ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 19
ORIN 6 Ọ̀run Ń Polongo Ògo Ọlọ́run
Fara Wé Àwọn Áńgẹ́lì Olóòótọ́
“Ẹ yin Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀.”—SM. 103:20.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
Àwọn nǹkan tá a kọ́ lára àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́.
1-2. (a) Báwo la ṣe yàtọ̀ sáwọn áńgẹ́lì? (b) Kí làwa àtàwọn áńgẹ́lì fi jọra?
NÍGBÀ tó o kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, Jèhófà pè ẹ́ wá sínú ìdílé ẹ̀. Àwọn èèyàn ẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ ló wà nínú ìdílé náà, gbogbo wọn sì ń jọ́sìn ẹ̀ níṣọ̀kan. (Dán. 7:9, 10) Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì, a lè máa ronú nípa bí wọ́n ṣe yàtọ̀ sí wa. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú kí Jèhófà tó dá àwa èèyàn làwọn áńgẹ́lì ti wà. (Jóòbù 38:4, 7) Wọ́n tún lágbára jù wá lọ. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n jẹ́ mímọ́, ìwà títọ́ wọn sì ju tàwa èèyàn lọ fíìfíì torí pé aláìpé ni wá.—Lúùkù 9:26.
2 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a yàtọ̀ sáwọn áńgẹ́lì, ọ̀pọ̀ nǹkan la fi jọra. Bí àpẹẹrẹ, àwa náà láwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní, a sì lómìnira láti ṣe ohun tá a fẹ́ bíi tàwọn áńgẹ́lì. Nǹkan míì tá a fi jọra ni pé ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ló ní orúkọ tiẹ̀, ìwà wa yàtọ̀ síra, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló sì ní ojúṣe tiẹ̀ nínú ètò Ọlọ́run. Paríparí ẹ̀, bó ṣe ń wu àwọn áńgẹ́lì láti jọ́sìn Ẹlẹ́dàá wa ló ń wu àwa náà.—1 Pét. 1:12.
3. Kí la lè kọ́ lára àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́?
3 Torí pé ọ̀pọ̀ nǹkan làwa àtàwọn áńgẹ́lì fi jọra, àpẹẹrẹ wọn lè ràn wá lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ nǹkan la sì lè kọ́ lára wọn. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ bíi tàwọn áńgẹ́lì àti bá a ṣe lè fìwà jọ wọ́n tó bá dọ̀rọ̀ ká fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn, bá a ṣe lè nífaradà àti bá a ṣe lè jẹ́ kí ìjọ Ọlọ́run mọ́.
ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ NÍRẸ̀LẸ̀
4. (a) Báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe ń fi hàn pé àwọn nírẹ̀lẹ̀? (b) Kí nìdí táwọn áńgẹ́lì fi nírẹ̀lẹ̀? (Sáàmù 89:7)
4 Àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ nírẹ̀lẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n mọ̀, wọ́n lágbára, wọ́n sì gbọ́n, síbẹ̀ ohun tí Jèhófà bá ní kí wọ́n ṣe ni wọ́n máa ń ṣe. (Sm. 103:20) Tí wọ́n bá lọ jíṣẹ́ tí Jèhófà rán wọn, wọn kì í fọ́nnu nípa ohun tí wọ́n lè ṣe tàbí kí wọ́n máa ṣe àṣehàn káwọn èèyàn lè mọ̀ pé wọ́n lágbára. Wọ́n mọ̀ pé àwọn èèyàn lè má mọ orúkọ àwọn, síbẹ̀ inú wọn máa ń dùn láti jíṣẹ́ tí Jèhófà bá rán wọn.a (Jẹ́n. 32:24, 29; 2 Ọba 19:35) Wọn kì í gba ògo tó tọ́ sí Jèhófà. Kí nìdí táwọn áńgẹ́lì fi nírẹ̀lẹ̀ gan-an? Ìdí ni pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún un gan-an.—Ka Sáàmù 89:7.
