ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/03 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 10
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 17
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 24
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 1
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 11/03 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 10

Orin 212

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ àtàwọn Ìfilọ̀ tí a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Nípa lílo àbá tó wà ní ojú ìwé 4, ṣe àṣefihàn kan tó bá ipò àdúgbò mu nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ November 15 lọni ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín. Nínú àṣefihàn náà, ṣàlàyé bí a ṣe ń rí owó láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ kárí ayé tí à ń ṣe.—Wo ojú ìwé 2 nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tàbí ojú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn Jí!

15 min: “Ẹ Wà ní Ìmúratán.”a Jẹ́ kí àwọn ará sọ ohun tí wọ́n ń ṣe tí àwọn àníyàn àti ìpínyà ọkàn ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí kì í fi í gba àkókò tó yẹ kí wọ́n lò láti lépa àwọn nǹkan tẹ̀mí.

20 min: Àwọn Wo Lò Ń Bá Kẹ́gbẹ́? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí a gbé ka ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run, ojú ìwé 47 sí 49. Nípa lílo àwọn ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a fà yọ ní ìpínrọ̀ 13, jẹ́ kí àwùjọ ṣàlàyé àwọn ìlànà Bíbélì tó yẹ kó darí wa bí a bá fẹ́ yan àwọn tí a óò bá kẹ́gbẹ́.

Orin 127 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 17

Orin 96

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìlàjì oṣù November sílẹ̀. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde méjì tàbí mẹ́ta tí wọ́n ní ìrírí alárinrin nínú iṣẹ́ ìsìn pápá nígbà tí wọ́n ń lo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a fi ń lọni lóṣù yìí. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan ti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

15 min: Ní Ẹ̀mí Fífúnni Ní Nǹkan. Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí tí a gbé ka ìsọfúnni tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 2003, ojú ìwé 27 sí 30.

18 min: “Gbígbóríyìn Fúnni Ń Mára Tuni.”b Fi àlàyé tó wà nínú ìwé Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 49 sí 50, ìpínrọ̀ 21, kún un. Ní kí àwọn kan tí wọ́n rí ìṣírí gbà látinú ọ̀rọ̀ ìgbóríyìn táwọn ẹlòmíràn sọ fún wọn ṣe àlàyé ṣókí.

Orin 58 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 24

Orin 213

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 4, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ December 1 àti Jí! December 8 lọni. A lè lo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó yàtọ̀ sí èyí tí a dábàá rẹ̀ lójú ìwé 4. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ lé lórí. Nínú ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi ìwé ìròyìn lọni láìjẹ́ bí àṣà nígbà tí a bá wà nínú ọkọ̀ tàbí lọ́nà mìíràn tó bá ipò àdúgbò mu.

10 min: Àpótí Ìbéèrè. Àsọyé tí alàgbà kan yóò sọ.

23 min: “Bí A Ṣe Lè Wà ní Ìbárẹ́ Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Jèhófà.”c Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Kí àwùjọ lóhùn sí i nípa ṣíṣàlàyé bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ náà ṣe bá kókó tí à ń jíròrò mu. Ṣètò ṣáájú pé kí akéde kan tàbí méjì sọ ohun tó ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú kí ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn sunwọ̀n sí i.

Orin 202 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 1

Orin 138

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìparí oṣù November sílẹ̀. Sọ ìwé tí a ó fi lọni ní oṣù December. Ní ṣókí, ṣàyẹ̀wò ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ kan tàbí méjì tá a dámọ̀ràn. Ṣàlàyé bí àwùjọ ṣe lè lo ìwé Watch Tower Publications Index láti ṣàwárí àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ mìíràn.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: Títóótun Tẹ́rùntẹ́rùn Láti Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́ June 1, 2000, ojú ìwé 16 sí 17, ìpínrọ̀ 9 sí 13. Ọ̀kan pàtàkì ni kíkọ́ni lọ́nà tó gbéṣẹ́ jẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Mímọ bí a ṣe lè sọ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà lọ́nà táwọn èèyàn á fi rí ẹ̀kọ́ kọ́ tí a ó sì sún wọn ṣiṣẹ́ ni yóò mú ká lè ran àwọn ẹni bí àgùntàn lọ́wọ́. Jíròrò àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: (1) Kí ni ìyàtọ̀ tó wà nínú wíwàásù àti kíkọ́ni? (2) Kí ló fà á tí àwọn kan fi ń lọ́ tìkọ̀ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (3) Báwo la ṣe lè mú kí ọ̀nà ìgbàkọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ wa sunwọ̀n sí i? (4) Báwo la ṣe lè rí i dájú pé ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ń lóye ohun tó ń kọ́? (5) Góńgó wo ló yẹ ká ran ẹni tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti lé bá?

Orin 70 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́