ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/04 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 12
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 19
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 26
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 2
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 1/04 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 12

Orin 224

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù January sílẹ̀. Nípa lílo àbá tó wà ní ojú ìwé 4, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ January 15 àti Jí! February 8 lọni. Lo àbá kẹta tó wà ní ojú ìwé 4 láti fi Jí! February 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, tẹnu mọ́ díẹ̀ lára àwọn ohun dáadáa tá a lè lò nínú ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ yẹn.

15 min: “Àǹfààní Títayọ Tó Wà Nínú Ọgbọ́n Ọlọ́run.”a Bí àkókò bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí.

20 min: “Máa Ṣọ́ Bí O Ṣe Ń Lo Àkókò Rẹ Lójú Méjèèjì.”b Ní kí àwùjọ sọ ohun tí wọ́n ń ṣe tí àwọn ohun tí kò ṣe pàtàkì kì í fi í gba àkókò tó yẹ kí wọ́n lò fún àwọn nǹkan tẹ̀mí mọ́ wọn lọ́wọ́.

Orin 106 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 19

Orin 95

15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Jíròrò “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àkànṣe Tuntun.” Ṣèfilọ̀ déètì tí ẹ óò ṣe àpéjọ àkànṣe tí ń bọ̀, kí o sì rọ gbogbo àwọn ará láti wà níbẹ̀. Bó bá jẹ́ pé oṣù díẹ̀ sí i ni ẹ óò ṣe àpéjọ náà, sọ pé kí àwọn tó bá fẹ́ láti ṣèrìbọmi sọ fún alábòójútó olùṣalága.

15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

15 min: “Báwo La Ṣe Lè Ran Àwọn Ọkọ Tàbí Aya Tí Kì Í Ṣe Ẹlẹ́rìí Lọ́wọ́?”c Fọ̀rọ̀ wá ẹnì kan tàbí ẹni méjì lẹ́nu wò, ìyẹn àwọn tí wọ́n di ìránṣẹ́ Jèhófà nítorí àpẹẹrẹ rere tí ọkọ tàbí aya wọn tó kọ́kọ́ gba òtítọ́ jẹ́.

Orin 73 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 26

Orin 158

12 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù January sílẹ̀. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 4, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ February 1 àti Jí! February 8 lọni. Lo àbá kẹrin tó wà ní ojú ìwé 4 láti fi Jí! February 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, kí a fi àwọn ìwé ìròyìn méjèèjì náà lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹyọ kan ṣoṣo la ó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nínú ọ̀kan lára àwọn ìgbékalẹ̀ náà, ṣàṣefihàn bí o ṣe lè fi ìwé ìròyìn lọ ẹnì kan tó ń gbé ládùúgbò rẹ.

15 min:  Fara Wé Pọ́ọ̀lù Gẹ́gẹ́ Bí Ó Ṣe Fara Wé Kristi. (1 Kọ́r. 11:1) Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Pọ́ọ̀lù ṣe bíi ti Jésù, ó lo àǹfààní tó ní láti wàásù fún “àwọn tí ó wà ní àrọ́wọ́tó.” (Ìṣe 17:17) Àǹfààní wo làwa náà ní láti ṣe ìyẹn ní ìpínlẹ̀ wa? Àwọn wo ló “wà ní àrọ́wọ́tó” níbi tá a ti lọ rajà, níbi iṣẹ́ tàbí ní ilé ìwé, tàbí nínú ọkọ̀ èrò? Àwọn wo la máa ń rí nígbà tá a bá wà nílé? Ní kí àwùjọ sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ti ní nígbà tí wọ́n ń wàásù fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ń bá pàdé nínú ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́.

18 min: Bí A Ṣe Lè Fi Àwọn Onígbàgbọ́ Ẹlẹgbẹ́ Wa Ṣọ̀rẹ́. (Òwe 18:24; 27:9) Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ, tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́, December 1, 2000, ojú ìwé 22 àti 23. Ọ̀kan lára àwọn ìbùkún tá à ń rí nínú ìjọsìn tòótọ́ ni pé ó ń fún wa láǹfààní láti yan àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́. Ìfararora tá a máa ń ní nígbà ìpàdé, lóde ẹ̀rí, àti láwọn ìgbà mìíràn jẹ́ orísun ìṣírí tó pọ̀ gan-an. Báwo la ṣe lè fi àwọn ẹlòmíràn ṣọ̀rẹ́ nínú ìjọ? Gbé ọ̀rọ̀ inú àpótí náà, “Ohun Mẹ́fà Tó Ń Ranni Lọ́wọ́ Láti Dọ́rẹ̀ẹ́ Tó Máa Wà Pẹ́ Títí” yẹ̀ wò, kí o sì ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí bí a ṣe lè fi kókó kọ̀ọ̀kan sílò nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ará.

Orin 177 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 2

Orin 204

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Mẹ́nu kan ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù February. Gbé “Àbá Nípa Bí A Ṣe Lè Fi Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà Lọni” yẹ̀ wò.

20 min: Àwọn Ìtẹ̀jáde Tuntun Tó Tẹ̀ Wá Lọ́wọ́ Mà Dùn Mọ́ Wa O! Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Inú wa dùn láti gba ìwé méjì tá a mú jáde ní Àpéjọ Agbègbè “Ẹ Fi Ògo Fún Ọlọ́run.” Ìwé Wo “Ilẹ̀ Dáradára” Náà yàtọ̀ pátápátá láàárín àwọn ìwé wa yòókù tó dá lórí Bíbélì. Nínú àwọn àwòrán tó gba ojú ewé méjì nínú ìwé náà, wàá rí onírúurú àwòrán nípa bí Ilẹ̀ Ìlérí náà ṣe rí gan-an. Sọ díẹ̀ lára kúlẹ̀kúlẹ̀ inú onírúurú àwọn àwòrán ilẹ̀ tó wà nínú ìwé náà. Dábàá àwọn ọ̀nà tó dáa tá a lè gbà lo ìwé yìí. Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà yóò fún àwọn ọmọ wa lókun nípa tẹ̀mí. Mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ tó bóde mu tó wà nínú ìwé náà, kí o sì fi hàn bí àwọn òbí àti àwọn ọmọ kéékèèké ṣe lè jàǹfààní nínú ìwé náà. Ní kí àwùjọ sọ àwọn ọ̀nà dáadáa tí wọ́n gbà ń lo àwọn ìwé tuntun yìí.

15 min: Máa Fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Sílò Nínú Gbogbo Ohun Tó O Bá Ń Ṣe Lójoojúmọ́. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Gba gbogbo àwọn tó wà láwùjọ níyànjú pé kí wọ́n máa lo ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́—2004. Sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìṣáájú tó wà ní ojú ìwé 3 àti 4. Ní kí àwùjọ sọ àkókò tí wọ́n rí pé ó dára jù fáwọn láti máa ka ẹsẹ ojoojúmọ́. Jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tòní àti àlàyé rẹ̀ pẹ̀lú àwùjọ. Sọ pé kí àwùjọ ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè fi ìsọfúnni tó wà nínú àlàyé yẹn sílò. Gba àwọn ará níyànjú pé nígbà tí wọ́n bá ń jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n máa ronú lórí báwọn yóò ṣe fi nǹkan tí wọ́n bá kọ́ sílò.

Orin 150 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò àpilẹ̀kọ náà pẹ̀lú àwùjọ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́