5. Báwo ni áńgẹ́lì kan ṣe fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ nígbà tó tọ́ àpọ́sítélì Jòhánù sọ́nà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
5 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì nírẹ̀lẹ̀. Ní nǹkan bí ọdún 96 Sànmánì Kristẹni, áńgẹ́lì kan tí ò sọ orúkọ ẹ̀ wá fi ìran àgbàyanu kan han àpọ́sítélì Jòhánù. (Ìfi. 1:1) Kí ni Jòhánù ṣe nígbà tó rí ìran yẹn? Ṣe ló fẹ́ jọ́sìn áńgẹ́lì náà. Àmọ́ áńgẹ́lì olóòótọ́ yẹn ò jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀, ó tètè sọ fún Jòhánù pé: “Ṣọ́ra! Má ṣe bẹ́ẹ̀! Ẹrú bíi tìẹ ni mí àti ti àwọn arákùnrin rẹ . . . Ọlọ́run ni kí o jọ́sìn!” (Ìfi. 19:10) Ẹ ò rí i pé áńgẹ́lì yẹn nírẹ̀lẹ̀ gan-an! Áńgẹ́lì yẹn ò fẹ́ kí Jòhánù gbé ògo fún òun tàbí kó máa yin òun. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sọ fún un pé Jèhófà nìkan ló yẹ kó jọ́sìn. Síbẹ̀ áńgẹ́lì yẹn ò ronú pé òun dáa ju Jòhánù lọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún kí wọ́n tó bí Jòhánù ni áńgẹ́lì yẹn ti ń jọ́sìn Jèhófà tó sì tún lágbára ju Jòhánù lọ, ó ṣì sọ fún Jòhánù pé ẹrú bíi tòun ló jẹ́. Lóòótọ́, áńgẹ́lì yẹn tọ́ Jòhánù sọ́nà, síbẹ̀ kò kanra mọ́ ọn, kò sì sọ̀rọ̀ àbùkù sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fi ohùn pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kí áńgẹ́lì náà mọ̀ pé ohun tí Jòhánù rí yẹn kà á láyà.
Áńgẹ́lì kan fi hàn pé òun nírẹ̀lẹ̀ nígbà tó ń bá Jòhánù sọ̀rọ̀ (Wo ìpínrọ̀ 5)
6. Báwo la ṣe lè nírẹ̀lẹ̀ bí àwọn áńgẹ́lì?
6 Báwo la ṣe lè nírẹ̀lẹ̀ bí àwọn áńgẹ́lì? Tá a bá ń ṣe ojúṣe wa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kò yẹ ká máa fọ́nnu tàbí ká retí pé káwọn èèyàn máa yìn wá torí àwọn àṣeyọrí tá a ṣe. (1 Kọ́r. 4:7) Yàtọ̀ síyẹn, kò yẹ ká máa rò pé a dáa ju àwọn míì lọ torí pé ó ti pẹ́ tá a ti ń sin Jèhófà tàbí torí àwọn ojúṣe pàtàkì tá a ní. Kódà, bí ojúṣe tá a ní bá ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe yẹ ká túbọ̀ máa nírẹ̀lẹ̀. (Lúùkù 9:48) Bíi tàwọn áńgẹ́lì, ó yẹ káwa náà máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kò sì yẹ ká máa gbé ara wa gẹ̀gẹ̀.
7. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nírẹ̀lẹ̀ tá a bá fẹ́ bá ẹnì kan wí tàbí tá a fẹ́ gbà á nímọ̀ràn?
7 Àwa náà lè fi hàn pé a nírẹ̀lẹ̀ tá a bá fẹ́ tọ́ ẹnì kan sọ́nà tàbí tá a fẹ́ gbà á nímọ̀ràn, ẹni náà lè jẹ́ arákùnrin, arábìnrin tàbí kó jẹ́ ọmọ wa. Nígbà míì, ó lè gba pé ká sojú abẹ níkòó. Àmọ́ tá a bá fara wé áńgẹ́lì tó tọ́ Jòhánù sọ́nà, a lè sojú abẹ níkòó síbẹ̀ ká sọ̀rọ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́, ká má sì fọ̀rọ̀ gún ẹni náà lára. Tá ò bá ronú pé a dáa ju ẹni náà lọ, ọ̀rọ̀ inú Bíbélì la máa fi gbà á nímọ̀ràn, àá bá a sọ̀rọ̀ tìfẹ́tìfẹ́, a ò sì ní kàn án lábùkù.—Kól. 4:6.
ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ NÍFẸ̀Ẹ́ ÀWA ÈÈYÀN
8. (a) Kí ni Lúùkù 15:10 sọ pé àwọn áńgẹ́lì máa ń ṣe tó fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn? (b) Báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? (Tún wo àwòrán.)
8 Àwọn áńgẹ́lì kì í ronú pé ọ̀rọ̀ àwa èèyàn ò kan àwọn tàbí kí wọ́n máa ronú pé a ò já mọ́ nǹkan kan. Dípò ìyẹn, wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa gan-an. Tí ẹnì kan tó ti fi Jèhófà sílẹ̀ bá ronú pìwà dà tó sì pa dà sọ́dọ̀ ẹ̀ tàbí tí ẹnì kan tó ń hùwà burúkú bá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tó yíwà ẹ̀ pa dà, tó sì wá jọ́sìn Jèhófà, inú àwọn áńgẹ́lì máa ń dùn. (Ka Lúùkù 15:10.) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn áńgẹ́lì máa ń ràn wá lọ́wọ́ bá a ṣe ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. (Ìfi. 14:6) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn fúnra wọn kì í wàásù ní tààràtà, wọ́n lè darí arákùnrin tàbí arábìnrin kan lọ sọ́dọ̀ ẹni tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Lóòótọ́ tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, a ò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé àwọn áńgẹ́lì ló darí wa lọ sọ́dọ̀ ẹni náà. Ó ṣe tán, Jèhófà lè lo àwọn nǹkan míì bí ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tàbí láti darí àwa ìránṣẹ́ ẹ̀. (Ìṣe 16:6, 7) Síbẹ̀, ó máa ń lo àwọn áńgẹ́lì ẹ̀ láti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan. Torí náà, tá a bá ń wàásù, ó dájú pé àwọn áńgẹ́lì wà ní sẹpẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́.—Wo àpótí náà, “Jèhófà Dáhùn Àdúrà Wọn.”b
Tọkọtaya kan ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ìwàásù níbi térò pọ̀ sí. Bí wọ́n ṣe ń lọ sílé, arábìnrin náà rí obìnrin kan tí ìdààmú bá. Arábìnrin náà gbà pé àwọn áńgẹ́lì lè darí wa sọ́dọ̀ àwọn tó nílò ìrànlọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run. Ìyẹn mú kó lọ sọ̀rọ̀ ìtùnú fún obìnrin náà (Wo ìpínrọ̀ 8)
9. Báwo làwa náà ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn bí àwọn áńgẹ́lì?
9 Báwo làwa náà ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn bí àwọn áńgẹ́lì? Tá a bá gbọ́ pé wọ́n ti gba ẹnì kan pa dà sínú ìjọ, ó yẹ kínú tiwa náà dùn bíi tàwọn áńgẹ́lì. Ó yẹ ká ṣe gbogbo nǹkan tá a lè ṣe kí ẹni náà lè mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ òun àti pé inú wa dùn pé ó ti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà. (Lúùkù 15:4-7; 2 Kọ́r. 2:6-8) A tún lè fara wé àwọn áńgẹ́lì tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Oníw. 11:6) Bí àwọn áńgẹ́lì sì ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń wàásù, ó yẹ káwa náà máa wá bá a ṣe máa ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, ṣé a lè ṣètò láti bá ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde ṣiṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Ṣé a lè ran àwọn àgbàlagbà tàbí àwọn tára wọn ò le lọ́wọ́ káwọn náà lè máa wàásù?
