Báwo Ni Ìbákẹ́gbẹ́ Kristẹni Ti Ṣe Pàtàkì Tó?
1 “Igi kan ò lè dágbó ṣe.” Ńṣe ni gbólóhùn yìí kàn ń ṣàtúnsọ ohun tí Bíbélì sọ nípa nǹkan pàtàkì kan tí èèyàn nílò, ìyẹn ìbákẹ́gbẹ́. (Òwe 18:1) Ìbákẹ́gbẹ́ Kristẹni wa máa ń pèsè ohun táa ń fẹ́ yìí. Àwọn ọ̀nà tó ṣàǹfààní wo ló ń gbà ṣe èyí?
2 Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́: Ọ̀kan lára àǹfààní tó gba iwájú jù lọ ni bí àwọn ará wa ṣe máa ń fún wa lókun tí wọ́n sì máa ń tì wá lẹ́yìn lóde ẹ̀rí. Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde “ní méjì méjì” láti lọ wàásù. (Máàkù 6:7; Lúùkù 10:1) Ní ìbámu pẹ̀lú àwòkọ́ṣe yìí, a ń rí i pé òótọ́ lohun tó wà nínú Oníwàásù 4:9, 10 nígbà táa bá ń bá àwọn ẹlòmíràn ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Bí a ti jùmọ̀ ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, ìgbàgbọ́, ìgbọràn, àti ìfẹ́ àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́ máa ń fún wa ní ìgboyà, ó sì máa ń mú kí ìtara wa túbọ̀ pọ̀ sí i.
3 Ó Máa Ń Ran Olúkúlùkù Wa Lọ́wọ́: Ẹgbẹ́ àwọn ara wa kárí ayé tún jẹ́ orísun ìṣírí àti ìtọ́sọ́nà fún kíkojú pákáǹleke àti ìdẹwò. Àwọn Kristẹni alábàákẹ́gbẹ́ wa lè pe àfiyèsí wa sí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tí olúkúlùkù wa ń ṣàníyàn nípa rẹ̀. Wọ́n tilẹ̀ lè gbàdúrà nítorí wa, bí àwa náà ṣe ń gbàdúrà nítorí wọn. (2 Kọ́r. 1:11) Dájúdájú, àpẹẹrẹ rere wọn sì ń sún wa láti ṣe ohun tó tọ́, ó sì ń fún wa lókun.
4 Láwọn Ìpàdé: A máa ń rí ìbùkún ìbákẹ́gbẹ́ Kristẹni nígbà tí a bá ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ déédéé. (Héb. 10:24, 25) Ìtọ́ni tẹ̀mí pọ̀ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé, lílọ sí ìpàdé wa sì máa ń jẹ́ ká sún mọ́ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Ìpàdé wọ̀nyí máa ń fún wa láǹfààní láti gbọ́ bí àwọn ará wa ṣe ń sọ ìgbàgbọ́ wọn jáde, yálà látorí pèpéle tàbí látinú àwùjọ. (Róòmù 1:12) Ìbákẹ́gbẹ́ wa túbọ̀ máa ń jinlẹ̀ sí i bí a ṣe ń bá ara wa jíròrò ṣáájú àti lẹ́yìn ìpàdé. Irú àkókò bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ ká láǹfààní láti sọ àwọn ìrírí tiwa tó ń gbé ìgbàgbọ́ ró. Nígbà tí a bá ń bá àwọn tó fẹ́ràn Jèhófà, tí wọ́n fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí wọ́n fẹ́ràn iṣẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì fẹ́ràn àwọn èèyàn rẹ̀ kẹ́gbẹ́ dáadáa, ó máa ń ní ipa rere lórí ìwà wa.—Fílí. 2:1, 2.
5 A nílò àwọn Kristẹni alábàákẹ́gbẹ́ wa. Láìsí wọn, yóò túbọ̀ ṣòro láti rìn ọ̀nà híhá tó lọ sí ìyè. Ṣùgbọ́n, bí wọ́n ti nífẹ̀ẹ́ wa tí wọ́n sì ń fún wa níṣìírí, a óò lè máa bá ìrìn wa sínú ayé tuntun òdodo ti Jèhófà nìṣó.—Mát. 7:14.