Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 12
Orin 43
8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: “Gbára Lé Okun Tí Jèhófà Ń Fúnni.”a Fi àlàyé ṣókí kún un látinú Ilé Ìṣọ́ October 1, 1999, ojú ìwé 18 àti 19, ìpínrọ̀ 6 sí 8.
22 min: “Máa Tẹ̀ Síwájú Nípa Tẹ̀mí Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ.” Kí alàgbà kan bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀. Jẹ́ kí ẹnì kan tí kò tíì pẹ́ tó di akéde ṣe àṣefihàn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tó múra sílẹ̀ dáadáa. Kí ó gbé e ka Ilé Ìṣọ́, November 15, nípa lílo àbá tó wà nínú “Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn.”
Orin 191 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 19
Orin 172
8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
22 min: Dènà Àwọn Àṣà Àtọwọ́dọ́wọ́ Tí Kò Wu Ọlọ́run! Àsọyé tí alàgbà kan sọ tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà August 15, 1995, ojú ìwé 28 sí 30. Mẹ́nu kan àwọn àṣà tí kò wu Ọlọ́run tó wọ́pọ̀ ní àgbègbè yín. Lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó bá a mu láti ṣàlàyé ìdí tí wọn kò fi yẹ fún àwọn Kristẹni.
Orin 195 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 26
Orin 177
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù November sílẹ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà nínú “Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn,” ṣe àṣefihàn méjì tí a múra sílẹ̀ dáadáa nípa bí a ṣe lè fi ìwé ìròyìn lọni. Kí ọ̀kan lo Ilé Ìṣọ́ December 1, kí ìkejì sì lo Jí! December 8. Lẹ́yìn náà, ṣàlàyé bí a ṣe lè rí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a ó lò nígbà tí a bá ń fi ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ tàbí àwọn ìtẹ̀jáde àfidípò rẹ̀ lọni ní oṣù December. Mẹ́nu kan àpẹẹrẹ kan tàbí méjì. (Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 1994, ojú ìwé 4; June 1993, ojú ìwé 4.)
15 min: “Ibo Ni Màá Ti Rí Àyè?” Àsọyé àti ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwùjọ. Fi àwọn kókó pàtàkì kún un látinú Ilé Ìṣọ́, October 1, 2000, ojú ìwé 20 àti 21, ìpínrọ̀ 9 àti 10, lábẹ́ ìsọ̀rí náà, “Bí Àwọn Kan Ṣe Wá Àyè fún Kíkẹ́kọ̀ọ́.” Sọ pé kí àwùjọ sọ nípa àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ tí wọ́n ti gbà wá àyè fún àwọn nǹkan tó túbọ̀ ṣe pàtàkì jù nípa yíyẹra fún àwọn ìgbòkègbodò tí kò pọn dandan. Tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ láti ṣètò àkókò fún dídákẹ́kọ̀ọ́ àti fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, àwọn ìpàdé ìjọ, iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá àti Bíbélì kíkà lójoojúmọ́.
15 min: Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Yin Jèhófà. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ọ̀pọ̀ jù lọ ìjọ ni àwọn ọ̀dọ́ wà tí wọ́n ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí tọ̀nà àní bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn àgbà ni wọ́n máa ń wàásù fún lọ́pọ̀ ìgbà jù lọ. (Sm. 148:12, 13; Mát. 21:15, 16) Nígbà táwọn òbí àtàwọn akéde yòókù bá fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀dọ́, tí wọ́n ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì ń fún wọn níṣìírí, inú àwọn ọ̀dọ́ máa ń dùn láti lọ sí òde ẹ̀rí. Sọ pé kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ọ̀nà tí a lè gbà mú kí àwọn ọ̀dọ́ kópa nínú iṣẹ́ ilé dé ilé àti ìpadàbẹ̀wò. Sọ pé kí àwọn òbí sọ ohun tí wọ́n ti ṣe láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn lọni, bí wọ́n ṣe lè lo Bíbélì nínú àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn àti bí wọ́n ṣe lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ lẹ́nu ọ̀nà. Tẹnu mọ́ àwọn àǹfààní tó wà nínú gbígbóríyìn fún àwọn ọmọ. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀dọ́ akéde kan tàbí méjì lẹ́nu wò kí o sì jẹ́ kí wọ́n sọ ohun tí wọ́n ń gbádùn nínú iṣẹ́ ìwàásù àti ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.
Orin 198 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 3
Orin 179
8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
17 min: Onírúurú Apá Tó Wà Nínú Ìwé Reasoning. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ṣàyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ tó tẹ̀ lé e yìí nípa bí onírúurú apá tó wà nínú ìwé náà ṣe wúlò gan-an láti fi ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì: Ìtumọ̀, irú bí ìtumọ̀ “Kingdom” [Ìjọba] (ojú ìwé 225 àti 226) tàbí “spirit” [ẹ̀mí] (ojú ìwé 380); àwọn ìfiwéra látinú onírúurú àwọn ìtumọ̀ tó ń fi àwọn ibi tí a ti lo orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì hàn àti bí a ṣe lò ó (ojú ìwé 191 sí 193) tàbí ohun tí hẹ́ẹ̀lì jẹ́ gan-an (ojú ìwé 169 àti 170); ìtòlẹ́sẹẹsẹ, kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn ohun tá a gbà gbọ́ tó mú ká yàtọ̀ sí àwọn ìsìn yòókù (ojú ìwé 199 sí 201) tàbí fífi bí èèyàn ṣe lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀ hàn (ojú ìwé 328 sí 330); ìtàn, tó fi ibi tí Kérésìmesì ti bẹ̀rẹ̀ hàn (ojú ìwé 176 sí 178) tàbí bí àwọn Kristẹni ìgbàanì kò ṣe dá sí tọ̀tún tòsì (ojú ìwé 273 sí 275); ẹ̀rí sáyẹ́ǹsì tó ń ti ìtàn ìṣẹ̀dá lẹ́yìn (ojú ìwé 85 àti 86) tàbí fífi ewu tó wà nínú lílo màríjúánà àti tábà hàn (ojú ìwé 108 sí 111). Fún àwọn akéde níṣìírí pé kí wọ́n máa lo ìwé àtàtà yìí tó ń ranni lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nígbàkigbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀ lóde ẹ̀rí.
20 min: “Àwọn Ìbùkún Tó Ń Wá Látinú Fífi Ìmọrírì Hàn fún Ìfẹ́ Tí Jèhófà Ní sí Wa, Apá Kìíní.”b Nígbà tí o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3 sí 6, sọ pé kí àwùjọ sọ àwọn ìrírí tó ń fúnni níṣìírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń wàásù láti ilé dé ilé, nígbà tí wọ́n ń jẹ́rìí ní òpópónà àti nígbà tí wọ́n ń ṣe ìpadàbẹ̀wò tí wọ́n sì ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Orin 200 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.