10. Kí la kọ́ nínú ohun tí Arábìnrin Sara ṣe?
10 Ká sọ pé ipò wa ò jẹ́ ká lè ṣe tó bá a ṣe fẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ńkọ́? A ṣì lè wá bá a ṣe lè bá àwọn áńgẹ́lì ṣiṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Arábìnrin Sarac tó ń gbé Íńdíà ṣe. Ó ti ń ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún nǹkan bí ogún (20) ọdún, àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàìsàn, kò sì lè kúrò lórí bẹ́ẹ̀dì mọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú kó rẹ̀wẹ̀sì gan-an. Àmọ́ Sara pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í láyọ̀ torí pé àwọn ará nínú ìjọ ràn án lọ́wọ́, òun náà sì ń ka Bíbélì déédéé. Ipò tó wà báyìí gba pé kó wá àwọn ọ̀nà míì tá á máa gbà wàásù. Torí pé kò lè jókòó débi tó máa kọ lẹ́tà, orí fóònù nìkan ló ti ń wàásù. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í pe àwọn ìpadàbẹ̀wò ẹ̀ nìyẹn, wọ́n sì tún jẹ́ kó mọ àwọn míì tó lè fẹ́ gbọ́ ìwàásù. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Láàárín oṣù díẹ̀, Sara ti ń kọ́ àádọ́rin (70) èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn sì pọ̀ ju nǹkan tóun nìkan lè dá ṣe lọ! Torí náà, ó ní káwọn míì nínú ìjọ máa bá òun darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ kan. Kódà, ọ̀pọ̀ lára wọn ló ti ń wá sípàdé báyìí. Ẹ wo bínú àwọn áńgẹ́lì ṣe máa dùn tó láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin bíi Sara tí wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù!
ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ NÍFARADÀ
11. Báwo làwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ ṣe fi hàn pé àwọn nífaradà gan-an?
11 Àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ ti fi hàn pé kò sí nǹkan táwọn ò lè fara dà. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni wọ́n ti ń fara da ìwà ìrẹ́jẹ àti ìwà ìkà tó ń ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ìṣojú wọn ni Sátánì àtàwọn áńgẹ́lì míì tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà ṣe di ọlọ̀tẹ̀. (Jẹ́n. 3:1; 6:1, 2; Júùdù 6) Kódà, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa áńgẹ́lì olóòótọ́ kan tí ẹ̀mí èṣù alágbára kan dí lọ́nà kó má bàa jíṣẹ́ Ọlọ́run. (Dán. 10:13) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn áńgẹ́lì rí i pé látìgbà tí Ọlọ́run ti dá Ádámù àti Éfà, ìwọ̀nba làwọn èèyàn tó pinnu láti sin Jèhófà. Láìka gbogbo ìyẹn sí, àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ yìí ṣì ń fìtara sin Jèhófà, wọ́n sì ń láyọ̀. Wọ́n mọ̀ pé tó bá tó àsìkò lójú Ọlọ́run, ó máa mú gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ kúrò.
12. Kí ló máa jẹ́ ká nífaradà?
12 Báwo la ṣe lè nífaradà bí àwọn áńgẹ́lì? Bí àwọn áńgẹ́lì, a máa ń rí ìwà ìrẹ́jẹ táwọn kan ń hù, kódà wọ́n máa ń rẹ́ àwa náà jẹ nígbà míì. Àmọ́ ó dá wa lójú pé tó bá tó àsìkò lójú Ọlọ́run, ó máa mú gbogbo ìwà ibi kúrò. Torí náà, bí àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ yẹn, a ò ní “jáwọ́ nínú ṣíṣe rere.” (Gál. 6:9) Jèhófà sì ti ṣèlérí pé òun máa ràn wá lọ́wọ́. (1 Kọ́r. 10:13) Ó tún yẹ ká gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, ìyẹn ló sì máa jẹ́ ká ní sùúrù, ká sì máa láyọ̀. (Gál. 5:22; Kól. 1:11) Tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí ẹ ńkọ́? Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, má sì jẹ́ kẹ́rù bà ẹ́. Jèhófà máa fún ẹ lókun, kò sì ní fi ẹ́ sílẹ̀ nígbà kankan.—Héb. 13:6.
ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ MÁA Ń JẸ́ KÍ ÌJỌ MỌ́
13. Iṣẹ́ pàtàkì wo làwọn áńgẹ́lì ń ṣe láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí? (Mátíù 13:47-49)
13 Jèhófà ti gbé iṣẹ́ pàtàkì kan fáwọn áńgẹ́lì láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. (Ka Mátíù 13:47-49.) Onírúurú èèyàn kárí ayé ló ń gbọ́ ìwàásù. Àwọn kan lára wọn máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti wá sin Jèhófà, àwọn míì kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀. Jèhófà ti yan àwọn áńgẹ́lì pé kí wọ́n “ya àwọn ẹni burúkú sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn olódodo.” Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé ara iṣẹ́ wọn ni láti jẹ́ kí ìjọ mọ́. Àmọ́, kì í ṣe pé àwọn tí ò sin Jèhófà mọ́ fún ìdí kan tàbí òmíì ò lè pa dà wá jọ́sìn ẹ̀, kì í sì í ṣe pé àwọn kan ò lè dẹ́ṣẹ̀ nínú ìjọ. Síbẹ̀, ó dá wa lójú pé àwọn áńgẹ́lì ń ṣe gbogbo nǹkan tí wọ́n lè ṣe láti jẹ́ kí ìjọ mọ́.
