Àsìkò Aláyọ̀ Láti Jẹun Tó Dọ́ṣọ̀ Nípa Tẹ̀mí
1. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láwọn nǹkan tí wọ́n nílò nípa tẹ̀mí?
1 Jèhófà máa ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láwọn nǹkan tí wọ́n nílò nípa tẹ̀mí, torí pé ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Bí ebi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tiẹ̀ ń pa ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé, àjẹyó àti àjẹṣẹ́kù làwa ń jẹ. (Aísá. 65:13) Àpéjọ Àgbègbè tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bọ́ wa nípa tẹ̀mí. Ṣó o ti ń múra sílẹ̀ láti lọ sí Àpéjọ Àgbègbè “Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Darí Wa” tó ń bọ̀ lọ́nà yìí? Àsè tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ ló ń dúró dè wá níbẹ̀.
2. Kí làwọn ohun tó yẹ ká ṣe bá a ti ń múra sílẹ̀ fún Àpéjọ Àgbègbè?
2 Múra Sílẹ̀: “Àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní.” (Òwe 21:5) Torí náà, kí ètò tó o ti ṣe láti wà ní Àpéjọ Àgbègbè yìí lọ́jọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta má bàa forí ṣánpọ́n, tètè sọ fún ọ̀gá rẹ bó o bá máa gbàyè níbi iṣẹ́. Bó o bá sì máa nílò ibi tó o máa dé sí, má gbàgbé láti ṣètò ẹ̀ sílẹ̀. Ó tún máa dáa kó o ṣètò láti gbé oúnjẹ tó o máa jẹ lọ́sàn-án wá, kó o lè jẹ ẹ́ pẹ̀lú àwọn ará níbẹ̀. Kó o sì ṣètò láti tètè máa dé ṣáájú àkókò, kó o lè ti wá ibi tó o máa jókòó sí, kó o lè wà níbẹ̀ láti kọrin, kẹ́ ẹ sì lè jọ fàdúrà bẹ̀rẹ̀ ìpàdé náà lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan.
3. Irú aṣọ wo ló yẹ ká ṣètò láti wọ̀?
3 A fẹ́ rí i dájú pé àwọn aṣọ tá a máa wọ̀ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, wọ́n sì bójú mu. (1 Tím. 2:9, 10) A máa ń láǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti jẹ́rìí fáwọn èèyàn nígbà Àpéjọ Àgbègbè. Bá a bá múra lọ́nà tó buyì kúnni nínú ìlú tá a ti máa ṣe àpéjọ náà, tá a sì fi báàjì àpéjọ wa sáyà, a máa yàtọ̀ sáwọn aláìgbàgbọ́, a sì máa gbayì lójú àwọn èèyàn.
4. Kí ló máa jẹ́ káwa àtàwọn ọmọ wa jàǹfààní ìpàdé náà lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́?
4 Fetí Sílẹ̀ Dáadáa: Ó dájú pé a ò ní fẹ́ pàdánù apá èyíkéyìí lára oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀ tó máa wà níbi àsè tẹ̀mí yìí! (Òwe 22:17, 18) Tá a bá ń ṣí Bíbélì wa síbi tí wọ́n ń kà lórí pèpéle, tá a sì ń kọ àwọn kókó pàtàkì sílẹ̀, ìyẹn á jẹ́ ká lè máa fọkàn bá ìpàdé náà lọ. Èyí á sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti jíròrò àwọn kókó pàtàkì tá a ti kọ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́. A ti kíyè sí pé láwọn ọdún àìpẹ́ yìí ńṣe làwọn ọ̀dọ́ kan máa ń jókòó pa pọ̀ láwọn àpéjọ, tí wọ́n á sì máa sọ̀rọ̀ nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n máa fi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí tẹlifóònù alágbèéká wọn. Ó máa dáa káwọn ọmọ wa, títí kan àwọn tó ti bàlágà nínú wọn jókòó tì wá, ká sì jọ máa fọkàn bá ìpàdé náà lọ dípò ká jẹ́ kí wọ́n lọ jókòó ti àwọn ọ̀dọ́ ẹlẹ́gbẹ́ wọn.
