ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/03 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 8
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 15
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 22
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 29
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 6
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 9/03 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

ÀKÍYÈSÍ: Ní ìgbà àpéjọ àgbègbè, a ó ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Kí àwọn ìjọ ṣe ìyípadà tó bá yẹ kó lè yọ àyè sílẹ̀ láti lọ sí Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ Fi Ògo fún Ọlọ́run.” Níbi tó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀, kí ẹ lo ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún láti fi ṣàtúnsọ àwọn ìmọ̀ràn pàtàkì tó bá ìjọ yín mu lára ìmọ̀ràn inú àkìbọnú ti oṣù yìí ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí ẹ ó ṣe kẹ́yìn kí ẹ tó lọ sí àpéjọ náà. Ní oṣù February 2004, a ó ṣètò odindi Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn kan láti fi ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì inú àpéjọ náà. Láti múra sílẹ̀ fún àtúnyẹ̀wò yẹn, gbogbo wa lè ṣàkọsílẹ̀ àwọn kókó tó ṣe pàtàkì ní àpéjọ títí kan àwọn kókó pàtó kan tí àwa fúnra wa fẹ́ fi sílò nínú ìgbésí ayé wa àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. A ó lè wá gba àwọn mìíràn níyànjú nípa ṣíṣàlàyé ọ̀nà tí a ti gbà fi àwọn ìmọ̀ràn wọ̀nyẹn sílò látìgbà tá a ti dé láti àpéjọ náà.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 8

Orin 10

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tí a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 láti fi ṣe àṣefihàn kan tó ṣeé lò tó dá lórí bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ September 15 lọni. Nínú àṣefihàn náà, kí ọmọ iléèwé tàbí òbí kan wàásù fún olùkọ́ kan.

10 min: Lẹ́tà Láti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì. Ìjíròrò láàárín akéde kan tó ti pẹ́ nínú ètò àti ọ̀dọ́ akéde kan. Á dára kí akéde tó ti pẹ́ náà jẹ́ alàgbà. Ọ̀dọ́ akéde náà béèrè lọ́wọ́ akéde tó ti pẹ́ yìí bóyá ó rí lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ, tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Akéde tó ti pẹ́ náà sọ pé irú lẹ́tà bẹ́ẹ̀ máa ń jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa láti ọdún 1964 títí di 1979. Wọ́n wá jọ jíròrò lẹ́tà tó wà ní ojú ìwé àkọ́kọ́, wọ́n sì mẹ́nu kan àwọn kókó inú rẹ̀.

25 min: “Ẹ̀yin Ọ̀dọ́—Ẹ Fi Ìpìlẹ̀ Tí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀ Lélẹ̀ De Ẹ̀yìn Ọ̀la.” aKí alàgbà bójú tó o, kí ó sì lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ lórí ìpínrọ̀ 5, kí ó mẹ́nu ba ayọ̀ àti ìbùkún tí ń bẹ nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.

Orin 170 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 15

Orin 199

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìlàjì oṣù September sílẹ̀. Ìròyìn ìnáwó.

15 min: “A Péjọ Pọ̀ Láti Yin Jèhófà Lógo.”b Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Rọ àwùjọ láti wà níbẹ̀ jálẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà láti àárọ̀ Friday títí dé ọ̀sán Sunday. Tẹnu mọ́ ọ̀n pé ó ṣe pàtàkì láti fi àwọn ohun tá a kọ́ sílò, ká má kàn gbọ́rọ̀ lásán. Sọ̀rọ̀ nípa àkíyèsí tó wà lókè yìí, tó dá lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún ọ̀sẹ̀ kan ní February 2004, nígbà tá a máa ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn kókó ọ̀rọ̀ àpéjọ àgbègbè. Gba àwùjọ níyànjú láti ṣe àkọsílẹ̀.

20 min: “Ẹ Fi Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Wọ Ara Yín Láṣọ.”c Ní kí àwùjọ sọ bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà ṣe bá kókó tí ẹ̀ ń sọ mu.

Orin 58 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 22

Orin 7

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 láti fi ṣe àṣefihàn méjì tó dá lórí bí a óò ṣe fi Ilé Ìsọ̀ October 1 àti Jí! October 8 lọni.

10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí Lọ́dún Tó Kọjá? Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn mẹ́nu kan àwọn kókó pàtàkì látinú ìròyìn ìjọ fún ọdún iṣẹ́ ìsìn 2003. Yin ìjọ fún iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ṣe.

