Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn, tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò, àmọ́ tí wọn kò tíì máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, ẹ fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Kẹ́ ẹ sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Bí onílé bá ti ní ìwé yìí, ẹ fún un ní ìwé èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́. July àti August: Ẹ lè lo èyíkéyìí lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó bá wà lọ́wọ́: Ẹmi Awọn Oku, Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye—Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? àti Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? Ẹ tún lè lo àwọn ìwé pẹlẹbẹ míì tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tí ìjọ bá ní lọ́wọ́.
◼ Ní àwọn ọ̀sẹ̀ àpéjọ àgbègbè, àyíká àti ti àkànṣe, kò ní sí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ, Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Torí náà, a rọ̀ yín láti ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ìpàdé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí fúnra yín, ẹ lè ṣe èyí nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín.
◼ Ẹṣin ọ̀rọ̀ àkànṣe àsọyé fún gbogbo ènìyàn ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2010 ni “Ìgbà Wo Ni Aráyé Máa Ní Ojúlówó Àlàáfíà Àti Ààbò?”