5. Báwo la ṣe lè túbọ̀ gbádùn Àpéjọ Àgbègbè náà?
5 Gbádùn Ìfararora: Oúnjẹ àjọjẹ máa ń dùn yàtọ̀. (Òwe 15:17) Bẹ́ẹ̀ náà ni ìfararora pẹ̀lú àwọn ará máa ń jẹ́ ká túbọ̀ gbádùn àwọn Àpéjọ Àgbègbè wa. Ẹ ò rí i pó máa ṣe wá láǹfààní tó pọ̀, tá a bá lo ìdánúṣe láti kí àwọn ará, ká sì gbádùn ìfararora pẹ̀lú wọn láwọn àkókò ìsinmi, ṣáájú àti lẹ́yìn ìpàdé ọjọ́ kọ̀ọ̀kan! (Sm. 133:1) Bí alága bá ti ní ká lọ jókòó sáyè wa kí ohùn orin tó bẹ̀rẹ̀, a gbọ́dọ̀ dá ìjíròrò tá a bá ń ṣe dúró, ká sì lọ jókòó sáyè wa.
6. Sọ ìrírí kan tíwọ fúnra rẹ ní tó fi hàn pé a lè jẹ́rìí fáwọn èèyàn nílùú tá a ti lọ ṣe Àpéjọ Àgbègbè.
6 Máà Jáfara Láti Wàásù: A máa ń láǹfààní tó ṣàrà ọ̀tọ̀ láti jẹ́rìí nígbà Àpéjọ Àgbègbè. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó bá wà níbi táwọn ará bá ti lọ jẹun nígbà típàdé parí ló sábà máa ń bi wọ́n láwọn ìbéèrè tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹṣin ọ̀rọ̀ àpéjọ tí wọ́n rí nínú báàjì tó wà láyà wọn. Àwọn ará sì ti lo àwọn àǹfààní wọ̀nyí láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú wọn, wọ́n sì ti tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́rìí òtítọ́ fún wọn. Wọ́n ti lo àwọn àǹfààní wọ̀nyẹn láti pe àwọn kan wá sáwọn àpéjọ wa.
7. Kí nìdí tó fi yẹ ká lọ sí Àpéjọ Àgbègbè tó ń bọ̀ lọ́nà?
7 Ọ̀pọ̀ àkókò la ti lò láti ṣètò àwọn ibi tá a máa lò, àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ àtàwọn àsọyé tá a máa gbọ́ ní Àpéjọ Àgbègbè. Gbogbo iṣẹ́ tá a ti ṣe pẹ̀lú ìfẹ́ àwọn ará lọ́kàn láti múra sílẹ̀ fún àsè tẹ̀mí dídọ́ṣọ̀ yìí fi bí Jèhófà ṣe ń tọ́jú wa hàn. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa rí i dájú pé a wà níbẹ̀, ká sì jẹ oúnjẹ tẹ̀mí yìí yó bámúbámú! Bá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a máa láǹfààní táwọn èèyàn ò ní nínú ayé nítorí pé ńṣe la máa “fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà” wa.—Aísá. 65:14.
[Àpótí tó wà lójú ewé 4]
Àwọn Ohun Tó Yẹ Ká Fi Sọ́kàn Nípa Àpéjọ Àgbègbè
◼ Àkókò Ìpàdé: Aago mẹ́sàn-án kọjá ogún ìṣẹ́jú [9:20] àárọ̀ ni ìpàdé máa bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Gbàrà tí ohùn orin bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í dún ni kí gbogbo wa ti wà lórí ìjókòó kí ìpàdé náà lè bẹ̀rẹ̀ lọ́nà tó bójú mu. Aago márùn-ún ku ìṣẹ́jú márùn-ún [4:55] ìrọ̀lẹ́ ni ìpàdé máa parí lọ́jọ́ Friday àti Saturday, aago mẹ́rin [4:00] ìrọ̀lẹ́ ló sì máa parí lọ́jọ́ Sunday.
◼ Ibi Ìgbọ́kọ̀sí: Gbogbo Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa ló láwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí táwọn arákùnrin wa máa ń bójú tó. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn.—1 Kọ́r. 14:40.
◼ Àwọn Tó O Lè Gbàyè Sílẹ̀ Fún: Àwọn tẹ́ ẹ bá jọ wọkọ̀, tàbí tẹ́ ẹ jọ ń gbé nínú ilé kan náà nìkan lo lè gbàyè ìjókòó sílẹ̀ fún.
