“Ìran Àpéwò ní Gbọ̀ngàn Ìwòran” Ni Yín!
1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Àwa ti di ìran àpéwò ní gbọ̀ngàn ìwòran fún ayé, àti fún àwọn áńgẹ́lì, àti fún àwọn ènìyàn.” (1 Kọ́r. 4:9) Kí lèyí túmọ̀ sí, ipa wo ló sì yẹ kí ó ní lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lónìí?
2 Bí ará Kọ́ríńtì kan bá gbọ́ gbólóhùn náà, “ìran àpéwò ní gbọ̀ngàn ìwòran,” ohun tó lè wá sọ́kàn rẹ̀ ni ohun tó máa ń kẹ́yìn ìdíje ìjà àjàkú akátá àwọn ará Róòmù, níbi tí àwọn èèyàn tí wọ́n fẹ́ pa yóò ti gba iwájú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òǹwòran kọjá kó tó di pé wọ́n á pa wọ́n ní ìpa ìkà. Bákan náà, àwùjọ ńlá kan, tí ó jẹ́ àwọn èèyàn àti áńgẹ́lì ń wo ìjìyà tí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní fara gbà nítorí jíjẹ́rìí nípa Ìjọba náà. (Héb. 10:32, 33) Ipa ọ̀nà ìṣòtítọ́ tí wọ́n tọ̀ ní ipa lórí ọ̀pọ̀ òǹwòran, gẹ́gẹ́ bí ìfaradà wa ti ń ṣe ní gbọ̀ngàn ìwòran òde òní. Ta la jẹ́ ohun àfiṣèranwò fún?
3 Fún Ayé Yìí àti Fáwọn Èèyàn: Nígbà mìíràn, àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn máa ń gbé ìròyìn jáde nípa iṣẹ́ àwa èèyàn Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a mọrírì ìròyìn rere tó jóòótọ́ tí kò sì lábòsí nínú tí wọ́n bá sọ nípa iṣẹ́ wa, a retí pé àwọn abanijẹ́ kò ní ṣàìsọ ìròyìn búburú káàkiri lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀, a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti dámọ̀ràn ara wa gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run “nípasẹ̀ ìròyìn búburú àti ìròyìn rere.” (2 Kọ́r. 6:4, 8) Àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ ọkàn nínú àwọn tó ń wò wá yóò rí i kedere pé àwa ni ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi ní tòótọ́.
4 Fún Àwọn Áńgẹ́lì: Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ń wò wá pẹ̀lú. Èṣù àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ ń wò wá, ṣùgbọ́n pẹ̀lú “ìbínú ńlá” ni, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti dá “iṣẹ́ jíjẹ́rìí Jésù” dúró. (Ìṣí. 12:9, 12, 17) Àwọn olóòótọ́ áńgẹ́lì Ọlọ́run ń wòran, inú wọn sì ń dùn kódà nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà. (Lúùkù 15:10) Ó yẹ kí mímọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì ń wo iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa pé ó jẹ́ kánjúkánjú gan-an, pé ó sì jẹ́ iṣẹ́ tó ṣàǹfààní tí a ń ṣe lórí ilẹ̀ ayé lónìí, fún wa lókun!—Ìṣí. 14:6, 7.
5 Nígbà tí o bá bá àtakò pàdé tàbí tí o bá ronú pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ ò ṣàṣeyọrí, máa rántí pé wọ́n ń wò ọ́ láyé lọ́run. Bí o ṣe ń fara dà tòótọ́tòótọ́ fi hàn pé o jẹ́ olùpàwàtítọ́mọ́. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, “ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́” tí o ń jà yóò jẹ́ kí o lè “di ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí.”—1 Tím. 6:12.