̀ lè sọ nípa bí ohun tí a kẹ́kọ̀ọ́ ní àpéjọpọ̀ ṣe kan ìgbésí ayé ẹni àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá ẹni. A lè sọ ìrírí kan tàbí méjì tí a yàn ní ṣókí. Bí apá yìí nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn yóò bá lárinrin, kí ó sì kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, gbogbo wa gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ dáadáa.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 11
Orin 125
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ táa mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: “Ǹjẹ́ O Mọrírì Àwọn Ohun Ọlọ́wọ̀?” Àsọyé tí alàgbà sọ. Tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó láti lọ sí àpéjọpọ̀ àgbègbè náà ní gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.
20 min: “Lo Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Lọ́ọ́lọ́ọ́ Láti Ru Ìfẹ́ Sókè.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ àti àwọn àṣefihàn. Mẹ́nu kan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ mélòó kan tí àwọn èèyàn ń sọ nípa rẹ̀ ládùúgbò rẹ. Àníyàn wo lèyí ń mú kí wọ́n ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la? Nípa lílo ìwé kékeré Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 2 àti 3, sọ àwọn àbá díẹ̀ nípa bí a ṣe lè múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí yóò yọrí sí ìjíròrò Bíbélì. Jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn tí wọ́n múra sílẹ̀ dáadáa, tó sì ṣeé mú lò.
Orin 224 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 18
Orin 2
13 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
16 min: “Fetí sí Àwọn Ọ̀rọ̀ Ìkéde Ọlọ́wọ̀.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹnu mọ́ àwọn ìdí tó fi yẹ kí gbogbo wa ti wà lórí ìjókòó wa nígbà tí ìpàdé bá bẹ̀rẹ̀.
16 min: “Máa Fi Ìwà Dídára Lọ́pọ̀lọpọ̀, Tó Ń Fògo fún Ọlọ́run Hàn.” Alàgbà kan bá àwùjọ ìdílé kan jíròrò àpilẹ̀kọ náà. Wọ́n ṣàyẹ̀wò ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe láti máa ṣe nǹkan létòlétò, láti máa hu ìwà rere, kí wọ́n máa mọ́ tónítóní, kí ìrísí àti ìwà wọn ní gbangba sì jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ.
Orin 203 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 25
Orin 93
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù September sílẹ̀. Ṣàyẹ̀wò Àpótí Ìbéèrè.
13 min: “Ìbùkún Jèhófà Ló Ń Sọ Wá Di Ọlọ́rọ̀.” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.—Wo ìwé Insight, Apá Kejì, ojú ìwé 804, ìpínrọ̀ 6 àti 7.
17 min: “Ẹ̀mí Àwọn Èèyàn Mà Wà Nínú Ewu!” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ náà.
Orin 30 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 2
Orin 169
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ fún ìjọ nípa ìwéwèé tí a ṣe láti pín Ìròyìn Ìjọba No. 36 kiri lákànṣe, tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní Monday, October 16, tí yóò sì máa bá a lọ títí di Friday, November 17. Rọ gbogbo àwùjọ, títí kan àwọn èwe àti àwọn ẹni tuntun, pé kí wọ́n sapá láti kópa ní kíkún. Kí àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí fún àwọn tó wà nínú àwùjọ wọn níṣìírí ní báyìí, kí wọ́n sì ṣètò wọn kí wọ́n lè kópa nínú rẹ̀ tìtaratìtara bí wọ́n bá ti lè ṣe tó. Sọ àwọn ìrírí tí ń gbéni ró tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba tó kọjá.
15 min: “Ṣé Kí N Ṣí Lọ Síbòmíràn?” Àsọyé tí alàgbà sọ. Ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ kí èèyàn lo agbára ìfòyemọ̀ nínú pípinnu láti ṣí lọ síbòmíràn. Jíròrò bí a ṣe lè fi ìmọ̀ràn tó wà ní Òwe 22:3 sílò. Ṣàlàyé ìkìlọ̀ tó wà nínú Ilé-Ìṣọ́nà, August 15, 1988, ojú ìwé 22.
15 min: Báwo La Ti Ṣe Sí Lọ́dún Tó Kọjá? Àsọyé tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sọ. Ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó ṣe pàtàkì nínú ìròyìn ìjọ fún ọdún iṣẹ́ ìsìn 2000. Gbóríyìn fún ìjọ nítorí ohun rere tí wọ́n gbé ṣe. Sọ àwọn àgbègbè tó ń fẹ́ àtúnṣe. Darí àfiyèsí sí bí ìjọ ti ṣe sí nínú wíwá sí ìpàdé, bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àti ṣíṣe déédéé nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Sọ àwọn góńgó gbígbéṣẹ́ tó wà fún ọdún tó ń bọ̀.
Orin 205 àti àdúrà ìparí.