Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 3
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 3
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 1-3
No. 1: 2 Sámúẹ́lì 2:12-23
No. 2: Ǹjẹ́ Jésù Lo Orúkọ Ọlọ́run Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ̀?
No. 3: Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Pa Wá Lára? (td 24B)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Bí Onílé Bá Sọ Pé, ‘Ẹ Kò Gba Jésù Gbọ́.’ Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Kí nìdí táwọn kan ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa fi máa ń sọ bẹ́ẹ̀? Ìbéèrè wo la lè bi wọ́n tó máa jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn wọn? Èwo nínú àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ni wọ́n máa fẹ́ gbọ́? Àwọn kókó wo la lè fi dá wọn lóhùn ní orí 4 ìwé Bíbélì fi Kọ́ni? Gba àwọn ará níyànjú láti ka ìdí tá a fi ṣe ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ fún onílé, bó ṣe wà ní ojú ìwé 2 nínú Ilé Ìṣọ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Gbádùn Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Ìjẹ́rìí Àjẹ́pọ̀. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tó dá lórí ìwé A Ṣètò Wa, ojú ìwé 108, ìpínrọ̀ 1 sí 3. Ní kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sọ ètò tó wà fún ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá àti ibi táwọn ará ti máa pàdé. Ní káwọn ará sọ àwọn àǹfààní tí wọ́n ti rí látàrí bí wọ́n ṣe ń kọ́wọ́ ti ètò yìí àti bí wọ́n ṣe ń bá àwọn tí wọ́n jọ wà ní àwùjọ kan náà ṣiṣẹ́.