Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò lóṣù January 1 sí 18: Ẹ lè lo ìwé èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. Ìwé míì tẹ́ ẹ tún lè lò bí àfidípò ni ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. January 19 sí February 15: Pínpín ìwé Àṣàrò Kúkúrú Lákànṣe. February 16 sí 28: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà la máa lò. Ìwé míì tẹ́ ẹ tún lè lò bí àfidípò ni ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la máa lò. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ wa míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kì í ṣe déédéé nínú ìjọ, ẹ sapá láti fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ká sì ní in lọ́kàn láti fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wọn.
◼ Ní ọ̀sẹ̀ February 23, 2009, a máa bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’ ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Káwọn ìjọ rí i pé àwọn ní ẹ̀dà tó pọ̀ tó lọ́wọ́ lákòókò náà.
◼ Káwọn ìjọ ṣètò tó rọrùn láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún yìí lọ́jọ́ Thursday, April 9, lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀. Kí ìjọ kọ̀ọ̀kan gbìyànjú láti dá Ìrántí Ikú Kristi ṣe. Tó bá jẹ́ pé àwọn ìjọ mélòó kan ni wọ́n ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára wọn lè lọ gba ibòmíràn tí wọ́n máa lò lálẹ́ ọjọ́ yẹn. A dábàá pé níbi tó bá ti ṣeé ṣe, ó kéré tán kí ogójì [40] ìṣẹ́jú wà láàárín ìgbà tí ìjọ kan bá ṣe tán kí ìjọ kejì tó bẹ̀rẹ̀ tiwọn, kí gbogbo àwọn tó bá wá síbi Ìrántí Ikú Kristi lè ráyè kíra wọn.
◼ Láwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe tá a máa ṣe lọ́dún 2009, a máa ya àwọn ibì kan sọ́tọ̀ fáwọn adití láwọn àpéjọ tá a tò sísàlẹ̀ yìí. Ibi tá a bá sì yà sọ́tọ̀ fún wọn yìí la ti máa túmọ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí Èdè Àwọn Adití ní Ìlànà Ti Amẹ́ríkà:
Akábọ (EE-08) Jan. 3 sí 4 àti Apr. 19
Akábọ (EE-24) Feb. 7 sí 8 àti May 16
Àkúrẹ́ (WE-12) Feb. 7 sí 8 àti Aug. 9
Àwì (EE-21) Feb. 7 àti May 2 sí 3
Bàdágìrì (WE-02) Apr. 4 sí 5 àti July 19
Benin City (ME-01) Mar. 7 sí 8 àti June 6
Dálùwọ́n (WE-29) Mar. 14 sí 15 àti June 14
Ẹnúgu (EE-17) Jan. 3 sí 4 àti Apr. 4
Ìbàdàn (WE-10) Jan. 24 sí 25 àti Apr. 4
Igurúta Àlì (EE-22) Feb. 22 àti July 4 sí 5
Iléṣà (WE-15) Apr. 11 sí 12 àti July 4
Ìlọrin (WE-17) Apr. 11 àti Aug. 1 sí 2
Kàdúná (NE-1b) Mar. 7 sí 8 àti Aug. 8
Ọ̀tà (WE-25) Apr. 12
Ùbogò (ME-07) Feb. 14 àti June 6 sí 7
Uyó (EE-20) Apr. 5 àti July 18 sí 19