◼ Oúnjẹ Ọ̀sán: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbé oúnjẹ tẹ́ ẹ máa jẹ lọ́sàn-án wá dípò tẹ́ ẹ fi máa fi Gbọ̀ngàn Àpéjọ sílẹ̀ láti lọ wá oúnjẹ rà lákòókò ìsinmi ọ̀sán. Ẹ lè fi kúlà kékeré tó máa ṣeé gbé sábẹ́ ìjókòó gbé oúnjẹ wá. A kò fẹ́ kẹ́ ẹ gbé kúlà gbẹ̀ǹgbẹ̀-gbẹ̀ǹgbẹ̀ àtàwọn àwo tánńganran wá sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ, bẹ́ẹ̀ la ò sì fàyè gba ọtí líle.
◼ Fífowó Ṣètìlẹ́yìn: Owó kékeré kọ́ là ń ná láti ṣètò Àpéjọ Àgbègbè. A lè fi hàn pé a mọyì iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé tá a bá ń fífínnúfíndọ̀ ṣètìlẹ́yìn. A sì lè sọ owó tá a bá fẹ́ fi ṣètìlẹ́yìn sínú àpótí tó wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba wa tàbí láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Tẹ́ ẹ bá fẹ́ fi ìwé sọ̀wédowó ṣètìlẹ́yìn ní Àpéjọ Àgbègbè, “Watch Tower” ni kẹ́ ẹ kọ sórí ìwé sọ̀wédowó náà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n máa sanwó náà fún, kẹ́ ẹ sì rí i dájú pé ẹ kọ “Watch” àti “Tower” lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.
◼ Jàǹbá Àtàwọn Ọ̀ràn Pàjáwìrì: Bí ọ̀ràn pàjáwìrì tó jẹ mọ́ ìlera bá ṣẹlẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, ẹ jọ̀wọ́ fi tó ọ̀kan lára àwọn tó ń bójú tó èrò létí, òun ló sì máa ràn yín lọ́wọ́ láti mọ bí aláìlera náà ṣe máa dé Ẹ̀ka Ìtọ́jú Ojú Ẹsẹ̀ káwọn òṣìṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀ràn ìtọ́jú ojú ẹsẹ̀ ní àpéjọ wa lè wo bí ọ̀ràn náà ṣe le tó kí wọ́n sì ṣèrànlọ́wọ́ tó bá yẹ kí wọ́n ṣe.
◼ Ẹ Fẹ̀sọ̀ Wakọ̀: Ẹ jọ̀wọ́, ẹ wakọ̀ jẹ́jẹ́ kẹ́ ẹ sì tẹ̀ lé àwọn òfin ìrìnnà nígbà tẹ́ ẹ bá ń lọ sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti nígbà tẹ́ ẹ bá ń pa dà sílé. Ẹ̀mí jọ àwa Kristẹni lójú, ìdí sì nìyẹn tá a fi máa ń fìṣọ́ra ṣàwọn nǹkan ká má bàa fẹ̀mí ara wa wewu. (Sm. 36:9) Káwọn arákùnrin tó bá ṣètò ọkọ̀ rí i dájú pé àwọn ń tẹ̀ ẹ́ mọ́ awakọ̀ létí pé kò gbọ́dọ̀ sáré àsápajúdé, pé kó wakọ̀ jẹ́jẹ́, kó má sì fẹ̀mí àwọn ará sínú ewu.
◼ Gbígba Ohùn àti Àwòrán Sílẹ̀: A kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni so ẹ̀rọ èyíkéyìí mọ́ wáyà iná tàbí ti ẹ̀rọ tá à ń lò ní àpéjọ láti gba ohùn tàbí àwòrán sílẹ̀. A ò sì fẹ́ kẹ́ ẹ fi dí ẹnikẹ́ni lọ́wọ́.
◼ Yíya Fọ́tò: Bó o bá máa ya fọ́tò nígbà tí àpéjọ bá ń lọ lọ́wọ́, jọ̀wọ́ má ṣe lo iná tó ń bù yẹ̀rì. Kò ní bọ́gbọ́n mu fẹ́ni kẹ́ni láti jáde lọ ya fọ́tò nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ la ò gba àwọn tó ń ya fọ́tò tà láyè láti wá ṣòwò nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ, kódà bí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ Ẹlẹ́rìí.
