Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 8
Orin 221
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tí a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ December 15 àti Jí! January 8 lọni. Lo àbá àkọ́kọ́ tó wà ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! January 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan ṣoṣo la óò sọ̀rọ̀ lé lórí.
20 min: “Wíwà ní Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Nínú Lílo Ìmọ̀ Iṣẹ́ Ẹ̀rọ Kọ̀ǹpútà.”a Àkìbọnú. Ka àwọn ìpínrọ̀ tó ṣe kókó, irú bí ìpínrọ̀ 4 sí 8 àti ìpínrọ̀ 12 àti 13, bí àkókò bá ṣe wà sí. Ní àfirọ́pò, ẹ lè ṣàgbéyẹ̀wò àwọn nǹkan mìíràn tó máa ń wáyé lágbègbè yín, èyí tó máa ń gba àkókò tó sì ṣeé ṣe kó léwu nínú.
15 min: “Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ti Ọdún 2004.” Àsọyé tí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò bójú tó. Fi àlàyé kún un látinú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 2003.
Orin 108 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 15
Orin 71
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìlàjì oṣù December sílẹ̀. Fún gbogbo àwọn ará níṣìírí láti wo fídíò náà, Transfusion-Alternative Health Care—Meeting Patient Needs and Rights ní ìmúrasílẹ̀ fún ìjíròrò tí yóò wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ní ọ̀sẹ̀ December 29. Jíròrò àpótí náà, “Jọ̀wọ́ Tètè Lọ.” Bí fọ́ọ̀mù S-70 bá wà, fi ọ̀kan han àwùjọ. Sọ àwọn ètò tó wà fún ìjẹ́rìí àkànṣe ní December 25 àti January 1.
15 min: Ìdákẹ́kọ̀ọ́ Jẹ́ Apá Kan Ìjọsìn. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ October 1, 2000, ojú ìwé 14 àti 15, ìpínrọ̀ 6 sí 10.
20 min: “Ran Àwọn Tó Ní ‘Ìtẹ̀sí-Ọkàn Títọ́’ Lọ́wọ́.’”b Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àbá fún ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò nínú àpótí tó wà ní ojú ìwé 3 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1997.
Orin 42 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 22
Orin 10
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Nípa lílo àbá tó wà ní ojú ìwé 8, ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ January 1 lọni. Lo àbá kejì tó wà ní ojú ìwé 8 láti fi Jí! January 8 lọni. Rán gbogbo àwọn ará létí nípa àkànṣe Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀, nígbà tá a máa ṣe àgbéyẹ̀wò fídíò Patient Needs and Rights, tí a ó sì jíròrò nípa káàdì Advance Medical Directive/Release tí a óò sì tún pín wọn.
10 min: “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká Tuntun.” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Sọ déètì àpéjọ àyíká yín tó ń bọ̀. Bó bá jẹ́ pé oṣù díẹ̀ ló kù kí ìjọ yín lọ sí àpéjọ àyíká, sọ pé kí àwọn tó fẹ́ láti ṣèrìbọmi sọ fún alábòójútó olùṣalága. Rọ gbogbo àwọn ará láti sapá gidigidi láti ké sí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn wá, kí gbogbo wọn sì wà níbẹ̀ jálẹ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.
20 min: “Wíwá Àwọn Ẹni Yíyẹ Rí.”c Ṣàlàyé bí a ṣe lè fi ìsọfúnni náà sílò ní ìpínlẹ̀ ìjọ. Ìgbà wo ló ṣeé ṣe jù pé kí àwọn èèyàn wà nílé? Àwọn àṣeyọrí wo la ti ṣe nípa ṣíṣiṣẹ́ lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́? Kí ni àwọn nǹkan tá a lè ṣe kí a lè rí àwọn èèyàn tí kì í fi bẹ́ẹ̀ sí nílé?
Orin 209 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 29
Orin 200
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti ìparí oṣù December sílẹ̀. Sọ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni lóṣù January.
17 min: “Fídíò Tó Sọ Nípa Ohun Pàtàkì Kan Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Lágbo Àwọn Onímọ̀ Ìṣègùn.” Alàgbà tó tóótun ni kó bójú tó o. Ka Ìṣe 15:28, 29, ní ṣókí kí o wá tẹnu mọ́ ọn pé ìdí pàtàkì tí àwa Kristẹni kì í fi í gba ẹ̀jẹ̀ sára ni pé a fẹ́ láti bọ̀wọ̀ fún òfin Ọlọ́run lórí ìjẹ́mímọ́ ẹ̀jẹ̀. Lẹ́yìn náà, bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò fídíò Patient Needs and Rights pẹ̀lú àwùjọ láìjáfara nípa lílo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà. Kádìí ìjíròrò yìí nípa kíka ìpínrọ̀ tó kẹ́yìn. Ní àfirọ́pò, kí a sọ àsọyé tí a gbé ka “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ June 15 àti October 15, 2000.
23 min: Fífi Ìgboyà Kojú Ìṣòro Ọ̀ràn Ìṣègùn. Àsọyé tí alàgbà tó tóótún yóò sọ nípa lílo ìwé àsọyé tí ẹ̀ka iléeṣẹ́ pèsè. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì látinú àpótí náà, “Àwọn Ìpèsè Tó Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Yẹra fún Ẹ̀jẹ̀.”
Orin 182 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 5
Orin 103
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: Òpò Yín Kì Í Ṣe Asán. (1 Kọ́r. 15:58) Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ṣètò ṣáájú láti fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn akéde tí wọ́n ti ń bá iṣẹ́ ìwàásù bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún láti sọ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ bí iṣẹ́ náà ṣe rí nígbà náà lọ́hùn-ún. Àwọn mélòó ló ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ nígbà náà? Báwo ni ìpínlẹ̀ tí wọ́n yàn fún ìjọ ṣe pọ̀ tó? Ǹjẹ́ àwọn èèyàn máa ń tẹ́tí sílẹ̀ nígbà yẹn tí ẹ bá lọ wàásù ìhìn Ìjọba náà fún wọn? Irú àwọn àtakò wo ni ẹ máa ń bá pàdé? Báwo ni àṣeyọrí tó ti ń wáyé nínú iṣẹ́ Ìjọba náà bí ọdún ti ń gorí ọdún ṣe pọ̀ tó?
25 min: “Kí Ló Ń Mú Kí Ìṣọ̀kan Tòótọ́ Láàárín Àwọn Kristẹni Ṣeé Ṣe?”d Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 5, ké sí àwùjọ láti sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní láwọn àpéjọ àgbáyé, nígbà tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé tó jẹ́ ti ètò àjọ náà tàbí iṣẹ́ ìrànwọ́ lákòókò wàhálà, èyí tó fi ìṣọ̀kan Kristẹni wa hàn.
Orin 7 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ jíròrò àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.