10 min: “Gbé Àwọn Góńgó Tí Wàá Lépa ní Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn Tuntun Kalẹ̀.”d Láti lè mọ bí a ṣe tẹ̀ síwájú sí, o lè béèrè bóyá àwọn kan wà tó ṣẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dáhùn nípàdé, bóyá àwọn kan wà tó ṣẹ̀sẹ̀ ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bóyá àwọn kan wà tó ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún ìgbà àkọ́kọ́ tàbí àwọn kan wà tó di aṣáájú ọ̀nà déédéé ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá.

15 min: “Jẹ́ Àpẹẹrẹ Nínú Ṣíṣe Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà.”e Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Tẹnu mọ́ ọ̀n pé ó yẹ ká kọ́wọ́ ti ètò ilé gbígbé tá a ṣe fún àǹfààní wa. Ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì kí olúkúlùkù wa hùwà ọmọlúwàbí.

Orin 30 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 29

Orin 194

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìparí oṣù September sílẹ̀. Sọ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní oṣù October.

10 min: “A Óò Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run.” Ọ̀rọ̀ tí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ yóò sọ. Pàfiyèsí àwọn ará sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún ìkẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó o bá ń ṣàlàyé ìpínrọ̀ kẹrin, fi àlàyé tó wà nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ewé 28, ìpínrọ̀ 1 àti ojú ewé 70 kún un.

15 min: “Aláàbọ̀ Ara Ni Wọ́n—Síbẹ̀ Wọ́n Ń Ṣàṣeyọrí.”f Fi àlàyé nípa bí àwọn mìíràn ṣe lè ṣèrànwọ́ kún un, kí o gbé àlàyé rẹ ka ìsọfúnni tó wà nínú Jí! February 22, 1991, ojú ìwé 22 àti 23, lábẹ́ ìsọ̀rí náà “Ki Ni A Le Ṣe?”

15 min: “Aṣọ Tí Ó Wà Létòlétò Ń Fi Hàn Pé A Bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run.”g Alàgbà ni kó bójú tó apá yìí. Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Ṣètò pé kí arákùnrin kan tó mọ̀wéé kà dáadáa ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan jáde ketekete.

Orin 132 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 6

Orin 170

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ní oṣù yìí, a fẹ́ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Sọ̀rọ̀ ṣókí lórí ìsọfúnni tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 2002, ojú ìwé 1, ìpínrọ̀ 1.

15 min: “Rí i Dájú Pé O Fi Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù Ṣáájú!” Àsọyé àti ìjíròrò tí a gbé ka àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ September 1, 1998, ojú ìwé 19 sí 21. Sọ àwọn ọjọ́ tí ìgbòkègbodò tẹ̀mí tó ń bọ̀ láwọn oṣù bíi mélòó kan níwájú yóò bọ́ sí, kí o sì gba àwùjọ níyànjú láti sàmì sí àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn lórí kàlẹ́ńdà tirẹ̀. Ní kí àwùjọ sọ ohun tí wọ́n máa ń ṣe láti rí i pé àwọn ò pàdánù àwọn ìpèsè tẹ̀mí kankan.

20 min: Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ fún Ẹ̀mí Ṣé-Ohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu alàgbà kan tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tá a tọ́ dàgbà nínú agbo ilé Kristẹni. Tọ́ka sí àwọn kókó bíi mélòó kan látinú Ilé Ìṣọ́ February 15, 2003. Kí làwọn ìṣòro tí arákùnrin náà dojú kọ níléèwé? (ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 3; ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 4 àti 5) Ǹjẹ́ ìwà táwọn mìíràn ń hù ní ipa tí kò dára lórí rẹ̀? (ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 4 sí 6) Ní báyìí tó ti dàgbà, ǹjẹ́ ó sì ní ìṣòro yìí? Kí ni ohun tó ràn án lọ́wọ́ láti má ṣe juwọ́ sílẹ̀ fún ẹ̀mí yìí? Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, sọ̀rọ̀ ṣókí lórí àwọn àǹfààní tó wà nínú bíbá èèyàn rere kẹ́gbẹ́, kí o gbé èyí ka Ilé Ìṣọ́ August 1, 1999, ojú ìwé 24 àti 25.

Orin 26 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

f Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

g Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́