Ẹ Fi Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Wọ Ara Yín Láṣọ
1 Ọ̀dọ́mọkùnrin olùṣọ́ àgùntàn kan gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì ṣẹ́gun jagunjagun alágbára kan. (1 Sám. 17:45-47) Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan fi sùúrù fara da àjálù. (Jóòbù 1:20-22; 2:9, 10) Ọmọ Ọlọ́run fi yé àwọn èèyàn pé ọ̀dọ́ Bàbá òun lòun ti gba ẹ̀kọ́ tóun fi ń kọ́ni. (Jòh. 7:15-18; 8:28) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kó ipa pàtàkì nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àpẹẹrẹ tá a mẹ́nu kàn wọ̀nyí. Bákan náà lónìí, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe kókó lójú onírúurú ipò tá à ń dojú kọ.—Kól. 3:12.
2 Nígbà Tí A Bá Ń Wàásù: Àwa Kristẹni òjíṣẹ́ ń fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún onírúurú èèyàn, a ò gbà pé àwọn kan wà tí kò yẹ ká wàásù fún nítorí ẹ̀yà, àṣà ìbílẹ̀ tí wọ́n ti wá tàbí irú ẹni tí wọ́n jẹ́. (1 Kọ́r. 9:22, 23) Bí àwọn kan bá hùwà àìlọ́wọ̀ sí wa tàbí tí ìgbéraga mú kí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ Ìjọba náà sílẹ̀, a kì í fìyẹn ṣèwà hù sí wọn, àmọ́ ńṣe là ń fi sùúrù bá iṣẹ́ wíwá àwọn ẹni yíyẹ rí nìṣó. (Mát. 10:11, 14) Dípò tí a óò fi gbìyànjú láti máa fi ìmọ̀ wa tàbí bí a ṣe mọ̀wé sí gbayì lójú àwọn èèyàn, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run la máa ń pàfiyèsí wọn sí, nítorí a mọ̀ pé ó máa ń yíni lérò padà ju ọ̀rọ̀ yòówù tá a lè sọ lọ. (1 Kọ́r. 2:1-5; Héb. 4:12) À ń fi ìyìn gbogbo àṣeyọrí wa fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe.—Máàkù 10:17, 18.
3 Nínú Ìjọ: Ó yẹ kí àwọn Kristẹni ‘fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara wọn lámùrè sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì’ pẹ̀lú. (1 Pét. 5:5) Bí a bá gbà pé àwọn mìíràn lọ́lá jù wá lọ, àwọn ọ̀nà tá ó máa gbà sin àwọn ará wa la ó máa wá dípò tí a óò fi máa retí pé kí wọ́n sìn wá. (Jòh. 13:12-17; Fílí. 2:3, 4) A ò ní máa ronú pé a ti kọjá ẹni tí yóò máa ṣe irú àwọn iṣẹ́ kan, bíi iṣẹ́ ìmọ́tótó Gbọ̀ngàn Ìjọba.
4 Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ń mú kí á máa ‘fara dà á fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì,’ èyí sì máa mú kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ìjọ. (Éfé. 4:1-3) Ó ń mú ká lè tẹrí ba fún àwọn tá a yàn láti mú ipò iwájú. (Héb. 13:17) Ó ń mú ká lè tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn tàbí ìbáwí tí wọ́n bá fún wa. (Sm. 141:5) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tún ń mú ká gbọ́kàn lé Jèhófà nígbà tí a bá ń ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tá a bá yàn fún wa nínú ìjọ. (1 Pét. 4:11) Gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ti ṣe, àwa náà gbà pé ìbùkún Ọlọ́run ló lè jẹ́ ká ṣàṣeyọrí, kì í ṣe mímọ̀ ọ́n ṣe wa.—1 Sám. 17:37.
5 Níwájú Ọlọ́run Wa: Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, ó yẹ ká ‘rẹ ara wa sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọ́run.’ (1 Pét. 5:6) Bí a bá wà nínú ìṣòro, o lè máa ṣe wá bíi pé kí Ìjọba Ọlọ́run tètè mú ìtura wá. Àmọ́, à ń fi ìrẹ̀lẹ̀ mú sùúrù, à ń dúró kí Jèhófà mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ ní àkókò tirẹ̀. (Ják. 5:7-11) Bíi ti Jóòbù olùpa ìwà títọ́ mọ́, ohun tó jẹ àwa náà lógún jù lọ ni pé kí “orúkọ Jèhófà máa bá a lọ láti jẹ́ èyí tí a bù kún fún.”—Jóòbù 1:21.
6 Wòlíì Dáníẹ́lì ‘rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run rẹ̀,’ ó tipa bẹ́ẹ̀ rí ojú rere Jèhófà, ó sì tún ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn mìíràn. (Dán. 10:11, 12) Ǹjẹ́ kí àwa náà fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ wọ ara wa láṣọ, ká mọ̀ pé “ìyọrísí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.”—Òwe 22:4.