14-15. Báwo la ṣe lè fara wé àwọn áńgẹ́lì tá a bá fẹ́ kí ìjọ Ọlọ́run mọ́ ní gbogbo ọ̀nà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
14 Báwo la ṣe lè fara wé àwọn áńgẹ́lì tá a bá fẹ́ kí ìjọ Ọlọ́run mọ́? A lè ṣe bẹ́ẹ̀ tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti má fàyè gba ìṣekúṣe tàbí àwọn ìwà míì tínú Ọlọ́run ò dùn sí. Kí èyí lè ṣeé ṣe, a gbọ́dọ̀ sapá láti ní àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, ká sì yẹra fún ìwàkiwà. Ìyẹn ló máa jẹ́ ká lè dáàbò bo ọkàn wa. (Sm. 101:3) A tún lè ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, kí ló yẹ ká ṣe tá a bá gbọ́ pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá? Torí pé a nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, a máa rọ̀ ọ́ pé kó lọ sọ fáwọn alàgbà. Tí ò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwa fúnra wa máa lọ sọ fáwọn alàgbà. Ìdí sì ni pé a fẹ́ kí ẹni náà tètè rí ìrànlọ́wọ́ gbà kó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.—Jém. 5:14, 15.
15 Ó bani nínú jẹ́ pé wọ́n máa ń mú àwọn kan tó dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kúrò nínú ìjọ. Tírú ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, a ò ní ‘kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ mọ́.’d (1 Kọ́r. 5:9-13) Ètò tí Jèhófà ṣe yìí ló máa ń jẹ́ kí ìjọ mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, tá ò bá kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tá a ti mú kúrò nínú ìjọ, à ń fi inúure hàn sí wọn nìyẹn. Ìdí ni pé bá a ṣe pinnu pé a ò ní bá wọn kẹ́gbẹ́ mọ́ lè mú kí wọ́n pe orí ara wọn wálé. Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú wa máa dùn, inú Jèhófà àtàwọn áńgẹ́lì náà sì máa dùn.—Lúùkù 15:7.
Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá gbọ́ pé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá? (Wo ìpínrọ̀ 14)e
16. Kí ni wàá máa ṣe kó o lè fara wé àwọn áńgẹ́lì?
16 Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní pé Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì, ká sì máa bá wọn ṣiṣẹ́! Ẹ jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ tó dáa tí wọ́n ní, bí ìrẹ̀lẹ̀, ìfaradà, bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn àti bí wọ́n ṣe ń mú kí ìjọ Ọlọ́run wà ní mímọ́. Tá a bá ń fara wé àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́, àwa náà máa wà lára ìdílé Jèhófà tó máa jọ́sìn ẹ̀ títí láé.
ORIN 123 Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run
a Àìmọye áńgẹ́lì ló wà lọ́run, àmọ́ méjì péré ni Bíbélì dárúkọ, ìyẹn Máíkẹ́lì àti Gébúrẹ́lì.—Dán. 12:1; Lúùkù 1:19.
b O lè rí àwọn ìrírí míì nínú Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wo àkòrí náà, “Jèhófà,” kó o wá lọ sí “Ọ̀run,” lẹ́yìn náà, kó o lọ sí “Àwọn Áńgẹ́lì.”
c A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.
d Bá a ṣe sọ nínú Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2024 #2, ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa lo ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ láti pinnu bóyá òun máa kí ẹni tí wọ́n mú kúrò nínú ìjọ tó bá wá sípàdé, àmọ́ kó jẹ́ ní ṣókí.
e ÀLÀYÉ ÀWÒRÁN: Arábìnrin kan ń rọ ọ̀rẹ́ ẹ̀ pé kó lọ sọ ohun tó ṣe fáwọn alàgbà. Àmọ́ nígbà tó rí i pé ọ̀rẹ́ òun ò lọ sọ lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, òun fúnra ẹ̀ lọ sọ fáwọn alàgbà.