Aláàbọ̀ Ara Ni Wọ́n—Síbẹ̀ Wọ́n Ń Ṣàṣeyọrí
1 Bí o bá jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ aláàbọ̀ ara, ó ṣì lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó láṣeyọrí. Ká sọ tòótọ́, ipò tó o wà lè fún ọ láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti wàásù àti láti gba àwọn ẹlòmíràn níyànjú.
2 Àǹfààní Láti Wàásù: Ọ̀pọ̀ àwọn aláàbọ̀ ara ló ń kó ipa kíkún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tí iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ṣe fún un ò jẹ́ kó lè rìn dáadáa, tí ò sì jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀ dáadáa, rí i pé òun lè máa fi ìwé ìròyìn sóde bí baálé rẹ̀ bá gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbà kọjá. Lọ́jọ́ kan, ó fi ọgọ́rin ìwé ìròyìn síta láàárín wákàtí méjì péré! Ipò tó o wà lè mú kí o bá àwọn tí a ò kì í tètè rí pàdé. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kà á sí pé ìpínlẹ̀ pàtàkì ni wọ́n jẹ́ fún ọ láti wàásù.
3 Ìwàásù rẹ lè wọ àwọn èèyàn lọ́kàn gan-an! Bí àwọn mìíràn ṣe ń rí i pé o ò juwọ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì rí bí òtítọ́ Bíbélì ṣe ṣàǹfààní fún ọ, ó lè mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ìjọba náà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, nígbà tó o bá bá àwọn èèyàn tó wà nínú ìṣòro pàdé, ìrírí rẹ ní ìgbésí ayé lè mú kó ṣeé ṣe fún ọ láti lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti tù wọ́n nínú.—2 Kọ́r. 1:4.
4 O Lè Fún Àwọn Ẹlòmíràn Lókun: Ǹjẹ́ ìtàn ìgbésí ayé Laurel Nisbet kì í jẹ́ ìṣírí fún ọ, ẹni tó jẹ́ pé ẹ̀rọ ló fi ń mí fún ọdún mẹ́tàdínlógójì, síbẹ̀ tó ran èèyàn mẹ́tàdínlógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ Bíbélì? Lọ́nà kan náà, àpẹẹrẹ rẹ lè jẹ́ ìṣírí fún àwọn onígbàgbọ́ bíi tìrẹ láti máa sa gbogbo ipá wọn nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.—g93-YR 1/22 ojú ìwé 18 sí 21.
5 Bí ipò rẹ ò bá tiẹ̀ jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ láti máa jáde òde ẹ̀rí bó o ṣe fẹ́, ó ṣì lè fún àwọn ẹlòmíràn lókun. Arákùnrin kan sọ pé: “Mo ti wá mọ̀ pé ìrànlọ́wọ́ kékeré kọ́ lẹni ti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aláàbọ̀ ara tó burú gan-an lè ṣe fáwọn míì. Igi lẹ́yìn ọgbà lèmi àti ìyàwó mi jẹ́ fún onírúurú àwọn èèyàn nínú ìjọ. Nítorí ipò tá a wà, ibí la máa ń wà nígbà gbogbo, kò sí pé wọ́n débi wọn ò bá wa.” Àmọ́, nítorí ipò rẹ gẹ́gẹ́ bí aláàbọ̀ ara, a mọ̀ pé ó lè má ṣeé ṣe fún ọ láti máa ṣe tó bó o ṣe fẹ́. Síbẹ̀síbẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ẹlòmíràn, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti máa kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Nítorí náà, tó o bá fẹ́ ìrànlọ́wọ́, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti sọ fáwọn alàgbà tàbí àwọn mìíràn tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ nínú ìjọ.
6 Jèhófà rí gbogbo ohun tó ò ń ṣe láti sìn ín, ìjọsìn tó ò ń fi gbogbo ọkàn rẹ ṣe sì ń múnú rẹ̀ dùn. (Sm. 139:1-4) Bó ṣe jẹ́ pé òun lo gbára lé, ó lè fún ọ lágbára láti lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó láṣeyọrí, tó sì nítumọ̀.—2 Kọ́r. 12:7-10.