◼ Fọ́ọ̀mù Padà-Lọ-Ṣèbẹ̀wò: Ẹ rí i dájú pé ẹ lo fọ́ọ̀mù tá a fi ń kọ ìsọfúnni nípa àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa, ìyẹn Please Follow Up (S-43), láti fi kọ ìsọfúnni nípa àwọn tẹ́ ẹ bá wàásù fún láìjẹ́-bí-àṣà nígbà Àpéjọ Àgbègbè. Káwọn akéde mú ẹ̀dà kan tàbí méjì fọ́ọ̀mù yìí wá sí Àpéjọ Àgbègbè. Tẹ́ ẹ bá ti Àpéjọ Àgbègbè dé, ẹ mú fọ́ọ̀mù tẹ́ ẹ bá ti kọ̀rọ̀ sí fún akọ̀wé ìjọ yín, kó lè ṣàwọn ètò tó bá yẹ nípa rẹ̀.
◼ Ilé Oúnjẹ Àtàwọn Tó Ń Tajà Lẹ́nu Ọ̀nà Gbọ̀ngàn Àpéjọ: Ó yẹ ká máa fìwà wa yin orúkọ Jèhófà lógo nígbà tá a bá wà ní ilé oúnjẹ. Kò ní bọ́gbọ́n mu láti lọ máa ra oúnjẹ tàbí ọjà èyíkéyìí nígbà típàdé bá ń lọ lọ́wọ́. Tẹ́ ẹ bá fẹ́ ra ohunkóhun, ohun tó máa dáa jù ni pé kẹ́ ẹ ti rà á kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀ tàbí kẹ́ ẹ dúró dìgbà típàdé bá parí.
◼ Àwòkẹ́kọ̀ọ́: Àwọn arábìnrin wa máa fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa bí wọn ò bá wé gèlè lọ́nà tó fi máa dí àwọn tó bá jókòó sẹ́yìn wọn lójú nígbà tí àwòkẹ́kọ̀ọ́ bá ń lọ lọ́wọ́ lọ́jọ́ Sunday. Èyí túbọ̀ ṣe pàtàkì láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó mọ níwọ̀n tá à ń lò báyìí títí kan àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó ṣeé lò bíi Gbọ̀ngàn Àpéjọ.—1 Kọ́r. 10:24.
◼ Ilé Gbígbé: Fi èso ti ẹ̀mí ṣèwà hù nígbà tí wọ́n bá ń fi ibi tó o máa dé sí nígbà àpéjọ hàn ẹ́. Má ṣe sùn sínú ilé tó wà ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ bí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé ò bá ní kó o dé síbẹ̀. Yàrá tí wọ́n bá sì fi ẹ́ sí ni kó o sùn, èyí á fi hàn pé o fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn. Kò ní bójú mu pé káwọn arákùnrin jẹ́ kílẹ̀ ṣú wọn sí yàrá àwọn arábìnrin tàbí kí wọ́n sùn síbẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà sì lọ̀rọ̀ rí pẹ̀lú àwọn arábìnrin wa. Ibi tí wọ́n bá ní ẹ ti lè dáná nìkan ni kẹ́ ẹ ti dáná. A ò ní fi hàn pé nǹkan tẹ̀mí jọ wá lójú tá a bá ń dáná nígbà tí ìpàdé bá ń lọ lọ́wọ́. (Lúùkù 10:38-42) Bóhun kóhun tó lè fa ìṣòro bá ṣẹlẹ̀ tàbí tó o bá níṣòro èyíkéyìí nínú yàrá tó o dé sí, rí i dájú pé o tètè fi tó Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ilé Gbígbé létí kí àpéjọ náà tó parí.
◼ Dída Ìdọ̀tí sí Ibi Tó Tọ́: Ó yẹ káwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ fi ọ̀rá omi, ìyẹn náílọ́ọ̀nù pure water, ti súìtì, bisikí àtàwọn nǹkan míì dá pàǹtí sílẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ, pàápàá níbi tí wọ́n bá jókòó sí. Èyí sì kan àwọn ibi tó yí Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà ká. Àwọn ohun ìkódọ̀tísí tó tóbi, tó sì pọ̀ tó máa wà láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ níbi tí gbogbo wa títí kan àwọn ọmọdé lè da ìdọ̀tí sí. Ó máa dáa ká kọ́ àwọn ọmọ láti kékeré pé ó ṣe pàtàkì pé kí àyíká wa máa wà ní mímọ́ tónítóní ní gbogbo ìgbà.