Báwo La Ṣe Lè Ran Àwọn Ọkọ Tàbí Aya Tí Kì Í Ṣe Ẹlẹ́rìí Lọ́wọ́?
1 Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ni wọ́n fẹ́ ẹni tí ìwà rẹ̀ dára sáwọn ará, tó sì nífẹ̀ẹ́ ìjọ àmọ́ tí ò fẹ́ di ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Ọkọ arábìnrin wa kan sọ pé: “Èrò ti lílọ láti ilé-dé-ilé jẹ́ ohun ìdínà ńláǹlà fún mi.” Àwọn mìíràn lè ní àwọn ìwà kan tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tí wọ́n ń hù tó yẹ kí wọ́n jáwọ́ nínú rẹ̀, tàbí kí wọ́n máa rò pé àwọn ò lè ráyè máa kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ìgbòkègbodò tẹ̀mí. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́?
2 Fi Ìfẹ́ Hàn sí Wọn: Tá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn tá a sì ń kíyè sí àwọn nǹkan tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn, èyí lè mú kí wọ́n tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì. (Fílí. 2:4) Àwọn tí kì í ṣe ẹ̀sìn kan náà pẹ̀lú ọkọ tàbí aya wọn tẹ́lẹ̀ sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn fi hàn sáwọn kí wọ́n tó di Ẹlẹ́rìí. Ọkọ arábìnrin wa tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lókè yẹn sọ pé: “José, alàgbà kan nínú ìjọ, ní ọkàn-ìfẹ́ àkànṣe sí mi. Mo lérò pé ìṣírí rẹ̀ ni ó pàpà jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ dáradára.” Ọkọ arábìnrin wa mìíràn sọ pé àwọn arákùnrin tó máa ń wá òun wá máa ń gbìyànjú láti bá òun sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí òun nífẹ̀ẹ́ sí. Ó sọ pé: “Mo wá bẹ̀rẹ̀ síí rí ìgbàgbọ́ [ìyàwó mi] láti inú ojú-ìwòye tí ó yàtọ̀ pátá. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ jẹ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n gbọ́n dáradára tí wọ́n lè sọ̀rọ̀ lórí onírúurú kókó-ẹ̀kọ́.”—1 Kọ́r. 9:20-23.
3 Ṣe Ìrànlọ́wọ́ Tí Wọ́n Nílò: Tá a bá nawọ́ ìrànlọ́wọ́ sí àwọn ọkọ tàbí aya tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, ìyẹn náà tún lè nípa tó dára lórí wọn. (Òwe 3:27; Gal. 6:10) Nígbà tí mọ́tò ọkọ arábìnrin wa kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ bà jẹ́, ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan ràn án lọ́wọ́. Ọkùnrin náà sọ pé “Ó wú mi lórí gan-an ni.” Arákùnrin mìíràn fi odindi ọjọ́ kan gbáko bá ọkọ arábìnrin wa kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ ṣiṣẹ́ níbi tó ti ń ṣe ọgbà yí ilé rẹ̀ ká. Ibi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n sì ń tàkúrọ̀sọ ni wọ́n ti dọ̀rẹ́. Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn ìyẹn, ọkùnrin yìí lọ bá arákùnrin náà, ó sì sọ fún un pé: “Àkókò tó wàyí fún mi láti yí ìgbésí ayé mi padà. Jọ̀wọ́, ṣé wàá máa bá mi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Ọkùnrin yìí tẹ̀ síwájú kíákíá, ó sì ti di Ẹlẹ́rìí tó ti ṣe ìrìbọmi báyìí.
4 Bá a ṣe ń wá àwọn ẹni yíyẹ kiri ní ìpínlẹ̀ wa, ẹ jẹ́ ká máa ran àwọn tí wọ́n fẹ́ onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa lọ́wọ́ pẹ̀lú.—1 Tím. 2:1-4.