ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/00 ojú ìwé 1
  • Ìbùkún Jèhófà Ló Ń Sọ Wá Di Ọlọ́rọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbùkún Jèhófà Ló Ń Sọ Wá Di Ọlọ́rọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Kò Tí ì Ní Ọ̀pọ̀ Nǹkan Tẹ̀mí Tó Báyìí Rí!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ǹjẹ́ o ‘Ní Ọrọ̀ Lọ́dọ̀ Ọlọ́run’?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • “Èso Ti Ẹ̀mí” Ń Fi Ògo Fún Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìbùkún Jèhófà Ní í Sọ Wá Dọlọ́rọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 9/00 ojú ìwé 1

Ìbùkún Jèhófà Ló Ń Sọ Wá Di Ọlọ́rọ̀

1 Iye owó tó bá ń wọlé fún èèyàn níbi iṣẹ́ rẹ̀ ni wọ́n sábà máa ń fi díwọ̀n àṣeyọrí rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi máa ń wo àwọn tó lówó pé àwọn ló láyọ̀, àwọn ló sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn jù lọ. Ṣùgbọ́n, àṣìṣe gbáà làwọn tó ń ronú pé owó lè ra ayọ̀ ń ṣe. (Oníw. 5:12) Àwọn tó bá “pinnu láti di ọlọ́rọ̀” nípa ti ara kò lè ní ayọ̀ pípẹ́ títí. (1 Tím. 6:9) Ṣùgbọ́n ọ̀ràn tàwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yàtọ̀, wọ́n láyọ̀ ní tòótọ́, àwọn ló sì lọ́rọ̀ jù lọ ní gbogbo ayé. (Òwe 10:22; Ìṣí. 2:9) Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?

2 Ẹ̀rí Pé A Jẹ́ Ọlọ́rọ̀: A ní ìjìnlẹ̀ òye púpọ̀ nípa tẹ̀mí, a sì lóye Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Jèhófà ń lo ètò àjọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé láti máa kọ́ wa nípa òun fúnra rẹ̀ àti nípa Ọmọ rẹ̀ fún àǹfààní wa ayérayé. Ìmọ̀ pípéye ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti sún mọ́ Jèhófà, kí a sì ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀. (Ják. 4:8) Fífòye mọ rere yàtọ̀ sí búburú àti títẹ̀ lé àwọn òfin Ọlọ́run ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn àrùn àti ewu kan. A ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà yóò pèsè fún wa, èyí sì ń yọrí sí ìtẹ́lọ́rùn tó dà bíi ti Ọlọ́run àti àlàáfíà ọkàn.—Mát. 6:33.

3 A ń gbádùn àlàáfíà àti ìṣọ̀kan láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará wa nípa tẹ̀mí nítorí pé a ń fi èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run hàn. Bí ìdè ìfẹ́ lílágbára ti so wá pọ̀ ṣọ̀kan, kò sí ìdí fún wa rárá láti ronú pé Ọlọ́run tàbí àwọn ará wa kọ̀ wá sílẹ̀ nígbà tí àjálù bá dé bá wa.—Gál. 6:10.

4 Ìgbésí ayé wa ní ìtumọ̀ àti ète gidi. A wò ó pé àǹfààní àgbàyanu ló jẹ́ láti máa kópa nínú ìwàásù ìhìn rere náà kárí ayé. Èyí ń mú ayọ̀ pípẹ́ títí wá bí a ti ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ pé kí àwọn náà lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa sìn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú wa nínú ìjọsìn mímọ́ gaara. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, tó jẹ́ ìṣúra tí kò ṣeé díye lé, ń fi ọlá fún Jèhófà, ó sì ń jẹ́ kí a ní ìtẹ́lọ́rùn pé a ń ṣe ipa tiwa nínú sísọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. A ń ní ẹ̀mí èrò orí tó dára, bí a ti mọ̀ pé ìrètí tí a ní nípa ọjọ́ iwájú máa tó dòótọ́.

5 Fífi Ìmọrírì Wa Hàn: Ǹjẹ́ kí a máa fi ìmọrírì hàn nígbà gbogbo nítorí àwọn ìbùkún Jèhófà, èyí tó ń sọ wá di ẹni tó lọ́rọ̀ jù lọ ní ayé. (Òwe 22:4) Wíwá àyè lójoojúmọ́ láti ṣàṣàrò nípa ohun táa ní ń sún wa láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìfẹ́ rẹ̀ ọlọ́làwọ́ àti láti máa bá a nìṣó láti fún un ní ìfọkànsìn wa tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́