Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 13
Orin 20
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù August sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ August 15 àti Jí! July–September. (Lo àbá kẹta lójú ìwé 8 fún Jí! July–September.) Nínú ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, lo àbá tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí, lójú ìwé 3 ìpínrọ̀ 3, gẹ́gẹ́ bí ìbéèrè tó o máa dáhùn nígbà tó o bá padà lọ.
20 min: Bá A Ṣe Ń Jàǹfààní Nínú Fífi Ara Wa Sábẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, orí 15.
15 min: “Bí Ìdílé Ṣe Lè Jọ Máa Sin Jèhófà.”a Ní kí àwùjọ sọ àǹfààní tí wọ́n máa ń rí báwọn àti ìdílé wọn bá jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí. O lè ti sọ fẹ́nì kan tàbí ẹni méjì kó tó dìgbà tó o máa ṣiṣẹ́ yìí pé kí wọ́n múra sílẹ̀ láti sọ̀rọ̀.
Orin 48 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 20
Orin 100
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: “Mọrírì Ètò Tí Jèhófà Ṣe Kó O Lè Mọ̀ọ́kọ Mọ̀ọ́kà.” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á bójú tó.
10 min: Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Nígbà Tó O Bá Kọ́kọ́ Wàásù Fẹ́nì Kan Lóṣù September. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni la máa lò lóṣù September, a sì máa sapá láti rí i pé a jíròrò ìpínrọ̀ mélòó kan pẹ̀lú onílé náà nígbà àkọ́kọ́ tá a bá wàásù fún un. Jíròrò àbá tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 2006, kó o sì ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì láti jẹ́ kí àwùjọ rí bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tá a bá wàásù fáwọn èèyàn.
15 min: “Àwọn Ọ̀nà Tí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ Gbà Ń Ràn Wá Lọ́wọ́.”b Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 5, fi àlàyé kún un látinú ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 41, ìpínrọ̀ 2.
Orin 6 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 27
Orin 98
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 8 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ September 1 àti Jí! July–September. (Lo àbá kẹrin lójú ìwé 8 fún Jí! July–September.)
10 min: ‘Ẹ Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Nípasẹ̀ Ọrọ̀ Àìṣòdodo.’ Alàgbà ni kó sọ ọ́ bí àsọyé. Kó gbé e ka Ilé Ìṣọ́ December 1, 1994, ojú ìwé 13 sí 18.
25 min: “Ohun Pàtàkì Tó Yẹ Ká Fojú Sùn Lọ́dún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Ń Bọ̀ Yìí.”c Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tàbí méjì tó ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ láìpẹ́ yìí. Báwo ló ṣe tún ìgbòkègbodò rẹ̀ tò? Àǹfààní wo ni wọ́n ti rí? Bó bá wà, ó dáa tí ọ̀kan lára àwọn tó o máa fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò bá jẹ́ ẹni tó ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nítorí pé ìdílé rẹ̀ kọ́wọ́ tì í. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 9, sọ déètì tí alábòójútó àyíká máa bẹ̀ yín wò, bó o bá mọ̀ ọ́n.
Orin 196 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 3
Orin 50
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ àtàwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù August sílẹ̀.
15 min: “A Mọyì Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tá A Ní!”d Bí àkókò bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ.
20 min: “Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ sí Í Ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Àwọn Tá À Ń Fún Ní Ìwé Ìròyìn.”e Ṣe àṣefihàn ṣókí kan tó dá lórí ọ̀kan lára àwọn àbá tó wà ní ìpínrọ̀ 2. Rán àwọn akéde létí pé wọ́n lè ròyìn ìkẹ́kọ̀ọ́ kan gẹ́gẹ́ bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí wọ́n bá ṣe é lẹ́ẹ̀mejì lẹ́yìn tí wọ́n ti fi bá a ṣe ń ṣe é han akẹ́kọ̀ọ́ náà, tí ìdánilójú sì wà pé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà á máa bá a lọ.
Orin 2 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.