Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
ÀKÍYÈSÍ: Nígbà Àpéjọ Àgbègbè, ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ máa wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Kí ìjọ kọ̀ọ̀kan ṣe ìyípadà tó bá yẹ sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sẹ̀ tí wọ́n máa lọ sí Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Darí Wa.” Kẹ́ ẹ lo ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tẹ́ ẹ máa ṣe kẹ́yìn kẹ́ ẹ tó lọ sí àpéjọ náà láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìmọ̀ràn àti ìránnilétí tó kan ìjọ yín nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí. Lẹ́yìn oṣù kan tàbí méjì tẹ́ ẹ bá ti Àpéjọ Àgbègbè dé, kẹ́ ẹ fi ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ogún ìṣẹ́jú ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì táwọn ará gbọ́ ní Àpéjọ Àgbègbè náà tó sì ti wúlò fún wọn lóde ẹ̀rí. (Ẹ lè lo apá tá a ṣètò pé kẹ́ ẹ fi bójú tó àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.) Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Ní káwọn ará sọ bí wọ́n ṣe ń fi ohun tí wọ́n kọ́ ní àpéjọ náà sílò tàbí ọ̀nà tí wọ́n rò pé àwọn lè gbà lò ó lóde ẹ̀rí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 8
Orin 204
8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ní káwọn ará sọ àwọn àpilẹ̀kọ táwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín ti nífẹ̀ẹ́ sí nínú àwọn ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé. Ní kí wọ́n sọ àwọn ìbéèrè àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lò láti nasẹ̀ àwọn àpilẹ̀kọ náà. Ṣàṣefihàn báwọn ará ṣe lè fi ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan lọni lóde ẹ̀rí.
12 min: Ran Akẹ́kọ̀ọ́ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Di Olùkọ́. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ January 15, 2007, ojú ìwé 29 àti 30, ìpínrọ̀ 14 sí 20. Ṣàṣefihàn ṣókí kan tó dá lórí bí akéde kan ṣe ń ṣàlàyé bá a ṣe máa ń sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn àti bá a ṣe ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ fún ẹni tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó sì wá sọ fún un pé kó wá sáwọn ìpàdé náà.
25 min: “Àsìkò Aláyọ̀ Láti Jẹun Tó Dọ́ṣọ̀ Nípa Tẹ̀mí.”a Akọ̀wé ìjọ ni kó bójú tó o. Sọ déètì àti ibi tí ìjọ yín ti fẹ́ ṣe Àpéjọ Àgbègbè tọdún yìí. Jíròrò àpótí náà, “Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè.”
Orin 127
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 15
Orin 94
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù September sílẹ̀. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
20 min: Báwo La Ṣe Ṣe sí Lọ́dún Tó Kọjá? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn tàbí alàgbà tó tóótun máa bójú tó. Ṣàyẹ̀wò bí ìjọ ṣe ṣe sí lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, kó o sì tẹnu mọ́ ibi tí wọ́n ti ṣe dáadáa. Gbóríyìn fáwọn ará. Ṣètò pé kí akéde kan tàbí méjì, tó o ti sọ fún tẹ́lẹ̀, sọ àwọn ìrírí tó tayọ tí wọ́n ní lóde ẹ̀rí lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ parí. Mẹ́nu ba kókó kan tàbí méjì tí ìjọ ní láti ṣiṣẹ́ lé lórí lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó ń bọ̀ kó o sì jíròrò àwọn àbá mélòó kan tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe.
15 min: Bá A Ṣe Lè Fara Da Ẹ̀tanú Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa. Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí, kó gbé e ka àwọn ìsọfúnni tí ètò Ọlọ́run ti tẹ̀ jáde lórí bí ẹ̀tanú ṣe lè nípa lórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ṣàlàyé bá a ṣe lè borí irú àwọn ẹ̀tanú bẹ́ẹ̀. Nígbà míì, ìwà tá à ń hù lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti nínú àwọn ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́ lè ṣe iṣẹ́ tó pọ̀ láti borí ẹ̀tanú, tá á sì mú káwọn èèyàn yí èrò wọn pa dà pé àwọn fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ìwà wa ní gbogbo ìgbà. (1 Pét. 2:12; 3:1; 2) Sọ àwọn ìrírí mélòó kan tó ṣẹlẹ̀ láyìíká yín tàbí èyí tó o kà nínú àwọn ìwé tí ètò Ọlọ́run ṣe tó fi bá a ṣe lè borí ẹ̀tanú hàn.
Orin 51
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 22
Orin 104
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Jíròrò lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ tó wà lójú ìwé 1.
15 min: Èrè Wà fún Iṣẹ́ Yín. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ April 15, 2005 ojú ìwé 28, ìpínrọ̀ 5 sí ìpínrọ̀ tó gbẹ̀yìn lójú ìwé 29. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tó nítara, ní kí wọ́n ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe pèsè fún wọn nípa tara tàbí bó ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí ohun kan ń jẹ wọ́n lọ́kàn.
20 min: “Tẹ̀ Lé Àwọn Ìṣísẹ̀ Rẹ̀ Pẹ́kípẹ́kí.”b Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.
Orin 190
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní September 29
Orin 45
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn ìparí oṣù September sílẹ̀.
20 min: “Jẹ́ Olóòótọ́ Nípa Jíjẹ́ Akéde Tó Ń Ṣe Déédéé.”c Ka ìpínrọ̀ 3 àti 4.
20 min: “Ojú Táwa Kristẹni Fi Ń Wo Ṣíṣe Èrú Nígbà Ìdánwò.”d Tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 7, ní kí ẹni méjì tàbí mẹ́ta sọ bí wọ́n ṣe kọ̀ láti ṣèrú nígbà ìdánwò. Tẹnu mọ́ bí ẹ̀rí ọkàn rere tí wọ́n ní ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́.
Orin 2
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 6
Orin 15
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: Àpótí Ìbéèrè. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Fàwọn ìsọfúnni tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2005, ojú ìwé 20 sí 22, ìpínrọ̀ 10 sí 16 kún un.
20 min: “Kọ́ Àwọn Èèyàn Láti Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.”e Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.
Orin 132
[Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
d Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
e Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.